Ìsíkíẹ́lì
42 Lẹ́yìn náà, ó mú mi wá sí àgbàlá ìta ní apá àríwá.+ Ó mú mi wá sí ilé tó ní àwọn yàrá ìjẹun tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àyè fífẹ̀ náà,+ ó wà ní àríwá ilé tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.+ 2 Gígùn rẹ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́* láti ẹnu ọ̀nà àríwá, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́. 3 Ó wà láàárín àgbàlá inú tó jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́+ àti pèpéle àgbàlá ìta. Àwọn ọ̀dẹ̀dẹ̀ rẹ̀ dojú kọra, wọ́n sì ní àjà mẹ́ta. 4 Ọ̀nà kan gba iwájú àwọn yàrá ìjẹun* náà+ tí fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá tí gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́,* ẹnu ọ̀nà àwọn yàrá náà sì dojú kọ àríwá. 5 Àwọn yàrá ìjẹun tó wà lókè pátápátá kéré sí àwọn èyí tó wà ní àjà àárín àti ti ìsàlẹ̀, torí pé ọ̀dẹ̀dẹ̀ wọn ti gbà lára àyè wọn. 6 Àjà mẹ́ta ló ní, àmọ́ wọn ò ní òpó bí àwọn òpó tó wà ní àgbàlá. Ìdí nìyẹn tí wọn kò fi ní àyè púpọ̀ bíi ti àjà ìsàlẹ̀ àti ti àárín.
7 Ògiri olókùúta tó wà níta lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn yàrá ìjẹun ní apá àgbàlá ìta tó dojú kọ àwọn yàrá ìjẹun yòókù jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn. 8 Àwọn yàrá ìjẹun tó wà ní apá àgbàlá ìta jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, àmọ́ àwọn tó dojú kọ ibi mímọ́ jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn. 9 Ọ̀nà kan wà ní ìlà oòrùn tí wọ́n lè gbà wọ àwọn yàrá ìjẹun náà láti àgbàlá ìta.
10 Àwọn yàrá ìjẹun tún wà lẹ́gbẹ̀ẹ́* ògiri olókùúta tó wà ní àgbàlá ní apá ìlà oòrùn, nítòsí àyè fífẹ̀ àti ilé náà.+ 11 Ọ̀nà kan gba iwájú wọn bíi ti àwọn yàrá ìjẹun tó wà ní àríwá.+ Wọ́n gùn bákan náà, wọ́n sì fẹ̀ bákan náà, ọ̀nà tí wọ́n ń gbà jáde níbẹ̀ àti bí wọ́n ṣe kọ́ ọ rí bákan náà. Ẹnu ọ̀nà wọn 12 dà bí ẹnu ọ̀nà àwọn yàrá ìjẹun tó wà ní apá gúúsù. Ẹnu ọ̀nà kan wà níbi tí ojú ọ̀nà náà ti bẹ̀rẹ̀ tí èèyàn lè gbà wọlé, níwájú ògiri olókùúta tó wà ní apá ìlà oòrùn.+
13 Ó wá sọ fún mi pé: “Yàrá ìjẹun mímọ́ ni àwọn yàrá ìjẹun tó wà ní àríwá àti àwọn èyí tó wà ní gúúsù tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àyè fífẹ̀ yẹn,+ ibẹ̀ ni àwọn àlùfáà tí wọ́n ń wá síwájú Jèhófà ti máa ń jẹ àwọn ọrẹ mímọ́ jù lọ.+ Ibẹ̀ ni wọ́n ń gbé àwọn ọrẹ mímọ́ jù lọ sí àti ọrẹ ọkà, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi, torí pé ibi mímọ́ ni.+ 14 Tí àwọn àlùfáà bá wọlé, kí wọ́n má ṣe jáde kúrò ní ibi mímọ́ lọ sí àgbàlá ìta láìkọ́kọ́ bọ́ aṣọ tí wọ́n fi ṣiṣẹ́,+ torí aṣọ mímọ́ ni. Wọ́n á wọ aṣọ míì kí wọ́n tó sún mọ́ ibi tí àwọn èèyàn lè dé.”
15 Nígbà tó wọn àwọn ibi tó wà ní inú tẹ́ńpìlì* tán, ó mú mi jáde gba ẹnubodè tó dojú kọ ìlà oòrùn,+ ó sì wọn gbogbo ibẹ̀.
16 Ó fi ọ̀pá esùsú* náà wọn apá ìlà oòrùn. Nígbà tó fi ọ̀pá náà wọ̀n ọ́n, gígùn rẹ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọ̀pá esùsú láti ẹ̀gbẹ́ kan dé ìkejì.
17 Ó fi ọ̀pá esùsú náà wọn apá àríwá, gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọ̀pá esùsú.
18 Ó fi ọ̀pá esùsú náà wọn apá gúúsù, gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọ̀pá esùsú.
19 Ó lọ yí ká apá ìwọ̀ oòrùn. Ó fi ọ̀pá esùsú náà wọ̀n ọ́n, gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọ̀pá esùsú.
20 Ó wọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Ó ní ògiri yí ká,+ ògiri náà jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọ̀pá esùsú ní gígùn, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọ̀pá esùsú.+ Wọ́n fi ògiri náà pààlà sáàárín ohun tó jẹ́ mímọ́ àti ohun tó jẹ́ ti gbogbo èèyàn.+