Àwọn Ọba Kìíní
22 Ọdún mẹ́ta gbáko ni kò fi sí ogun láàárín Síríà àti Ísírẹ́lì. 2 Ní ọdún kẹta, Jèhóṣáfátì ọba+ Júdà lọ sọ́dọ̀ ọba Ísírẹ́lì.+ 3 Ìgbà náà ni ọba Ísírẹ́lì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé àwa la ni Ramoti-gílíádì?+ Síbẹ̀, à ń wò, a ò ṣe nǹkan kan láti gbà á lọ́wọ́ ọba Síríà.” 4 Ó wá sọ fún Jèhóṣáfátì pé: “Ṣé wàá tẹ̀ lé mi lọ jà ní Ramoti-gílíádì?” Jèhóṣáfátì dá ọba Ísírẹ́lì lóhùn pé: “Ìkan náà ni èmi àti ìwọ. Ìkan náà ni àwọn èèyàn mi àti àwọn èèyàn rẹ. Ìkan náà sì ni àwọn ẹṣin mi àti àwọn ẹṣin rẹ.”+
5 Àmọ́, Jèhóṣáfátì sọ fún ọba Ísírẹ́lì pé: “Jọ̀wọ́, kọ́kọ́ wádìí ọ̀rọ̀+ lọ́dọ̀ Jèhófà.”+ 6 Torí náà, ọba Ísírẹ́lì kó àwọn wòlíì jọ, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọkùnrin, ó sì bi wọ́n pé: “Ṣé kí n lọ bá Ramoti-gílíádì jà tàbí kí n má lọ?” Wọ́n dá a lóhùn pé: “Lọ, Jèhófà yóò sì fi í lé ọba lọ́wọ́.”
7 Jèhóṣáfátì wá sọ pé: “Ṣé kò sí wòlíì Jèhófà níbí ni? Ẹ jẹ́ ká tún wádìí lọ́dọ̀ rẹ̀.”+ 8 Ni ọba Ísírẹ́lì bá sọ fún Jèhóṣáfátì pé: “Ọkùnrin kan ṣì wà tí a lè ní kó bá wa wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà;+ ṣùgbọ́n mo kórìíra rẹ̀,+ nítorí kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi rí, àfi ibi.+ Mikáyà ni orúkọ rẹ̀, ọmọ Ímílà ni.” Síbẹ̀, Jèhóṣáfátì sọ pé: “Kí ọba má sọ bẹ́ẹ̀.”
9 Torí náà, ọba Ísírẹ́lì pe òṣìṣẹ́ ààfin kan, ó sì sọ fún un pé: “Lọ pe Mikáyà ọmọ Ímílà wá kíákíá.”+ 10 Lásìkò náà, ọba Ísírẹ́lì àti Jèhóṣáfátì ọba Júdà wà ní ìjókòó, kálukú lórí ìtẹ́ rẹ̀, wọ́n wọ ẹ̀wù oyè, wọ́n sì wà ní ibi ìpakà tó wà ní àtiwọ ẹnubodè Samáríà, gbogbo àwọn wòlíì sì ń sọ tẹ́lẹ̀ níwájú wọn.+ 11 Ìgbà náà ni Sedekáyà ọmọ Kénáánà ṣe àwọn ìwo irin fún ara rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ohun tí o máa fi kan* àwọn ará Síríà pa nìyí títí wàá fi pa wọ́n run.’” 12 Ohun kan náà ni gbogbo àwọn wòlíì tó kù ń sọ tẹ́lẹ̀, wọ́n ń sọ pé: “Lọ sí Ramoti-gílíádì, wàá ṣẹ́gun; Jèhófà yóò sì fi í lé ọba lọ́wọ́.”
13 Òjíṣẹ́ tó lọ pe Mikáyà sọ fún un pé: “Wò ó! Ohun rere ni àwọn wòlíì ń sọ fún ọba, ọ̀rọ̀ wọn kò ta kora. Jọ̀wọ́, má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ wọn, kí o sì sọ ohun rere.”+ 14 Ṣùgbọ́n Mikáyà sọ pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, ohun tí Jèhófà bá sọ fún mi ni màá sọ.” 15 Lẹ́yìn náà, ó wọlé sọ́dọ̀ ọba, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Mikáyà, ṣé ká lọ bá Ramoti-gílíádì jà àbí ká má lọ?” Lójú ẹsẹ̀, ó fèsì pé: “Lọ, wàá ṣẹ́gun; Jèhófà yóò sì fi í lé ọba lọ́wọ́.” 16 Ni ọba bá sọ fún un pé: “Ìgbà mélòó ni màá ní kí o búra pé òótọ́ lo máa sọ fún mi ní orúkọ Jèhófà?” 17 Nítorí náà, ó sọ pé: “Mo rí i tí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì tú ká lórí àwọn òkè,+ bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́. Jèhófà sọ pé: ‘Àwọn yìí kò ní ọ̀gá. Kí kálukú pa dà sí ilé rẹ̀ ní àlàáfíà.’”
18 Nígbà náà, ọba Ísírẹ́lì sọ fún Jèhóṣáfátì pé: “Ǹjẹ́ mi ò sọ fún ọ pé, ‘Kò ní sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi, àfi ibi’?”+
19 Mikáyà bá sọ pé: “Nítorí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà: Mo rí Jèhófà tó jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀,+ gbogbo ọmọ ogun ọ̀run sì dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, lápá ọ̀tún àti lápá òsì.+ 20 Jèhófà sì sọ pé, ‘Ta ló máa tan Áhábù, kí ó lè lọ kí ó sì kú ní Ramoti-gílíádì?’ Ẹni tibí ń sọ báyìí, ẹni tọ̀hún sì ń sọ nǹkan míì. 21 Ni ẹ̀mí* kan+ bá jáde wá, ó dúró níwájú Jèhófà, ó sì sọ pé, ‘Màá tàn án.’ Jèhófà béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, ‘Báwo lo ṣe máa ṣe é?’ 22 Ó dáhùn pé, ‘Màá jáde lọ, màá sì di ẹ̀mí tó ń tanni jẹ ní ẹnu gbogbo wòlíì rẹ̀.’+ Torí náà, ó sọ pé, ‘O máa tàn án, kódà, wàá ṣe àṣeyọrí. Lọ, kí o sì ṣe bẹ́ẹ̀.’ 23 Wò ó, Jèhófà ti fi ẹ̀mí tó ń tanni jẹ sí ẹnu gbogbo àwọn wòlíì rẹ yìí,+ àmọ́ àjálù ni Jèhófà sọ pé ó máa bá ọ.”+
24 Sedekáyà ọmọ Kénáánà wá sún mọ́ tòsí, ó sì gbá Mikáyà létí, ó sọ pé: “Ọ̀nà wo ni ẹ̀mí Jèhófà gbà kúrò lára mi tó fi wá bá ọ sọ̀rọ̀?”+ 25 Mikáyà dá a lóhùn pé: “Wò ó! Wàá rí ọ̀nà tó gbà lọ́jọ́ tí o máa lọ sá pa mọ́ sí yàrá inú lọ́hùn-ún.” 26 Ìgbà náà ni ọba Ísírẹ́lì sọ pé: “Mú Mikáyà, kí o sì fà á lé ọwọ́ Ámọ́nì olórí ìlú àti Jóáṣì ọmọ ọba. 27 Kí o sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí ọba sọ nìyí: “Ẹ fi ọ̀gbẹ́ni yìí sínú ẹ̀wọ̀n,+ kí ẹ sì máa fún un ní oúnjẹ díẹ̀ àti omi díẹ̀, títí màá fi dé ní àlàáfíà.”’” 28 Àmọ́ Mikáyà sọ pé: “Tí o bá pa dà ní àlàáfíà, á jẹ́ pé Jèhófà kò bá mi sọ̀rọ̀.”+ Ó tún sọ pé: “Ẹ fọkàn sí i o, gbogbo ẹ̀yin èèyàn.”
29 Ni ọba Ísírẹ́lì àti Jèhóṣáfátì ọba Júdà bá lọ sí Ramoti-gílíádì.+ 30 Ọba Ísírẹ́lì sì sọ fún Jèhóṣáfátì pé: “Màá para dà, màá sì lọ sójú ogun, ṣùgbọ́n ní tìrẹ, wọ ẹ̀wù oyè rẹ.” Torí náà, ọba Ísírẹ́lì para dà,+ ó sì bọ́ sójú ogun. 31 Ọba Síríà ti pàṣẹ fún àwọn méjìlélọ́gbọ̀n (32) tó jẹ́ olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ pé:+ “Ẹ má ṣe bá ẹnikẹ́ni jà, ì báà jẹ́ ẹni kékeré tàbí ẹni ńlá, àfi ọba Ísírẹ́lì.” 32 Gbàrà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rí Jèhóṣáfátì, wọ́n sọ lọ́kàn ara wọn pé: “Ó dájú pé ọba Ísírẹ́lì nìyí.” Nítorí náà, wọ́n yíjú sí i láti bá a jà; Jèhóṣáfátì sì bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé kí wọ́n ran òun lọ́wọ́. 33 Nígbà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rí i pé kì í ṣe ọba Ísírẹ́lì, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n pa dà lẹ́yìn rẹ̀.
34 Àmọ́, ọkùnrin kan ṣàdédé ta ọfà rẹ̀,* ó sì ba ọba Ísírẹ́lì láàárín ibi tí ẹ̀wù irin rẹ̀ ti so pọ̀. Torí náà, ọba sọ fún ẹni tó ń wa kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ pé: “Yí pa dà, kí o sì gbé mi jáde kúrò lójú ogun,* nítorí mo ti fara gbọgbẹ́ gan-an.”+ 35 Ìjà náà le gan-an jálẹ̀ ọjọ́ yẹn, kódà wọ́n ní láti gbé ọba nàró nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin bí wọ́n ṣe ń bá àwọn ará Síríà jà. Ẹ̀jẹ̀ ọgbẹ́ náà ń dà jáde sínú kẹ̀kẹ́ ogun náà, ó sì kú ní ìrọ̀lẹ́.+ 36 Nígbà tí oòrùn ń wọ̀, ìkéde kan wáyé káàkiri ibùdó pé: “Kí kálukú lọ sí ìlú rẹ̀! Kí kálukú sì lọ sí ilẹ̀ rẹ̀!”+ 37 Bí ọba ṣe kú nìyẹn, wọ́n gbé e wá sí Samáríà, wọ́n sì sin ín sí Samáríà. 38 Nígbà tí wọ́n fọ kẹ̀kẹ́ ogun náà létí adágún odò tó wà ní Samáríà, àwọn ajá lá ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, àwọn aṣẹ́wó sì wẹ̀ níbẹ̀,* gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ.+
39 Ní ti ìyókù ìtàn Áhábù àti gbogbo ohun tí ó ṣe àti ilé* tó fi eyín erin kọ́+ àti gbogbo ìlú tí ó kọ́, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn àwọn ọba Ísírẹ́lì? 40 Níkẹyìn, Áhábù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀;+ Ahasáyà+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
41 Jèhóṣáfátì+ ọmọ Ásà di ọba lórí Júdà ní ọdún kẹrin Áhábù ọba Ísírẹ́lì. 42 Ẹni ọdún márùndínlógójì (35) ni Jèhóṣáfátì nígbà tó jọba, ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Ásúbà ọmọ Ṣílíháì. 43 Ó ń rìn ní gbogbo ọ̀nà Ásà+ bàbá rẹ̀. Kò yà kúrò nínú rẹ̀, ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú Jèhófà.+ Àmọ́ kò mú àwọn ibi gíga kúrò, àwọn èèyàn náà ṣì ń rúbọ, wọ́n sì ń mú ẹbọ rú èéfín ní àwọn ibi gíga.+ 44 Jèhóṣáfátì ń ṣe ohun tí á jẹ́ kí àlàáfíà máa wà láàárín òun àti ọba Ísírẹ́lì.+ 45 Ní ti ìyókù ìtàn Jèhóṣáfátì àti àwọn nǹkan ńlá tó gbé ṣe àti bí ó ṣe jagun, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn àwọn ọba Júdà? 46 Ó tún lé ìyókù àwọn aṣẹ́wó ọkùnrin tó wà ní tẹ́ńpìlì+ jáde ní ilẹ̀ náà, ìyẹn àwọn tó ṣẹ́ kù nígbà ayé Ásà bàbá rẹ̀.+
47 Nígbà náà, kò sí ọba ní Édómù;+ ìjòyè kan ló wà nípò ọba.+
48 Jèhóṣáfátì tún ṣe àwọn ọkọ̀ òkun Táṣíṣì* láti máa fi kó wúrà+ wá láti Ófírì, ṣùgbọ́n wọn ò lè lọ torí pé àwọn ọkọ̀ òkun náà fọ́ ní Esioni-gébérì.+ 49 Ìgbà náà ni Ahasáyà ọmọ Áhábù sọ fún Jèhóṣáfátì pé: “Jẹ́ kì àwọn ìránṣẹ́ mi bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ lọ nínú àwọn ọkọ̀ òkun náà,” ṣùgbọ́n Jèhóṣáfátì kò gbà.
50 Níkẹyìn, Jèhóṣáfátì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀,+ wọ́n sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ sí Ìlú Dáfídì baba ńlá rẹ̀; Jèhórámù+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
51 Ahasáyà+ ọmọ Áhábù di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà lọ́dún kẹtàdínlógún Jèhóṣáfátì ọba Júdà, ó sì fi ọdún méjì ṣàkóso lórí Ísírẹ́lì. 52 Ó ń ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, ó sì ń rìn ní ọ̀nà bàbá rẹ̀+ àti ti ìyá rẹ̀+ àti ní ọ̀nà Jèróbóámù ọmọ Nébátì, ẹni tó mú kí Ísírẹ́lì dẹ́ṣẹ̀.+ 53 Ó ń sin Báálì+ nìṣó, ó ń forí balẹ̀ fún un, ó sì ń mú Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì+ bínú bí bàbá rẹ̀ ti ṣe.