ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kọ́ríńtì 12
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Kọ́ríńtì

      • Àwọn ìran tí Pọ́ọ̀lù rí (1-7a)

      • ‘Ẹ̀gún nínú ara’ Pọ́ọ̀lù (7b-10)

      • Àwọn àpọ́sítélì adára-má-kù-síbìkan ò sàn jù ú lọ (11-13)

      • Bí ọ̀rọ̀ àwọn ará Kọ́ríńtì ṣe jẹ Pọ́ọ̀lù lógún (14-21)

2 Kọ́ríńtì 12:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 2:17
  • +Iṣe 22:17, 18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    12/2018, ojú ìwé 8

2 Kọ́ríńtì 12:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    12/2018, ojú ìwé 8

    Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná, ojú ìwé 12

    Ilé Ìṣọ́,

    12/15/2004, ojú ìwé 30

    10/15/2004, ojú ìwé 8-10

    7/15/2000, ojú ìwé 27

2 Kọ́ríńtì 12:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    12/2018, ojú ìwé 8

    Ilé Ìṣọ́,

    7/15/2015, ojú ìwé 8-9

    7/15/2008, ojú ìwé 28

    10/15/2004, ojú ìwé 8-10

    6/15/1997, ojú ìwé 5

2 Kọ́ríńtì 12:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “máa lù mí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ga 4:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    11/2019, ojú ìwé 9

    Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́,

    5/2019, ojú ìwé 4

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/2014, ojú ìwé 5

    6/15/2008, ojú ìwé 3-4

    12/15/2006, ojú ìwé 24

    8/15/2006, ojú ìwé 21

    8/1/2005, ojú ìwé 21-22

    2/15/2002, ojú ìwé 13-14

    3/1/2000, ojú ìwé 4

    6/1/1997, ojú ìwé 25

    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba,

    5/1998, ojú ìwé 1

    Jí!,

    5/22/1997, ojú ìwé 18-19

2 Kọ́ríńtì 12:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    11/2019, ojú ìwé 9

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/2014, ojú ìwé 5

    1/1/2009, ojú ìwé 30

    12/15/2006, ojú ìwé 24

2 Kọ́ríńtì 12:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 40:29

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    7/2020, ojú ìwé 14-19

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    11/2019, ojú ìwé 9

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    1/2018, ojú ìwé 9

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2008, ojú ìwé 6

    12/15/2006, ojú ìwé 24

    8/1/2005, ojú ìwé 21-22

    2/15/2002, ojú ìwé 18-19

    3/1/2000, ojú ìwé 4

    6/1/1997, ojú ìwé 25

    Jí!,

    5/22/1997, ojú ìwé 18-19

2 Kọ́ríńtì 12:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Flp 4:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    7/2020, ojú ìwé 14-19

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    1/2018, ojú ìwé 9

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2010, ojú ìwé 18

    6/15/2008, ojú ìwé 3-4, 6

    9/15/2004, ojú ìwé 13-14

2 Kọ́ríńtì 12:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kọ 11:23

2 Kọ́ríńtì 12:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn àmì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kọ 6:4
  • +Iṣe 14:3; 15:12; Ro 15:18, 19

2 Kọ́ríńtì 12:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 9:11, 12; 2Kọ 11:9

2 Kọ́ríńtì 12:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 20:33
  • +1Kọ 4:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/1997, ojú ìwé 20

    10/1/1996, ojú ìwé 29

2 Kọ́ríńtì 12:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “fún ọkàn yín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kọ 1:6; Kol 1:24; 1Tẹ 2:8; Heb 13:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba,

    6/2007, ojú ìwé 1

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2000, ojú ìwé 21

    9/15/2000, ojú ìwé 22-23

2 Kọ́ríńtì 12:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kọ 11:9

2 Kọ́ríńtì 12:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kọ 8:6

2 Kọ́ríńtì 12:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “òfófó.”

2 Kọ́ríńtì 12:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

  • *

    Tàbí “ìwà ọ̀dájú.” Ní Gíríìkì, a·selʹgei·a. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2012, ojú ìwé 31

Àwọn míì

2 Kọ́r. 12:1Iṣe 2:17
2 Kọ́r. 12:1Iṣe 22:17, 18
2 Kọ́r. 12:7Ga 4:13
2 Kọ́r. 12:9Ais 40:29
2 Kọ́r. 12:10Flp 4:13
2 Kọ́r. 12:112Kọ 11:23
2 Kọ́r. 12:122Kọ 6:4
2 Kọ́r. 12:12Iṣe 14:3; 15:12; Ro 15:18, 19
2 Kọ́r. 12:131Kọ 9:11, 12; 2Kọ 11:9
2 Kọ́r. 12:14Iṣe 20:33
2 Kọ́r. 12:141Kọ 4:14
2 Kọ́r. 12:152Kọ 1:6; Kol 1:24; 1Tẹ 2:8; Heb 13:17
2 Kọ́r. 12:162Kọ 11:9
2 Kọ́r. 12:182Kọ 8:6
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Kọ́ríńtì 12:1-21

Ìwé Kejì sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì

12 Mo ní láti yangàn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò ṣàǹfààní, màá kọjá lọ sínú àwọn ìran tó ju ti ẹ̀dá lọ+ àti àwọn ìfihàn Olúwa.+ 2 Mo mọ ọkùnrin kan nínú Kristi, ẹni tí a gbà lọ sí ọ̀run kẹta lọ́dún mẹ́rìnlá (14) sẹ́yìn, bóyá nínú ara tàbí lóde ara, mi ò mọ̀, àmọ́ Ọlọ́run mọ̀. 3 Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀, bóyá nínú ara tàbí láìsí ara, mi ò mọ̀; àmọ́ Ọlọ́run mọ̀, 4 ẹni tí a gbà lọ sínú párádísè, tí ó gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ṣeé sọ, tí kò sì bófin mu fún èèyàn láti sọ. 5 Màá fi irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ yangàn, àmọ́ mi ò ní fi ara mi yangàn, àfi àwọn àìlera mi. 6 Ká tiẹ̀ ní mo fẹ́ yangàn, mi ò ní jẹ́ aláìnírònú, torí òtítọ́ ni màá sọ. Àmọ́ mi ò ṣe bẹ́ẹ̀, kí ẹnikẹ́ni má bàa gbóríyìn fún mi ju ohun tó rí tí mò ń ṣe tàbí ohun tó gbọ́ tí mò ń sọ, 7 lórí pé mo gba àwọn ìfihàn tó ṣàrà ọ̀tọ̀.

Kí n má bàa ro ara mi ju bó ṣe yẹ lọ, a fi ẹ̀gún kan sínú ara mi,+ áńgẹ́lì Sátánì, láti máa gbá mi ní àbàrá,* kí n má bàa ro ara mi ju bó ṣe yẹ lọ. 8 Ẹ̀ẹ̀mẹta ni mo bẹ Olúwa nípa èyí kó lè kúrò lára mi. 9 Àmọ́, ó sọ fún mi pé: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mi ti tó fún ọ, torí à ń sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.”+ Nítorí náà, ṣe ni màá kúkú máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, tí màá sì máa fi àìlera mi yangàn, kí agbára Kristi lè máa wà lórí mi bí àgọ́. 10 Torí náà, mò ń láyọ̀ nínú àìlera, nínú ìwọ̀sí, ní àkókò àìní, nínú inúnibíni àti ìṣòro, nítorí Kristi. Torí nígbà tí mo bá jẹ́ aláìlera, ìgbà náà ni mo di alágbára.+

11 Mo ti di aláìnírònú. Ẹ̀yin lẹ sì sọ mí di bẹ́ẹ̀, torí ó yẹ kí ẹ ti dámọ̀ràn mi. Nítorí kò sí ohun kankan tó fi hàn pé àwọn àpọ́sítélì yín adára-má-kù-síbìkan sàn jù mí lọ, ká tiẹ̀ ní mi ò já mọ́ nǹkan kan.+ 12 Ní tòótọ́, ẹ ti rí àwọn àmì tó fi hàn pé mo jẹ́ àpọ́sítélì nínú ọ̀pọ̀ ìfaradà,+ nínú àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu* àti àwọn iṣẹ́ agbára.+ 13 Nítorí ọ̀nà wo ni àǹfààní tí ẹ ní gbà kéré sí ti àwọn ìjọ yòókù, yàtọ̀ sí pé èmi fúnra mi ò sọ ara mi di ẹrù sí yín lọ́rùn?+ Ẹ dárí jì mí tinútinú lórí àìtọ́ yìí.

14 Ẹ wò ó! Ìgbà kẹta nìyí tí mo ti ṣe tán láti wá sọ́dọ̀ yín, mi ò sì ní sọ ara mi di ẹrù sí yín lọ́rùn. Nítorí ẹ̀yin fúnra yín ni mò ń wá, kì í ṣe àwọn ohun ìní yín;+ torí a kò retí pé kí àwọn ọmọ+ máa to nǹkan jọ fún àwọn òbí wọn, àwọn òbí ni kó máa ṣe bẹ́ẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn. 15 Ní tèmi, tayọ̀tayọ̀ ni màá ná gbogbo ohun tí mo ní, màá sì ná ara mi tán pátápátá fún yín.*+ Tó bá jẹ́ pé báyìí ni mo nífẹ̀ẹ́ yín tó, ṣé ó yẹ kí ìfẹ́ tí ẹ ní fún mi kéré sí tèmi? 16 Àmọ́ bó ti wù kó rí, mi ò sọ ara mi di ẹrù sí yín lọ́rùn.+ Síbẹ̀, ẹ̀ ń sọ pé, mo jẹ́ “ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́,” mo sì ń fi “ẹ̀tàn” mú yín. 17 Mi ò fi ìkankan nínú àwọn tí mo rán sí yín yàn yín jẹ, àbí mo ṣe bẹ́ẹ̀? 18 Mo rọ Títù pé kó wá sọ́dọ̀ yín, mo sì rán arákùnrin kan pẹ̀lú rẹ̀. Títù ò yàn yín jẹ rárá, àbí ó ṣe bẹ́ẹ̀?+ Irú ẹ̀mí kan náà la ní, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ipa ọ̀nà kan náà la sì ń rìn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

19 Ṣé ohun tí ẹ̀ ń rò látìgbà yìí wá ni pé à ń gbèjà ara wa níwájú yín? Iwájú Ọlọ́run la ti ń sọ̀rọ̀ ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi. Ẹ̀yin ẹni ọ̀wọ́n, ká lè gbé yín ró la fi ń ṣe gbogbo ohun tí à ń ṣe. 20 Ẹ̀rù ń bà mí pé tí mo bá dé, mo lè má bá yín bí mo ṣe fẹ́, mo sì lè má rí bí ẹ ṣe rò, dípò bẹ́ẹ̀, ó lè jẹ́ wàhálà, owú, ìbínú ńlá, awuyewuye, sísọ̀rọ̀ ẹni láìdáa, ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́,* ìgbéraga àti rúdurùdu ni màá bá nílẹ̀. 21 Ó sì tún lè jẹ́ pé tí mo bá dé, Ọlọ́run mi á dójú tì mí níwájú yín, kó sì di pé màá ṣọ̀fọ̀ lórí ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ti dẹ́ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ àmọ́ tí wọn ò ronú pìwà dà kúrò nínú ìwà àìmọ́ àti ìṣekúṣe* pẹ̀lú ìwà àìnítìjú* tí wọ́n hù.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́