ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g01 1/8 ojú ìwé 28
  • Òdòdó Tulip Ni Ò Jẹ́ Kébi Pa Wọ́n Kú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Òdòdó Tulip Ni Ò Jẹ́ Kébi Pa Wọ́n Kú
  • Jí!—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Tulip—Òdòdó tí Ó ti La Pákáǹleke Kọjá
    Jí!—1996
  • Kí Lẹni Tó Bá Sanra Jọ̀kọ̀tọ̀ Lè Rí Ṣe Sí I?
    Jí!—2004
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dín Bí Mo Ṣe Sanra Kù?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—2001
g01 1/8 ojú ìwé 28

Òdòdó Tulip Ni Ò Jẹ́ Kébi Pa Wọ́n Kú

LÁÀÁRÍN àwọn oṣù ẹ̀yìn Ogun Àgbáyé Kejì ní ilẹ̀ Yúróòpù, Ìjọba Násì fòfin de kíkó oúnjẹ gba ojú omi lọ sí àwọn ìlú ńláńlá tó wà ní ìwọ̀ oòrùn Netherlands. Àwọn àbájáde ìgbésẹ̀ yìí ba nǹkan jẹ́ gan-an ni, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó la àkókò ọ̀hún já ti lè jẹ́rìí sí i.

Bó ti sábà máa ń rí, ènìyàn kan nílò nǹkan bí ẹgbẹ̀jọ [1,600] sí ẹgbẹ̀rìnlá [2,800] èròjà afúnnilágbára lójúmọ́. Àmọ́, nígbà tó fi máa di April 1945, ìwọ̀nba nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] sí ẹgbẹ̀ta [600] èròjà afúnnilágbára tí àwọn kan lára àwọn tó ń gbé ní Amsterdam, Delft, The Hague, Leiden, Rotterdam, àti Utrecht ń rí jẹ lójúmọ́ lohun tó kù tó ń so ẹ̀mí wọn ró. Àwọn èèyàn gbà gbọ́ pé ó kéré tán, ẹgbàárùn-ún [10,000] àwọn aráàlú ni Ebi Ìgbà Òtútù ọdún 1944 àti 1945 lù pa, nítorí àìjẹunkánú.

Gẹ́gẹ́ bí obìnrin kan tó rù ú là tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Susan Monkman ti sọ, ńṣe ni àwọn ìdílé rẹ̀ fàbọ̀ sórí jíjẹ iṣu ìdí òdòdó tulip. Obìnrin yìí tún sọ pé: “Gbágun-gbàgun ni iṣu ìdí òdòdó tulip náà rí, kò sí béèyàn ṣe le fi omi gbígbóná bọ̀ ọ́ tó tó máa rọ̀. Àmọ́, pẹ̀lú ìdùnnú la fi rọra ń fọgbọ́n jẹ ẹ́ lẹ́nu. Ńṣe ló máa ń dá egbò sí wa lọ́fun fún ọjọ́ bí i mélòó kan.” Láti lè dín èyí kù, ńṣe la máa wá kárọ́ọ̀tì bí i mélòó kan tàbí ewéko sugar beet, bó bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó, tí a óò sì jẹ ẹ́ papọ̀ pẹ̀lú iṣu ìdí òdòdó tulip náà.

Ọgọ́rùn-ún gíráàmù iṣu ìdí òdòdó tulip ní èjìdínláàádọ́jọ [148] èròjà afúnnilágbára, gíráàmù mẹ́ta èròjà protein, èròjà ọ̀rá ìwọ̀n gíráàmù díẹ̀, àti gíráàmù méjìlélọ́gbọ̀n èròjà carbohydrate nínú. Nítorí náà, jíjẹ iṣu ìdí òdòdó tulip tí kò dùn yìí ni kò jẹ́ kí ebi pa ọ̀pọ̀ àwọn ará Netherlands kú.

Híhu ìwà ìkà tó lékenkà sí ọmọnìkejì ẹni, àpẹẹrẹ irú èyí tó ti wà nínú ọkàn àìmọye èèyàn lónìí tí kò sì ṣeé mú kúrò bọ̀rọ̀, fi bí ìran ènìyàn ṣe nílò ìlérí tí Bíbélì ṣe hàn ní kíákíá, èyí tó sọ pé: “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí [Ọlọ́run], nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.”—2 Pétérù 3:13.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 28]

Internationaal Bloembollen Centrum, Holland

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́