ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ws orí 18 ojú ìwé 144-151
  • Iduroṣinṣin sí Ètò-Àjọ Ọlọrun Ti A Lè Fojuri Lonii

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Iduroṣinṣin sí Ètò-Àjọ Ọlọrun Ti A Lè Fojuri Lonii
  • Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Iduroṣinṣin Nigba Akoko Ifisẹwọn
  • Ètò-Àjọ Ọlọrun ‘Olori Okunfa Ayọ̀’ Wọn
  • Ibukun Olugbẹsan Rẹ̀
  • Fifi Iduroṣinṣin Ranti Ètò-Àjọ Jehofa
    Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
  • “Babiloni” Alailaabo Ni A Ti Ṣedajọ Iparun Fún
    Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
  • Wà Láìséwu Gẹ́gẹ́ Bí Apá Kan Ètò Àjọ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ǹjẹ́ Ò Ń Bá Ètò Jèhófà Rìn Bó Ṣe Ń Tẹ̀ Síwájú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
ws orí 18 ojú ìwé 144-151

Ori 18

Iduroṣinṣin sí Ètò-Àjọ Ọlọrun Ti A Lè Fojuri Lonii

1, 2. Bawo ni o ṣe yẹ ki a loye ẹsẹ iwe mímọ́ naa ní Orin Dafidi 50:5?

NINU Orin Dafidi 16:10 a kọwe rẹ̀ pe: “Nitori iwọ ki yoo fi ọkan mi silẹ ní ipo oku [“ṣìọ́ọ̀lù,” NW]; bẹẹ ni iwọ ki yoo jẹ́ ki [aduroṣinṣin, NW] rẹ ki ó ri idibajẹ.” Bakan naa ninu Orin Dafidi 50:5 a kọ ọ pe: “Kó [awọn aduroṣinṣin, NW] mi jọ pọ̀ si ọdọ mi: awọn ti ó fi ẹbọ ba mi dá majẹmu.” Awọn wọnni ti wọn bá Jehofa dá majẹmu ha ni awọn ti wọn pese “ẹbọ” naa bi? Bẹẹkọ, awọn aduroṣinṣin wọnyi kò fi araawọn ṣe “ẹbọ” lẹnikọọkan, ni jíjọ̀wọ́ ẹran ara wọn ki wọn baa lè ṣe adehun pẹlu Ọlọrun.

2 Bawo ni a ṣe dá majẹmu naa, nigba naa? Lori “ẹbọ” “aduroṣinṣin” naa ti a kò fi ọkan rẹ̀ silẹ ninu ṣìọ́ọ̀lù ṣugbọn ti a ji dide kuro ninu oku. Aposteli Peteru lo awọn ọ̀rọ̀ inu Orin Dafidi 16:10 naa fun Jesu Kristi o si ń baa lọ lati sọ pe: “O [Dafidi] ri eyi tẹlẹ, o sọ ti ajinde Kristi pe, a ko fi ọkàn rẹ̀ silẹ ni ipo oku, bẹẹ ni ara rẹ̀ kò rí idibajẹ. Jesu naa yii ni Ọlọrun ti ji dide.”​—⁠Iṣe 2:​25, 27, 31, 32.

3. Awọn wo ni a kojọpọ ní ibamu pẹlu aṣẹ ti ó wà ninu Orin Dafidi 50:5, eeṣe ti a si gbọdọ sun wọn lati jẹ aduroṣinṣin si Ọlọrun?

3 Jesu ti a ti ji dide yii ni Alarina majẹmu titun naa, lori ipilẹ ẹbọ rẹ̀ ni a gbà fi majẹmu titun naa mulẹ. (Heberu 9:​15, 17) Nitori naa awọn wo ni a o kojọpọ ní ibamu pẹlu aṣẹ ti o wà ninu Orin Dafidi 50:5? Awọn ni awọn ọmọ-ẹhin Jesu ti wọn wà ninu majẹmu titun naa nititori irubọ rẹ̀. Lati inu imọriri fun Jehofa fun ẹbọ alailafiwe yii, a gbọdọ sun wọn lati fi ẹri jijẹ aduroṣinṣin si i hàn.

4, 5. (a) Aṣeyọri wo ni Satani Eṣu ní nigba ogun agbaye kìn-ín-ní ninu awọn isapa rẹ̀ lati pa ètò-àjọ Jehofa ti a lè fojuri run? (b) Nibo ni a ṣi orile-iṣẹ Society lọ, eesitiṣe? (c) Ní ibadọgba ode-oni pẹlu Orin Dafidi 137:1, ki ni ipo ẹdun ọkan, tabi iṣarasihuwa, àṣẹ́kù aduroṣinṣin naa jẹ́ nigba ti wọn ronu nipa ipo idalọwọkọ tí ètò-àjọ Ọlọrun wà?

4 Nigba ti a gbé Ijọba Jehofa kalẹ ní ọ̀run ní 1914, awọn orilẹ-ede binu fufu ní idoju ìjà kọ Ijọba yẹn nipa lilọwọ ninu ogun agbaye kìn-ínní, Ọlọrun si gba eyi laaye. (Orin Dafidi 2:​1, 2) Satani Eṣu gbiyanju lati lo ijakadi ayé yii lati pa apá ti ó ṣee fojuri ninu ètò-àjọ Jehofa run. O ṣaṣeyọri ní mimu ki a sọ aarẹ Watch Tower Bible and Tract Society sẹwọn ninu ọgba ẹwọn ti ijọba apapọ ní Atlanta, Georgia. Awọn aṣoju Society meje miiran ni a fi si ẹwọn pẹlu rẹ̀.

5 Nitori inunibini naa, orile-iṣẹ Society ní Brooklyn, New York, ni a ṣí lọ si ilé àyágbé kan ní Pittsburgh, Pennsylvania. A ṣe eyi lati mu ki títẹ iwe irohin Ilé-Ìṣọ́nà (Gẹẹsi) jade maa tẹsiwaju. Wọn ń reti iṣelogo ti ọ̀run ti awọn oluṣotitọ laipẹ si ìgbà yẹn. Ṣugbọn awọn àṣẹ́kù yẹn ni wọn fẹrẹẹ maa sọkun bi wọn ti ronu nipa ipo itẹmọlẹ, idalọwọkọ ti ètò-àjọ Jehofa wà.​—⁠Orin Dafidi 137:⁠1.

Iduroṣinṣin Nigba Akoko Ifisẹwọn

6-8. Nigba ifisẹwọn rẹ̀, bawo ni aarẹ Society, J. F. Rutherford, ṣe ṣafihan iduroṣinṣin si ètò-àjọ Jehofa?

6 Ni ṣiṣafihan iduroṣinṣin si ètò-àjọ Jehofa nigba akoko ifiṣẹwọn rẹ̀, aarẹ Watch Tower Society, J. F. Rutherford, ní December 25, 1918, kọ lẹta akanṣe kan si J. A. Bohnet, iranṣẹ Jehofa ẹlẹgbẹ rẹ̀ kan ti ó gbẹkẹle. A dari iwe naa si i ní ọfiisi Society ní Pittsburgh. Rutherford kọ awọn ọ̀rọ̀ ti ó tẹ̀lé e yii:

7 “Nitori pe mo kọ̀ lati fohunṣọkan pẹlu Babiloni, ṣugbọn ti mo fi pẹlu iṣotitọ gbiyanju lati ṣiṣẹsin Oluwa mi, mo wà lẹwọn, mo si dupẹ fun eyi. . . . Emi yoo fẹ itẹwọgba ati ẹrin musẹ Rẹ̀ ki ń si wà lẹwọn, ju ki n fohunṣọkan tabi gbọ ti Ẹranko naa ki n si wà lominira ki n si gba oriyin gbogbo ayé. Iriri onibukun, alarinrin kan ni lati jiya fun iṣẹ-isin iṣotitọ si Oluwa. Ninu Ijọba naa, awa yoo diyele ẹrin musẹ Baba ju ohun gbogbo miiran lọ. Eyi ni o gbọdọ wà ni ipo ti o ṣe pataki julọ ninu ọkan olukuluku ọmọ Ọlọrun. Awa ń fojusọna fun isopọṣọkan ti yoo sọ wa di Ọkan nibẹ. Mo layọ, sibẹ mo ń ṣaniyan lati ri gbogbo yin lẹẹkan sii. Apejọpọ ati ipade ọdọọdun sunmọ etile. Ki ẹmi Kristi kun ọkan-aya gbogbo awọn ti yoo wá . . .

8 “Pupọ ṣì wà sibẹ sii lati ṣe. Ojurere nlanla ni yoo jẹ́ lati nipin-in ninu rẹ̀. Kiki awọn wọnni ti wọn fẹran Rẹ̀ dé gongo ni wọn jẹ́ oluṣotitọ ti a o si tipa bẹẹ ṣe ojurere si. . . . Ijẹrii kikankikan ni a gbọdọ fifunni ṣaaju ọjọ alayọ yẹn. . . . Awọn ọna igbaṣe ati ohun-eelo atẹhinwa ki yoo lè kaju awọn ohun ti a ń beere, ṣugbọn Oluwa yoo pese ní ọna rere Rẹ̀. . . . Inu mi dun pe a pa iriri ọgba ẹwọn yii mọ́ dè wá kaka ti ìbá fi jẹ́ fun Arakunrin Russell. Kò si ìgbà kan ri ju isinsinyi lọ ti mo tii koriira aiṣododo delẹdelẹ ti mo si fẹ ododo ti mo si ń yánhànhàn lati ran awọn ẹlomiran lọwọ. . . . Iṣẹgun Sioni ti sunmọ etile.”

Ètò-Àjọ Ọlọrun ‘Olori Okunfa Ayọ̀’ Wọn

9. Iṣarasihuwa olorin wo ni awọn aṣoju Society ti a fi sẹwọn naa fihan?

9 Bi o tilẹ jẹ pe ninu ayé a fun awọn iranṣẹ Jehofa ni orukọ buburu bi alaiduroṣinṣin, ọ̀dàlẹ̀, ati alainifẹẹ ilu ẹni, wọn ko kọ ètò-àjọ Jehofa silẹ. Wọn kọ̀ lati fohunṣọkan labẹ ikimọlẹ yẹn. Wọn yàn lati padanu ìlò ọwọ́ ọtun wọn tabi yadi ju ki wọn gbagbe ètò-àjọ Ọlọrun ki wọn ma si ṣe jẹ́ ki o jẹ́ ‘olori okunfa ayọ̀’ wọn.​—⁠Orin Dafidi 137:​5, 6.

10, 11. (a) Ki ni ohun ti àṣẹ́kù aduroṣinṣin naa gbadura fun, awọn ọ̀rọ̀ olorin wo ni wọn da ohùn wọn pọ̀ mọ́ nipa Edomu? (b) Ki ni ó ti ṣeeṣe fun awọn ọta ètò-àjọ Jehofa ti a lè fojuri lati ṣe, ki si ni ohun ti iru awọn ọta bẹẹ kò ṣereti lae?

10 Awọn ọta Jehofa fi pẹlu arankan yọ̀ lori igbegbeesẹ lodisi awọn aṣoju ti ilẹ̀-ayé fun ètò-àjọ rẹ̀ kárí-ayé. Ṣugbọn awọn iranṣẹ Jehofa gbadura fun ọjọ ẹsan rẹ̀ lati dé nitori gbogbo awọn iwa iwọsi yii ti a kojọ gegere sori ètò-àjọ rẹ̀. Wọn da ohùn wọn pọ̀ mọ́ awọn ọ̀rọ̀ naa ti olorin naa sọ nipa Edomu igbaani pe: “Oluwa ranti ọjọ Jerusalemu lara awọn ọmọ Edomu, awọn ẹni ti ń wi pe, Wó o palẹ, wó o palẹ, de ipilẹ rẹ̀!” (Orin Dafidi 137:⁠7; Galatia 4:26) Áà, bẹẹkọ, Jehofa fẹran ètò-àjọ-bí-ìyàwó rẹ̀ lọna ṣiṣọwọn pupọ ju pe ki ó gbagbe ohun ti awọn ti ó jẹ́ apakan ètò-àjọ Eṣu sọ ti wọn si ṣe si awọn aduroṣinṣin ti inu ètò-àjọ rẹ̀ ori ilẹ̀-ayé.

11 Bi a bá fi gbogbo bi awọn nǹkan ṣe farahan lóde ní ìgbà naa wò ó, awọn agbọrandun oloṣelu ti Babiloni Nla wọnyẹn wó ètò-àjọ Jehofa ti a lè fojuri “palẹ, de ipilẹ rẹ̀” niti tootọ. Wọn kò reti lae lati ri i ki o gberi lati inu ekuru ki o si di ètò-àjọ kárí-ayé eyi ti ó wá dà lonii.

Ibukun Olugbẹsan Rẹ̀

12. (a) Ta ni fi ẹri hàn bi oludande awọn eniyan Jehofa ti a dì ní igbekun ní Babiloni igbaani, njẹ Orin Dafidi 137:​8, 9 ha tọkasi i ni ẹkunrẹrẹ itumọ bi? (b) Ki ni awọn ẹsẹ wọnyi sọtẹlẹ nipa olugbẹsan ètò-àjọ Ọlọrun ori ilẹ̀-ayé?

12 Jehofa lo alakooso ilẹ̀ Persia naa Kirusi lati dá awọn eniyan rẹ̀ nide kuro lọwọ Babiloni agbara ayé igbaani. Ṣugbọn ni ẹkunrẹrẹ itumọ naa, Kirusi kọ ni ẹni ti a ní lọkan ninu awọn ọ̀rọ̀ ipari Orin Dafidi 137, eyi ti ó tọkasi Babiloni Nla, ilẹ-ọba isin eke agbaye: “Iwọ, ọmọbinrin Babeli, ẹni ti a o parun; ibukun ni fun ẹni ti ó san an fun ọ bi iwọ ti hù si wa. Ibukun ni ẹni ti ó mú ti ó si fi ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ ṣán okuta.”​—⁠Orin Dafidi 137:​8, 9.

13, 14. Eeṣe ti ẹni “ibukun” naa ninu Orin Dafidi 137:​8, 9 kò fi le tọkasi awọn alaṣẹ oṣelu ti ó pa Babiloni Nla run?

13 Ta ni ẹni “ibukun” naa yoo jẹ? Ẹni “ibukun” naa ha duro fun “iwo mẹwaa” iṣapẹẹrẹ naa ti o wà lori “ẹranko ẹhanna” naa, ẹhin ẹni ti eto-igbekalẹ isin aṣẹwo ogbologboo naa ti gun pẹlu pọ̀pọ̀ṣìnṣìn ọ̀ṣọ́ aṣehan fun igba pipẹ sẹhin bi? Rara, nitori pe awọn oṣelu olupa ilẹ-ọba isin eke agbaye run kò pa a run lati ṣi ọna silẹ fun ijọsin mimọgaara ti Ọlọrun otitọ naa. Wọn kò ṣe e fun ogo Ọlọrun Bibeli. Bawo, nigba naa, ni awọn wọnyi ṣe lè jẹ́ ẹni “ibukun” ti olorin naa tọkasi niti gidi?

14 Awọn alaṣẹ oṣelu ayé yii kò ṣaṣeyọri iṣẹ ilodisi isin yii nitori ifẹ wọn fun awọn olujọsin Jehofa. Eeṣe ti kò fi ri bẹẹ? Idi ni pe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yoo dènà igbesẹ wọn lati sọ gbogbo ayé di alaini ọlọrun patapata. Nitori naa awọn alaṣẹ oṣelu wulẹ jẹ́ irinṣẹ ti Ọlọrun awọn Ẹlẹ́rìí naa lò lati mú ète rẹ̀ ṣẹ.​—⁠Ìfihàn 17:⁠17.

15. Ta ni o ń sun awọn alaṣẹ oṣelu ṣiṣẹ niti gidi, nipasẹ ta si ni?

15 Nipa bayii, bi o tilẹ jẹ pe awọn alaṣẹ oṣelu wọnyi ni a lè lò ní taarata fun pipa ilẹ-ọba isin eke agbaye rẹ́ raurau, Jehofa Ọlọrun gan-⁠an ni o ń sun wọn ṣe e. Bawo? Oun ń lo Ọmọkunrin rẹ̀ ọba ti a ti fun ní agbara, Kirusi Titobiju naa, Jesu Kristi. Nipa bayii, Jesu Kristi ninu agbara Ijọba ní ẹni “ibukun” naa ti olorin naa sọ tẹ́lẹ̀!

16. Bawo ni Jehofa ṣe pa “awọn ọmọ wẹ́wẹ́” Babiloni run?

16 Nigba ti ó jẹ́ pe Jehofa yoo daabobo awọn aduroṣinṣin rẹ̀, oun, ní ero iṣapẹẹrẹ kan, yoo gbá gbogbo olukuluku “awọn ọmọ wẹ́wẹ́” isin ti eto-igbekalẹ ẹ̀kọ́ eke ti ó dabi aṣẹwo mú yoo si fọ́ wọn mọ́ ohun ti ń rọdẹdẹ loke bi “okuta”​—⁠Ijọba alaiyẹhun ti Jehofa Ọlọrun nipasẹ Jesu Kristi.

17. (a) Ní ibamu pẹlu Isaiah 61:​1, 2, ki ni Jesu yoo polongo rẹ̀ lẹhin ti a ba ti fi ẹmi mímọ́ Ọlọrun yàn án? (b) Bawo ni a ṣe ń mu ipolongo naa ṣẹ lonii?

17 Nigba ti ó wà lori ilẹ̀-ayé, Jesu ni a fi ẹmi mímọ́ Alatilẹhin atọrunwa rẹ̀ yàn kii ṣe kiki “lati kede ọdun itẹwọgba Oluwa wa” nikan ni ṣugbọn lati polongo “ọjọ ẹsan Ọlọrun wa” pẹlu. (Isaiah 61:​1, 2; Luku 4:​16-⁠21) Ní akoko tiwa, nigba “ọjọ ikẹhin” eto-igbekalẹ awọn nǹkan isinsinyi, Jehofa ń mu ki awọn iranṣẹ rẹ̀ oluṣotitọ polongo “ọjọ ẹsan Ọlọrun wa” ní ibi gbogbo ti eniyan ń gbe gẹgẹ bi ikilọ si gbogbo awọn orilẹ-ede. Ninu ipolongo yii àṣẹ́kù naa ni “ogunlọgọ nla” awọn ọmọ-ẹhin Jesu Kristi ẹni bi agutan ti ń pọ̀ sii ti darapọ mọ́, gẹgẹ bi a ti riran ri i tẹ́lẹ̀ ninu Ìfihàn 7:​9-⁠17.

18. Ninu ayọ̀ wo ni awọn aduroṣinṣin ti Ọlọrun yoo ṣajọpin rẹ̀?

18 Gbogbo awọn wọnyi, àṣẹ́kù naa ati “ogunlọgọ nla,” ti ṣegbọran si aṣẹ angẹli naa ninu Ìfihàn 18:4. Wọn ti jade kuro ninu Babiloni Nla. Eeṣe ti iru igbesẹ bẹẹ fi jẹ́ kanjukanju? Nitori pe wọn gbọdọ sa kuro ninu Babiloni Nla ki a to fọ́ “awọn ọmọ wẹ́wẹ́” ti isin rẹ̀ si wẹ́wẹ́ ki a si sọ wọn dahoro nipasẹ “ẹranko ẹhanna” naa ati “iwo mẹwaa” rẹ̀ kete ṣaaju Armageddoni. Awọn aduroṣinṣin wọnyi yoo ṣajọpin ayọ̀ Kirusi Titobiju naa, Jesu Kristi. Wọn yoo darapọ mọ́ awọn ọ̀run ní wiwi pe: “Hallelujah; ti Oluwa Ọlọrun wa ni igbala, ati ọla agbara. Nitori otitọ ati ododo ní idajọ rẹ̀: nitori o ti ṣe idajọ agbere nla ni, ti ó fi agbere rẹ̀ ba ilẹ̀-ayé jẹ́.”​—⁠Ìfihàn 19:​1, 2; fiwe Jeremiah 51:​8-⁠11.

19. Ayọ̀ wo ni àṣẹ́kù aduroṣinṣin naa ń gbadun rẹ̀ nisinsinyi, ayọ̀ titobi ju wo ni o si ń duro dè wọn?

19 Lati 1919 Jehofa ti ṣe “ohun nla” fun awọn eniyan rẹ̀. (Orin Dafidi 126:​1-⁠3) Nitori imugbooro agbara idasilẹ lominira rẹ̀ yii, ti ó ń fihan pe oun ni “Ọlọrun oloootọ,” àṣẹ́kù naa ti a ti dasilẹ lominira ṣì ní idunnu ọkan-aya sibẹ. (Deuteronomi 7:9) Wọn ní ayọ̀ jijinlẹ, ṣugbọn ayọ̀ titobiju kan wa ti ó ń duro dè wọn. Eyi yoo jẹ́ nigba ti wọn yoo lè da araawọn pọ̀ mọ́ ayọ̀ ti Kirusi Titobiju, Ọba ti ń ṣakoso naa, Jesu Kristi, nigba ti ó bá fọ́ gbogbo “awọn ọmọ wẹ́wẹ́” ètò-àjọ elèṣù wọnyẹn si wẹ́wẹ́.

20. Awọn miiran wo ni wọn ń ṣajọpin ninu ayọ̀ àṣẹ́kù awọn ẹni-ami-ororo naa, eesitiṣe?

20 Araadọta ọkẹ “awọn igbekun” Babiloni Nla tẹ́lẹ̀ ni a ti ran lọwọ lati sa kuro ninu ètò-àjọ isin ti a ti ké egbe lé lori yẹn ṣaaju iparun gbigbonajanjan rẹ̀. Abajade naa ti jẹ́ “ogunlọgọ nla” ti “awọn agutan miiran.” Nisinsinyi iye wọn, kárí-ayé, ti ju 4,000,000 lọ, laisi aala si iye naa ti a ó ṣì gbà silẹ lọwọ ewu iparun ilẹ-ọba isin eke agbaye naa. Ninu iduroṣinṣin si ètò-àjọ Jehofa, wọn ń pin ninu ayọ̀ àṣẹ́kù naa ni didarapọ mọ́ wọn ni pipolongo ọjọ ẹsan Jehofa lori Babiloni Nla onisin.

21. Ki ni ó gbọdọ jẹ́ iṣarasihuwa wa si Babiloni Nla ati awọn igbekun rẹ̀?

21 Ki o maṣe si ifohunṣọkan kankan pẹlu ilẹ-ọba isin eke agbaye, nigba naa. Ki a maṣe pada sinu rẹ̀ rara ní awọn ọjọ ipadanu agbara rẹ̀ yii. Njẹ ki awa ki o lè maa tẹsiwaju lati maa ran awọn igbekun Babiloni Nla pupọ sii lọwọ bi o bá ti lè ṣeeṣe to lati jade kuro ninu eto-igbekalẹ ti a ti ké egbe le lori yẹn ṣaaju ki Kirusi Titobiju naa tó jere ijagunmolu alayọ rẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́