ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 8/1 ojú ìwé 31
  • Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Lákòókò Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì—Olùṣọ́ Àgùntàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Wọ́n Ń Fi Ìyọ́nú Ṣolùṣọ́ Àwọn Àgùtàn Kékeré Náà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • ‘Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ọkàn-àyà Mi’
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • Fifi Jẹlẹnkẹ Bojuto Awọn Agutan Ṣiṣeyebiye Ti Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 8/1 ojú ìwé 31

Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe

◼ Ki ni imọran pataki ti Owe 27:23 pese fun awọn oluṣọ agutan tẹmi ati bakan naa fun awọn Kristẹni ni gbogbogboo?

Ẹsẹ naa kà pe: “Iwọ maa ṣaniyan lati mọ iwa agbo ẹran rẹ, ki iwọ ki o si bojuto awọn ọ̀wọ́ ẹran rẹ.” (Owe 27:23) Ẹsẹ iwe yii ni a ti lo lọpọ igba lati fun awọn oluṣọ agutan tẹmi ni iṣiri lati fi ifẹ han ninu awọn Kristẹni ninu ijọ ati lati dojulumọ pẹlu ipo ati iṣoro wọn. Iru iṣiri bayii tọ́, niwọn bi Bibeli ti fi awọn alagba we awọn oluṣọ agutan ati ijọ we agbo agutan kan. (Iṣe 20:28, 29; 1 Peteru 5:2-4) Sibẹsibẹ, bi o tilẹ jẹ pe awọn ilana ti o wa loke yii ṣee fisilo, ẹsẹ yii niti gidi kii ṣe nipa awọn oluṣọ agutan tẹmi.

Iwe Owe ni ninu ọpọlọpọ ẹsẹ ti o dá duro gedegbe gẹgẹ bi awọn gbolohun imọran alaifi bọpobọyọ, ṣugbọn Owe 27:23 jẹ apakan ninu awujọ awọn ẹsẹ: “Iwọ maa ṣaniyan lati mọ iwa agbo ẹran rẹ, ki iwọ ki o si bojuto awọn ọ̀wọ́ ẹran rẹ. Nitori pe ọrọ̀ kii wà titilae: ade a ha sì maa wà dé irandiran? Koriko yọ, ati ọmunu koriko fi ara han, ati ewebẹ awọn oke kojọ pọ. Awọn ọdọ-agutan ni fun aṣọ rẹ, awọn obukọ si ni iye owo oko. Iwọ o si ni wara ewurẹ tó fun ounjẹ rẹ, fun ounjẹ awọn ara ile rẹ ati fun ounjẹ awọn iranṣẹbinrin rẹ.”—Owe 27:23-27.

Ayọ ti a misi yii gbe ọna igbesi-aye kan ga ti a sami si nipasẹ aapọn, iṣiṣẹ kára, iwọntunwọnsi, ati mimọyi gbigbarale Jehofa. O ṣe eyi nipa titẹnumọ igbesi-aye oniwọntunwọnsi ti oluṣọ agutan Isirẹli kan, boya ni iyatọ si igbesi-aye aláfẹfẹyẹ̀yẹ̀ ti a gbekari ibaṣepọ okòwò ati ọrọ̀ ojú ẹsẹ̀.

“Iṣura,” tabi ọrọ̀ ti a jere ninu idawọle okowo kiakia, pẹlu iyì (“ade”) ti o yọrisi le fi irọrun parẹ, gẹgẹ bi ọpọlọpọ ti le jẹrii sii. Ohun pupọ ni a le tipa bayii sọ ni itilẹhin fun igbesi-aye oniwọntunwọnsi, iru eyi ti awọn oluṣọ agutan igba atijọ ntẹle ni bibojuto agbo ẹran. Iru ọna igbesi-aye yẹn kii wulẹ ṣe oniwọntunwọnsi ni ero ti jijẹ alaibikita. Oluṣọ agutan kan nilati bojuto agbo ẹran rẹ̀ daradara, ni riri i daju pe awọn agutan naa ni a daabobo. (Saamu 23:4) Boya, ni fifun wọn ni afiyesi, oun ri agutan kan ti nṣaisan tabi ti o farapa, oun le da ororo atunilara le e lori. (Saamu 23:5; Esekiẹli 34:4; Sekaraya 11:16) Ninu awọn ọran ti o pọ julọ oluṣọ agutan alaapọn naa ti o nṣaniyan nipa agbo ẹran rẹ yoo ri pe awọn isapa oun mu eso jade—ibisi kẹrẹkẹrẹ ninu agbo ẹran rẹ.

Oluṣọ agutan oṣiṣẹ kára ti o si jẹ oluṣọra ni orisun iranwọ ti o ṣee gbarale—Jehofa. Bawo ni o ṣe jẹ bẹẹ? O dara, Ọlọrun npese awọn asiko ati iyipo ti o saba maa nyọri si koriko ti o to lati bọ́ agbo ẹran naa. (Saamu 145:16) Nigba ti awọn akoko ba yipada, ti papa tutu ko sì sí mọ ni pẹtẹlẹ, o le wà lọpọ yanturu ni awọn oke, nibiti oluṣọ agutan alafiyesi daradara kan le kó awọn ẹran rẹ lọ.

Owe 27:26, 27 mẹnuba ọkan ninu aṣeyọri iru iṣẹ alaapọn bẹẹ—ounjẹ ati aṣọ wiwọ. Ki a gbà bẹẹ, apejuwe naa kii ṣe ti awọn ounjẹ ajẹtẹrun aláfẹfẹyẹ̀yẹ̀ tabi akanṣe awọn ounjẹ dídọ́ṣọ̀, bẹẹ ni ko si fun oṣiṣẹ kan ni idi lati reti aṣọ wiwọ aláṣà ìgbàlódé tabi aṣọ ti o dara julọ. Ṣugbọn bi oun ba fẹ lati tẹ̀síwájú ninu isapa, oluṣọ agutan naa ati idile rẹ le mu lati inu agbo ẹran naa wàrà (ati wàràkàṣì nipa bayii), ati bakan naa òwú fun híhun aṣọ awọleke ninipọn.

Nitori naa imọran naa: “Iwọ maa ṣaniyan lati mọ iwa agbo ẹran rẹ” ni pataki kii ṣe fun awọn alaboojuto ode oni; o wà fun gbogbo awọn Kristẹni. O tẹnumọ iniyelori jijẹ onitẹlọrun pẹlu ohun agbeniro ati aṣọ ti a rí gba nipasẹ iṣẹ ti o ṣe deedee, alaapọn, ninigbẹkẹle pe Jehofa ki yoo ṣá wa tì. (Saamu 37:25; 2 Tẹsalonika 3:8, 12; Heberu 13:5) Ni fifi Owe 27:23-27 wera pẹlu imọran ti o wà ni Luuku 12:15-21 ati 1 Timoti 6:6-11, awa yoo ri bi imọran Ọlọrun ti ṣe deedee lori ọran yii. Nitori naa olukuluku wa le tun Owe 27:23-27 kà, ni bibeere lọwọ araawa, ‘Emi ha fi eyi sọkan ti mo si nfi i silo ninu igbesi-aye mi ojoojumọ bi?’

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́