ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 9/1 ojú ìwé 13-16
  • Máa Gbóríyìn Fáwọn Èèyàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Gbóríyìn Fáwọn Èèyàn
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìmọ̀ràn Tó Tuni Lára Tó Sì Fi Ọ̀wọ̀ Hàn
  • Bá A Ṣe Lè Máa Fi Ọgbọ́n Gbóríyìn Fúnni
  • Jésù Ò Lẹ́gbẹ́ Nínú Gbígbóríyìn Fáwọn Èèyàn
  • Àwọn Alàgbà Tó Ń Sọ̀rọ̀ Ìgbóríyìn Tó Yẹ
  • ‘Ọ̀rọ̀ Tó Bọ́ Sákòókò Mà Dára o!’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún—Nípa Gbígbóríyìn fún Wọn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Gbígbóríyìn Fúnni Ń Mára Tuni
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Gbóríyìn fún Àwọn Èèyàn?
    Jí!—2012
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 9/1 ojú ìwé 13-16

Máa Gbóríyìn Fáwọn Èèyàn

ǸJẸ́ o ti gbọ́ rí tí ẹnì kan ń ṣàròyé pé ọ̀gá òun níbi iṣẹ́ kì í fi bẹ́ẹ̀ yin òun? Àbí ìwọ alára tiẹ̀ ti ṣàròyé nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí? Tàbí kẹ̀ tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ́ ni ọ́, ǹjẹ́ o ti sọ ọ́ rí pé àwọn òbí rẹ tàbí àwọn olùkọ́ rẹ kì í gbóríyìn fún ọ?

Ó ṣeé ṣe kí díẹ̀ lára ohun táwọn èèyàn wọ̀nyí sọ jóòótọ́. Àmọ́ ọkùnrin ará Jámánì kan tó jẹ́ pé iṣẹ́ rẹ̀ ni kó máa rọ àwọn èèyàn láti ṣe ohun tí wọ́n mọ̀ pé ó tọ́, sọ ohun kan. Ó ní táwọn òṣìṣẹ́ bá ń ṣàròyé lọ́nà yìí, ohun tó ń dùn wọ́n kì í kúkú ṣe pé àwọn ọ̀gá wọn ò yìn wọ́n, àmọ́ pé àwọn ọ̀gá náà kò fi bẹ́ẹ̀ bìkítà nípa wọn. Èyí tó wù kó jẹ́, ó dájú pé ohun kan ń fẹ́ àtúnṣe nínú ọ̀ràn náà. Kí àjọṣe àárín àwa àtàwọn mìíràn tó lè dán mọ́rán, gbígbóríyìn fún wọn àti bíbìkítà nípa wọn ṣe pàtàkì gan-an.

Bákan náà lọ̀rọ̀ rí tá a bá ń sọ nípa ìjọsìn. Ó yẹ kí ẹ̀mí ìgbóríyìnfúnni, ẹ̀mí ìfẹ́, àti bíbìkítà nípa àwọn ẹlòmíràn hàn kedere nínú ìjọ Kristẹni. Ohun tó sì máa mú káwọn tó wà nínú ìjọ lè máa ṣe ohun tó dára yìí ni pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. Àmọ́ bó ti wù kí ìfẹ́ wà nínú ìjọ kan tó, a ṣì lè ṣe dáadáa sí i. Pẹ̀lú èyí lọ́kàn wa, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ẹni mẹ́ta kan yẹ̀ wò tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere tá a bá ń sọ nípa gbígbóríyìn fúnni. Àwọn ni: Élíhù, ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó gbé ayé ṣáájú àkókò àwọn Kristẹni, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, àti Jésù Kristi fúnra rẹ̀.

Ìmọ̀ràn Tó Tuni Lára Tó Sì Fi Ọ̀wọ̀ Hàn

Élíhù, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìbátan Ábúráhámù, ran Jóòbù lọ́wọ́ gan-an kí Jóòbù lè ní èrò tó tọ́ nípa àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Élíhù jẹ́ ẹni tó ń fọ̀rọ̀ rora rẹ̀ wò tó sì ní ọ̀wọ̀. Ó ní sùúrù títí dìgbà tó kàn án láti sọ̀rọ̀. Nígbà tó jẹ́ pé àṣìṣe Jóòbù nìkan làwọn tó pera wọn lọ́rẹ̀ẹ́ rẹ̀ rí, Élíhù yin Jóòbù pé ó gbé ìgbésí ayé tó múnú Ọlọ́run dùn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó tún fún Jóòbù nímọ̀ràn. Tìfẹ́tìfẹ́ ló fi ṣe é, ó sì hàn pé ó bìkítà nípa Jóòbù, ó ka Jóòbù sí ọ̀rẹ́ rẹ̀ nípa pípè é lórúkọ, èyí táwọn yòókù kò ṣe. Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ló fi sọ fún Jóòbù pé: “Jóòbù, jọ̀wọ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí o sì fi etí sí gbogbo ohun tí mo ń sọ.” Ó tún fi ara rẹ̀ sípò Jóòbù, ó ní: “Wò ó! Bí ìwọ ti jẹ́ sí Ọlọ́run tòótọ́ gẹ́lẹ́ ni èmi jẹ́; amọ̀ ni a fi mọ mí jáde, èmi pẹ̀lú.” Lẹ́yìn náà ló wá gbóríyìn fún Jóòbù nípa sísọ pé: “Bí ọ̀rọ̀ èyíkéyìí bá wà láti sọ, fún mi lésì; sọ̀rọ̀, nítorí tí èmi ní inú dídùn sí òdodo rẹ.”—Jóòbù 33:1, 6, 32.

Bíbá àwọn èèyàn lò tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ àti lọ́nà tí yóò mára tù wọ́n jẹ́ ọ̀nà kan tá a lè gbà sọ pé à ń gbóríyìn fún wọn. Ohun tí à ń tipa bẹ́ẹ̀ sọ fẹ́ni tí à ń bá sọ̀rọ̀ ni pé, ‘Mo kà ẹ́ sẹ́ni tó yẹ kí n fún láfiyèsí àtẹni tó yẹ kí n bọ̀wọ̀ fún.’ À ń tipa báyìí jẹ́ kẹ́ni náà mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ òun àti pé a bìkítà nípa rẹ̀.

Jíjẹ́ ẹni tó ń bọ̀wọ̀ fúnni ju pé ká kàn máa ṣe ohun tí gbogbo èèyàn gbà pé ó dára. Kí ọ̀rọ̀ ìgbóríyìn tá a bá sọ tó lè wọ àwọn èèyàn lọ́kàn, àyẹ́sí wa àti ọ̀wọ̀ tí à ń fi hàn sí wọn gbọ́dọ̀ wá látinú ọkàn wa. Ó gbọ́dọ̀ hàn pé a bìkítà nípa wọn lóòótọ́, a sì nífẹ̀ẹ́ wọn.

Bá A Ṣe Lè Máa Fi Ọgbọ́n Gbóríyìn Fúnni

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ipa tí ọgbọ́n inú ń kó nínú gbígbóríyìn fáwọn èèyàn hàn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó ń wàásù nílùú Áténì nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì, ó jẹ́ káwọn ọ̀mọ̀ràn kan tí wọ́n jẹ́ Gíríìkì mọ̀ pé ẹ̀sìn Kristẹni ló tọ̀nà. Kíyè sí bó ṣe fọgbọ́n inú bójú tó ipò tó ṣòro yìí. “Àwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Epikúréì àti àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí Sítọ́ìkì bẹ̀rẹ̀ sí bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà àríyànjiyàn, àwọn kan a sì sọ pé: ‘Kí ni ohun tí onírèégbè yìí ní í sọ?’ Àwọn mìíràn a sọ pé: ‘Ó dà bí pé ó jẹ́ akéde àwọn ọlọ́run àjúbàfún ti ilẹ̀ òkèèrè.’” (Ìṣe 17:18) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí Pọ́ọ̀lù, kò jẹ́ kínú bí òun, ó fèsì pé: “Ẹ̀yin ènìyàn Áténì, mo ṣàkíyèsí pé nínú ohun gbogbo, ó jọ pé ẹ kún fún ìbẹ̀rù àwọn ọlọ́run àjúbàfún ju àwọn mìíràn lọ.” Dípò kí Pọ́ọ̀lù máa sọ fún wọn pé òrìṣà tí wọ́n ń bọ kò dáa rárá, ńṣe ló gbóríyìn fún wọn pé ẹ̀sìn jẹ wọ́n lọ́kàn gan-an.—Ìṣe 17:22.

Ṣé alágàbàgebè ni Pọ́ọ̀lù ni? Rárá o. Ó mọ̀ pé kì í ṣe tóun láti máa dá àwọn tóun ń bá sọ̀rọ̀ lẹ́jọ́, bẹ́ẹ̀ ló sì mọ̀ pé ìgbà kan wà tóun náà kò mọ òtítọ́. Iṣẹ́ tí Jésù gbé fún un ni pé kó sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn, kì í ṣe pé kó máa dá wọn lẹ́jọ́. Látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sóun fúnra rẹ̀, ó mọ ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní ti wá mọ̀. Ohun náà ni pé, àwọn kan tó máa ń fi gbogbo ọkàn wọn ti ẹ̀sìn èké lẹ́yìn máa ń wá dẹni tó ń ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn gbágbáágbá nígbà tó bá yá.

Ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù gbà bójú tó ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣiṣẹ́ gan-an, ó sì sèso rere. “Àwọn ènìyàn kan dara pọ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì di onígbàgbọ́, lára wọn pẹ̀lú ni Díónísíù, adájọ́ kan ní kóòtù Áréópágù, àti obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dámárì, àti àwọn mìíràn ní àfikún sí wọn.” (Ìṣe 17:34) Ẹ ò rí i pé ó bọ́gbọ́n mu bí Pọ́ọ̀lù ṣe yin àwọn ará Áténì pé wọ́n jẹ́ ẹni tó gbà gbọ́ tinútinú dípò kó máa sọ̀rọ̀ sí wọn pé wọn ò ní ìmọ̀ tó péye, bó tilẹ̀ jẹ́ pé irọ́ lohun tí wọ́n gbà gbọ́! Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé àwọn tí wọ́n fi irọ́ ṣì lọ́nà máa ń ní ọkàn tó dára.

Nígbà tí wọ́n ní kí Pọ́ọ̀lù wá sọ tẹnu rẹ̀ níwájú Hẹ́rọ́dù Àgírípà Kejì, ó tún lo ọgbọ́n inú. Àwọn èèyàn mọ̀ pé Hẹ́rọ́dù ń bá Bernice tó jẹ́ àbúrò rẹ̀ ṣèṣekúṣe, ó sì hàn gbangba pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ta ko èyí. Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù kò sọ̀rọ̀ kankan tó fi hàn pé ó dá a lẹ́bi. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó wá ohun kan tó dára nípa Hẹ́rọ́dù tó fi lè gbóríyìn fún un. Ó ní: “Nípa gbogbo ohun tí àwọn Júù fẹ̀sùn rẹ̀ kàn mí, Ágírípà Ọba, mo ka ara mi sí aláyọ̀ pé iwájú rẹ ni èmi yóò ti gbèjà ara mi lónìí yìí, ní pàtàkì, níwọ̀n bí ìwọ ti jẹ́ ògbógi nínú gbogbo àṣà àti àríyànjiyàn láàárín àwọn Júù.”—Ìṣe 26:1-3.

Ẹ ò rí i pé ó bọ́gbọ́n mu táwa náà bá lè máa lo irú ọgbọ́n yìí nígbà tá a bá ń bá àwọn èèyàn lò! Gbígbóríyìn fún aládùúgbò wa, àwọn tá a jọ jẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́, tàbí ẹnì kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ lè mú kí àárín àwa àtàwọn gún régé, kí wọ́n sì máa hùwà tó dára. Gbígbóríyìn fáwọn èèyàn á jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn, èyí sì lè mú kó ṣeé ṣe fún wa nígbà míì láti ran àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè fi ìwà tó bá ìmọ̀ pípéye mu rọ́pò èrò tí kò tọ́ tí wọ́n ní nípa wa àti ìwà tí kò bójú mu tí wọ́n ń hù.

Jésù Ò Lẹ́gbẹ́ Nínú Gbígbóríyìn Fáwọn Èèyàn

Jésù gbóríyìn fáwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Jésù ti jíǹde tó sì padà sókè ọ̀run, ó lo àpọ́sítélì Jòhánù láti bá ìjọ méje tó wà ní Éṣíà Kékeré sọ̀rọ̀, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti darí rẹ̀. Ó rí i dájú pé òun gbóríyìn fáwọn tó ṣe dáadáa. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìjọ tó wà nílùú Éfésù, Págámù, àti Tíátírà, ó lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi: “Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ, àti òpò àti ìfaradà rẹ, àti pé ìwọ kò lè gba àwọn ènìyàn búburú mọ́ra”; “ìwọ ń bá a nìṣó ní dídi orúkọ mi mú ṣinṣin, ìwọ kò sì sẹ́ ìgbàgbọ́ rẹ nínú mi”; àti, “Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ, àti ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ìfaradà rẹ, àti pé àwọn iṣẹ́ rẹ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ pọ̀ ju àwọn ti ìṣáájú.” Kódà nílùú Sádísì, tí ìjọ tó wà níbẹ̀ nílò ìmọ̀ràn tó lágbára, Jésù kíyè sáwọn kan níbẹ̀ tí wọ́n yẹ fún ìgbóríyìn, ó ní: “Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìwọ ní àwọn orúkọ díẹ̀ ní Sádísì tí wọn kò sọ ẹ̀wù àwọ̀lékè wọn di ẹlẹ́gbin, dájúdájú, wọn yóò bá mi rìn nínú èyí tí ó funfun, nítorí wọ́n yẹ.” (Ìṣípayá 2:2, 13, 19; 3:4) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà ni Jésù fi lélẹ̀ yìí!

Ó yẹ ká máa fara wé Jésù. A ò gbọ́dọ̀ bẹnu àtẹ́ lu ọ̀pọ̀ èèyàn nítorí àṣìṣe táwọn èèyàn díẹ̀ ṣe. Bẹ́ẹ̀ la ò sì gbọ́dọ̀ bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lórí ohun tó yẹ kí wọ́n ṣiṣẹ́ lé lórí láìjẹ́ pé á tún sọ̀rọ̀ ìgbóríyìn tó tọ́ fún wọn. Àmọ́, ó dára ká máa rántí pé tó bá jẹ́ kìkì ìgbà tí à ń gbèrò láti fún àwọn èèyàn nímọ̀ràn nìkan là ń gbóríyìn fún wọn, wọ́n lè má ka ọ̀rọ̀ ìgbóríyìn wa sí. Rí i pé gbogbo ìgbà tó bá ti ṣeé ṣe ló máa ń gbóríyìn fáwọn èèyàn! Nípa báyìí, bó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n nílò ìmọ̀ràn nígbà mìíràn, wọ́n á yára tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn náà.

Àwọn Alàgbà Tó Ń Sọ̀rọ̀ Ìgbóríyìn Tó Yẹ

Arábìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Cornelia tó ń sìn báyìí ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Yúróòpù sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i ní nǹkan bí ọdún márùndínlógójì sẹ́yìn. Ó ní alábòójútó arìnrìn-àjò kan tó ń bẹ ìjọ àwọn wò béèrè lọ́wọ́ òun bóyá òun máa ń ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti bóyá òun máa ń ka àwọn ìwé ìròyìn wa. Ó ní: “Ojú tì mí díẹ̀.” Àmọ́, ó jẹ́wọ́ fún arákùnrin náà pé kì í ṣe gbogbo àpilẹ̀kọ tó ń jáde lóun máa ń kà. Ó ní: “Dípò kí arákùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ sí mi, ńṣe ló yìn mí pé mò ń ka àwọn tí mo lè kà. Ọ̀rọ̀ ìgbóríyìn rẹ̀ yẹn fún mi níṣìírí débi pé àtìgbà yẹn ni mo ti pinnu pé màá máa ka gbogbo àpilẹ̀kọ tó bá jáde.”

Arákùnrin Ray tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kan nílẹ̀ Yúróòpù náà rántí ọjọ́ àkọ́kọ́ rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Alága àwọn alábòójútó ìjọ rẹ̀, tó ní iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó ń ṣe àti ìdílé tó ń bójú tó, tó tún ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ nínú ìjọ, wọnú Gbọ̀ngàn Ìjọba nírọ̀lẹ́ ọjọ́ náà ó sì lọ sọ́dọ̀ Ray tààràtà, ó wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ o gbádùn ọjọ́ àkọ́kọ́ tó o lò lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà yìí?” Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́ta ọdún báyìí tí èyí ṣẹlẹ̀, àmọ́ Ray ṣì ń rántí bí alàgbà náà ṣe fi òun sọ́kàn.

Gẹ́gẹ́ báwọn ìrírí méjì wọ̀nyí ti fi hàn, tá a bá ń sọ̀rọ̀ ìmọrírì fáwọn èèyàn látọkànwá nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe, tá a sì ń sọ ọ́ tìfẹ́tìfẹ́, tí kì í ṣe pé à ń sọ ohun tá ò ronú nípa rẹ̀ tàbí ọ̀rọ̀ dídùn lásán, èyí lè mú kí wọ́n túbọ̀ máa ṣe dáadáa gan-an. Nínú ìjọ Kristẹni, a ní ọ̀pọ̀ ìdí tó fi yẹ ká máa gbóríyìn fáwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa. Ìwọ tiẹ̀ ronú ná nípa ìfẹ́ tí wọ́n ní tó mú kí wọ́n máa sin Jèhófà, àwọn ìdáhùn tí wọ́n ń múra rẹ̀ sílẹ̀ dáadáa, bí wọ́n ṣe dẹni tó borí ìbẹ̀rù àwùjọ kí wọ́n bàa lè máa sọ àwọn àsọyé tàbí kópa nínú àwọn apá mìíràn nínú ìpàdé, títí kan bí wọn ò ṣe fọwọ́ yẹpẹrẹ mú iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ kíkọ́ni, àti bí wọ́n ṣe ń sapá láti rí i pé ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti lílé nǹkan tẹ̀mí ló jẹ wọ́n lógún. Tá a bá ń gbóríyìn fáwọn mìíràn, àwa fúnra wa yóò rí ìbùkún tó pọ̀ gan-an. Á jẹ́ ká láyọ̀ á sì jẹ́ ká ní èrò tó dára nínú ọkàn wa.—Ìṣe 20:35.

Ó dára káwọn alàgbà nínú ìjọ máa yin àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin nítorí iṣẹ́ dáadáa tí wọ́n ń ṣe. Tó bá sì wá pọn dandan kí wọ́n fún wọn nímọ̀ràn, tìfẹ́tìfẹ́ ló yẹ kí wọ́n ṣe é. Wọn ò ní máa retí pé káwọn ará ṣe gbogbo nǹkan láìsí àléébù kankan débi pé tí wọ́n bá ṣe ohun kan tó kù díẹ̀ káàtó, àṣìṣe ńlá ni wọ́n á kà á sí.

Àwọn alàgbà tí wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Élíhù tó fi ọ̀wọ̀ àti ìfẹ́ hàn, tí wọ́n ń lo ọgbọ́n inú bíi ti Pọ́ọ̀lù nígbà tí wọ́n bá ń bá àwọn ará sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn bí Jésù ti ṣe, yóò jẹ́ ìṣírí gidi fáwọn arákùnrin wọn. Ọ̀rọ̀ ìgbóríyìn yóò jẹ́ káwọn mìíràn túbọ̀ ṣe dáadáa sí i, á sì jẹ́ kí àjọṣe àárín àwa pẹ̀lú wọn túbọ̀ dán mọ́rán kí ayọ̀ sì wà láàárín wa. Ó dájú pé nígbà ìrìbọmi Jésù, inú rẹ̀ dùn gan-an nígbà tó gbọ́ tí Baba rẹ̀ ọ̀run yìn ín pé: “Ìwọ ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́”! (Máàkù 1:11) Ẹ jẹ́ ká máa múnú àwọn arákùnrin wa dùn nípa gbígbóríyìn fún wọn tọkàntọkàn àti nípa sísọ̀rọ̀ tó máa gbé wọn ró fún wọn.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ọgbọ́n inú tí Pọ́ọ̀lù lò jẹ́ kó rí àwọn àbájáde tó dára, ó lè rí bẹ́ẹ̀ fáwa náà pẹ̀lú

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ọ̀rọ̀ ìgbóríyìn tá a sọ tìfẹ́tìfẹ́ tó sì wá látinú ọkàn wa lè jẹ́ káwọn mìíràn túbọ̀ ṣe dáadáa sí i

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́