Kọ́ Ọmọ Rẹ
Ǹjẹ́ Ó Máa Ń Ṣe Ẹ́ Bíi Pé Àjèjì Ni Ẹ́?
ÀJÈJÌ ni ẹni tí kì í ṣe ara àwọn èèyàn kan. Ó lè jẹ́ ẹni tí àwọ̀ rẹ̀ tàbí orílẹ̀-èdè rẹ̀ yàtọ̀ tàbí kí ọ̀nà tó ń gbà sọ̀rọ̀ tàbí ṣe nǹkan yàtọ̀. Ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé àjèjì ni ẹ́?—a
Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin kan tó ní irú èrò yìí pé òun jẹ́ àjèjì. Mefibóṣẹ́tì ni orúkọ rẹ̀. Jẹ́ ká wo irú èèyàn tó jẹ́ àti ìdí tó fi ní irú èrò yìí. Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé àjèjì ni ẹ́, o lè kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan lára Mefibóṣẹ́tì.
Mefibóṣẹ́tì jẹ́ ọmọ Jónátánì tó jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ fún Dáfídì. Ṣáájú kí Jónátánì tó kú lójú ogun, ó sọ fún Dáfídì pé: ‘Ṣe dáadáa sí àwọn ọmọ mi.’ Nígbà tí Dáfídì di ọba, ó rántí ọ̀rọ̀ Jónátánì ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà. Lákòókò yìí, Mefibóṣẹ́tì ṣì wà láàyè. Nígbà tí Mefibóṣẹ́tì wà lọ́mọdé, jàǹbá burúkú kan ṣẹlẹ̀ sí i. Ìyẹn kò sì jẹ́ kó lè rìn dáadáa mọ́. Ǹjẹ́ o rí ìdí tó fi rò pé àjèjì lòun?—
Dáfídì fẹ́ láti ṣe ọmọ Jónátánì lóore. Nítorí náà, Dáfídì ṣètò pé kí Mefibóṣẹ́tì ní ilé kan nítòsí ilé òun ní Jerúsálẹ́mù, Dáfídì tún fún un ní àyè kan níbi tábílì tí Dáfídì ti ń jẹun. Dáfídì sọ fún Síbà àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n máa ṣèránṣẹ́ fún Mefibóṣẹ́tì. Dáfídì dá ọmọ Jónátánì lọ́lá gan-an ni! Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?—
Ìjàngbọ̀n ṣẹlẹ̀ nílé Dáfídì. Ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin Dáfídì tó ń jẹ́ Ábúsálómù gbéjà ko Dáfídì, ó sì fẹ́ gba ìjọba. Dáfídì ní láti sá lọ kó má bàa kú. Nígbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń bá Dáfídì lọ, Mefibóṣẹ́tì náà fẹ́ bá a lọ. Àwọn ọ̀rẹ́ Dáfídì yìí mọ pé Dáfídì ló tọ́ láti jẹ́ ọba. Àmọ́ Mefibóṣẹ́tì kò lè lọ nítorí pé kò lè rìn dáadáa.
Síbà wá sọ fún Dáfídì pé, ìdí tí Mefibóṣẹ́tì fi dúrò sílé ni pé, ó fẹ́ láti di ọba. Dáfídì gba irọ́ tí Síbà pa fún un gbọ́! Nítorí náà, ó fún Síbà ní gbogbo ohun ìní Mefibóṣẹ́tì. Kò pẹ́ tí Dáfídì fi ṣẹ́gun Ábúsálómù, ó sì pa dà sí Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí Dáfídì délé, ó gbọ́ ohun tó fà á tí Mefibóṣẹ́tì kò fi bá òun lọ. Dáfídì ní kí Mefibóṣẹ́tì àti Síbà jọ pín ohun ìní náà. Kí lo rò pé Mefibóṣẹ́tì máa ṣe?—
Kò bínú kó wá sọ pé, ìpinnu tí Dáfídì ṣe kò dára. Mefibóṣẹ́tì mọ̀ pé ọba kò fẹ́ wàhálà kó bàa lè ṣèjọba rẹ̀ dáadáa. Nítorí náà, ó ní kí Síbà gba gbogbo ohun ìní náà. Ohun tó jẹ ìdùnnú Mefibóṣẹ́tì ni pé Dáfídì ìrànṣẹ́ Jèhófà ti pa dà sí Jerúsálẹ́mù láti máa jọba nìṣó.
Ìyà jẹ Mefibóṣẹ́tì gan-an. Ó sábà máa ń ṣe é bíi pé àjèjì ni òun. Àmọ́ Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì tọ́jú rẹ̀. Kí la rí kọ́ nínú ìtàn yìí?— Tí a bá ṣe ohun tó tọ́ pàápàá, àwọn kan lè purọ́ mọ́ wa. Jésù sọ pé: “Bí ayé bá kórìíra yín, ẹ mọ̀ pé ó ti kórìíra mi kí ó tó kórìíra yín.” Wọ́n tiẹ̀ pa Jésù pàápàá! Ó dá wa lójú pé tí a bá ṣe ohun tó tọ́, Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ yóò nífẹ̀ẹ́ wa, Ọmọ rẹ̀ Jésù yóò nífẹ̀ẹ́ wa pẹ̀lú.
Kà á nínú Bíbélì rẹ
2 Sámúẹ́lì 4:4; 9:1-10; 19:24-30
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó bá jẹ́ ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kí ọmọ náà sọ tinú rẹ̀.