Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
October 15, 2014
© 2014 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
DECEMBER 1-7, 2014
Ní Ìgbàgbọ́ Tó Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin Nínú Ìjọba Ọlọ́run
OJÚ ÌWÉ 7 • ORIN: 108, 129
DECEMBER 8-14, 2014
Ẹ̀yin Yóò Di “Ìjọba Àwọn Àlùfáà”
DECEMBER 15-21, 2014
Máa Ṣìkẹ́ Àǹfààní Tó O Ní Láti Jẹ́ Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Jèhófà!
OJÚ ÌWÉ 23 • ORIN: 120, 44
DECEMBER 22-28, 2014
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
▪ Ní Ìgbàgbọ́ Tó Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin Nínú Ìjọba Ọlọ́run
▪ Ẹ̀yin Yóò Di “Ìjọba Àwọn Àlùfáà”
Ìjọba Mèsáyà ni Jèhófà máa lò láti mú ohun tó ní lọ́kàn fún ayé àti aráyé ṣẹ. Bí a ó ti máa jíròrò ọ̀nà tí onírúurú májẹ̀mú tí Bíbélì sọ gbà tan mọ́ Ìjọba Ọlọ́run, mọ ìdí tó fi yẹ ká ní ìgbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú Ìjọba Ọlọ́run.
▪ Máa Ṣìkẹ́ Àǹfààní Tó O Ní Láti Jẹ́ Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Jèhófà!
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àpẹẹrẹ àwọn kan tó sin Jèhófà láyé àtijọ́ àti lóde òní. Èyí máa jẹ́ ká túbọ̀ mọyì àǹfààní tá a ní láti jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Àǹfààní ńlá tó yẹ ká máa ṣìkẹ́ sì ni èyí jẹ́.
▪ “Ẹ Máa Gbé Èrò Inú Yín Ka Àwọn Nǹkan Ti Òkè”
Àwọn ohun tó fẹ́ jin ìgbàgbọ́ wa lẹ́sẹ̀ pọ̀ gan-an láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Kí la lè kọ́ lára àwọn ọkùnrin olóòótọ́ ìgbàanì, bí Ábúráhámù àti Mósè táwọn náà dojú kọ àwọn ohun tó fẹ́ jin ìgbàgbọ́ wọn lẹ́sẹ̀? Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká lè máa gbé èrò inú wa ka Jèhófà Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀, èyí sì máa jẹ́ ká lè máa fara dà á.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
3 Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Taiwan
18 Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nígbèésí Ayé Mi Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run
ÀWÒRÁN IWÁJÚ ÌWÉ: Àwọn arábìnrin méjì wà ní ìtòsí òkè Mbololo ní gúúsù ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà, wọ́n ń wàásù fáwọn tó ń kọjá lọ lójú ọ̀nà tó lọ sí ìlú Tausa ní àgbègbè Taita
KẸ́ŃYÀ
IYE ÈÈYÀN
44,250,000
IYE AKÉDE
26,060
IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ
43,034
ÀWỌN TÓ WÁ SÍBI ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI LỌ́DÚN 2013
60,166