ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w14 10/15 ojú ìwé 3-6
  • Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Taiwan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Taiwan
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • WỌ́N RÍ I PÉ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ Ń FÚNNI LÁYỌ̀
  • OHUN TÍ WỌ́N ṢE NÍGBÀ TÍ WỌN KÒ TÈTÈ MỌ ÈDÈ TÍ WỌ́N Ń KỌ́
  • IṢẸ́ OÚNJẸ ÒÒJỌ́ WO NI WỌ́N Ń ṢE?
  • “GBÁDÙN IBI TÓ O TI BẸ̀RẸ̀”
  • IBI TÍ KÒ LÉWU, TÓ RỌRÙN LÁTI GBÉ TÓ SÌ LÁRINRIN
  • “WỌ́N TIẸ̀ TÚN LÈ NÍLÒ IRÚ ÈMI YÌÍ!”
  • Pípolongo Ìhìn Rere Láwọn Oko Ìrẹsì ní Taiwan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Ìsẹ̀lẹ̀!
    Jí!—2000
  • A Ń Bá A Nìṣó Láti Wàásù Òtítọ́ Bíbélì ní Ireland
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
w14 10/15 ojú ìwé 3-6

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Taiwan

NǸKAN bí ọdún márùn-ún sẹ́yìn ni Choong Keon àti Julie ìyàwó rẹ̀ tí wọ́n ti tó nǹkan bí ẹni ọdún márùndínlógójì [35], ti ń sìn bí aṣáájú-ọ̀nà déédéé ní ìlú Sydney lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Choong Keon sọ pé: “Iṣẹ́ àbọ̀ṣẹ́ là ń ṣe, a sì ń gbé ìgbé ayé ìrọ̀rùn. Ojú ọjọ́ dára gan-an níbi tá à ń gbé, kì í tutù jù tàbí kó gbóná jù, a sì ń gbádùn ara wa. A ò jìnnà sáwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn mọ̀lẹ́bí wa.” Síbẹ̀, ẹ̀rí ọkàn Choong Keon àti Julie ń dà wọ́n láàmù. Kí nìdìí? Wọ́n mọ̀ pé àwọn láǹfààní láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ Jèhófà, àmọ́ wọ́n ń lọ́ra láti ṣe àwọn ìyípadà tí ó yẹ.

Ní àpéjọ àgbègbè ọdún 2009, wọ́n gbọ́ àsọyé kan tó wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an, tó sì mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ohun tí wọ́n fẹ́ fi ìgbésí ayé wọn ṣe. Ẹni tó sọ àsọyé náà darí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àwọn tí wọ́n lè mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i. Ó sọ pé: “Wo àpèjúwe yìí ná: Kí awakọ̀ kan tó lè darí ọkọ̀ sọ́tùn-ún tàbí sósì, ọkọ̀ náà gbọ́dọ̀ wà lórí ìrìn. Bákan náà, Jésù lè fi ẹ̀mí Ọlọ́run darí wa láti mọ bí a ṣe lè mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbòòrò sí i, àmọ́, ìyẹn á jẹ́ lẹ́yìn tá a bá ti sapá gidigidi kí ọwọ́ wa lè tẹ àfojúsùn náà.”a Ńṣe ló rí lára àwọn tọkọtaya náà bíi pé àwọn gan-an ni ẹni tó ń sọ àsọyé náà ń bá wí. Ní àpéjọ àgbègbè yẹn kan náà, wọ́n fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu tọkọtaya míṣọ́nnárì kan tí wọ́n ń sìn lórílẹ̀-èdè Taiwan. Tọkọtaya náà sọ bí wọ́n ṣe ń gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn àti pé àìní ṣì wà lórílẹ̀-èdè náà. Ọ̀rọ̀ yìí tún wọ Choong Keon àti Julie lára gan-an, àfi bíi pé àwọn méjèèjì ni wọ́n ń bá wí.

Julie sọ pé: “Lẹ́yìn àpéjọ àgbègbè yẹn, a gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè ní ìgboyà láti kó lọ sí orílẹ̀-èdè Taiwan. Àmọ́, ẹ̀rù ń bà wá, ó ń ṣe wá bíi pé a fẹ́ ṣàdédé kán lu odò kan tó jìn.” Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó jẹ́ kí wọ́n lè ṣe ìpinnu tó tọ́ ni ìwé Oníwàásù 11:4, tó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣọ́ ẹ̀fúùfù kì yóò fún irúgbìn; ẹni tí ó bá sì ń wo àwọsánmà kì yóò kárúgbìn.” Arákùnrin Choong Keon sọ pé: “A pinnu pé a ò ní dúró ká máa ṣọ́ nǹkan kan mọ́, àmọ́ a fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ‘fún irúgbìn’ ká sì máa ‘kárúgbìn.’” Wọ́n gbàdúrà nípa rẹ̀ léraléra, wọ́n ka ìtàn àwọn míṣọ́nnárì, wọ́n fi ọ̀pọ̀ lẹ́tà orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ránṣẹ́ sáwọn tó ti kó lọ sí orílẹ̀-èdè Taiwan, àwọn tó wà lọ́hùn-ún náà sì fi ọ̀pọ̀ ìsọfúnni ránṣẹ́ sí wọn nípa bí ipò nǹkan ti rí níbẹ̀. Tọkọtaya yìí ta ọkọ̀ wọn, àga àti tábìlì àtàwọn ohun èlò ilé míì. Oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà ni wọ́n kó lọ sí Taiwan.

WỌ́N RÍ I PÉ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ Ń FÚNNI LÁYỌ̀

Àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n ju ọgọ́rùn-ún [100] lọ, tí wọ́n wá láti ilẹ̀ òkèèrè, ni wọ́n ń sìn báyìí láwọn àgbègbè tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i lórílẹ̀-èdè Taiwan. Ọjọ́ orí àwọn tó ń sìn lórílẹ̀-èdè yìí bẹ̀rẹ̀ látorí ọdún mọ́kànlélógún [21] sí mẹ́tàléláàádọ́rin [73], wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, irú bí Amẹ́ríkà, Faransé, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Japan, Kánádà, Korea, Ọsirélíà àti Sípéènì. Àwọn arábìnrin tí kò tíì lọ́kọ ju àádọ́ta [50] lọ láàárín wọn. Kí ló mú kí àwọn arákùnrin àti arábìnrin yìí máa fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù ní ilẹ̀ òkèèrè? Jẹ́ ká gbọ́ ohun tí díẹ̀ lára wọ́n sọ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Laura

Arábìnrin kan tí kò tíì lọ́kọ tó wá láti orílẹ̀-èdè Kánádà, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Laura ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní ìwọ̀-oòrùn Taiwan. Kó tó di pé ó lọ sí àgbègbè yìí, kò fẹ́ràn iṣẹ́ ìwàásù rárá. Laura sọ pé: “Mi ò kì í gbádùn iṣẹ́ ìwàásù, torí pé mi ò kì í lo àkókò tí ó pọ̀ tó lóde ẹ̀rí débi tí màá fi já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.” Àmọ́, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan lórílẹ̀-èdè Kánádà sọ fún un pé kó jẹ́ káwọn jọ lọ sí orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò káwọn lọ wàásù níbẹ̀ fún oṣù kan. Laura sọ pé: “Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí màá lo àkókò tó pọ̀ lóde ẹ̀rí, ó yà mí lẹ́nu pé iṣẹ́ ìwàásù lárinrin tó bẹ́ẹ̀!”

Ìrírí tí Laura ní yìí dùn mọ́ ọn nínú gan-an, èyí ló mú kó pinnu láti kó lọ sí ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè lórílẹ̀-èdè Kánádà. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè Ṣáínà, ó sì ń dara pọ̀ mọ́ àwùjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Ṣáínà. Ó fi ṣe àfojúsùn rẹ̀ láti kó lọ sí orílẹ̀-èdè Taiwan, ó sì kó lọ síbẹ̀ ní oṣù September ọdún 2008. Laura sọ pé: “Ó tó nǹkan bí ọdún kan kí ara mi tó mọlé níbẹ̀, àmọ́ ní báyìí mi ò tiẹ̀ ronú láti pa dà sí Kánádà mọ́ torí ibí yìí ti di ilé mi.” Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe rí lára rẹ̀ báyìí? Laura sọ pé: “Mò ń gbádùn rẹ̀ gan-an báyìí. Kò sí nǹkan tó ń fúnni láyọ̀ tó kéèyàn rí bí àwọn téèyàn ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ń yí ìgbésí ayé wọn pa dà torí pé wọ́n ti wá mọ Jèhófà. Iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tí mò ń ṣe ní orílẹ̀-èdè Taiwan ti jẹ́ kí n ní irú ayọ̀ yìí.”

OHUN TÍ WỌ́N ṢE NÍGBÀ TÍ WỌN KÒ TÈTÈ MỌ ÈDÈ TÍ WỌ́N Ń KỌ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Brian àti Michelle

Nǹkan bí ẹni ọdún márùndínlógójì [35] ni tọkọtaya kan tí orúkọ wọn ń jẹ́ Brian àti Michelle, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n ń gbé, àmọ́ wọ́n kó lọ sí orílẹ̀-èdè Taiwan ní nǹkan bí ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn. Ó kọ́kọ́ ń ṣe wọ́n bíi pé wọn ò ṣe tó bó ṣe yẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Arákùnrin kan tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì sọ fún wọn pé: “Kódà, ì báà tiẹ̀ jẹ́ ìwé àsàrò kúkúrú lẹ fún ẹnì kan, ẹ máa rántí pé ó lè jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí ẹni náà máa gbọ́ nípa Jèhófà nìyẹn. Nǹkan ńlá nìyẹn sì jẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù!” Ọ̀rọ̀ tí arákùnrin yìí sọ fún Brian àti Michelle níṣìírí. Arákùnrin míì sọ fún wọn pé: “Tí ẹ kò bá fẹ́ kó sú yín bẹ́ ẹ ṣe ń kọ́ èdè Ṣáínà, bí òye ohun tẹ́ ẹ̀ ń gbọ́ ní àpéjọ kọ̀ọ̀kan bá ṣe ń yé yín sí ni kẹ́ ẹ fi máa díwọ̀n ibi tẹ́ ẹ ti tẹ̀ síwájú dé kì í ṣe ohun tí ẹ ń mọ̀ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.” Tọkọtaya yìí tẹ̀ síwájú lóòótọ́, wọ́n sì ń ṣe dáadáa lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà títí dòní.

Kí ló máa mú kó wù ẹ́ láti kọ́ èdè ilẹ̀ òkèèrè? Gbìyànjú láti lọ wo bí orílẹ̀-èdè tó wù ẹ́ láti lọ sìn ṣe rí. Lọ sí ìpàdé wọn, mọ àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wà ní àgbègbè náà, kó o sì bá wọn lọ sí òde ẹ̀rí. Brian sọ pé: “Tó o bá ti rí i pé ọ̀pọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere tí ẹ̀ ń wàásù fún wọn, tó o sì rí i bí àwọn arákùnrin àti arábìnrin ṣe yọ̀ mọ́ ẹ, orí rẹ á wú, wàá sì múra tán láti lọ sìn ní ilẹ̀ òkèèrè láìka ìṣòro tó lè wà níbẹ̀ sí.”

IṢẸ́ OÚNJẸ ÒÒJỌ́ WO NI WỌ́N Ń ṢE?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Kristin àti Michelle

Iṣẹ́ olùkọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì ni ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó ń sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i lórílẹ̀-èdè Taiwan ń ṣe. Ẹja àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n ń pa nínú òkun ni Arákùnrin Kristin àti Michelle ìyàwó rẹ̀ ń tà. Kristin sọ pé: “Mi ò ṣe irú iṣẹ́ yìí rí, àmọ́ ohun tí mò ń tà yìí ló jẹ́ kí n ṣì lè wà lórílẹ̀-èdè yìí.” Nígbà tó yá, Kristin bẹ̀rẹ̀ sí í ní àwọn oníbàárà tó ń bá a rajà déédéé. Iṣẹ́ àbọ̀ṣẹ́ yìí ló fi ń gbọ́ bùkátà òun àti ìyàwó rẹ̀, wọ́n sì ní àkókò tó pọ̀ tó láti ṣe iṣẹ́ tó gbé wọn wá síbẹ̀, ìyẹn iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tó jẹ́ iṣẹ́ pípẹja ènìyàn.

“GBÁDÙN IBI TÓ O TI BẸ̀RẸ̀”

Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni Arákùnrin William àti Jennifer ìyàwó rẹ̀ ti wá, nǹkan bí ọdún méje sẹ́yìn ni wọ́n kó wá sí orílẹ̀-èdè Taiwan. William sọ pé: “Kò rọrùn rárá kéèyàn máa kọ́ èdè tuntun, kó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, kó máa bójú tó ìjọ, kó sì tún máa gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀, ó máa ń tánni lókun nígbà míì.” Àmọ́, báwo ni wọ́n ṣe ṣe é tí ọ̀kan kò fi pa èkejì lára, tí wọ́n sì ń láyọ̀? Wọn kò jẹ́ kí àfojúsùn wọn pọ̀ jù. Bí àpẹẹrẹ, wọn kò ṣe ju ara wọn lọ nígbà tí wọ́n ń kọ́ èdè Ṣáínà, kódà nígbà tí wọn ò tètè mọ èdè náà, wọn ò ba ọkàn jẹ́ jù.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

William àti Jennifer

William rántí pé alábòójútó arìnrìn-àjò kan sọ fún òun pé, Gbádùn ibi tó o ti bẹ̀rẹ̀, kó o sì tún gbádùn ibi tí wàá parí ẹ̀ sí.” Ìyẹn ni pé lẹ́yìn téèyàn bá ti ní àfojúsùn tẹ̀mí, ó yẹ kínú èèyàn máa dùn sí gbogbo ohun tó ń ṣe kí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ àfojúsùn náà. William sọ pé bí òun àti ìyàwó òun ṣe tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí ti mú kí àwọn lè ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan, wọ́n ń tẹ́tí sí ìmọ̀ràn àwọn arákùnrin tó wà ní àgbègbè ibi tí wọ́n wà, wọ́n ṣe àyípadà nínú bí wọ́n ṣe ń ṣe nǹkan kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn ní orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kó lọ láṣeyọrí. William sọ pé, “Ó tún jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ohun rírẹwà tó wà lágbègbè náà.”

Bíi ti Arákùnrin William àti Jennifer ìyàwó rẹ̀, arábìnrin kan tí kò tíì lọ́kọ tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Megan tóun náà wá láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Ó ń sapá kí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ àfojúsùn rẹ̀, ìyẹn láti mọ èdè Ṣáínà sọ dáadáa. Ohun tó máa ń ṣe ni pé, ní gbogbo òpin ọ̀sẹ̀ ó máa ń tẹ̀ lé àwùjọ àwọn akéde kan lọ wàásù láwọn ìpínlẹ̀ tó yàtọ̀ tó sì rẹwà. Wọ́n máa ń lọ sí etíkun ìlú Kaohsiung, ìyẹn etíkun tó tóbi jù ní orílẹ̀-èdè Taiwan. Arábìnrin Megan tún máa ń wàásù láti inú ọkọ̀ ojú-omi kan dé ọkọ̀ ojú-omi mìíràn, ó sì máa ń wàásù fún àwọn apẹja tó wá láti orílẹ̀-èdè Bangladesh, Íńdíà, Indonesia, Philippines, Thailand, àti Vanuatu. Arábìnrin Megan sọ pé: “A máa ń bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, torí pé àkókò kúkúrú ni àwọn apẹja yẹn máa ń lò ní etíkun. Mo sábà máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹni mẹ́rin tàbí márùn-ún pa pọ̀ kí n lè kárí gbogbo wọn.” Arábìnrin Megan sọ bí ó ṣe ń tẹ̀ síwájú sí nínú èdè Ṣáínà tó ń kọ́, ó ní: “Ṣe ló ń ṣe mi bíi pé kí n ti mọ̀ ọ́n sọ dáadáa, àmọ́ mo máa ń rántí ọ̀rọ̀ tí arákùnrin kan sọ fún mi pé, ‘Ṣe gbogbo ohun tí o bá lè ṣe, Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ, wàá sì ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ.’”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Megan

IBI TÍ KÒ LÉWU, TÓ RỌRÙN LÁTI GBÉ TÓ SÌ LÁRINRIN

Kí Arábìnrin Cathy, tó wá láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó kó lọ sí orílẹ̀-èdè míì, ó ṣèwádìí kó lè mọ ibi tí kò léwu fún arábìnrin tí kò tíì lọ́kọ. Ó gbàdúrà sí Jèhófà nípa rẹ̀, ó sì kọ̀wé sí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì mélòó kan kó lè mọ ewu tàbí ìṣòro tí arábìnrin tí kò tíì lọ́kọ lè ní nílẹ̀ òkèèrè. Lẹ́yìn èyí, ó fara balẹ̀ wo gbogbo èsì tí wọ́n kọ ránṣẹ́ pa dà sí i, ó sì wò ó pé orílẹ̀-èdè Taiwan tẹ́ òun lọ́rùn.

Nígbà tó di ọdún 2004, Arábìnrin Cathy kó lọ sí orílẹ̀-èdè Taiwan, ọmọ ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n [31] ni nígbà yẹn. Ó sì jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ òun lọ́rùn. Ó sọ pé: “Mo ní kí àwọn ará júwe ibi tí mo ti lè máa ra èso àti ewébẹ̀ lówó pọ́ọ́kú fún mi. Ìmọ̀ràn gidi tí wọ́n fún mi jẹ́ kí n lè máa ṣọ́ owó ná.” Kí ló mú kí ìwọ̀nba ohun díẹ̀ tẹ́ Arábìnrin Cathy lọ́rùn? Ó sọ pé: “Mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́, kí oúnjẹ tí mò ń jẹ àti aṣọ tí mo ní tẹ́ mi lọ́rùn. Jèhófà dáhùn àdúrà mi torí ó jẹ́ kí n lè ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ìwọ̀nba ohun tí mo ní, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ohun tó wù mí ni mo ní. Inú mi dùn pé mi o ṣe ju ara mi lọ, èyí sì jẹ́ kí n lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tẹ̀mí.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Cathy

Yàtọ̀ sí pé ìwọ̀nba ohun díẹ̀ tẹ́ Arábìnrin Cathy lọ́rùn, ìgbé ayé rẹ̀ tún lárinrin. Ó sọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀, ó ní: “Mò ń wàásù ní àgbègbè tí àwọn èèyàn ti nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere. Èyí máa ń mú inú mi dùn gan-an!” Nígbà tó dé orílẹ̀-èdè Taiwan, ìjọ méjì tí wọ́n ń fi èdè Ṣáínà ṣèpàdé ló wà ní ìlú tó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, àmọ́ ìjọ méje ló wà níbẹ̀ báyìí. Arábìnrin Cathy sọ pé: “Ojoojúmọ́ ni inú mi máa ń dùn pé irú ìtẹ̀síwájú yìí ṣojú mi àti pé mo nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìkórè yìí, èyí mú kí n máa gbádùn ìgbésí ayé mi!”

“WỌ́N TIẸ̀ TÚN LÈ NÍLÒ IRÚ ÈMI YÌÍ!”

Báwo ni Arákùnrin Choong Keon àti Julie ìyàwó rẹ̀ tí a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ṣe ń ṣe sí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn? Arákùnrin Choong Keon kọ́kọ́ ronú pé òun ò fi bẹ́ẹ̀ ran ìjọ lọ́wọ́ torí pé òun kò gbọ́ èdè Ṣáínà dáadáa. Àmọ́ àwọn ará ìjọ kò ronú bẹ́ẹ̀. Arákùnrin Choong Keon sọ pé: “Nígbà tí wọ́n pín ìjọ wa sí méjì, wọ́n fún mi ní àfikún iṣẹ́ ìsìn púpọ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ìgbà yẹn ni mo wá mọ̀ ọ́n lára pé mò ń sìn níbi tí àìní wà.” Ó rẹ́rìn-ín músẹ́, ó wá sọ pé: Àìní ibẹ̀ pọ̀ débi pé wọ́n tiẹ̀ tún lè nílò irú èmi yìí!” Arákùnrin Choong Keon ti di alàgbà báyìí. Julie ìyàwó rẹ̀ sọ pé: “Inú wa dùn pé ọwọ́ wa tẹ àwọn àfojúsùn wa, ọkàn wa balẹ̀, a sì ń láyọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ. A wá síbí ká lè ràn wọ́n lọ́wọ́, àmọ́ ìrírí amóríyá gágá tá a ní níbí ran àwa gan-an lọ́wọ́. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ kí a wá sìn ní orílẹ̀-èdè yìí!”

A ṣì nílò àwọn òṣìṣẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Ṣé o ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí ilé ìwé rẹ, tí o kò sì tíì mọ ohun tí o fẹ́ fi ìgbésí ayé rẹ ṣe? Ṣé àpọ́n ni ọ́ tàbí o kò tíì lọ́kọ, tó sì wù ọ́ kó o wúlò nínú ètò Jèhófà? Ǹjẹ́ ó wù ẹ́ kí ìdílé rẹ ní àwọn ìrírí àtàtà nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? Ǹjẹ́ o ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ tí o sì ní ìrírí tó o lè fi ran àwọn míì lọ́wọ́? Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ìbùkún jìngbìnnì lo máa rí tí o bá pinnu láti mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ gbòòrò sí i, tí o sì lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i.

a Wo ìwé “Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná” Nípa Ìjọba Ọlọ́run, orí 16, ojú ìwé 5 àti 6.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́