OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Kí ló ń ṣẹlẹ̀ nígbà tá a bá kú?
ÀWỌN KAN GBÀ GBỌ́ PÉ ẹni tó bá ti kú máa lọ gbé ní ibòmíì, àwọn kan sì gbà pé ikú ni òpin ohun gbogbo. Kí ni ìwọ́ gbà gbọ́?
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
‘Àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá.’ (Oníwàásù 9:5) Tẹ́nì kan bá ti kú, kò mọ nǹkan kan mọ́.
OHUN MÍÌ TÁ A LÈ KỌ́ NÍNÚ BÍBÉLÌ
Ọkùnrin àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run dá, ìyẹn Ádámù pa dà di erùpẹ̀ lẹ́yìn tó kú. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7; 3:19) Bákan náà, gbogbo àwọn tó bá kú máa pa dà di erùpẹ̀.—Oníwàásù 3:19, 20.
Ẹni tó bá ti kú ni a ti dá sílẹ̀ pátápátá kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. (Róòmù 6:7) Ìyẹn ni pé kò tún sí ìyà kankan fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ lẹ́yìn téèyàn bá ti kú.
Ǹjẹ́ àwọn òkú lè jíǹde?
KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?
Bẹ́ẹ̀ ni
Bẹ́ẹ̀ kọ́
Kò dá mi lójú
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
‘Àjíǹde yóò wà.’—Ìṣe 24:15.
KÍ LÀWỌN NǸKAN MÍÌ TÍ BÍBÉLÌ SỌ?
Bíbélì sábà máa ń fi ikú wé oorun. (Jòhánù 11:11-14) Bá a ṣe lè jí ẹni tó ń sùn lójú oorun, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọlọ́run lè jí ẹni tó bá ti kú.—Jóòbù 14:13-15.
Ọ̀pọ̀ àjíǹde tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn ló wà nínú Bíbélì, èyí jẹ́ kó dá wa lójú pé àwọn òkú máa jíǹde.—1 Àwọn Ọba 17:17-24; Lúùkù 7:11-17; Jòhánù 11:39-44.