ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w18 June ojú ìwé 26-29
  • Gbogbo Ìgbà Ni Jèhófà Máa Ń Tù Mí Nínú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbogbo Ìgbà Ni Jèhófà Máa Ń Tù Mí Nínú
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • WỌ́N RÀN MÍ LỌ́WỌ́ NÍPA TẸ̀MÍ
  • MO GBÁDÙN IṢẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ GAN-AN
  • MO ṢUBÚ, ÀMỌ́ MO PA DÀ DÌDE
  • ÀDÁNÙ TÓ KÓ Ẹ̀DÙN ỌKÀN BÁ WA
  • MÒ Ń LÁYỌ̀ BÍ MO ṢE Ń RAN ÀWỌN MÍÌ LỌ́WỌ́
  • Mo Kún fun Ìmoore fun Itilẹhin Jehofa tí Kìí Kùnà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àádọ́rin Ọdún Rèé Tí Mo Ti Ń Di Ibi Gbígbárìyẹ̀ Lára Aṣọ Ẹni Tí Í Ṣe Júù Mú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • A Mọ Ohun Tó Tọ́, A Sì Ṣe É
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Gẹgẹ Bi Opó kan, Mo Rí Ìtùnú Tootọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
w18 June ojú ìwé 26-29
Edward àti Lene Bazely

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Gbogbo Ìgbà Ni Jèhófà Máa Ń Tù Mí Nínú

Gẹ́gẹ́ BÍ EDWARD BAZELY ṢE SỌ Ọ́

Wọ́n bí mi ní November 9, 1929 nílùú Sukkur àtijọ́ lápá ìwọ̀ oòrùn Indus River ní Pakistan. Àsìkò yẹn làwọn òbí mi gba ìdìpọ̀ ìwé kan tó ní oríṣiríṣi àwọ̀ tó fani mọ́ra. Ọwọ́ míṣọ́nnárì kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n sì ti gbà á. Àwọn ìwé yẹn ṣàlàyé Bíbélì, wọ́n sì wà lára ohun tó jẹ́ kí n di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

ÌDÌPỌ̀ àwọn ìwé aláwọ̀ mèremère ni wọ́n ń pe àwọn ìwé yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì kéré, síbẹ̀ àwọn àwòrán tó wà nínú rẹ̀ wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Torí náà, àtikékeré lohun tí mo kà nínú àwọn ìwé yẹn ti mú kó wù mí láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Nígbà tó ku díẹ̀ kí Ogun Àgbáyé Kejì wọ orílẹ̀-èdè Íńdíà, ṣe ni nǹkan dojú rú fún mi. Àwọn òbí mi pínyà, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi kọ ara wọn sílẹ̀. Mi ò mọ ìdí táwọn méjèèjì fi ní láti kọ ara wọn sílẹ̀ torí mo nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an. Èmi nìkan ni wọ́n bí, torí náà mi ò rẹ́ni fojú jọ mi ò sì rẹ́ni fọ̀rọ̀ lọ̀. Ọkàn mi gbọgbẹ́, gbogbo nǹkan sì tojú sú mi.

Ìlú Karachi ni èmi àti màmá mi ń gbé nígbà yẹn. Lọ́jọ́ kan, dókítà àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Fred Hardaker wàásù délé wa. Ẹ̀sìn kan náà lòun àti míṣọ́nnárì tó fún wa ní ìwé aláwọ̀ mèremère yẹn ń ṣe. Ó béèrè lọ́wọ́ màmá mi bóyá wọ́n á fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ màmá mi ò gbà. Màmá mi wá sọ pé ó ṣeé ṣe kí n nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Bó sì ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn torí ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e ni Arákùnrin Hardaker bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé tí wọ́n ń ṣe nílé ìwòsàn Arákùnrin Hardaker. Àwọn Ẹlẹ́rìí àgbàlagbà bíi méjìlá ló ń pàdé fún ìjọsìn níbẹ̀. Wọ́n mú mi bí ọmọ, wọ́n sì máa ń tù mí nínú. Mi ò lè gbàgbé bí wọ́n ṣe máa ń jókòó tì mí, tí wọ́n á sì fà mí mọ́ra tí wọ́n bá ń bá mi sọ̀rọ̀. Ohun tí mo nílò gan-an nìyẹn.

Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn, Arákùnrin Hardaker ní ká jọ lọ wàásù. Wọ́n kọ́ mi bí wọ́n ṣe ń lo ẹ̀rọ giramafóònù káwọn tá à ń wàásù fún lè gbọ́ àsọyé Bíbélì tí wọ́n gbohùn rẹ̀ sílẹ̀. Díẹ̀ lára àwọn àsọyé yẹn sojú abẹ níkòó, torí náà àwọn kan ò nífẹ̀ẹ́ sí i. Síbẹ̀, inú mi máa ń dùn láti wàásù fáwọn èèyàn. Mo mọyì ẹ̀kọ́ Bíbélì gan-an, mo sì ń fìtara sọ ọ́ fáwọn èèyàn.

Bí àwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè Japan ṣe ń sún mọ́ orílẹ̀-èdè Íńdíà, àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì bẹ̀rẹ̀ sí í fúngun mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tó máa di July 1943, èmi náà kojú inúnibíni. Ọ̀gá iléèwé wa tó jẹ́ àlùfáà ìjọ Áńgílíkà lé mi kúrò nílé ìwé torí ó ní “mi ò kì í ṣe ọmọ gidi.” Ó sọ fún màmá mi pé bí mo ṣe ń bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kẹ́gbẹ́ yẹn ń kó bá àwọn ọmọ tó kù nílé ìwé. Inú bí màmá mi gan-an, wọ́n sì ní àwọn ò gbọ́dọ̀ rí mi pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́. Kódà, wọ́n tún lé mi lọ sọ́dọ̀ bàbá mi ní Peshawar, ìyẹn ìlú kan tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [1,370] kìlómítà sí apá àríwá. Ṣe ni ìgbàgbọ́ mi bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn torí pé mi ò lọ sípàdé, mi ò sì bá àwọn ará kẹ́gbẹ́ mọ́.

WỌ́N RÀN MÍ LỌ́WỌ́ NÍPA TẸ̀MÍ

Nígbà tó di ọdún 1947, mo pa dà sí Karachi kí n lè wá iṣẹ́. Nígbà tí mo débẹ̀, mo lọ sọ́dọ̀ Arákùnrin Hardaker nílé ìwòsàn wọn. Inú wọn dùn gan-an, wọ́n sì kí mi tọ̀yàyà-tọ̀yàyà.

Wọ́n rò pé ara mi ò yá ni mo ṣe wá sílé ìwòsàn, torí náà, wọ́n bi mí pé: “Kí ló ń ṣe ẹ́?”

Mo sọ fún wọn pé: “Dókítà, koko lara mi le, àmọ́ mo ti ń kú lọ nípa tẹ̀mí. Mo fẹ́ kẹ́ ẹ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

Wọ́n ní: “Ó dáa, ìgbà wo lo fẹ́ ká bẹ̀rẹ̀?”

Mo ní: “Tó bá ṣeé ṣe, ẹ jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ báyìí.”

Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, wọ́n kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́, mo sì gbádùn rẹ̀ gan-an. Inú mi dùn pé mo pa dà sáàárín àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Gbogbo ohun tí màmá mi lè ṣe ni wọ́n ṣe kí n má bàa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, mo pinnu pé bíná ń jó, bí ìjì ń jà, kò sóhun tó lè gba òtítọ́ yìí lọ́wọ́ mi. Torí náà, ní August 31, 1947, mo ṣèrìbọmi. Nígbà tí mo sì pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17], mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé.

MO GBÁDÙN IṢẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ GAN-AN

Ìlú Quetta ni wọ́n kọ́kọ́ rán mi lọ, ìyẹn ibùdó kan táwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń lò tẹ́lẹ̀. Lọ́dún 1947, wọ́n pín Íńdíà náà sí méjì, ó wá di orílẹ̀-èdè Íńdíà àti orílẹ̀-èdè Pakistan.a Èyí dá ìjà ńlá sílẹ̀ láàárín àwọn ẹlẹ́sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó wà lágbègbè yẹn, débi pé ọ̀pọ̀ ló sá kúrò nílùú wọn. Àwọn tó tó mílíọ̀nù mẹ́rìnlá [14,000,000] ló sá fi ilé wọn sílẹ̀. Àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí tó wà ní Íńdíà ṣí lọ sí Pakistan, àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù àtàwọn ẹlẹ́sìn Sikh sì lọ sí Íńdíà. Àsìkò tí wàhálà yẹn ń ṣẹlẹ̀ ni mo lọ sílùú Quetta. Èrò kún inú ọkọ̀ ojú irin tí mo wọ̀ láti Karachi lọ sílùú Quetta bámú débi pé, irin kan ni mo dì mú níta.

Edward Bazely àtàwọn mí ì ní àpéjọ àyíká kan ní Íńdíà lọ́dún 1948

Mo lọ sí àpéjọ àyíká ní Íńdíà lọ́dún 1948

Nígbà tí mo dé Quetta, mo pàdé George Singh tó ti tó nǹkan bí ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25], aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe sì ni. Arákùnrin George fún mi ní àlòkù kẹ́kẹ́ kan kí n lè máa fi wàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yẹn torí òkè pọ̀ gan-an níbẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, mo máa ń dá wàásù ni. Láàárín oṣù mẹ́fà péré, àwọn mẹ́tàdínlógún [17] ni mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn kan lára wọn sì wá sínú òtítọ́. Ọ̀kan lára wọn ni sójà kan tó ń jẹ́ Sadiq Masih, òun ló ran èmi àti George lọ́wọ́ láti tú àwọn ìwé wa kan sí èdè Urdu, ìyẹn èdè àjùmọ̀lò tí wọ́n ń sọ ní Pakistan. Kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà tí Sadiq bẹ̀rẹ̀ sí í fìtara wàásù.

Edward Bazely àtàwọn mí ì ń lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì nínú ọkọ̀ òkun Queen Elizabeth

Ìgbà tí mò ń lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì nínú ọkọ̀ ojú omi Queen Elizabeth

Nígbà tó yá, mo pa dà sí Karachi mo sì bá àwọn míṣọ́nnárì méjì ṣiṣẹ́, ìyẹn Arákùnrin Henry Finch àti Arákùnrin Harry Forrest. Àwọn méjèèjì ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ni, mo sì mọyì ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n fún mi gan-an. Mo rántí ìgbà kan tí èmi àti Arákùnrin Finch lọ wàásù lápá àríwá Pakistan. Nígbà tá a dé àwọn abúlé tó wà láwọn ẹsẹ̀ òkè ńláńlá tó wà níbẹ̀, a rí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sọ èdè Urdu tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gan-an. Ọdún méjì lẹ́yìn ìyẹn, èmi náà lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, ètò Ọlọ́run sì rán mi pa dà sí Pakistan láti wá ṣiṣẹ́ adelé alábòójútó àyíká. Ilé àwọn míṣọ́nnárì tó wà ní Lahore ni mò ń gbé pẹ̀lú àwọn arákùnrin mẹ́ta míì tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì.

MO ṢUBÚ, ÀMỌ́ MO PA DÀ DÌDE

Ó bani nínú jẹ́ pé lọ́dún 1954, àwọn míṣọ́nnárì tó wà ní Lahore ní èdèkòyédè láàárín ara wọn, ìyẹn sì mú kí ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣe àwọn àyípadà kan. Torí pé èmi náà gbè sápá kan nínú èdèkòyédè yẹn, wọ́n bá mi wí gan-an. Ọ̀rọ̀ yẹn dùn mí, ó sì ń ṣe mí bíi pé mi ò tóótun mọ́. Mo wò ó pé á dáa kí n bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé mi lákọ̀tun, torí náà mo pa dà sí Karachi, lẹ́yìn náà mo kó lọ sílùú London, lórílẹ̀-èdè England.

Ọ̀pọ̀ àwọn ará tó wà nínú ìjọ tí mo wà ló jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Ọ̀kan lára wọn ni Arákùnrin Pryce Hughes tó jẹ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ka ní Bẹ́tẹ́lì tó wà nílùú London, ṣe ló mú mi bí ọmọ. Lọ́jọ́ kan, ó sọ fún mi pé ìgbà kan wà tí Arákùnrin Joseph F. Rutherford tó ń múpò iwájú nínú ètò Ọlọ́run bá òun wí gan-an. Ó ní òun fẹ́ gbèjà ara òun, àmọ́ Arákùnrin Rutherford pa òun lẹ́nu mọ́, ó sì bá òun wí kíkankíkan. Ó yà mí lẹ́nu pé Arákùnrin Hughes ń rẹ́rìn-ín bó ṣe ń sọ̀rọ̀ yẹn. Ó sọ fún mi pé nígbà tó kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀, inú bí òun, àmọ́ nígbà tó yá, òun gbà pé òun nílò ìbáwí yẹn torí pé Jèhófà ló ń fìfẹ́ hàn sóun. (Héb. 12:6) Ọ̀rọ̀ yìí wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, ó sì jẹ́ kí n pa dà ní ayọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

Àsìkò yẹn ni màmá mi náà kó wá sí London, wọ́n sì gbà kí Arákùnrin John E. Barr tó wá di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n tẹ̀ síwájú gan-an, wọ́n sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1957. Mo pa dà gbọ́ pé bàbá mi gbà káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n tó kú.

Lọ́dún 1958, mo fẹ́ Arábìnrin Lene, ọmọ ìbílẹ̀ Denmark ni àmọ́ ìlú London ló ń gbé. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, inú wa dùn gan-an nígbà tá a bí Jane, àkọ́bí nínú ọmọ márùn-ún tá a ní. Inú mi tún dùn pé mo ní àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú Ìjọ Fulham tí mo wà. Àmọ́ nígbà tó yá, àìlera ìyàwó mi gba pé ká kó lọ síbi tí kò fi bẹ́ẹ̀ tutù. Ìdí nìyẹn tá a fi kó lọ sílùú Adelaide, lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà lọ́dún 1967.

ÀDÁNÙ TÓ KÓ Ẹ̀DÙN ỌKÀN BÁ WA

Nínú ìjọ tuntun tá a wà, àwọn àgbàlagbà tó jẹ́ ẹni àmì òróró méjìlá [12] ló wà láàárín wa, wọ́n sì ń fìtara wàásù gan-an. Kò pẹ́ táwa náà fi bẹ̀rẹ̀ sí í kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí.

Lọ́dún 1979, a bí Daniel ọmọ wa karùn-ún. Àmọ́ àtìgbà tá a ti bí i ló ti ní àrùn Down syndrome, tí kì í jẹ́ kí ọpọlọ ọmọ jí pépé,b wọ́n sì sọ fún wa pé kò ní pẹ́ kú. Kódà ní báyìí, mi ò lè ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe bà mí lọ́kàn jẹ́ tó. A sapá gan-an láti bójú tó o, àmọ́ a ò pa àwọn ọmọ mẹ́rin tó kù tì. Nígbà míì, àwọ̀ Daniel máa di búlúù torí pé ihò méjì tó wà lọ́kàn rẹ̀ kò jẹ́ kó lè mí dáadáa, ọ̀pọ̀ ìgbà la sì máa ń gbé e dìgbàdìgbà lọ sílé ìwòsàn. Láìka àìlera yìí sí, ó gbọ́n gan-an, ara ẹ̀ sì yọ̀ mọ́ọ̀yàn. Yàtọ̀ síyẹn, ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Tá a bá gbàdúrà ká tó jẹun, Daniel máa ń yọ ọwọ́ rẹ̀ kóńkóló jáde, á pàtẹ́wọ́, á mi orí rẹ̀, á wá fọ̀yàyà sọ pé “Àmín!” Ìgbà yẹn ló máa tó jẹun.

Nígbà tí Daniel pé ọmọ ọdún mẹ́rin, ó ní àìsàn leukemia, ìyẹn àìsàn jẹjẹrẹ tó máa ń ba ẹ̀jẹ̀ jẹ́. Ìṣòro yìí kó ẹ̀dùn ọkàn bá èmi àti ìyàwó mi gan-an, gbogbo nǹkan sì tojú sú mi. Àmọ́, nígbà tí nǹkan dójú ẹ̀, alábòójútó àyíká wa, ìyẹn Arákùnrin Neville Bromwich wá sílé wa. Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, bí omi ṣe ń bọ́ lójú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ló ń gbá wa mọ́ra, gbogbo wa sì jọ sunkún. Àwọn ọ̀rọ̀ tó bá wa sọ tù wá nínú gan-an, kódà nǹkan bí aago kan òru ló kúrò nílé wa. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni Daniel kú. Ikú rẹ̀ lohun tó tíì kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa jù. Síbẹ̀, a fara dà á torí a mọ̀ pé kò sóhun tó lè mú Daniel kúrò nínú ìfẹ́ Jèhófà, kódà kì í ṣe ikú pàápàá. (Róòmù 8:​38, 39) Ṣe ló ń ṣe wá bíi pé ká ti rí i nínú Párádísè.​—Jòh. 5:​28, 29.

MÒ Ń LÁYỌ̀ BÍ MO ṢE Ń RAN ÀWỌN MÍÌ LỌ́WỌ́

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀mejì ni mo ti ní àrùn rọpárọsẹ̀, síbẹ̀ alàgbà ṣì ni mí nínú ìjọ. Tí mo bá rí àwọn tó ń kojú ìṣòro, àánú wọn máa ń ṣe mí torí mo mọ bó ṣe ń rí téèyàn bá wà nínú ìṣòro, torí náà, mi ò kì í dá wọn lẹ́jọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, mo máa ń bi ara mi pé: ‘Irú ilé wo ni wọ́n ti tọ́ ẹni náà dàgbà? Kí lojú ẹni náà ti rí? Báwo ni mo ṣe lè fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ wọn? Báwo ni mo ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà?’ Mo máa ń gbádùn kí n máa ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn torí bí mo ṣe ń tu àwọn míì nínú tí mo sì ń gbé wọn ró, ṣe lèmi náà ń rí ìtùnú gbà.

Edward Bazely àti arákùnrin mí ì ń ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ ìdílé kan

Inú mi máa ń dùn gan-an tí mo bá ń ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn

Ó máa ń ṣe mí bíi ti onísáàmù tó sọ pé: ‘Nígbà tí ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè di púpọ̀ nínú mi, Jèhófà tù mí nínú, ó sì ṣìkẹ́ mi.’ (Sm. 94:19) Jèhófà dúró tì mí nígbà tí mo ní ìṣòro nínú ìdílé mi, nígbà tí wọ́n ṣe inúnibíni sí mi torí ìgbàgbọ́ mi, nígbà tí mo ní ìjákulẹ̀ àtìgbà tí mo ní ẹ̀dùn ọkàn. Torí náà, mo lè fi gbogbo ẹnu sọ pé Baba onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà!

a West Pakistan (tó ń jẹ́ Pakistan báyìí) àti East Pakistan (tó ń jẹ́ Bangladesh báyìí) ló para pọ̀ jẹ́ orílẹ̀-èdè Pakistan tẹ́lẹ̀.

b Wo àpilẹ̀kọ náà, “Raising a Child With Down Syndrome​—The Challenge and the Reward” nínú Jí! June, 2011 lédè Gẹ̀ẹ́sì.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́