Gbogbo Àwùjọ Dunnú sí Ìmújáde Ìwé Tuntun ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè
Ìwé Tuntun Tẹnu Mọ́ Ìmọ̀ Ọlọrun
1 Ní àpéjọpọ̀ àgbègbè wa tí ó kọjá, ẹ wo bí inú wa ti dùn tó fún gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà! Ní ọ̀sán Saturday, ayọ̀ wa kún rẹ́rẹ́ nígbà tí a gbọ́ ìfilọ̀ nípa ìwé tuntun náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, àti àwọn ìsọfúnni lórí rẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e. Ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé nílò ìmọ̀ tí Ọlọrun nìkan ṣoṣo lè fi fúnni—ìmọ̀ Ọlọrun àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi.—Owe 2:1-6; Joh. 17:3.
2 Ẹ wo bí olùbánisọ̀rọ̀ ti ṣàpèjúwe àwọn apá ẹ̀ka ìwé náà kedere! Àwọn àkọlé orí ìwé tí ń fani mọ́ra, àwọn àkàwé gbígbéṣẹ́, ìgbékalẹ̀ òtítọ́ lọ́nà dídáni lójú, àwọn ìbéèrè rírọrùn, àti, ní òpin orí kọ̀ọ̀kan, àpótí tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Dán Ìmọ̀ Rẹ Wò,” wà lára àwọn apá ẹ̀ka tí yóò fa gbogbo àwọn tí ó bá kà á mọ́ra. Ṣùgbọ́n àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wa ní pàtàkì yóò jàǹfààní bí wọ́n tí ń yára kánkán jèrè àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ Bibeli.
3 Nínú ọ̀rọ̀ àsọparí ní Saturday àti Sunday, a fún wa níṣìírí láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ní lílo ìwé tuntun yìí. Nísinsìnyí, ó ṣeé ṣe kí a ti dojúlùmọ̀ pẹ̀lú àwọn ohun tí ó wà nínú rẹ̀. Ó dájú pé ẹ ti jíròrò kókó tí ẹ ní láti fi sọ́kàn nígbà tí ẹ bá ń fi ìwé yìí lọni nínú pápá.
4 Àwọn Kókó Tí Ó Yẹ fún Àtúnyẹ̀wò: O lè rántí pé nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ ń gbé kókó ẹ̀kọ́ náà “Ìdí Tí Aráyé Fi Nílò Ìmọ̀ Ọlọrun,” kalẹ̀, ó tẹnu mọ́ àwọn kókó díẹ̀, tí ó ní àwọn tí ó tẹ̀ lé e yìí nínú: (1) Nígbà tí o bá ń lo ìwé yìí láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́, kò bọ́gbọ́n mu láti mú àwọn àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ míràn tí ó lè mú kí àwọn kókó pàtàkì lọ́jú pọ̀, wọnú ọ̀rọ̀ náà; pọkàn pọ̀ sórí sísọ ohun tí ìwé náà ń ṣàlàyé ní orí kọ̀ọ̀kan. (2) Àwọn orí náà kò gùn jù, kí ó baà lè ṣeé ṣe fún yín, lọ́pọ̀ ìgbà jù lọ, láti parí ẹyọ kan nígbà kọ̀ọ̀kan tí ẹ bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́. (3) Ní òpin orí kọ̀ọ̀kan, àwọn ìbéèrè tí ó wà nínú àpótí tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Dán Ìmọ̀ Rẹ Wò” yóò pèsè àtúnyẹ̀wò tí ó ṣe ṣókí.
5 Lílò Ó fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli: Ọ̀pọ̀ akéde ti béèrè bóyá ó dára láti bẹ̀rẹ̀ sí i lo ìwé tuntun yìí fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wọn dípò èyí tí wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀. Bí o bá ti rìn jìnnà nínú ìwé tí o fi ń báni kẹ́kọ̀ọ́ ní lọ́ọ́lọ́ọ́, yóò dára láti parí kíkẹ́kọ̀ọ́ ìtẹ̀jáde yẹn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a dámọ̀ràn pé kí o bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé Ìmọ̀. Bí o bá lo ìwé pẹlẹbẹ tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, nasẹ̀ ìwé tuntun náà ní àkókò yíyẹ, kí o sì bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Ìsọfúnni síwájú sí i lórí lílo ìwé Ìmọ̀ yóò fara hàn nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti àwọn oṣù tí ń bọ̀.
6 Jehofa ti pèsè ìwé tuntun yìí láti ràn wá lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa ìmọ̀ tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. Nísinsìnyí a ní láti múra sílẹ̀ dáradára, kí á sì nípìn-ín kíkún nínú iṣẹ́ tí ó ṣì kù láti ṣe.