Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún January
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 1
Orin 133
7 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a ṣà yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
13 min: “Fi Òye Inú Wàásù.” Jíròrò àwọn kókó pàtàkì, kí o sì jẹ́ kí a ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ kan tàbí méjì. Jẹ́ kí ìjọ mọ àwọn ìwé ògbólógbòó tí ó wà lọ́wọ́ ní lọ́ọ́lọ́ọ́.
25 min: “Ẹ Jẹ́ Alayọ Ki Ẹ Sì Wà Letoleto.” Ọ̀rọ̀ àsọyé tí ń tani jí láti ẹnu alàgbà láti inú Ilé-Ìṣọ́nà ti April 1, 1993, ojú ìwé 28 sí 31. Nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ kúkúrú kan, ṣàlàyé ìdí tí ó fi jẹ́ ìpèníjà láti láyọ̀ kí a sì wà létòlétò nínú gbogbo ohun tí a ń ṣe. Tọ́ka sí Jehofa àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ayọ̀ àti ètò nínú gbogbo ìgbòkègbodò wọn. Lẹ́yìn náà, tẹnu mọ́ àwọn kókó pàtàkì tí ó tẹ̀ lé e yìí: (1) Maṣe Rorò Mọ́ Araarẹ. (2) Ààyè Aja Tabi Òkú Kinniun? (3) Ba Araarẹ Lò Lọna Ti Ń Mú Èrè Wá. (4) Bá Awọn Ẹlomiran Lò Lọna Ti Ń Mú Èrè Wá. (5) Bikita fun Ẹnikọọkan. (6) Wà Pẹkipẹki Pẹlu Agbo Naa. Ka àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ bíbá a mu tí a yàn, kí o sì ṣe ìfisílò tí ó yẹ. Parí ọ̀rọ̀ rẹ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìyànjú onífẹ̀ẹ́ fún gbogbo àwùjọ láti làkàkà láti kojú ìpèníjà jíjẹ́ ẹni tí ó wà létòlétò, tí ó sì láyọ̀.
Orin 28 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 8
Orin 138
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ní ṣókí, jíròrò ìṣòro kò-sí-nílé tí ń ga sókè. Fún àwọn akéde níṣìírí láti jèrè àkókò náà nípa lílo àtinúdá láti tọ àwọn ènìyàn tí ó lè máa kọjá lọ, tí ó lè dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, tàbí tí ó lè jókòó sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, lọ.
15 min: Ìníyelórí Ìdáàbòbò Tí Káàdì Advance Medical Directive/Release Ní. Alàgbà jíròrò ìjẹ́pàtàkì kíkọ ọ̀rọ̀ kún káàdì Advance Medical Directive/Release dáadáa, àti mímú un lọ́wọ́ ní gbogbo ìgbà àti àìní náà fún àwọn ọmọdé láti ní Identity Card lọ́wọ́ ní gbogbo ìgbà, pẹ̀lú ìjọ. Gẹ́gẹ́ bí àkọlé káàdì náà ti fi hàn, ó ń pèsè ìsọfúnni ṣáájú nípa ohun tí a fẹ́ (tàbí ohun tí a kò fẹ́) ní ti ìtọ́jú ìṣègùn. Èé ṣe tí a fi ń ṣe èyí lọ́dọọdún? Káàdì tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ̀rọ̀ kún lágbára ju èyí tí a lè kà sí èyí tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tàbí èyí tí kò fi ìdánilójú ìgbàgbọ́ wa ti lọ́ọ́lọ́ọ́ hàn. Káàdì náà ń gbẹnu sọ fún ọ nígbà tí o kò bá lè sọ̀rọ̀ fúnraà rẹ. A óò pín káàdì náà láṣàálẹ́ òní. A ní láti fara balẹ̀ kọ̀rọ̀ kún wọn nílé, ṣùgbọ́n a kò gbọdọ̀ fọwọ́ sí wọn. Gẹ́gẹ́ bí a ti ń ṣe láti ọdún méjì sẹ́yìn, a óò fọwọ́ sí i, a óò sì jẹ́rìí sí i níbi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, lábẹ́ àbójútó olùdarí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ. Àwọn tí ń fọwọ́ sí i gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí gbọ́dọ̀ rí ẹni tí ó ni káàdì náà nígbà tí ó ń fọwọ́ sí i. A óò ṣe èyí lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ tí a óò ṣe ní ọ̀sẹ̀ January 15. Gbogbo akéde tí ó ti ṣe ìrìbọmi ni ó lè kọ̀rọ̀ kún inú káàdì Advance Medical Directive/Release. Àwọn akéde tí kò tí ì ṣe ìrìbọmi lè fẹ́ láti kọ ìtọ́sọ́nà tiwọn jáde, nípa mímú àwọn èdè ìsọ̀rọ̀ inú káàdì yìí bá ipò àti ìgbàgbọ́ wọn mu. Àwọn òbí lè ran àwọn ọmọ wọn tí kò tí ì ṣe ìrìbọmi lọ́wọ́ láti kọ̀rọ̀ kún inú Identity Card.
20 min: “Ẹ Jẹ́ Olùṣe—Kì Í Ṣe Olùgbọ́ Lásán.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Bí àkókò bá ti yọ̀ọ̀da tó, jíròrò ìjẹ́pàtàkì ìgbọràn, tí a gbé karí ìwé Insight, Ìdìpọ̀ 2, ojú ìwé 521, ìpínrọ̀ 1 àti 2.
Orin 70 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 15
Orin 77
12 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó. Gbóríyìn tí ó yẹ fúnni fún ṣíṣètìlẹ́yìn fún ìnáwó iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere ládùúgbò àti kárí ayé.
15 min: Àìní àdúgbò. (Tàbí “Pa Òye Ìjẹ́kánjúkánjú Rẹ Mọ́,” ọ̀rọ̀ àsọyé tí a gbé karí Ilé-Ìṣọ́nà ti October 1, 1995. ojú ìwé 25 sí 28.)
18 min: “Padà Lọ Láti Gba Àwọn Díẹ̀ Là.” Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìgbékalẹ̀ tí a dábàá. Dámọ̀ràn níní góńgó bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé tuntun náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun.
Orin 156 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 22
Orin 200
5 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
20 min: “Jàǹfààní Láti Inú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun fún 1996—Apá 1.” Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alábòójútó ilé ẹ̀kọ́. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìtọ́ni tí a pèsè fún àwọn iṣẹ́ àyànfúnni akẹ́kọ̀ọ́ nínú ìtọ́ni Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun, tí ó fara hàn nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti December 1995.
20 min: “Sọ̀rọ̀ Láìṣojo.” Ọ̀rọ̀ àsọyé àti ìjíròrò láti ẹnu alàgbà. Ṣàtúnyẹ̀wò ètò iṣẹ́ ìsìn tí ìjọ ní fún Sunday. Gbóríyìn fúnni fún ṣíṣètìlẹ́yìn dáradára, kí o sì fúnni lábàá níbi tí a nílò láti ṣiṣẹ́ lé lórí.
Orin 92 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 29
Orin 31
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
15 min: “Idi Ti Ìpín Aláròyé Kìí Fií Ṣe Ọ̀kan Ti Ó Jẹ́ Alayọ.” Ìjíròrò ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ Ilé-Ìṣọ́nà ti March 15, 1993, ojú ìwé 19 sí 22. A gbọ́dọ̀ kárí àkójọpọ̀ náà dáradára. Tọ́ka sí ọ̀nà yíyẹ láti tẹ̀ lé ní bíbójú tó àròyé títọ̀nà, láti inú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà. Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ wà lójú fò, kí wọ́n sì fún àròyé tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ní àfiyèsí kíákíá. Ṣàlàyé ojú tí Ọlọrun fi ń wo àwọn aláròyé àti bí ìtẹ̀sí náà ṣe lè léwu tó fún ẹnì kọ̀ọ̀kan àti fún ìjọ. Rọ gbogbo àwùjọ láti ṣiṣẹ́ kára ní bíborí ẹ̀mí àròyé. Tẹnu mọ́ àǹfààní yíyẹra fún ẹ̀mí búburú ti ṣíṣàròyé nípa ìpín wa nínú ìgbésí ayé. Ó yẹ kí o ka àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn kókó pàtàkì, kí o sì lò wọn.
20 min: Fi Ìwé Walaaye Titilae Lọni Ní February. Darí àfiyèsí sórí ìtọ́ka àwọn àkòrí, kí o sì fi onírúurú kókó ẹ̀kọ́ tí ìwé náà kárí han onílé. Fi tìtaratìtara lo àwọn àwòrán láti ru ọkàn-ìfẹ́ àti ìyánhànhàn sókè. Fún àpẹẹrẹ, a lè lo àwọn àwòrán tí ó wà lójú ìwé 9 sí 13, 150 sí 153, àti 156 sí 162 láti fi ṣàpèjúwe àwọn ipò inú ayé lónìí àti àwọn ipò tí yóò wáyé nínú Paradise lórí ilẹ̀ ayé. Ké sí àwùjọ láti sọ̀rọ̀ lórí àwọn àwòrán wọ̀nyí, ní fífi ìyàtọ̀ ipò ìsinsìnyí wéra pẹ̀lú àwọn ìbùkún ìgbésí ayé nínú Paradise. Rí i dájú pé o ní àwọn kókó ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ tí ń runi lọ́kàn sókè fún ìlò nínu pápá. Rán gbogbo àwùjọ létí láti gba àwọn ẹ̀dà tí wọn yóò lò nínú iṣẹ́ ìsìn ní òpin ọ̀sẹ̀ yìí.
Orin 143 àti àdúrà ìparí.