ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/96 ojú ìwé 1
  • Ta Ni Yóò Fetí sí Ìhìn Iṣẹ́ Wa?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ta Ni Yóò Fetí sí Ìhìn Iṣẹ́ Wa?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Ti Ní Irinṣẹ́ Tuntun fún Bíbẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Máyà Le Láti Ṣe Ìpadàbẹ̀wò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • ‘Àwọn Tí Ń mú Ìhìn Rere Ohun Tí Ó Dára Jù Wá’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ìgbétásì Kíkẹ́sẹ Járí Pẹ̀lú Ìròyìn Ìjọba
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 12/96 ojú ìwé 1

Ta Ni Yóò Fetí sí Ìhìn Iṣẹ́ Wa?

1 Ju ti ìgbà kígbà rí nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn, òjò ìsọfúnni, tí èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú rẹ̀ kò wúlò, tí ó sì ń ṣini lọ́nà, ń rọ̀ sórí àwọn ènìyàn. Nítorí èyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn kò mọ ohun tí wọn yóò ṣe mọ́, ó sì wá di ìpènijà fún wa láti mú kí wọ́n fetí sí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Wọn kò lóye ipa rere tí fífetí sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ní lórí wọn.—Luk. 11:28.

2 Inú wá dùn pé, ní ọ̀pọ̀ ibi lórí ilẹ̀ ayé, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́wàá mẹ́wàá ènìyàn ń fetí sí ìhìn iṣẹ́ yẹn, wọ́n sì ń tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé tí a fi ń lọ̀ wọ́n. Àmọ́ ṣáá o, ní àwọn ìpínlẹ̀ míràn, ìdáhùn padà náà kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ ìkésíni tí a ń ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni kò mú àbájáde rere wá, a sì lè ṣe kàyéfì nípa àwọn ẹni tí yòó fetí sí ìhìn iṣẹ́ wa.

3 A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún dídi ẹni tí a kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “‘Olúkúlùkù ẹni tí ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a óò gbà là.’ Bí ó ti wù kí ó rí, báwo ni wọn yóò ṣe ké pe ẹni tí wọn kò . . . gbọ́ nípa rẹ̀? Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe gbọ́ láìsí ẹnì kan láti wàásù? . . . Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ẹsẹ̀ àwọn wọnnì tí ń polongo ìhìn rere àwọn ohun rere ti dára rèǹtè rente tó!’” (Rom. 10:13-15) Bí a bá gbin irúgbìn Ìjọba taápọntaápọn, Ọlọ́run yóò mú kí ó dàgbà nínú àwọn aláìlábòsí ọkàn.—1 Kọr. 3:6.

4 Àṣírí Náà ni Láti Ṣe Ìpadàbẹ̀wò Déédéé: Ní àwọn ìpínlẹ̀ tí ó ti jọ pé ìwọ̀n kéréje ní ń fetí sí ìhìn iṣẹ́ wa, ó ṣe pàtàkì pé kí a pọkàn pọ̀ sórí mímú ọkàn ìfẹ́ èyíkéyìí tí a rí dàgbà, yálà a fi ìwé sóde tàbí a kò ṣe bẹ́ẹ̀. Èé ṣe tí ìwọ yóò fi tètè dórí ìpinnu pé, kò sí ohunkóhun tí a óò lè ṣàṣeparí? Nígbà tí a bá fún irúgbìn, a kò mọ ibi tí yóò ti méso jáde. (Onw. 11:6) Bí a bá ti múra dáradára nígbà tí a bá padà lọ láti ṣàjọpín ohun kan láti inú Ìwé Mímọ́, ì báà jẹ́ ọ̀rọ̀ ṣókí, ó lè ṣeé ṣe fún wa láti dé inú ọkàn ẹni náà. A lè fi ìwé àṣàrò kúkúrú sílẹ̀ fún un tàbí kí a fi àwọn ìwé ìròyìn ti lọ́ọ́lọ́ọ́ lọ̀ ọ́. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó lè ṣeé ṣe fún wa láti fi bí a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án. Yóò yà wá lẹ́nu gidigidi láti rí i bí Jèhófà ti ń bù kún ìsapá wa tó.—Orin Da. 126:5, 6.

5 A fi ìwé àṣàrò kúkúrú kan sílẹ̀ fún obìnrin kan tí ó fìfẹ́ díẹ̀ hàn. A kò rí i nílé títí di oṣù méjì lẹ́yìn náà, ọwọ́ rẹ̀ sì dí gan-an láti sọ̀rọ̀. A tún fi ìwé àṣàrò kúkúrú kan náà sílẹ̀ fún un. Láìka ìsapá onítẹpẹlẹmọ́ tí akéde náà ṣe láti rí i nílé sí, ó gba oṣù mẹ́ta mìíràn láti rí i, kìkì láti rí i pé, ara rẹ̀ kò dá. Arábìnrin náà tún padà kàn sí i ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e, wọ́n sì jùmọ̀ sọ̀rọ̀ ráńpẹ́ lórí àṣàrò kúkúrú náà. Nígbà tí arábìnrin náà padà lọ ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e, obìnrin náà fi ojúlówó ọkàn-ìfẹ́ hàn nínú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà. Ìyípadà nínú ìgbésí ayé rẹ̀ mú kí àìní rẹ̀ nípa tẹ̀mí jẹ ẹ́ lọ́kàn. A bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ tọ̀yàyàtọ̀yàyà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti ìgbà náà wá.

6 Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ òtítọ́ pẹ̀lú gbogbo ohun tí a bá fẹ́ kí ó dàgbà, yálà òdòdó, ewébẹ̀, tàbí ọkàn-ìfẹ́ nínú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba, ìtọ́júdàgbà ṣe pàtàkì. Èyí ń gba àkókò, okun, ẹ̀mí aájò, àti ìpinnu láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀. Ní ọdún tí ó kọjá, iye tí ó ju ìdá mẹ́ta mílíọ̀nù ènìyàn, tí irúgbìn Ìjọba ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbèrú nínú wọn, ni a batisí! Bí a bá ń bá a lọ láti wàásù, ó dájú pé a óò rí ènìyàn púpọ̀ sí i tí yóò fetí sí ìhìn iṣẹ́ wa.—Fi wé Gálátíà 6:9.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́