Yíyọ̀ǹda Ara Wa Tinútinú
1 Onísáàmù náà, Dáfídì, sọ tẹ́lẹ̀ pé, àwọn ènìyàn Jèhófà “yóò yọ̀ǹda ara wọn tinútinú,” ìyẹn ni pé, gẹ́gẹ́ bí “àwọn olùyọ̀ǹda tí ó ti múra tán.” (Orin Da. 110:3, NW, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé) Èyí dájúdájú ń ní ìmúṣẹ láàárín ẹgbẹ́ àwọn ará wa kárí ayé. Nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọdún iṣẹ́ ìsìn mẹ́rin tí ó ti kọjá, àwọn ènìyàn Jèhófà ti lo wákàtí tí ó lé ní bílíọ̀nù kan nínú títan ìhìn rere Ìjọba kálẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni ó sì wà, tí a lè gbà yọ̀ǹda ara wa tinútinú láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, ní àfikún sí iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn.
2 Àwọn Ọ̀nà Tí A Lè Gbà Fi Ìmúratán Wa Hàn: Àwọn kan nínú ìjọ lè nílò ìrànlọ́wọ́ láti dé ìpàdé. Èé ṣe tí o kò fi yọ̀ǹda láti jẹ́ kí wọ́n bá ọ lọ? Àwọn mìíràn lè máa ṣàìsàn, ṣàìlera, tàbí wà ní ilé ìwòsàn. O ha lè lo àtinúdá láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn tàbí ṣèrànwọ́ fún wọn ní ọ̀nà míràn? Ẹnì kan tàbí ìdílé kan lè wà tí ó nílò ìṣírí. O ha ti ronú nípa kíké sí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ láti wà pẹ̀lú yín nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan bí? Aṣáájú ọ̀nà tàbí akéde kan lè nílò alábàáṣiṣẹ́pọ̀ kan nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Èé ṣe tí o kò fi yọ̀ǹda ara rẹ láti bá a ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn? Díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí a lè gbà fi tinútinú ṣe ohun rere sí àwọn tí wọ́n bá wa tan nínú ìgbàgbọ́ nìyí.—Gal. 6:10.
3 Àwọn arákùnrin lè fi ìmúratán wọn láti di ẹni tí a lò nínú ètò àjọ Jèhófà hàn nípa sísakun láti kúnjú ìwọ̀n àwọn ohun tí ń múni tóótun láti di alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. (1 Tim. 3:2-10, 12, 13; Títù 1:5-9) Bí a ti ń pọ̀ sí i ní iye, a túbọ̀ ń nílò àwọn arákùnrin títóótun, tí wọ́n ṣe tán láti mú ipò iwájú nínú wíwàásù àti kíkọ́ni àti nínú ṣíṣolùṣọ́ àgùntàn ìjọ.—1 Tim. 3:1.
4 Bóyá àwọn kan lára wá lè yọ̀ǹda ara wa fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ní kíkún sí i, nípa fíforúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ aṣáájú ọ̀nà lóòrèkóòrè. Pẹ̀lúpẹ̀lù, nípa títún ìtòlẹ́sẹẹsẹ wa tò dáradára sí i, ó lè ṣeé ṣe fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀ láìdáwọ́dúró tàbí kí a wọnú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà déédéé pàápàá. Àwọn àyíká ipò wa ha lè yọ̀ǹda fún wa láti lè ṣí lọ sí àgbègbè kan tí àìní púpọ̀ sí i wà fún ìrànlọ́wọ́ bí? A ha lè yọ̀ǹda ara wa láti ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì, kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ fi kún ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ kárí ayé náà ní tààràtà bí? Iṣẹ́ tún ń lọ ní pẹrẹu nínú iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, Ilẹ̀ Àpéjọ, àti àwọn ilé ẹ̀ka jákèjádò ayé, níbi tí a ti nílò àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni gan-an. A mọyì àwọn tí wọ́n ti yọ̀ǹda ara wọn fún àwọn iṣẹ́ àtàtà wọ̀nyí gidi gan-an, a sì ti bù kún wọn ní jìgbìnnì!—Luk. 6:38.
5 Àwọn àkókò alárinrin ni a wà yìí. Jèhófà, nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ń lo àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti ṣàṣeparí iṣẹ́ àgbàyanu kan lórí ilẹ̀ ayé! Nígbàkigbà tí Jèhófà, nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀, bá ké sí wa láti ṣàjọpín nínú ìgbòkègbodò Ìjọba púpọ̀ sí i, yóò dára kí a béèrè lọ́wọ́ ara wa pé, ‘Mo ha ṣì ń yọ̀ǹda ara mi tinútinú bí?’ Lẹ́yìn náà, kí a yẹ ọkàn àti ipò àyíká wa wò tàdúràtàdúrà. Ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run wa yóò sún wa láti ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀, kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ọkàn-àyà Jèhófà yọ̀ gidigidi!—Sef. 3:17.