Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún December
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní December 2
Orin 134
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
15 min: “Ta Ni Yóò Fetí sí Ìhìn Iṣẹ́ Wa?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àwọn kókó láti inú Jí!, September 22, 1987, ojú ìwé 5, lórí ìdí tí ìhìn iṣẹ́ wa fi ń fani lọ́kàn mọ́ra, kún un.
20 min: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Pèsè Ìtọ́sọ́nà.” (Ìpínrọ̀ 1 sí 6) Fi ìpínrọ̀ 1 àti 2 nasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ. (Fi kókó tí ó wà nínú ìwé Reasoning, ojú ìwé 58 sí 60 kún un, ní líla “Reasons for considering the Bible” [Àwọn ìdí fún gbígbé Bíbélì yẹ̀ wò] lẹ́sẹẹsẹ, ní ṣókí.) Jẹ́ kí àwọn akéde dídángájíá ṣàṣefihàn àwọn ìgbékalẹ̀ tí a dábàá nínú ìpínrọ̀ 3 sí 6. Jẹ́ kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí (1) bí àwọn ìbéèrè tí a béèrè ṣe ṣèrànwọ́ láti ru ìfẹ́ sókè, (2) bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a lò ṣe bá kókó tí a ń jíròrò mu, (3) bí ìpadàbẹ̀wò ṣe bẹ̀rẹ̀ níbi tí a parí ọ̀rọ̀ sí nígbà ìkésíni àkọ́kọ́, àti (4) bí a ṣe fi ìkẹ́kọ̀ọ́ lọni.
Orin 75 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní December 9
Orin 100
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Tọ́ka sí díẹ̀ lára àwọn kókó ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ tí ó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́, tí a lè lò nínú iṣẹ́ ìsìn ní ọ̀sẹ̀ yìí.
15 min: Ríran Àwọn Àgbàlagbà Lọ́wọ́ Láti Nípìn-ín Nínú Iṣẹ́ Ìsìn. Ọ̀pọ̀ akéde àgbàlagbà olùṣòtítọ́ ní ọkàn-ìfẹ́ mímú hánhán láti nípìn-ín nínú wíwàásù pẹ̀lú ìjọ, ṣùgbọ́n ìwọ̀nba ni ibi tí agbára wọ́n mọ nítorí ọjọ́ ogbó àti àìlera ara. Àwọn ọ̀nà wà tí a lè gbà gba tiwọn rò, láti lè fi wọ́n kún àwùjọ iṣẹ́ ìsìn wa: Yọ̀ǹda láti pèsè ohun ìrìnnà fún wọn; ṣètò fún wọn láti ṣiṣẹ́ ní àwọn ilé tí kò fi bẹ́ẹ̀ sí àtẹ̀gùn púpọ̀ láti gùn; jẹ́ kí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wà nítòsí, kí wọ́n baà lè sinmi nínú rẹ̀ nígbà tí ó bá rẹ̀ wọ́n; yọ̀ǹda láti gbé wọn lọ sí àwọn ìpadàbẹ̀wò wọn; jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìwọ yóò gbé wọn lọ sí ilé, tí ó bá ti rẹ̀ wọ́n. Àwọn àgbàlagbà ń mọrírì àwọn ìrànlọ́wọ́ tí a ń ṣe fún wọn. Mẹ́nu kan àwọn ọ̀nà míràn tí ẹ gbà ń gba tiwọn rò ládùúgbò. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Awa Mọriri Awọn Agbaagba!” tí ó wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà, June 1, 1986, ojú ìwé 28 àti 29.
20 min: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Pèsè Ìtọ́sọ́nà.” (Ìpínrọ̀ 7 sí 9) Sọ̀rọ̀ lórí “Aini Kan fun Itọsọna” nínú Ilé-Ìṣọ́nà, May 1, 1993, ojú ìwé 3. Ṣàlàyé ìdí tí ó fi yẹ kí ìgbékalẹ̀ wá tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì wíwá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ orísun gíga lọ́lá jù—Ọlọ́run. Jẹ́ kí akéde ṣàṣefihàn àwọn ìgbékalẹ̀ inú ìpínrọ̀ 7 àti 8. Tẹnu mọ́ ọn pé, góńgó wá gbọ́dọ̀ jẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìwé Ìmọ̀, nígbẹ̀yìngbẹ́yín.
Orin 197 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní December 16
Orin 209
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Fúnni ní àbá díẹ̀ lórí bí a ṣe lè fọgbọ́n dáhùn padà sí àwọn ìkíni ọdún. Ṣèfilọ̀ àwọn ètò tí a ṣe fún ìjẹ́rìí àkànṣe ní December 25.
15 min: “Yíyọ̀ǹda Ara Wa Tinútinú.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àlàyé inú Ilé-Ìṣọ́nà, November 1, 1984, ojú ìwé 22, kún un.
20 min: “Yíyọ Ayọ̀ Ìbísí tí Ọlọ́run Ń fi Fúnni.” Ọ̀rọ̀ àsọyé tí ó kún fún ìtara, láti ẹnu alàgbà. Sọ àpẹẹrẹ tàbí ẹ̀rí ìbísí ní àwọn orílẹ̀-èdè tí a dárúkọ, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú àwọn Yearbook lọ́ọ́lọ́ọ́.
Orin 41 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní December 23
Orin 93
10 min: Àwọn Ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó. Ṣèfilọ̀ àwọn ètò tí a ṣe fún ìjẹ́rìí àkànṣe ní January 1.
15 min: Àwọn àìní àdúgbò. Tàbí kí alàgbà kan sọ̀rọ̀ lórí “Ìfẹ̀yìntì Lẹ́nu Iṣẹ́—Ilẹ̀kùn Ṣíṣísílẹ̀ Kan sí Ìgbòkègbodò Ìṣàkóso Ọlọ́run Ha Ni Bí?” nínú Ilé-Ìṣọ́nà, July 15, 1996, ojú ìwé 24 àti 25.—Wo Insight, Ìdìpọ̀ 2, ojú ìwé 794, ìpínrọ̀ 2 àti 3.
20 min: “Fíforúkọ Sílẹ̀ Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run.” Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alábòójútó ilé ẹ̀kọ́. Sọ iye àwọn tí ó ti forúkọ sílẹ̀ ládùúgbò, kí o sì gba gbogbo àwọn tí ó bá ṣeé ṣe fún láti forúkọ sílẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣàtúnyẹ̀wò ìtọ́ni fún iṣẹ́ àyànfúnni àwọn akẹ́kọ̀ọ́, tí ó wà nínú “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run fún 1997.”
Orin 166 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní December 30
Orin 223
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Bí a óò bá yí àkókò ìpàdé yín padà ní ọdún tuntun yìí, fún gbogbo àwùjọ níṣìírí onínúure láti máa bá a lọ láti pésẹ̀ déédéé pẹ̀lú ìjọ ní àwọn àkókò tuntun náà.
15 min: Jíròrò “Wàásù Ìjọba Náà.” Ka gbogbo ìpínrọ̀.
20 min: Ṣàyẹ̀wò Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Tí A Óò Fi Lọni ní January. Fi Ayọ̀—Bi A Ṣe Lè Rí I, Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, Igbesi Aye Yii Ha Ni Gbogbo Ohun Ti O Wà Bi?, tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye lọni. Ní lílo ìwé Reasoning, ojú ìwé 9 sí 14, ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó bá ọ̀kọ̀ọ̀kan ìwé náà mu, ní ṣókí. Ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ kan tàbí méjì.
Orin 137 àti àdúrà ìparí.