ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 3/1 ojú ìwé 29-31
  • Ìgbétásì Kíkẹ́sẹ Járí Pẹ̀lú Ìròyìn Ìjọba

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbétásì Kíkẹ́sẹ Járí Pẹ̀lú Ìròyìn Ìjọba
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtìlẹyìn Onítara Ọkàn fún Ìgbétásì Náà
  • Àwọn Ìhùwàpadà Ojú Ẹsẹ̀
  • Àwọn Ará Ìlú Ṣèrànwọ́ Nínú Pípín in
  • A Kò Yọ Ẹnikẹ́ni Sílẹ̀
  • A Máa Pín Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Lákànṣe ní January 19 sí February 15, 2009!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Pín Ìròyìn Ìjọba No. 35 Kiri Lọ́nà Gbígbòòrò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • ‘Púpọ̀ Rẹpẹtẹ Lati Ṣe Ninu Iṣẹ́ Oluwa’
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • A Ti Ní Irinṣẹ́ Tuntun fún Bíbẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 3/1 ojú ìwé 29-31

Ìgbétásì Kíkẹ́sẹ Járí Pẹ̀lú Ìròyìn Ìjọba

“ÈÉṢE Tí Ìgbésí-Ayé Fi Kún Fún Ìṣòro Tóbẹ́ẹ̀?—Paradise kan láìsí wàhálà ha ṣeé ṣe bí?” Èyí ni àkọlé Ìròyìn Ìjọba No. 34, ìwé àṣàrò kúkúrú olójú ewé mẹ́rin tí a pín ní ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó pọ̀ jù lọ ní èdè 139 ní àárín April àti May ọdún tí ó kọjá. Àwọn Ẹlẹ́rìí ní Jàmáíkà ṣàpèjúwe ìgbétásì iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí pé ó jẹ́ “ọ̀kan lára ohun pàtàkì ní ọdún yìí.” Àwọn Ẹlẹ́rìí ní Belgium pè é ní “orísun ayọ̀ ńláǹlà fún àwọn ará.” Ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Czech, èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní àǹfààní láti lọ́wọ́ nínú pípín Ìròyìn Ìjọba. Ọ́fíìsì ẹ̀ka ròyìn pé: “Ìgbétásì náà mú ẹ̀mí ìtara àti ìtara ọkàn wá.” Ìmọ̀lára tí ó rí bákan náà ni a gbọ́ láti ọ̀pọ̀ ilẹ̀ míràn.

Ìròyìn Ìjọba No. 34 ní àkànṣe ìhìn iṣẹ́ fún àwọn tí wọ́n ń kẹ́dùn tí wọ́n sì ń kígbe nítorí àwọn ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe ní orúkọ ìsìn. (Esekieli 9:4) Ó ní ìtùnú fún àwọn tí a ti da ìgbésí ayé wọn láàmú nítorí “awọn àkókò lílekoko tí ó nira lati bálò” tí kò sí ohun tí wọ́n lè ṣe sí i. (2 Timoteu 3:1) Ní títọ́ka sí Bibeli, ìwé àṣàrò kúkúrú náà fi hàn pé àwọn ìṣòro ìgbésí ayé ni a óò yanjú láìpẹ́. Paradise kan láìsí wàhálà dájú. (Luku 23:43) Ọ̀pọ̀ tí wọ́n ka Ìròyìn Ìjọba ni ìhìn iṣẹ́ rẹ̀ yí lérò padà. Ọkùnrin kan ní Togo sọ fún Ẹlẹ́rìí kan pé: “Òtítọ́ ni ohun tí o sọ.”

Láìṣeé sẹ́, ìpínkiri Ìròyìn Ìjọba gba àfiyèsí tí ó kọyọyọ. Ní Denmark, onílé kan sọ fún Ẹlẹ́rìí kan tí ó fi ìwé àṣàrò kúkúrú lọ̀ ọ́ pé: “Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti United States ni. Ṣáájú kí n tó kúrò, ẹnì kan fún mi ní ìwé àṣàrò kúkúrú yín. Nísinsìnyí, mo ṣẹ̀ṣẹ̀ dé síhìn-ín ni, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ sì ni a fún mi ní ìwé àṣàrò kúkúrú kan náà ní èdè Danish!”

Ìtìlẹyìn Onítara Ọkàn fún Ìgbétásì Náà

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kárí ayé fi pẹ̀lú ìtara ọkàn dara pọ̀ nínú iṣẹ́ pípín ìwé àṣàrò kúkúrú náà. Austria, El Salvador, Haiti, Hungary, Itali, New Caledonia, jẹ́ kìkì díẹ̀ lára ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tí ń ròyìn góńgó tuntun àwọn akéde ní àárín àwọn oṣù tí a ń pín Ìròyìn Ìjọba.

Ní Zambia, alábòójútó àyíká kan ti dá Deborah, ọmọbìnrin rẹ̀ ọlọ́dún mẹ́ta lẹ́kọ̀ọ́ láti fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọni láti ilé dé ilé. Nígbà ìgbétásì Ìròyìn Ìjọba No. 34, Deborah fi iye tí ó lé ní ẹ̀dà 45 ìwé àṣàrò kúkúrú náà síta. Màmá rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn kan tí wọ́n gba Ìròyìn Ìjọba náà lọ́wọ́ Deborah.

Ní Gúúsù Áfíríkà, ọ̀dọ́langba kan fi ìwé àṣàrò kúkúrú lọ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Cashia. Cashia ka ìwé àṣàrò kúkúrú náà ó sì sọ pé: “Èyí kàmàmà—wíwà láàyè títí láé nínú paradise kan lórí ilẹ̀ ayé! Èé ṣe tí a kò ti sọ èyí fún mi tẹ́lẹ̀?” A bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Láàárín ọ̀sẹ̀ kan, Cashia gba ìwé àṣàrò kúkúrú mìíràn. Ìkejì wá láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ òkèèrè, tí ó jẹ́ onísìn Roman Kátólíìkì, tí ń gbé ní Cyprus. Ọ̀rẹ́ rẹ̀ òkèèrè yìí ṣàlàyé fún Cashia, ìdí tí àwọn ẹ̀kọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì fi jẹ́ èké, ó sì sọ fún un pé òun ti pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe lè retí, ìyẹn fún ìpinnu Cashia láti máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ lókun gidigidi.

Ọmọkùnrin ọlọ́dún mẹ́wàá kan ní Switzerland dara pọ̀ mọ́ ìyá rẹ̀ nínú pípín ìwé àṣàrò kúkúrú náà. Ó fi ẹ̀dà kan lé obìnrin kan lọ́wọ́, ó sì fún un ní ìṣírí láti fara balẹ̀ kà á. Obìnrin náà béèrè lọ́wọ́ ọmọkùnrin náà bí ó bá gba ohun tí àwòrán tí ó wà lẹ́yìn ìwé náà ń ṣàkàwé gbọ́ ní tòótọ́—ìwàláàyè láìlópin lórí ilẹ̀ ayé. Kí ni ìdáhùn ọmọkùnrin náà? “Bẹ́ẹ̀ ni, ó dá mi lójú gbangba.” Obìnrin náà ṣí i payá pé òún ń wá ìgbàgbọ́ tòótọ́ nítorí pé ọ̀pọ̀ ìtakora wà nínú ìsìn tòun. Nígbà tí ó ṣe ìpadàbẹ̀wò, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.

Àwọn Ìhùwàpadà Ojú Ẹsẹ̀

Nígbà míràn, Ìròyìn Ìjọba máa ń mú kí àwọn tí wọ́n kà á hùwà padà lójú ẹsẹ̀. Lẹ́yìn kíka ìwé àṣàrò kúkúrú náà, ọmọbìnrin ọlọ́dún 11 kan ní Belgium jẹ́wọ́ fún ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa pé, òún tí ń jalè ní àwọn ilé ìtajà. Ìyá ọmọbìnrin náà kò fẹ́ láti tú àṣírí ọ̀ràn náà, ṣùgbọ́n ohun tí ọmọbìnrin náà kà sún ẹ̀rí ọkàn rẹ̀, ó sì fi dandan lé e pé òun yóò lọ rí ọ̀gá ilé ìtajà náà. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ìyá náà gbà kí ọmọbìnrin rẹ̀ padà lọ sí ilé ìtajà náà pẹ̀lú Ẹlẹ́rìí náà. Ìjẹ́wọ́ rẹ̀ ya ọ̀gá ilé ìtajà náà lẹ́nu. Nígbà tí ó gbọ́ pé ohun tí ó kọ́ nínú Ìròyìn Ìjọba ni ó sún un láti hùwà ní ọ̀nà yìí, ó gba ẹ̀dà kan fún ara rẹ̀ láti rí ohun tí ó wà nínú rẹ̀ tí ó lágbára tó bẹ́ẹ̀. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ọmọbìnrin náà ń tẹ̀ síwájú nísinsìnyí.

Ẹlẹ́rìí kan ní Cameroon fi ẹ̀dà Ìròyìn Ìjọba sílẹ̀ fún ọkùnrin kan, ó sì ròyìn pé: “Nígbà tí a padà débẹ̀, a rí i pé ó ti fàlà sí ìdí rẹ̀, ó sì ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè. Lẹ́yìn tí ó ti rí ìdáhùn tí ó tẹ́ ẹ lọ́rùn gbà, ó sọ pé: ‘Òtítọ́ hán-ún ni pé ìsìn ti dá kún àìláyọ̀ aráyé. Ìwé àṣàrò kúkúrú yín ti ràn mí lọ́wọ́ láti lóye púpọ̀, ṣùgbọ́n èmi yóò fẹ́ láti mọ̀ sí i.’” Ó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé nísinsìnyí.

Ẹlẹ́rìí kan tí ń ṣèbẹ̀wò láti ilé dé ilé ní Uruguay fi ìwé àṣàrò kúkúrú sílẹ̀ fún ọkùnrin kan. Ẹlẹ́rìí náà ń bá iṣẹ́ ìwàásù láti ilé dé ilé rẹ̀ lọ, ó sì ṣiṣẹ́ yíká àwọn ilé náà títí ó fi padà dé ẹ̀yìnkùlé ilé ọkùnrin náà. Ìyàlẹ́nu ni ó jẹ́ fún un láti rí i pé ọkùnrin náà ń dúró dè é, pẹ̀lú ìwé àṣàrò kúkúrú náà lọ́wọ́. Ó ti kà á, ó sì ń fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i. A bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ lójú ẹsẹ̀.

Àwọn Ará Ìlú Ṣèrànwọ́ Nínú Pípín in

Ní Japan, ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan tọ ọkùnrin kan tí ó ti lé ní 50 ọdún lọ, ó sì fi ìwé àṣàrò kúkúrú náà lọ ọ. Ọkùnrin náà béèrè pé: “Báwo ni o ti máa ṣe ìwé ìléwọ́ náà nígbà tí o bá pàdé àwọn ènìyàn tí kò ríran?” Ẹlẹ́rìí náà jẹ́wọ́ pé òun kò mọ̀. Ọkùnrin náà ní kí ó dúró ná, ó sì padà wọnú ilé rẹ̀ lọ. Ó padà dé pẹ̀lú ẹ̀dà Ìròyìn Ìjọba, ó sì sọ pé: “Mo ti gba ìwé ìléwọ́ yẹn. Mo lérò pé ó ní ìsọfúnni tí ó runi lọ́kàn sókè, tí ó sì ṣe pàtàkì, nítorí náà, mo tún un kọ sí Ìwé Àwọn Afọ́jú. Jọ̀wọ́ lo èyí fún àwọn tí wọ́n jẹ́ afọ́jú.” Ọkùnrin náà lo ọ̀pọ̀ wákàtí láti tún Ìròyìn Ìjọba náà kọ sí Ìwé Àwọn Afọ́jú, kí àwọn afọ́jú má baà pàdánù ohun tí ó wà nínú rẹ̀.

Ní Slovakia, ọkùnrin kan fẹ́ràn ìwé àṣàrò kúkúrú náà debi pé ó ṣe 20 ẹ̀dà míràn, ó sì ń pín àwọn ẹ̀dà aláwọ̀ dúdú àti funfun yìí fúnra rẹ̀. Akéde kan ní Switzerland fi Ìròyìn Ìjọba sílẹ̀ fún ìdílé kan, ó sì ń bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ ní òkè ilé tí ìdílé náà ń gbé. Bí ó ti ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀, ọ̀dọ́mọkùnrin kan láti inú ìdílé náà pàdé rẹ̀, ẹni tí ó béèrè fún ẹ̀dà 19 ìwé àṣàrò kúkúrú náà sí i. Ní ilé ẹ̀kọ́ ọmọkùnrin náà, a fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní iṣẹ́ àyànfúnni láti kọ nípa àwọn ìṣòro, kí wọ́n sì wá àwọn ojútùú wọn. Ó fẹ́ ẹ̀dà Ìròyìn Ìjọba fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ kíláàsì ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀.

A Kò Yọ Ẹnikẹ́ni Sílẹ̀

Àwọn tí wọ́n nípìn-ín nínú ìgbétásì náà gbìyànjú láti rí i dájú pé a kò yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀. Ní New Caledonia, àwọn Ẹlẹ́rìí méjì ń rìnrìn àjò lọ sí àgbègbè ìpínlẹ̀ ẹ̀yà kan tí ó jìnnà réré, láti pín Ìròyìn Ìjọba náà. Nígbà tí wọ́n ń lọ, wọ́n ṣàkíyèsí ojú ọ̀nà kan tí ó dà bíi pé ènìyàn kì í gbà, ṣùgbọ́n, bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n pinnu láti rí i bí ẹnikẹ́ni bá ń gbé ní òpin rẹ̀. Wọ́n fi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn sílẹ̀, wọ́n sì fẹsẹ̀ rìn gba ọ̀nà náà lọ, wọ́n ń la odò kọjá títí tí wọ́n fi rí ilé kan nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Tọkọtaya kan tí wọn kò tí ì gbọ́ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa rí ni ń gbé ibẹ̀, wọ́n sì tẹ́wọ́ gba ẹ̀dà Ìròyìn Ìjọba náà. Lẹ́yìn náà, àwọn akéde náà ṣe ìpadàbẹ̀wò síbẹ̀, ó sì yà wọ́n lẹ́nu láti rí i pé tọkọtaya náà ti tún ọ̀nà náà àti àwọn afárá kéékèèké mélòó kan ṣe, kí àwọn Ẹlẹ́rìí náà baà lè wa ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn wá síbi ilé náà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé.

Ní Poland, Ẹlẹ́rìí kan ní láti rìn gba ibì kan tí iṣẹ́ ìkọ́lé ti ń lọ lọ́wọ́ kí ó baà lè fi ẹ̀dà Ìròyìn Ìjọba lọ onílé kan. Àwọn òṣìṣẹ́ náà ń wò ó bí ó ti ń rìn padà bọ̀ kọjá ibi tí iṣẹ́ ìkọ́lé náà tí ń lọ lọ́wọ́. Níkẹyìn, ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ náà pè é, ó sì sọ fún un láti má ṣe gbàgbé àwọn. Nígbà tí ó tọ̀ wọ́n lọ, wọ́n dáwọ́ dúró, wọ́n sì fara balẹ̀ tẹ́tí sílẹ̀ bí ó ti ń nasẹ̀ ìwé àṣàrò kúkúrú náà. Wọ́n tẹ́wọ́ gba ọ̀pọ̀ ẹ̀dà Ìròyìn Ìjọba náà àti àwọn ìwé ìròyìn, lẹ́yìn náà, nígbà tí ó ṣe ìpadàbẹ̀wò, wọ́n tẹ́wọ́ gba ọ̀pọ̀ ìwé ńlá.

Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ Ìròyìn Ìjọba No. 34 ni a pín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè. Ìhìn iṣẹ́ rẹ̀ ti ní àbájáde tí ó lágbára. Ọ̀pọ̀ ti kọ́ pé paradise kan láìsí wàhálà ṣeé ṣe. Àdúrà wa ni pé kí àwọn ọlọ́kàn títọ́ máa bá a lọ ní dídáhùn padà, àti níkẹyìn kí wọ́n wà lára “àwọn ọlọ́kàn tútù” tí yóò ‘jogún ayé, tí wọn yóò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.’—Orin Dafidi 37:11.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 31]

Máa Bá a Lọ Ní Pípín Ìwé Ìròyìn!

Ìgbétásì kíkẹ́sẹ járí ti pípín Ìròyìn Ìjọba No. 34 wáyé ní April àti May 1995 ní ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn orílẹ̀-èdè. Láàárín àwọn oṣù méjì wọ̀nyí, ìpínkiri ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! tún wáyé lọ́nà kíkàmàmà. Fún àpẹẹrẹ, arákùnrin kan ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Czech ròyìn pé ní April, òún fi 250 ẹ̀dà Ìròyìn Ìjọba àti ìwé ìròyìn 750 sóde. Ní Guadeloupe, wọ́n yan Saturday, April 15, gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àkànṣe fún ìwé ìròyìn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo akéde ní orílẹ̀-èdè náà ni ó nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ náà! Slovakia ní góńgó tuntun nínú pínpín ìwé ìròyìn ní April. Irú àwọn ìròyìn báyìí wá láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè míràn.

Nítorí náà, èé ṣe tí o kò fi oṣù April àti May 1996 ṣe oṣù àrà ọ̀tọ̀ fún pípín ìwé ìròyìn? Àwọn ìjọ lè ṣètò àwọn ọjọ́ àkànṣe fún ìwé ìròyìn. Àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan lè ṣàjọpín nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ní ọ̀nà yìí, àti àwọn ọ̀nà míràn, a lè fún pípín ìwé ìròyìn ní ìṣírí, ìhìn iṣẹ́ pàtàkì tí a polongo nínú Ìròyìn Ìjọba No. 34 yóò sì máa bá a lọ ní títàn kálẹ̀. Nígbà náà, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣẹlẹ̀ ní ọdún tí ó kọjá, dájúdájú, Jehofa yóò bù kún ẹ̀mí ìtara tí a fi hàn.—2 Timoteu 4:22.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́