ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/08 ojú ìwé 1
  • Máa Fọgbọ́n Lo Àkókò Rẹ Lóde Ẹ̀rí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Fọgbọ́n Lo Àkókò Rẹ Lóde Ẹ̀rí
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Pápá Tó Ń Gbéni Ró, Tó Ń Múni Gbára Dì, Tó sì Ń Mú Ká Wà Létòlétò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Ìpàdé fún Iṣẹ́ Ìsìn Pápá
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Bá A Ṣe Lè Jàǹfààní Tó Kún Rẹ́rẹ́ Nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Pápá
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Bí O Ṣe Lè Jàǹfààní Látinú Àwùjọ Tí Ò Ń Dara Pọ̀ Mọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 1/08 ojú ìwé 1

Máa Fọgbọ́n Lo Àkókò Rẹ Lóde Ẹ̀rí

1 Ó dájú pé a ṣì ní ohun púpọ̀ láti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, àmọ́ àkókò tó ṣẹ́ kù kò tó nǹkan. (Jòh. 4:35; 1 Kọ́r. 7:29) Bá a bá ń ṣètò ara wa dáadáa, tí ìmúrasílẹ̀ wa sì múná dóko, a ó lè máa fọgbọ́n lo àkókò tá a ti ṣètò fún iṣẹ́ ìwàásù.

2 Múra Sílẹ̀: Kó o tó lọ sí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, rí i dájú pé o ti ní àwọn ìwé tó o máa lò lóde ẹ̀rí, o sì ti múra ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ sílẹ̀ dáadáa. Lẹ́yìn àdúrà ìparí, tètè máa lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Èyí á jẹ́ kí ìwọ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ lè ṣe púpọ̀ sí i níwọ̀nba àkókò tẹ́ ẹ ní láti lò lóde ẹ̀rí.

3 Bó bá jẹ́ pé ìwọ ni wọ́n yàn láti darí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, bẹ̀rẹ̀ ìpàdé náà lákòókò, má sì fàkókò ṣòfò. Má ṣe jẹ́ kí ìpàdé náà kọjá ìṣẹ́jú mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Rí i dájú pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ti mọ ẹni tó máa bá ṣiṣẹ́ àti ibi tó ti máa ṣiṣẹ́ kó o tó ní kí wọ́n máa lọ.

4 Lóde Ẹ̀rí: Kété lẹ́yìn tí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá bá ti parí, tètè máa lọ sí ìpínlẹ̀ ìwàásù tẹ́ ẹ ti fẹ́ ṣiṣẹ́, má wulẹ̀ dúró láìyẹ. Bó o bá fẹ́ tètè ṣíwọ́, ṣètò mọ́tò tó o máa wọ̀ padà sílé, kó o má bàa dí àwọn ẹlòmíì tí wọ́n fẹ́ pẹ́ lóde ẹ̀rí lọ́wọ́. Nígbà tó o bá ń wàásù, máa rántí pé ó ṣeé ṣe káwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ máa dúró dè ẹ́. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe lo máa ní láti fọgbọ́n yọ́ ẹni tó bá ń ṣàtakò rannto sílẹ̀ tàbí kó o ṣètò láti padà lọ sọ́dọ̀ ẹni tó bá fìfẹ́ hàn.—Mát. 10:11.

5 Bó o bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò, o lè yẹ ìrìn-àjò tí kò pọn dandan sílẹ̀ tó o bá kọ́kọ́ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó wà ládùúgbò kan náà kó o tó lọ sádùúgbò míì. O tiẹ̀ lè pe àwọn kan lára àwọn tó o fẹ́ lọ wò lórí fóònù kó o lè mọ̀ bóyá wọ́n máa wà nílé. (Òwe 21:5) Bó bá jẹ́ pé o máa pẹ́ níbi tó o fẹ́ lọ, o lè ṣètò pé káwọn ará wàásù nítòsí tàbí kí wọ́n ṣe ìpadàbẹ̀wò ládùúgbò yẹn.

6 Àkókò ìkórè yanturu táwọn olóòótọ́ ọkàn ń pọ̀ sí i la wà yìí. (Mát. 9:37, 38) Iṣẹ́ náà máa dópin láìpẹ́. Nítorí náà, ó yẹ kó máa wù wá láti fọgbọ́n lo àkókò wa lóde ẹ̀rí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́