Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 14
Orin 41
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù January sílẹ̀. Àwọn ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ míì tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ January 1 àti Jí! January-March. (Lo àbá kẹta lójú ìwé 8 fún Jí! January-March.)
15 min: “Máa Fọgbọ́n Lo Àkókò Rẹ Lóde Ẹ̀rí.”a Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu arákùnrin kan tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere ní ti bó ṣe máa ń darí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá. Báwo ló ṣe máa ń múra ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá sílẹ̀, báwo ló sì ṣe ń fọgbọ́n lo àkókò rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
20 min: “Ẹ Jẹ́ Kí Àsọjáde Yín Máa Fìgbà Gbogbo Jẹ́ Èyí tí A Fi Iyọ̀ Dùn.”b Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ kejì, ka Jòhánù 4:7-15, 39.
Orin 85
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 21
Orin 215
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Sọ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a máa lò lóṣù February, kó o sì ṣe àṣefihàn kan tó bá ìwé náà mu. Fún gbogbo àwọn ará níṣìírí láti wo fídíò wa tó dá lórí àwọn ìtọ́jú ìṣègùn míì tá a lè gbà dípò ẹ̀jẹ̀, ìyẹn Transfusion-Alternative Health Care—Meeting Patient Needs and Rights láti fi múra sílẹ̀ fún ìjíròrò tá a máa ṣe ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn lọ́sẹ̀ tó máa bẹ̀rẹ̀ ní February 4.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
25 min: “Jẹ́rìí Kúnnákúnná sí Ìhìn Rere.”c (Ìpínrọ̀ 1 sí 10) Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó bójú tó iṣẹ́ yìí. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn akéde méjì tàbí mẹ́ta tí wọ́n ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lọ́dún tó kọjá láìka bọ́wọ́ wọn ṣe dí tó tàbí pé wọ́n jẹ́ aláìlera sí. Báwo ni wọ́n ṣe ṣe é? Kí ló fún wọn láyọ̀? Nígbà tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 7, sọ àwọn ètò tó ti wà nílẹ̀ láti darí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá lóṣù March, April, àti May.
Orin 177
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 28
Orin 52
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù January sílẹ̀. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Jíròrò Ilé Ìṣọ́ February 1 àti Jí! January-March pẹ̀lú àwùjọ. Lẹ́yìn tó o bá ti ṣàkópọ̀ ṣókí nípa ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan, ní káwọn ará sọ àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣeé ṣe kó fa àwọn èèyàn lọ́kàn mọ́ra ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, kí wọ́n sì sọ ìdí tí wọ́n fi rò bẹ́ẹ̀. Ní kí wọ́n mẹ́nu ba àwọn kókó kan látinú àwọn àpilẹ̀kọ tí wọ́n ní lọ́kàn láti lò lóde ẹ̀rí. Ìbéèrè wo ni wọ́n lè fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò? Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ni wọ́n máa fẹ́ láti kà látinú àpilẹ̀kọ náà? Báwo ni wọ́n á ṣe so ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà mọ́ àpilẹ̀kọ yẹn? Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni nípa lílo ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tó wà lójú ìwé 8. (Lo àbá kẹrin lójú ìwé 8 fún Jí! January-March.)
20 min: “Jẹ́rìí Kúnnákúnná sí Ìhìn Rere.”d (Ìpínrọ̀ 11 sí 17) Bí ìwé ìkésíni tá a ṣe lákànṣe láti fi pe àwọn èèyàn síbi Ìrántí Ikú Kristi bá ti wà lọ́wọ́, pín ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan fún gbogbo àwùjọ nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 14, kó o sì sọ ètò tí ìjọ ti ṣe láti pín ìwé náà ní gbogbo ìpínlẹ̀ ìwàásù yín.
15 min: “Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Di Akéde Ìjọba Ọlọ́run.”e Bí àkókò bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí.
Orin 22
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 4
Orin 161
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Sọ̀rọ̀ lórí Àpótí Ìbéèrè.
10 min: Ṣé Ò Ń Lo Ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́? Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ọ̀rọ̀ ìṣáájú inú ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ ti ọdún 2008. Sọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa ṣàyẹ̀wò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ojoojúmọ́ àti àlàyé rẹ̀. Ní káwọn ará sọ bí wọ́n ṣe máa ń ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ àtàwọn àǹfààní tí wọ́n ti rí látinú rẹ̀. O lè ti sọ fẹ́nì kan tàbí méjì tẹ́lẹ̀ pé kí wọ́n múra sílẹ̀ láti dáhùn. Ṣàlàyé ráńpẹ́ lórí Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ọdún 2008.
25 min: “Má Fi Falẹ̀!” Alàgbà ni kó bójú tó iṣẹ́ yìí. Ní tààràtà ni kó o bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò lórí fídíò Patient Needs and Rights, àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà ni kó o sì lò. Mú ìjíròrò náà wá síparí nípa kíka ìpínrọ̀ tó kẹ́yìn kó o sì gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tá a tọ́ka sí. Ṣàlàyé bí ẹni tí kò bá tí ì ṣèpinnu ara ẹni nípa àwọn oògùn tó ní èròjà ẹ̀jẹ̀ nínú, àtàwọn ìtọ́jú tó la ẹ̀jẹ̀ lọ, ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa lílo ìwé ìbéèrè tó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù December 2006, kó sì wá kọ ìpinnu rẹ̀ sórí káàdì DPA. Àwọn kan tó ti kọ ìpinnu wọn sórí káàdì DPA tẹ́lẹ̀ lè fẹ́ ṣàwọn àtúnṣe kan lórí ohun tí wọ́n ti yàn tẹ́lẹ̀, bí wọ́n bá rí i pé ó pọn dandan, wọ́n lè gba káàdì DPA míì, kí wọ́n sì kọ ọ̀rọ̀ sínú rẹ̀. Jíròrò “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ June 15, 2004, gẹ́gẹ́ bí àfirọ́pò.
Orin 4
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
e Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.