ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/09 ojú ìwé 6
  • Wá Àwọn Ẹni Yíyẹ Kàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wá Àwọn Ẹni Yíyẹ Kàn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ọ̀nà Tá À Ń Gbà Wàásù Ìhìn Rere
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Ṣó O Ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Tara Ẹ?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Ṣé Wàá Fẹ́ Ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Tìrẹ?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Wíwá Àwọn Ẹni Yíyẹ Rí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
km 9/09 ojú ìwé 6

Wá Àwọn Ẹni Yíyẹ Kàn

1. Báwo la ṣe ń fi hàn pé a mọyì àǹfààní tá a ní láti máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù?

1 Jésù ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ kó bàa lè tu àwọn ọlọ́kàn tútù nínú. (Aísá. 61:1, 2) Àwa tá a jẹ́ ikọ̀ àti aṣojú ikọ̀ tí ń dípò fún Kristi lónìí pẹ̀lú ní àǹfààní ṣíṣeyebíye láti fara wé Jésù nípa ṣíṣàì jẹ́ kó rẹ̀ wá bá a ti ń jẹ́rìí kúnnákúnná tá a sì ń wá àwọn ẹni yíyẹ kàn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa.—Mát. 10:11; 2 Kọ́r. 5:20.

2. Ọ̀nà wo ni Pọ́ọ̀lù gbà wàásù níbi tó bá ti lè rí àwọn èèyàn, kí sì ni àbájáde rẹ̀?

2 Wàásù Níbi Tó O Bá Ti Lè Rí Àwọn Èèyàn: Ó jẹ́ àṣà àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ́kọ́ lọ sínú sínágọ́gù láti wàásù fún àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe. (Ìṣe 14:1) Ní ìlú Fílípì, òun àti Sílà wá àwọn èèyàn lọ sí ibi tí wọ́n “ronú pé ibi àdúrà wà.” Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wàásù fún àwùjọ àwọn obìnrin tí wọ́n bá níbẹ̀, ọ̀kan nínú wọn tó ń jẹ́ Lìdíà, sì yára tẹ́wọ́ gba òtítọ́.—Ìṣe 16:12-15.

3. Àwọn ibo la ti lè láǹfààní láti wàásù láfikún sí ìwàásù ilé-dé-ilé?

3 Yàtọ̀ sí wíwàásù láti ilé dé ilé, ǹjẹ́ o tún lè wàásù fáwọn èèyàn láwọn ibi ìgbọ́kọ̀sí, ibùdó eré ìtura, àwọn ibi tí wọ́n ti ń gbani síṣẹ́, ibi táwọn èèyàn ń gbà lọ gbà bọ̀ ní òpópónà, láwọn ibi ìṣòwò àti láwọn ibi ìtajà tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín? Bóyá o sì lè wàásù fáwọn tó ń gbé láwọn ilé tí wọ́n ṣe géètì sí àti àwọn ilé ìgbàlódé tí kì í rọrùn láti wọ̀ nípa kíkọ lẹ́tà sí wọn tàbí nípa títẹ̀ wọ́n láago. Bó o bá ń wà lójúfò tó o sì ń lọ sí ibi tó o ti lè rí àwọn èèyàn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, èyí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ‘ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa.’—1 Kọ́r. 15:58.

4. Ọ̀nà míì wo la tún lè gbà rí ẹni wàásù fún bí ìpínlẹ̀ ìwàásù tí ìjọ wa ní kò bá tó nǹkan?

4 Ọ̀pọ̀ akéde ti ní àǹfààní láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i nípa lílọ sí ìjọ mìíràn ní orílẹ̀-èdè wọn tàbí ní ilẹ̀ òkèèrè. Àwọn kan ti kọ́ èdè míì kí wọ́n bàa lè wàásù fáwọn tó ti orílẹ̀-èdè míì wá.

5. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àkókò tá à ń gbé yìí, kí la sì gbọ́dọ̀ pinnu láti ṣe?

5 Gbogbo wa gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé “pápá náà ni ayé.” (Mát. 9:37; 13:38) Bí òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí ṣe ń sún mọ́lé, olúkúlùkù wa gbọ́dọ̀ ṣàyẹ̀wò ara rẹ̀ dáadáa, kó bàa lè mọ ipò tí òun wà, ẹ̀bùn tí òun ní, àwọn àǹfààní tó ṣí sílẹ̀ fún òun, àti onírúurú ọ̀nà tí òun lè gbà mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun gbòòrò sí i. Jèhófà mú kó dá wa lójú pé bá a bá fi ire Ìjọba Ọlọ́run sí ipò kìíní, òun á tì wá lẹ́yìn fún gbogbo ìsapá tá a bá fi tọkàntọkàn ṣe láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbòòrò sí i.—Mát. 6:33.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́