ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ONÍWÀÁSÙ 7-12
“Rántí Ẹlẹ́dàá Rẹ Atóbilọ́lá . . . Ní Àwọn Ọjọ́ Tí O Wà Ní Ọ̀dọ́kùnrin”
Ọ̀nà tó o lè gbà rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá ni pé kó o ṣiṣẹ́ sìn ín nígbà tí eegun ọ̀dọ́ ṣì wà
Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ní okun àti agbára láti bójú tó iṣẹ́ tó lágbára tó sì gba àròjinlẹ̀
Ó yẹ kí àwọn ọ̀dọ́ lo àkókò àti okun wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run kí ọjọ́ ogbó tó dín agbára wọn kù