ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 21-23
Ẹni Tó Lẹ́tọ̀ọ́ Lábẹ́ Òfin Ni Ọba Tọ́ Sí
Bíi Ti Orí Ìwé
Jésù ni ẹni tí Ìsíkíẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ọba tọ́ sí “lọ́nà òfin.”
Láti inú ẹ̀yà wo ni Mèsáyà ti wá?
Ta ni Jèhófà sọ fún pé ìjọba rẹ̀ máa wà títí láé?
Láti apá ọ̀dọ̀ ta ni Mátíù ti ṣàlàyé ìlà ìdílé tí wọ́n ti máa bí Jésù láti fi hàn pé ó lẹ́tọ̀ọ́ lọ́nà òfin láti jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì?