ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb18 March ojú ìwé 7
  • “Ẹ Máa Bá A Nìṣó ní Ṣíṣọ́nà”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Máa Bá A Nìṣó ní Ṣíṣọ́nà”
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Wàá “Máa Bá A Nìṣó Ní Ṣíṣọ́nà”?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ẹ̀kọ́ Tí Àpèjúwe Wúńdíá Mẹ́wàá Kọ́ Wa
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Ṣé O Ò Gbàgbé Ìkìlọ̀ Jésù?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Ìlanilóye fun “Ipari Eto-Igbekalẹ Awọn Nǹkan”
    Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
mwb18 March ojú ìwé 7
Àwọn wúńdíá mẹ́wàá inú àkàwé Jésù

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 25

“Ẹ Máa Bá A Nìṣó ní Ṣíṣọ́nà”

25:​1-12

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni Jésù fi àkàwé nípa àwọn wúńdíá mẹ́wàá náà bá sọ̀rọ̀, síbẹ̀ gbogbo Kristẹni pátá làwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì inú ẹ̀ kàn. (w15 3/15 12-16) “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà.” (Mt 25:13) Ǹjẹ́ o lè ṣàlàyé àkàwé Jésù yìí?

  • Ọkọ ìyàwó (ẹsẹ 1)​—Jésù

  • Àwọn wúńdíá olóye tó múra sílẹ̀ (ẹsẹ 2)​—Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n múra sílẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé lé wọn lọ́wọ́ títí dé òpin láìkù-síbì-kan, tí wọ́n sì tàn bí ìmọ́lẹ̀ títí dé òpin (Flp 2:15)

  • Igbe ta: “Ọkọ ìyàwó ti dé!” (ẹsẹ 6)​—Àwọn àmì tó fi hàn pé Jésù ti dé

  • Àwọn òmùgọ̀ wúńdíá (ẹsẹ 8)​—Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n lọ pàdé ọkọ ìyàwó àmọ́ tí wọn ò bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, tí wọn ò sì pa ìwà títọ́ wọn mọ́

  • Àwọn wúńdíá olóye kò fún àwọn òmùgọ̀ wúńdíá náà ní òróró (ẹsẹ 9)​—Lẹ́yìn èdìdì ìkẹyìn, àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró kò ní lè ran ẹnikẹ́ni tó di aláìṣòótọ́ lọ́wọ́, ẹ̀pa kò ní bóró mọ́

  • “Ọkọ ìyàwó dé” (ẹsẹ 10)​—Jésù dé ní apá ìparí ìpọ́njú ńlá náà láti ṣe ìdájọ́

  • Àwọn wúńdíá olóye wọlé pẹ̀lú ọkọ ìyàwó síbi àsè ìgbéyàwó náà, a sì ti ilẹ̀kùn (ẹsẹ 10)​—Jésù máa kó àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró rẹ̀ lọ sí ọ̀run, àmọ́ àwọn ẹni àmì òróró aláìṣòótọ́ máa pàdánù èrè wọn ní ọ̀run

Àkàwé náà kò kọ́ wá pé èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ẹni àmì òróró ló máa di aláìṣòótọ́, tó sì máa gba pé kí òun fi ẹlòmíì rọ́pò wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀kọ́ ló jẹ́ fún àwọn ẹni àmì òróró lẹ́nì kọ̀ọ̀kan pé wọ́n ní òmìnira láti yàn bóyá wọ́n máa wà ní ìmúrasílẹ̀ tí wọ́n á sì wà lójúfò tàbí wọ́n máa hùwà òmùgọ̀ àti àìṣòótọ́. Jésù gbà wọ́n níyànjú pé: “Ẹ wà ní ìmúratán.” (Mt 24:44) Láìka ìrétí tá a ní sí, Jésù fẹ́ kí gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ múra ọkàn wọn sílẹ̀ kí wọ́n lè jẹ́ olóòótọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé ìlànà kan náà tó bá kan ọ̀rọ̀ wíwà lójúfò.

Báwo ni mo ṣe ń fi hàn pé mo wà lójúfò?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́