ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb21 July ojú ìwé 5
  • “Ẹ Má Ṣàníyàn Láé”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Má Ṣàníyàn Láé”
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Láìpẹ́, Ẹnikẹ́ni Kì Yóò Tòṣì Mọ́!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ayé Tẹ́nikẹ́ni Ò Ti Ní Tòṣì Sún Mọ́lé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Jẹ́ Káwọn Òtòṣì Mọ̀ Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Òṣì Yóò Dópin Láìpẹ́
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
mwb21 July ojú ìwé 5
Bàbá àti ìyà pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn mẹ́rin ń fẹsẹ̀ rìn lọ sípàdé. Nǹkan ò rọrùn ládùúgbò tí wọ́n ń gbé, tálákà sì ni wọ́n.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

“Ẹ Má Ṣàníyàn Láé”

Ní Ísírẹ́lì àtijọ́, Jèhófà máa ń ran àwọn aláìní lọ́wọ́. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà ṣèrànwọ́ fáwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ tó jẹ́ aláìní lónìí?

  • Ó jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ní èrò tó tọ́ nípa owó.​—Lk 12:15; 1Ti 6:6-8

  • Ó jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè níyì lójú ara wa.​—Job 34:19

  • Ó kọ́ wa pé ó yẹ ká jẹ́ òṣìṣẹ́ kára, ká sì yẹra fún ìwà burúkú.​—Owe 14:23; 20:1; 2Kọ 7:1

  • Ó jẹ́ ká ní àwọn ará tó nífẹ̀ẹ́ wa kárí ayé.​—Jo 13:35; 1Jo 3:17, 18

  • Ó jẹ́ ká nírètí.​—Sm 9:18; Ais 65:21-23

Kò yẹ ká máa ṣàníyàn, tó bá tiẹ̀ dà bíi pé ìṣòro wa pọ̀ lápọ̀jù. (Ais 30:15) Jèhófà máa pèsè gbogbo ohun tá a nílò tá a bá ṣáà ti fi Ìjọba ẹ̀ sípò àkọ́kọ́ láyé wa.​—Mt 6:31-33.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁ ṢE JẸ́ KÍ ÌFẸ́ RẸ YẸ̀ LÁÉ . . . TÓ O BÁ TIẸ̀ JẸ́ TÁLÁKÀ​—CONGO, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Rẹ Yẹ̀ Láé . . . Tó O Bá Tiẹ̀ Jẹ́ Tálákà—Congo.’ Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin lọ sí àpéjọ. Èyí tó pọ̀ jù lára wọn ló gbé àga àtàwọn ẹrù míì dání.

    Báwo làwọn ará tó ń gbé nítòsí ibi tí wọ́n ti fẹ́ ṣe àpéjọ ṣe ń fìfẹ́ hàn sáwọn tó máa ń rìnrìn àjò wá síbi àpéjọ náà?

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Rẹ Yẹ̀ Láé . . . Tó O Bá Tiẹ̀ Jẹ́ Tálákà—Congo.’ Arákùnrin kan ń tẹ́ bẹ́ẹ̀dì yàrá ẹ̀ fún àwọn ará tó ń bọ̀ láti ọ̀nà jìnjìn síbi àpéjọ.

    Báwo ni fídíò yìí ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn aláìní?

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Rẹ Yẹ̀ Láé . . . Tó O Bá Tiẹ̀ Jẹ́ Tálákà—Congo.’ Àwọn ará ń múra láti lọ sí àpéjọ.

    Tá a bá tiẹ̀ jẹ́ tálákà, báwo la ṣe lè máa fìfẹ́ hàn sáwọn aláìní bíi ti Jèhófà?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́