MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jèhófà Ò Ní Gbàgbé Iṣẹ́ Wa
Nígbà míì, àwọn èèyàn kì í mọyì gbogbo ohun tá a ṣe fún wọn tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ rántí ẹ̀. Àmọ́ ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ Jèhófà náà rí? Rárá o, Ọlọ́run mọyì wa, kò sì ní gbàgbé gbogbo iṣẹ́ tá a ṣe. Kódà, kò ní fi wá sílẹ̀ tí àìlera ò bá tiẹ̀ jẹ́ ká lè ṣe tó ti tẹ́lẹ̀ mọ́.—Heb 6:10.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ JÈHÓFÀ KÒ NÍ GBÀGBÉ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Àwọn iṣẹ́ wo ni Arákùnrin Hibshman ti ṣe nínú ètò Ọlọ́run?
Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ṣe tó fi hàn pé kò gbàgbé Arákùnrin Hibshman lẹ́yìn tí ìyàwó ẹ̀ kú, àti lẹ́yìn tí ara tó ti dara àgbà ò jẹ́ kó lè ṣe tó bó ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀?
Kí nìdí tó o fi gbà pé Jèhófà bù kún Arákùnrin Hibshman lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tó ń ṣe?—Owe 10:22