ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb23 January ojú ìwé 5
  • Jẹ́ Kí Ìgbàgbọ́ Tó O Ní Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Túbọ̀ Lágbára

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Kí Ìgbàgbọ́ Tó O Ní Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Túbọ̀ Lágbára
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Ṣe Àwọn Ìpinnu Tó Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Máa Ka Bíbélì Lójoojúmọ́ Kó O Lè Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • “Ẹ Máa Ṣe Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Náà Sọ”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Kó O sì Gbà Pé Àwọn Nǹkan Kan Wà Tó Ò Mọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
mwb23 January ojú ìwé 5
Àwòrán: Arábìnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ ń ka Bíbélì. 1. Ó kọ àwọn tí Bíbélì mẹ́nu kàn àti àsìkò tí wọ́n gbé láyé sórí pátákó. 2. Ó ń ka Bíbélì “Ìtumọ̀ Ayé Tuntun” ẹ̀dà tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ lórí ìkànnì jw.org. 3. Ó ń wo àwòrán àwọn ilẹ̀ tí Bíbélì mẹ́nu kàn. 4. Ó ya àwòrán àlùfáà àgbà, ó sì kọ orúkọ apá kọ̀ọ̀kan lára ẹ̀wù rẹ̀.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jẹ́ Kí Ìgbàgbọ́ Tó O Ní Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Túbọ̀ Lágbára

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè tún ayé wa ṣe. (Heb 4:12) Àmọ́ ká tó lè jàǹfààní látinú àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú ẹ̀, àfi kó dá wa lójú pé “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ni lóòótọ́. (1Tẹ 2:13) Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa nínú Bíbélì lágbára sí i?

Máa ka apá kan nínú Bíbélì lójoojúmọ́. Bó o ṣe ń kà á, máa kíyè sí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà ni òǹṣèwé Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá fara balẹ̀ wo àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú ìwé Òwe, wàá rí i pé ó ṣì wúlò lákòókò wa yìí.​—Owe 13:20; 14:30.

Ṣètò láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Sapá láti mọ àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run ló mí sí Bíbélì. Nínú Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wo àkòrí náà “Bíbélì” lẹ́yìn náà “Bíbélì Ní Ìmísí Ọlọ́run.” Yàtọ̀ síyẹn, tó o bá ṣàyẹ̀wò ìsọfúnni tó wà ní Àfikún A3 nínú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, á túbọ̀ dá ẹ lójú pé Bíbélì ò tíì yí pa dà.

JẸ́ KÍ ÀWỌN ARÁ WO FÍDÍÒ ÌDÍ TÁ A FI GBÀ GBỌ́ PÉ . . . Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN NI BÍBÉLÌ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÓ TẸ̀ LÉ E YÌÍ:

  • Báwo ni ògiri tẹ́ńpìlì tí wọ́n ṣàwárí ní ìlú Karnak, lórílẹ̀-èdè Íjíbítì ṣe jẹ́ ká gbà pé òótọ́ ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

  • Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ò tíì yí pa dà?

  • Báwo ni bí Bíbélì ṣe wà títí di àkókò wa yìí ṣe fi hàn pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni lóòótọ́?​—Ka Àìsáyà 40:8

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́