ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w22 December ojú ìwé 15
  • Ǹjẹ́ O Rántí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Rántí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Ẹ Má Ṣe Dí Iṣẹ́ Náà Lọ́wọ́’
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Yọ̀ǹda Ara Ẹ fún Iṣẹ́ Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Má Ṣe Pa Àwọn Tẹ́ Ẹ Jọ Ń Sin Jèhófà Tì
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Àwọn Nǹkan Wo Lo Lè Fi Ṣe Àfojúsùn ní Ọdún Iṣẹ́ Ìsìn Tó Ń Bọ̀?
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
w22 December ojú ìwé 15

Ǹjẹ́ O Rántí?

Nígbà tó o ka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lọ́dún yìí, ṣó o gbádùn ẹ̀? Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀, tó ò ń tẹ́tí sí i, tó o sì ń ronú nípa ẹ̀?

Ó máa jẹ́ kó o ṣe ìpinnu tó dáa, wàá túbọ̀ mọ̀ọ̀yàn kọ́, ìgbàgbọ́ ẹ á túbọ̀ lágbára, ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà á sì máa pọ̀ sí i.​—w22.01, ojú ìwé 30-31.

Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń fọkàn tán Jèhófà àtàwọn tó ń lò láti bójú tó wa?

Ìsinsìnyí gan-an ló yẹ ká kọ́ láti máa fọkàn tán Jèhófà pé ó máa ń ṣohun tó tọ́. Kò yẹ ká máa rò ó lẹ́ẹ̀mejì ká tó tẹ̀ lé ohun táwọn alàgbà bá sọ fún wa. Nígbà ìpọ́njú ńlá, ètò Ọlọ́run lè ní ká ṣe ohun kan tó jọ pé kò bọ́gbọ́n mu tàbí tí kò yé wa. Àmọ́, tó bá ti mọ́ wa lára láti máa tẹ̀ lé ohun tí wọ́n sọ fún wa báyìí, ó máa rọrùn fún wa nígbà yẹn.​—w22.02, ojú ìwé 4-6.

Kí ni áńgẹ́lì náà ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ‘wọ́n á rí okùn ìwọ̀n ní ọwọ́ Serubábélì ìyẹn gómìnà àwọn Júù’? (Sek. 4:8-10)

Ìran yìí jẹ́ kó dá àwọn èèyàn Ọlọ́run lójú pé bí tẹ́ńpìlì yẹn tiẹ̀ kéré lójú àwọn kan, wọ́n máa parí ẹ̀, bí Jèhófà ṣe fẹ́ kó rí ló máa rí gẹ́lẹ́, tẹ́ńpìlì yẹn sì máa múnú Jèhófà dùn.​—w22.03, ojú ìwé 16-17.

Báwo la ṣe lè “jẹ́ àpẹẹrẹ . . . nínú ọ̀rọ̀”? (1 Tím. 4:12)

Tó o bá wà lóde ìwàásù, sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́, kó o sì bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn. Máa fayọ̀ kọrin, máa dáhùn déédéé nípàdé, máa sọ òótọ́, máa sọ ọ̀rọ̀ tó ń gbé àwọn èèyàn ró, má sì ṣe máa sọ ọ̀rọ̀ èébú.​—w22.04, ojú ìwé 6-9.

Kí nìdí tó fi jẹ́ pé gbogbo nǹkan tó wà lára ẹranko ẹhànnà mẹ́rin tó wà nínú Dáníẹ́lì orí 7 ló wà lára ẹranko kan ṣoṣo tí Ìfihàn 13:1, 2 sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀?

Ẹranko tí Ìfihàn orí 13 sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ kò ṣàpẹẹrẹ ìjọba kan ṣoṣo irú bí ìjọba Róòmù. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹranko ẹhànnà yìí ṣàpẹẹrẹ gbogbo àwọn ìjọba alágbára tó ṣàkóso ayé jálẹ̀ ìtàn aráyé.​—w22.05, ojú ìwé 9.

Kí ló máa fi hàn pé a fọkàn tán Jèhófà pé ó máa ṣèdájọ́ òdodo?

Tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ wá tàbí tó bú wa, ẹ má ṣe jẹ́ ká di ẹni náà sínú tàbí ká tutọ́ sókè ká fojú gbà á. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká fi ọ̀rọ̀ náà lé Jèhófà lọ́wọ́. Ó dájú pé Jèhófà máa mú gbogbo ẹ̀dùn ọkàn tí ẹ̀ṣẹ̀ ti fà kúrò.​—w22.06, ojú ìwé 10-11.

Kí ló yẹ kí arákùnrin tó fẹ́ gbàdúrà nípàdé fi sọ́kàn?

Kò yẹ kó fi àdúrà ṣe ìfilọ̀ fáwọn ará tàbí kó fi na àwọn ará lẹ́gba ọ̀rọ̀. Kò yẹ kí arákùnrin tó máa gbàdúrà sọ “ọ̀rọ̀ púpọ̀,” pàápàá níbẹ̀rẹ̀ ìpàdé. (Mát. 6:7)​—w22.07, ojú ìwé 24-25.

Báwo ni “àwọn tó sọ ohun burúkú dàṣà” ṣe máa ní “àjíǹde ìdájọ́”? (Jòh. 5:29)

Jèhófà ò ní dá wọn lẹ́bi nítorí ohun tí wọ́n ṣe kí wọ́n tó kú. Ohun tí wọ́n bá ṣe lẹ́yìn tí wọ́n jíǹde ni Jèhófà máa fi dá wọn lẹ́jọ́.​—w22.09, ojú ìwé 18.

Ìfilọ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ wo ni Arákùnrin J. F. Rutherford ṣe ní àpéjọ kan ní September 1922?

Ní àpéjọ kan tí wọ́n ṣe ní Cedar Point, Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Arákùnrin Rutherford sọ pé: “Ọba náà ti ń ṣàkóso! Ẹ̀yin ni aṣojú tó ń polongo rẹ̀. Torí náà, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere Ọba náà àti Ìjọba rẹ̀!”​—w22.10, ojú ìwé 3-5.

Nǹkan mẹ́ta wo ni Àìsáyà orí 30 sọ pé Jèhófà ń ṣe fún wa ká lè fara dà á?

Orí Bíbélì yìí sọ fún wa pé Jèhófà (1) máa ń tẹ́tí sí wa, ó sì máa ń gbọ́ àdúrà wa, (2) ó máa ń tọ́ wa sọ́nà àti pé (3) ó máa ń ṣe àwọn nǹkan rere fún wa báyìí, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.​—w22.11, ojú ìwé 9.

Kí ló mú ká gbà pé àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Sáàmù 37:10, 11, 29 ṣẹ nígbà àtijọ́, ó sì tún máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú?

Ohun tí Dáfídì sọ yẹn jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe rí nílẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́, irú bí ìgbà tí Sólómọ́nì ṣàkóso. Jésù sọ̀rọ̀ nípa Párádísè ọjọ́ iwájú, ó sì fa ọ̀rọ̀ yọ nínú ẹsẹ 11. (Mát. 5:5; Lúùkù 23:43)​—w22.12, ojú ìwé 8-10, 14.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́