ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 43
‘Jèhófà Máa Sọ Ẹ́ Di Alágbára’
“[Jèhófà] máa fún yín lókun, ó máa sọ yín di alágbára, ó sì máa fẹsẹ̀ yín múlẹ̀ gbọn-in.”—1 PÉT. 5:10.
ORIN 38 Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Báwo ni Ọlọ́run ṣe fún àwọn tó ń sìn ín lágbára nígbà àtijọ́?
BÍBÉLÌ sábà máa ń sọ pé àwọn olóòótọ́ èèyàn ní ìgbàgbọ́ tó lágbára. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo ìgbà lẹni tó nígbàgbọ́ jù lára wọn máa ń rò pé òun lágbára. Bí àpẹẹrẹ, Ọba Dáfídì sọ pé òun “lágbára bí òkè,” àmọ́ nígbà kan, ó tún sọ pé “jìnnìjìnnì bá mi.” (Sm. 30:7) Sámúsìn ní agbára tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nígbà tí ẹ̀mí Ọlọ́run fún un lókun, síbẹ̀ ó mọ̀ pé láìsí agbára tí Ọlọ́run fún òun, òun ‘ò ní lókun mọ́, òun ò sì ní yàtọ̀ sí gbogbo ọkùnrin yòókù.’ (Oníd. 14:5, 6; 16:17) Agbára tí Jèhófà fún àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yẹn ló jẹ́ kí wọ́n lókun.
2. Kí nìdí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ pé òun jẹ́ aláìlera, síbẹ̀ òun tún jẹ́ alágbára? (2 Kọ́ríńtì 12:9, 10)
2 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà gbà pé òun nílò agbára látọ̀dọ̀ Jèhófà. (Ka 2 Kọ́ríńtì 12:9, 10.) Bíi ti ọ̀pọ̀ lára wa, Pọ́ọ̀lù náà ní àìsàn tó ń bá a fínra. (Gál. 4:13, 14) Nígbà míì, kì í rọrùn fún un láti ṣe ohun tó tọ́. (Róòmù 7:18, 19) Yàtọ̀ síyẹn, ìdààmú máa ń bá a torí kò mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sóun. (2 Kọ́r. 1:8, 9) Síbẹ̀ nígbà tí Pọ́ọ̀lù jẹ́ aláìlera, ó di alágbára. Lọ́nà wo? Jèhófà ló fún Pọ́ọ̀lù lágbára tó nílò. Òun ló sì fún un lókun.
3. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Jèhófà sọ pé òun máa fún àwa náà lágbára. (1 Pét. 5:10) Àmọ́, a ò lè rí irú agbára bẹ́ẹ̀ gbà tá ò bá ṣe ipa tiwa. Wo àpèjúwe yìí ná. Ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ ló máa ń jẹ́ kí ọkọ̀ rìn. Àmọ́ ọkọ̀ náà ò ní lè gbéra, àfi tí awakọ̀ bá tẹná ẹ̀. Lọ́nà kan náà, Jèhófà ṣe tán láti fún wa lóhun tá a nílò, àmọ́ a gbọ́dọ̀ ṣe ipa tiwa láti gbà á. Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà pèsè tó máa mú ká lágbára? Kí ló sì yẹ ká ṣe ká lè rí okun gbà? A máa rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yẹn tá a bá wo bí Jèhófà ṣe fún àwọn mẹ́ta kan nínú Bíbélì lókun. Àwọn mẹ́ta náà ni, wòlíì Jónà, Màríà ìyá Jésù àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. A tún máa rí bí Jèhófà ṣe ń fún àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lókun lónìí.
ÀDÚRÀ ÀTI ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ MÁA FÚN Ẹ LÓKUN
4. Báwo la ṣe lè rí okun gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà?
4 Ọ̀kan lára ohun tó máa ń jẹ́ ká rí okun gbà lọ́dọ̀ Jèhófà ni pé ká máa gbàdúrà sí i. Tí Jèhófà bá fẹ́ dáhùn àdúrà wa, ó máa ń fún wa ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́r. 4:7) A tún lè rí okun gbà tá a bá ń ka Bíbélì, tá a sì ń ronú nípa ohun tá a kà. (Sm. 86:11) Bákan náà, ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nínú Bíbélì máa ń fún wa “ní agbára.” (Héb. 4:12) Torí náà, tó o bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, tó ò ń ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, wàá rí okun tó o nílò láti fara dà á, o ò ní pàdánù ayọ̀ rẹ, wàá sì lè ṣe iṣẹ́ tí ò rọrùn láṣeyọrí. Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe fún wòlíì Jónà lókun.
5. Kí nìdí tí wòlíì Jónà fi nílò okun?
5 Wòlíì Jónà nílò okun. Ó sá fún iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un. Nítorí ẹ̀, ìjì líle kan fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ̀mí ẹ̀ àtẹ̀mí àwọn tó wà pẹ̀lú ẹ̀ nínú ọkọ̀. Nígbà tí wọ́n jù ú sínú òkun, inú ikùn ẹja ńlá kan ló ti bá ara ẹ̀. Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára Jónà? Ṣé ó rò pé òun máa kú ni? Ṣé ó ṣeé ṣe kó máa rò pé Jèhófà ti pa òun tì? Ó dájú pé ìdààmú máa bá Jónà gan-an.
Bíi ti wòlíì Jónà, báwo lo ṣe lè rí okun gbà tó o bá ní ìṣòro? (Wo ìpínrọ̀ 6-9)
6. Kí ni Jónà 2:1, 2, 7 sọ pé ó fún Jónà lókun nígbà tó wà nínú ikùn ẹja?
6 Kí ni Jónà ṣe kó lè rí okun gbà nígbà tó wà nínú ikùn ẹja? Ó gbàdúrà sí Jèhófà. (Ka Jónà 2:1, 2, 7.) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jónà ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ó dá a lójú pé Jèhófà máa gbọ́ àdúrà tó fìrẹ̀lẹ̀ gbà torí ó ti ronú pìwà dà. Jónà ronú nípa àwọn ohun tó ti kà nínú Ìwé Mímọ́. Kí ló mú ká sọ bẹ́ẹ̀? Nígbà tó ń gbàdúrà ní Jónà orí 2, ó lo àwọn ọ̀rọ̀ àtàwọn gbólóhùn tó wà nínú ìwé Sáàmù. (Bí àpẹẹrẹ, fi Jónà 2:2, 5 wé Sáàmù 69:1; 86:7.) Ó hàn gbangba pé Jónà mọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà dáadáa. Bó ṣe ń ronú nípa wọn nígbà tó wà nínú ìṣòro mú kó dá a lójú pé Jèhófà máa ran òun lọ́wọ́. Nígbà tó yá, Jèhófà gba Jónà sílẹ̀, ó sì múra tán láti ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un.—Jónà 2:10–3:4.
7-8. Báwo ni arákùnrin kan ní Taiwan ṣe rí okun gbà nígbà tó níṣòro?
7 Àpẹẹrẹ Jónà máa ràn wá lọ́wọ́ tá a bá níṣòro. Bí àpẹẹrẹ, àìsàn tó le gan-an ń ṣe Arákùnrin Zhimingb ní Taiwan. Yàtọ̀ síyẹn, ó ń fara da àtakò tí ìdílé ẹ̀ ń ṣe sí i torí pé ó ń sin Jèhófà. Àdúrà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ ló jẹ́ kó rí okun gbà lọ́dọ̀ Jèhófà. Ó sọ pé: “Nígbà míì tí ìṣòro bá dé, ìdààmú kì í jẹ́ kí n lè fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́.” Àmọ́, kò jẹ́ kó sú òun. Ó sọ pé: “Màá kọ́kọ́ gbàdúrà sí Jèhófà. Lẹ́yìn náà, màá ki ẹ̀rọ tá a fi ń gbọ́ orin bọ etí kí n lè gbọ́ orin Ìjọba Ọlọ́run. Kódà nígbà míì, mo máa ń fi ohùn jẹ́jẹ́ kọ àwọn orin náà títí ara mi á fi balẹ̀. Lẹ́yìn náà, màá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́.”
8 Arákùnrin Zhiming jàǹfààní gan-an nínú ìdákẹ́kọ̀ọ́ tó ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tára ẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yá lẹ́yìn tí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ fún un, nọ́ọ̀sì kan sọ fún un pé ẹ̀jẹ̀ ò tó lára ẹ̀, àfi kó gbẹ̀jẹ̀ sára. Àmọ́ kó tó ṣiṣẹ́ abẹ yẹn, ó kà nípa arábìnrin kan tó ti ṣe irú iṣẹ́ abẹ náà rí. Ẹ̀jẹ̀ arábìnrin náà kéré gan-an sí tiẹ̀, arábìnrin náà ò gbẹ̀jẹ̀, síbẹ̀ kò kú, ara ẹ̀ sì yá. Ohun tí Zhiming kà yẹn fún ìgbàgbọ́ ẹ̀ lókun gan-an.
9. Tí ìṣòro bá kó ìdààmú bá ẹ, kí lo lè ṣe? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
9 Tó o bá níṣòro, ṣé ìdààmú máa ń bá ẹ débi pé o ò ní lè sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ tó o bá ń gbàdúrà sí Jèhófà? Ṣé ó máa ń rẹ̀ ẹ́ débi pé o ò ní lè kẹ́kọ̀ọ́? Má gbàgbé pé ọ̀rọ̀ ẹ yé Jèhófà dáadáa. Torí náà, tó o bá tiẹ̀ gbàdúrà ṣókí, ó dájú pé Jèhófà máa ṣe ohun tó o fẹ́. (Éfé. 3:20) Tí ìrora àti ìdààmú tó bá ẹ ò bá jẹ́ kó o lè kàwé tàbí kó o lè kẹ́kọ̀ọ́, o lè máa gbọ́ Bíbélì tàbí àwọn ìwé ètò Ọlọ́run tá a gbohùn ẹ̀ sílẹ̀. Ó tún máa ṣe ẹ́ láǹfààní tó o bá gbọ́ ọ̀kan lára àwọn orin wa tàbí kó o wo fídíò kan lórí ìkànnì jw.org. Torí náà, tó o bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, tó o sì ń lo gbogbo ohun tí Jèhófà pèsè kó o lè rí ìdáhùn àdúrà ẹ, ìyẹn á fi hàn pé o fẹ́ kí Jèhófà fún ẹ lókun.
JẸ́ KÁWỌN ARÁKÙNRIN ÀTÀWỌN ARÁBÌNRIN Ẹ FÚN Ẹ LÓKUN
10. Báwo làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ṣe ń fún wa lókun?
10 Jèhófà máa ń lo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa láti fún wa lókun. Wọ́n máa ń jẹ́ “orísun ìtùnú” fún wa tí ìṣòro bá dé bá wa tàbí tí wọ́n bá ní ká ṣe iṣẹ́ tó le. (Kól. 4:10, 11) Irú àwọn ọ̀rẹ́ yìí máa ń ràn wá lọ́wọ́ gan-an ní “ìgbà wàhálà.” (Òwe 17:17) Nígbà tá a bá rẹ̀wẹ̀sì, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa máa ń pèsè ohun tá a nílò, wọ́n máa ń tù wá nínú, wọ́n sì máa ń jẹ́ kí àjọṣe àwa àti Jèhófà túbọ̀ lágbára. Ẹ jẹ́ ká wo bí Màríà ìyá Jésù ṣe rí okun gbà lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n jọ sin Ọlọ́run.
11. Kí nìdí tí Màríà fi nílò okun?
11 Màríà nílò okun kó lè ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Wo bí àníyàn Màríà ṣe máa pọ̀ tó nígbà tí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì jíṣẹ́ ńlá kan fún un. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò tíì ṣègbéyàwó, ó sọ pé ó máa lóyún. Kò tíì tọ́ ọmọ rí, àmọ́ òun ló máa tọ́ ọmọ tó máa di Mèsáyà. Yàtọ̀ síyẹn, torí pé Màríà kò tíì ní ìbálòpọ̀ rí, báwo ló ṣe máa ṣàlàyé fún Jósẹ́fù àfẹ́sọ́nà ẹ̀ pé òun ti lóyún? Ó dájú pé ìyẹn ò ní rọrùn rárá.—Lúùkù 1:26-33.
12. Bí Lúùkù 1:39-45 ṣe sọ, báwo ni Màríà ṣe rí okun tó nílò gbà?
12 Báwo ni Màríà ṣe rí okun tó nílò gbà kó lè ṣe iṣẹ́ ńlá tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí? Ó jẹ́ káwọn ẹlòmíì ran òun lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó ní kí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì túbọ̀ ṣàlàyé iṣẹ́ náà fún òun. (Lúùkù 1:34) Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ó rìnrìn àjò lọ sí “ilẹ̀ olókè” ní Júdà láti lọ wo mọ̀lẹ́bí ẹ̀ Èlísábẹ́tì. Ìrìn àjò yẹn sì dáa gan-an torí pé Èlísábẹ́tì gbóríyìn fún Màríà, Jèhófà sì fẹ̀mí ẹ̀ darí Èlísábẹ́tì láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ amóríyá nípa ọmọ tí Màríà máa bí. (Ka Lúùkù 1:39-45.) Màríà sọ pé Jèhófà “ti fi apá rẹ̀ ṣe ohun tó lágbára.” (Lúùkù 1:46-51) Torí náà, Jèhófà lo Gébúrẹ́lì àti Èlísábẹ́tì láti fún Màríà lókun.
13. Báwo ni arábìnrin kan ní Bòlífíà ṣe rí okun gbà nígbà tó ní káwọn ará ran òun lọ́wọ́?
13 Bíi ti Màríà, àwa náà lè rí okun gbà lọ́dọ̀ àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà. Arábìnrin Dasuri lórílẹ̀-èdè Bòlífíà nílò irú okun bẹ́ẹ̀. Nígbà tí àyẹ̀wò fi hàn pé bàbá ẹ̀ ní àìsàn kan tó lè gbẹ̀mí ẹ̀, tí wọ́n sì dá a dúró sílé ìwòsàn, Dasuri ló dúró tì í, tó sì ń tọ́jú ẹ̀ níbẹ̀. (1 Tím. 5:4) Iṣẹ́ yẹn ò rọrùn rárá. Dasuri sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ló ń ṣe mí bíi pé ẹ̀mí mi ò lè gbé e mọ́.” Ṣé ó ní káwọn ará ran òun lọ́wọ́? Rárá, kò kọ́kọ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé, “Mi ò fẹ́ yọ àwọn ará lẹ́nu. Mo rò lọ́kàn mi pé ‘Jèhófà ló máa ràn mí lọ́wọ́.’ Àmọ́ mo wá rí i pé bí mi ò ṣe jẹ́ káwọn ará ràn mí lọ́wọ́ ló ń mú kí n máa dá àwọn ìṣòro mi gbé.” (Òwe 18:1) Dasuri pinnu pé òun máa kọ lẹ́tà sáwọn ọ̀rẹ́ òun mélòó kan, ó sì sọ ìṣòro ẹ̀ fún wọn. Ó sọ pé: “Okun tí mo rí gbà lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mi kọjá àfẹnusọ. Wọ́n gbé oúnjẹ wá fún mi nílé ìwòsàn, wọ́n sì fi àwọn ẹsẹ Bíbélì tù mí nínú. Ó mà tù mí lára o bí mo ṣe mọ̀ pé àwọn ará ò dá wa dá ìṣòro wa torí pé ara ìdílé ńlá Jèhófà ni gbogbo wa. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa máa ń ṣe tán láti pèsè ohun tá a nílò, wọ́n máa ń bá wa kẹ́dùn, wọ́n sì máa ń dúró tì wá nígbà ìṣòro.”
14. Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ káwọn alàgbà ràn wá lọ́wọ́?
14 Àwọn alàgbà wà lára àwọn tí Jèhófà ń lò láti fún wa lókun. Jèhófà máa ń lò wọ́n láti fún wa níṣìírí, kí wọ́n sì mára tù wá. (Àìsá. 32:1, 2) Torí náà, tí nǹkan kan bá ń dà ẹ́ láàmú, sọ nǹkan náà fáwọn alàgbà. Tí wọ́n bá láwọn fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́, má kọ ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n fẹ́ ṣe fún ẹ. Ìdí sì ni pé Jèhófà lè lò wọ́n láti mú kí ìgbàgbọ́ ẹ lágbára.
JẸ́ KÁWỌN NǸKAN TÓ Ò Ń RETÍ MÁA FÚN Ẹ LÓKUN
15. Ìrètí wo ni gbogbo àwa Kristẹni ní?
15 Àwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì máa ń jẹ́ ká nírètí, ó sì ń jẹ́ ká lágbára láti máa sin Jèhófà nìṣó. (Róòmù 4:3, 18-20) Àwọn Kristẹni kan nírètí láti gbé ọ̀run títí láé, àwọn yòókù sì nírètí láti gbé ayé títí láé nínú Párádísè. Ìrètí tá a ní yìí ń fún wa lókun ká lè fara da ìṣòro, ká máa wàásù ìhìn rere, ká sì máa ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lọ́wọ́. (1 Tẹs. 1:3) Ìrètí yẹn kan náà ló fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lókun.
16. Kí nìdí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi nílò okun?
16 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nílò okun kó lè ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Kọ́ríńtì, ó fi ara ẹ̀ wé ohun èlò tá a fi amọ̀ ṣe. Ó sọ pé wọ́n ‘há òun gádígádí, ọkàn òun dà rú, wọ́n ṣe inúnibíni sí òun, wọ́n sì gbé òun ṣánlẹ̀.’ Kódà, ẹ̀mí ẹ̀ máa ń wà nínú ewu. (2 Kọ́r. 4:8-10) Ìgbà tí Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kẹta ló kọ àwọn ọ̀rọ̀ yẹn. Ó ṣeé ṣe kó má mọ̀ nígbà yẹn pé ọ̀pọ̀ ìṣòro ṣì máa dé bá òun. Àwọn alátakò hùwà ìkà sí i, wọ́n fàṣẹ ọba mú un, ọkọ̀ ẹ̀ rì sínú òkun, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n.
17. Kí ni 2 Kọ́ríńtì 4:16-18 sọ pé ó fún Pọ́ọ̀lù lókun láti fara da ìṣòro ẹ̀?
17 Pọ́ọ̀lù rí okun gbà torí pé ó tẹjú mọ́ ohun tó ń retí, ìyẹn sì jẹ́ kó fara da àwọn ìṣòro ẹ̀. (Ka 2 Kọ́ríńtì 4:16-18.) Ó sọ fáwọn ará Kọ́ríńtì pé tí òun bá tiẹ̀ “ń joro,” òun ò ní jẹ́ kó sú òun. Èrè ọjọ́ iwájú ni Pọ́ọ̀lù tẹjú mọ́. Kò sí ìṣòro tí ò lè fara dà torí ìrètí tó ní láti gbé ọ̀run títí láé jẹ́ “ògo tí ó tóbi gan-an.” Pọ́ọ̀lù máa ń ronú nípa ìrètí yẹn, torí náà, ó ń di “ọ̀tun láti ọjọ́ dé ọjọ́.”
18. Báwo ni ìrètí tí Arákùnrin Tihomir àti ìdílé ẹ̀ ní ṣe fún wọn lókun?
18 Ìrètí tí Arákùnrin Tihomir tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Bulgaria ní fún un lókun. Lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn, àbúrò ẹ̀ ọkùnrin tó ń jẹ́ Zdravko kú nínú jàǹbá ọkọ̀ kan. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, ẹ̀dùn ọkàn bá Tihomir, ìbànújẹ́ sì dorí ẹ̀ kodò. Kí òun àti ìdílé ẹ̀ lè fara da ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, wọ́n fojú inú wo bí àjíǹde ṣe máa rí. Ó sọ pé: “Bí àpẹẹrẹ, a máa ń sọ̀rọ̀ nípa ibi tá a ti máa kí Zdravko káàbọ̀, oúnjẹ tá a máa fún un, àwọn tá a máa pè síbi ayẹyẹ tá a fẹ́ fi kí i káàbọ̀ àtohun tá a máa sọ nípa àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn.” Tihomir sọ pé bóun ṣe tẹjú mọ́ àwọn ohun rere tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú ti jẹ́ kí ìdílé òun fara dà á, káwọn sì dúró dìgbà tí Jèhófà máa jí àbúrò òun dìde.
Báwo ni ìgbésí ayé ẹ ṣe máa rí nínú ayé tuntun? (Wo ìpínrọ̀ 19)c
19. Báwo lo ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ tó o ní nínú àwọn ìlérí Jèhófà túbọ̀ lágbára? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
19 Báwo lo ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ tó o ní nínú àwọn ìlérí Jèhófà túbọ̀ lágbára? Bí àpẹẹrẹ, tó o bá nírètí láti gbé ayé títí láé, ka ohun tí Bíbélì sọ nípa bí Párádísè ṣe máa rí, kó o sì ronú lé e lórí. (Àìsá. 25:8; 32:16-18) Ronú nípa bí nǹkan ṣe máa rí nínú ayé tuntun. Máa fojú inú wo ara ẹ níbẹ̀. Ta lo rí níbẹ̀? Ohùn wo lò ń gbọ́? Báwo ló ṣe rí lára ẹ? Kó lè rọrùn fún ẹ láti fojú inú rí ohun tá à ń sọ yìí, wo àwòrán Párádísè tó wà nínú àwọn ìwé wa tàbí kó o wo fídíò orin Ayé Tuntun, Ó Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dé Tán tàbí Fojú Inú Wò Ó. Tá a bá ń fojú inú wo àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ nínú ayé tuntun, àá rí i pé “ìgbà díẹ̀” ló kù káwọn ìṣòro wa dópin, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kí wọ́n bò wá mọ́lẹ̀. (2 Kọ́r. 4:17) Àwọn ohun tí Jèhófà ṣèlérí yìí máa fún ẹ lókun.
20. Tó o bá rẹ̀wẹ̀sì, báwo lo ṣe lè pa dà lókun?
20 Tá a bá rẹ̀wẹ̀sì, “Ọlọ́run ló máa fún wa lágbára.” (Sm. 108:13) Jèhófà ti pèsè ohun tó máa fún ẹ lókun. Torí náà, tó o bá fẹ́ kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ kan tí wọ́n gbé fún ẹ, láti fara da ìṣòro ẹ, kó o sì máa láyọ̀ nìṣó, gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntọkàn, kó o sì máa dá kẹ́kọ̀ọ́ kó o lè rí ìtọ́sọ́nà ẹ̀. Jẹ́ kí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ẹ ràn ẹ́ lọ́wọ́. Máa ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà máa ṣe fún ẹ lọ́jọ́ iwájú. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run máa lo ‘agbára rẹ̀ ológo láti fún ẹ ní gbogbo agbára tó o nílò, kó o lè fara dà á pẹ̀lú sùúrù àti ìdùnnú.’—Kól. 1:11.
ORIN 33 Ju Ẹrù Rẹ Sọ́dọ̀ Jèhófà
a Àpilẹ̀kọ yìí máa ran àwọn tó ń fara da ìṣòro lọ́wọ́ tàbí àwọn tó rò pé àwọn ò ní lè ṣe iṣẹ́ tí ètò Ọlọ́run gbé fún wọn. A máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe máa ń fún wa lókun àtohun tá a máa ṣe ká lè rí okun yẹn gbà.
b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
c ÀWÒRÁN: Arábìnrin kan tí ò lè gbọ́rọ̀ rárá ń ronú nípa àwọn ìlérí Jèhófà nínú Bíbélì, ó sì ń wo fídíò orin kó lè rọrùn fún un láti fojú inú wo bí ìgbésí ayé ẹ̀ ṣe máa rí nínú ayé tuntun.