ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lfs àpilẹ̀kọ 18
  • Mo Jèrè Ọkọ Mi “Láìsọ Ohunkóhun”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mo Jèrè Ọkọ Mi “Láìsọ Ohunkóhun”
  • Ìtàn Ìgbésí Ayé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbéèrè Kan Tí Mi Ò Lè Kọ̀
  • Àtakò Tó Túbọ̀ Le Sí I
  • Nǹkan Yí Pa Dà
  • Mo Kún fun Ìmoore fun Itilẹhin Jehofa tí Kìí Kùnà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • “Jèhófà, O Wá Mi Kàn!”
    Jí!—2004
  • Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Mo Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́ Bíbélì ní Romania
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ìtàn Ìgbésí Ayé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
lfs àpilẹ̀kọ 18
Ibolya Bartha.

IBOLYA BARTHA | ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Mo Jèrè Ọkọ Mi “Láìsọ Ohunkóhun”

Ọ̀pọ̀ nǹkan ló mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, mo rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́yàyà, wọ́n sì máa ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn. Bí wọ́n tún ṣe máa ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, inú mi dùn nígbà tí wọ́n kọ́ mi pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an àti pé ó fẹ́ ká gbádùn ayé wa lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́ ọkọ mi ò fara mọ́ ohun tí mò ń kọ́, ìyẹn sì mú kí nǹkan ṣòro fún mi.

Ibolya àti István lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn.

Èmi àti ọkọ mi lọ́jọ́ ìgbéyàwó wa

Ọdún 1952 ni wọ́n bí mi lórílẹ̀-èdè Ròmáníà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ìyá mi, wọn ò fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn wọn. Torí náà, mi kì í lọ sípàdé. Yàtọ̀ síyẹn, ìjọba Kọ́múníìsì ló ń ṣàkóso orílẹ̀-èdè Ròmáníà nígbà yẹn, wọ́n sì fòfin de iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Torí náà, títí mo fi pé ẹni ọdún mẹ́rìndínlógójì (36), mi ò mọ nǹkan kan nípa Jèhófà àti ohun tí Bíbélì sọ. Àmọ́ lọ́dún 1988, nígbà tí èmi àti István ọkọ mi ń gbé nílùú Satu-Mare, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó tún ayé mi ṣe.

Ìbéèrè Kan Tí Mi Ò Lè Kọ̀

Lọ́jọ́ kan, màmá mi wá kí mi. Wọ́n sọ pé: “Mo fẹ́ lo kí ẹ̀gbọ́n mi. Ṣé ká jọ lọ? Lẹ́yìn náà, a lè jọ ṣeré jáde.” Mo gbà láti tẹ̀ lé wọn torí kò sí nǹkan tí mò ń ṣe.

Nígbà tá a dé ọ̀dọ̀ ẹ̀gbọ́n màmá mi, a rí i pé wọ́n ń ṣe ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́, a sì rí àwọn bíi mẹ́sàn-án míì tí wọ́n jọ ń kẹ́kọ̀ọ́. À ṣé màmá mi ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe dáadáa pa dà, wọ́n sì ń fìtara jọ́sìn Jèhófà. Ohun tí mọ gbọ́ nípàdé yẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an.

Nígbà tí wọ́n parí ìpàdé náà, ẹni tó bójú tó ìpàdé náà wá bá mi, ó sọ fún mi pé: “János lorúkọ mi. Ṣé o gbádùn ohun tó o gbọ́ lónìí? Mo kíyè sí i pé o fara balẹ̀ tẹ́tí sílẹ̀.” Mo wá sọ fún un pé mi ò lọ sí irú ìpàdé báyìí rí, màá tún fẹ́ pa dà wá. Ó tún wá bi mí pé: “Ṣé wàá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?” Mi ò lè sọ pé rárá. Mo wá rí i pé ṣe ni Jèhófà dìídì fà mí sọ́dọ̀ àwọn èèyàn ẹ̀.

Lọ́jọ́ kejì, János fi Arábìnrin Ida hàn mí, òun ló sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́, ẹ̀rù ń bà mí pé báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe máa rí lára ọkọ mi, tó bá gbọ́ pé mò ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo gbìyànjú láti bá ọkọ mi sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, àmọ́ pàbó ló já sí. Mo sì mọ̀ pé ohun tí mò ń ṣe kò dùn mọ́ ọn nínú.

Láìfi ìyẹn pè, mi ò dá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dúró, nígbà tó sì di August 1989 mo ṣèrìbọmi. Oṣù mẹ́rin lẹ́yìn náà, ìjọba Kọ́múníìsì tó ń ṣàkóso forí ṣánpọ́n, wọ́n sì pa olórí ìjọba náà.

Àtakò Tó Túbọ̀ Le Sí I

Ìjọba tuntun yẹn fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lómìnira láti máa ṣèpàdé ká sì tún máa wàásù. Àmọ́ ní tèmi, òmìnira yìí mú kí ọkọ mi túbọ̀ máa ta kò mí. Ó sọ fún mi pé, “Ohun tó o gbà gbọ́ kò kàn mí o, tèmi ni pé mi ò fẹ́ rí i kó o máa wàásù láti ilé délé.”

Mo mọ̀ pé mi ò ní yéé wàásù. (Ìṣe 4:20) Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í fọgbọ́n ṣe é. Lọ́jọ́ kan, àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ mi rí mi níbi tí mo ti ń wàásù láti ilé délé, wọ́n sì sọ fún ọkọ mi. Nígbà tí mo délé, ṣe lọkọ mi bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo mọ́ mi, ó sọ pé: “Ò ń dójú tì mí, o sì ń dójú ti ìdílé wa!” Ló bá yọ ọ̀bẹ sí mi, ó gbé e sí mi lọ́rùn. Ó sọ pé òun á pa mí tí mi ò bá yéé wàásù.

Mo bẹ ọkọ mi, mo sì jẹ́ kó dá a lójú pé mo nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Ó dà bíi pé ohun tí mo sọ yẹn fi í lọ́kàn balẹ̀ fúngbà díẹ̀. Àmọ́, nígbà tí mo kọ̀ láti lọ síbi ìgbéyàwó mọ̀lẹ́bí wa kan tí wọ́n ṣe nílé ìjọsìn, inú tún bí ọkọ mi. Ìyẹn sì mú kó máa sọ̀rọ̀ burúkú sí mi.

Ọdún mẹ́tàlá (13) gbáko ni mo fi fara da ìbínú ọkọ mi. Ní gbogbo àkókò yẹn, ó máa ń halẹ̀ mọ́ mi pé òun máa kọ̀ mí sílẹ̀. Àwọn ìgbà kan tiẹ̀ wà tó tì mí mọ́ta. Nígbà míì, á ní kí n kẹ́rù mi, kí n sì pa dà sọ́dọ̀ àwọn ẹbí mi.

Kí ló ràn mí lọ́wọ́ láwọn àkókò yẹn? Àdúrà ni. Mo bẹ Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́, kó jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀, ó sì dáhùn àdúrà mi. (Sáàmù 55:22) Àwọn ará náà ò fi mí sílẹ̀ rárá. Bí àpẹẹrẹ, àwọn alàgbà àtàwọn arábìnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ràn mí lọ́wọ́ kí n má bàa fi Jèhófà sílẹ̀. Wọ́n rán mi létí ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn aya tí wọ́n jèrè àwọn ọkọ wọn “láìsọ ohunkóhun” torí pé wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. (1 Pétérù 3:1) Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ sí mi jẹ́ kí n rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn.

Nǹkan Yí Pa Dà

Lọ́dún 2001, àìsàn rọpárọsẹ̀ ṣe ọkọ mi, kò sì lè rìn mọ́. Lẹ́yìn tó lo oṣù kan nílé ìwòsàn, ó tún lo ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń tójú àwọn tó ní àìsàn rọpárọsẹ̀. Ní gbogbo àkókò yẹn, ṣe ni mo dúró tì í. Mo máa ń fún un lóúnjẹ, mo máa ń bá a sọ̀rọ̀, mo sì rí i pé gbogbo ohun tó fẹ́ ni mò ń ṣe fún un.

Àwọn ará ìjọ náà wá kí i. Àwọn kan lára wọn bá wa ṣiṣẹ́ ilé. Àwọn alàgbà máa ń bẹ̀ wá wò, wọ́n ń tù wá nínú wọ́n sì máa ń ràn wá lọ́wọ́. Àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe yìí jẹ́ kí ọkọ mi rí ìfẹ́ tó wà láàárín wa, àti bá a ṣe máa ń ran ara wa lọ́wọ́.

Àwọn nǹkan yìí jẹ́ kó kábàámọ̀ àwọn nǹkan tó ti ṣe sí mi. Ó kíyè sí i pé yàtọ̀ sáwọn ará tó wá wò ó, kò sí ìkankan nínú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ tó wá kí i. Torí náà, nígbà tó kúrò nílé ìwòsàn, ó sọ pé, “Mo fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì fẹ́ di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Ṣe lomijé ayọ̀ ń bọ́ lójú mi bó ṣe sọ ọ̀rọ̀ yìí.

Ní May 2005, ọkọ mi ṣèrìbọmi. Torí pé kò lè rìn, ṣe làwọn arákùnrin kan ti kẹ̀kẹ́ ẹ̀ lọ sétí odò ìrìbọmi, wọ́n rọra gbé e wọnú omi, wọ́n sì ṣèrìbọmi fún un. Ọkọ mi wá di ẹni tó ń fìtara wàásù. Mo máa ń rántí àwọn àkókò mánigbàgbé tá a jọ lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ó yà mí lẹ́nu pé ọkọ mi tó máa ń ta kò mí tẹ́lẹ̀ ti wá ń wàásù fáwọn èèyàn báyìí.

Ọkọ mi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, kódà ó máa ń lo àkókò ẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì máa ń há àwọn ẹsẹ Bíbélì sórí. Ó gbádùn kó o máa jíròrò àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn pẹ̀lú àwọn ará nínú ìjọ. Ó sì máa ń lo àkókò yẹn láti fún àwọn ará níṣìírí.

István ọkọ Ibolya jókòó lórí kẹ̀kẹ́ arọ kan, wọ́n sì fẹ́ jọ ya fọ́tò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wọn.

Àwa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa ní àpéjọ agbègbè kan

Ó dùn mí pé kàkà kí ìlera ọkọ mi máa sàn, ṣe ló ń burú sí i. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn apá kan ara ẹ̀ máa ń daṣẹ́ sílẹ̀, débi pé kò lè sọ̀rọ̀ mọ́, kò sì lè dìde ńlẹ̀. Ṣé èyí wá dín ìtara ẹ̀ kù? Rárá o! Débi tágbára ẹ̀ gbé e dé, ó ṣì máa ń ka Bíbélì, ó sì ń kẹ́kọ̀ọ́. Táwọn ará bá wá kí i, ó máa ń lo ẹ̀rọ kan láti bá wọn sọ̀rọ̀, kó sì fún wọn lókun. Arákùnrin kan sọ pé: “Inú mi máa ń dùn gan-an láti rí István. Tí mo bá pa dà délé lẹ́yìn tí mo lọ rí i, ṣe lara máa ń tù mí, tí mo sì máa ń lókun.”

Ní December 2015, István ọkọ mi ọ̀wọ́n kú. Àdánù ńlá lèyí jẹ́ fún mi, ó bà mí nínú jẹ́ gan-an. Àmọ́ lápá kan, ṣe lọkàn mi tún balẹ̀ torí kí ọkọ mi tó kú, ó ti di ọ̀rẹ́ Jèhófà, èyí sì múnú mi dùn gan-an. Mo mọ̀ pé Jèhófà máa rántí ọkọ mi àti ìyá mi nígbà àjíǹde. Inú mi sì máa dùn gan an lọ́jọ́ tí mo bá gbá wọn mọ́ra, tí mo sì kí wọn káàbọ̀ sínú ayé tuntun.

Ọdún márùndínlógójì (35) ti kọjá báyìí lẹ́yìn tí èmi àti ìyá mi lọ rí ẹ̀gbọ́n wọn, mi ò sì lè gbàgbé ọjọ́ yẹn láé. Mo ti lé lẹ́ni àádọ́rin (70) ọdún báyìí, mo sì ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Èyí sì ni ọ̀nà tó dáa jù tí mo lè gbà dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fáwọn nǹkan tó ti ṣe fún mi. (Sáàmù 116:12) Nígbà tí ọkọ mi ń ṣe inúnibíni sí mi, Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ gan-an, ó jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀, ó sì jẹ́ kí n lè jẹ́ adúróṣinṣin sí i. Mo wá rí i pé láìka inúnibíni yòówù kí wọ́n máa ṣe sí wa, nǹkan lè yí pa dà. Mi ò tiẹ̀ ronú ẹ̀ rí pé ọkọ mi lè di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ mo jèrè ọkọ mi láìsọ ohunkóhun.

Ibolya àti arábìnrin kan dúró síbi àtẹ ìwé. Ibolya sì ń fi ìwé “Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!” wàásù fún obìnrin kan.
    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́