ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 1/22 ojú ìwé 30
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
  • Jí!—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 1/22 ojú ìwé 30

Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Ilé Iṣẹ́ Kátabá Ọ̀wọ́ ìtẹ̀jáde náà, “Ṣíṣekúpa Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Ènìyàn Láti Mú Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Owó Wọlé” (May 22, 1995) kún fún ẹ̀kọ́ àti òye. Àwòrán tí ó wà ní ẹ̀yìn rẹ̀ (“Agbárí Pẹ̀lú Sìgá Lẹ́nu”) láti ọwọ́ Vincent van Gogh ń bani lẹ́rù! Bóyá àwòrán yìí nìkan ṣoṣo yóò tó láti mú kí àwọn ènìyàn díẹ̀ ṣíwọ́ kátabá mímu tàbí ó kéré tán, kí ó fawọ́ àwọn díẹ̀ sẹ́yìn nínú bíbẹ̀rẹ̀ rẹ̀.

M. B., United States

Níwọ̀n bí mo ti ń ṣiṣẹ́ fún ẹgbẹ́ American Cancer Society, ní pàtàkì, mo háragàgà láti ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wọ̀nyí. Mo fi ẹ̀dà kan ránṣẹ́ sí obìnrin tí ó jẹ́ alága ẹ̀ka àdúgbò ti ẹgbẹ́ oníkátabá ọ̀fẹ́. Ìjójúlówó ìwé náà àti ìwádìí rẹ̀ wú u lórí, ó sì béèrè fún ẹ̀dà 35 fún àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.

J. O., United States

Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó oṣù mẹ́ta tí èmi àti ọkọ mi ti fi kátabá mímu sílẹ̀, ṣùgbọ́n mo ṣì tún ń ní òòfà ọkàn fún sìgá. Nígbà náà ni mo ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí, ó sì mú kí n mọ̀ pé díẹ̀ nínú àwọn èròjà tí ó wà nínú sìgá lóró tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi jẹ́ pé, ó lòdì sófin láti dà wọ́n sí kòtò pàǹtírí! Èyí fún mi lókun láti kórìíra ohun tí kò dára.

L. T., South Africa

Òjìyà Ìṣiṣẹ́gbòdì Adènà Àrùn Tí Ń Gbógun Ti Ara Rẹ̀ Ẹ ṣeun púpọ̀ fún ìsọfúnni lórí ìṣiṣẹ́gbòdì adènà àrùn tí ń gbógun ti ara rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Ní Báyìí Ó Ku Mia Ku Jehofa.” (February 22, 1995) Mo jẹ́ ọmọ ọdún 18, mo sì ti ń jìyà lọ́wọ́ àìsàn yìí fún nǹkan bí ọdún méjì. Ó ń fúnni níṣìírí láti mọ bí àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wa yòókù ní apá ibi yíyàtọ̀ síra lórí ilẹ̀ ayé ṣe ń fara da ìjìyà, kí a sì rí bí Ẹlẹ́dàá wa ṣe ń fi tìfẹ́tìfẹ́ tì wá lẹ́yìn nígbà gbogbo.

J. A. Y., Itali

Àwọn Òbí Tí Wọ́n Jẹ́ Ìṣòro Mo ti gbàdúrà fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kan bí “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Bí Àwọn Òbí Mi Bá Kùnà Ńkọ́?” (May 22, 1995) Ẹ ò rí i bí inú mi ti bàjẹ́ tí ọkàn mi sì gbọgbẹ́ tó nígbà tí a yọ ìyá mi lẹ́gbẹ́ kúrò nínú ìjọ Kristian! Mo fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣíwọ́ ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà, ìjíhìnrere alákòókò kíkún. Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà fún mi lókun láti ‘ṣiṣẹ́ ìgbàlà mi yọrí pẹlu ìbẹ̀rù ati ìwárìrì’ dípò dídààmú gidigidi nípa ìdúró Mọ́mì pẹ̀lú Jehofa. (Filippi 2:12) Ẹ ṣeun púpọ̀.

J. P., Philippines

Mo jẹ́ Kristian kan tí ó ti ṣe ìrìbọmi, ṣùgbọ́n, ó ṣòro fún mi láti bọ̀wọ̀ fún bàbá mi, tí ó máa ń yó kẹrí wá sílé lójoojúmọ́. Bí mo ti ń ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí, mo kàn ń sọkún ṣáá ni. Nísinsìnyí tí mo ti kà á, ìmọ̀lára àti ìrònú òdì mi sí bàbá mi ti dín kù gidi gan-an, inú mi sì túbọ̀ tutù pẹ̀sẹ̀.

N. M., Japan

Ìsìn Christian Science Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Àwọn Ìpàdé Àpérò Láti Mú Ipò-Ìbátan Tí Ó Wà Láàárín Àwọn Dókítà àti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Sunwọ̀n Síi” (March 22, 1995) gbé àlàyé kan jáde lórí ọ̀nà tí ìsìn Christian Science ń gbà bójú tó àìsàn. Fún ire gbígbé ìgbọ́ra-ẹni-yé ró láàárín ìsìn wa, mo fẹ́ láti mú un dá àwọn òǹkàwé yín lójú pé nípa gbígbára lé ìwòsàn tẹ̀mí, àwọn onísìn Christian Science mọrírì ìwàláàyè ènìyàn, wọ́n sì ń dáàbò bò ó gẹ́gẹ́ bí a ti gbà gbọ́ pé Kristi Jesu fi hàn wá láti ṣe. Àkọsílẹ̀ àwọn ìwòsàn tí ó ní ẹ̀rí tí a tẹ̀ jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn wa fún èyí tí ó ju ọgọ́rùn-ún ọdún lọ, fi hàn pé ìjọsìn Ọlọrun ni ìsúnniṣe wa, kì í ṣe ìjẹ́rìíkú. Ìlera nípa ti ẹ̀mí, ti ìwà híhù, àti ti ara sì máa ń jẹ́ ìyọrísí rẹ̀ nígbà gbogbo.

M. V. W., Alábòójútó, Ìgbìmọ̀ Lórí Ìtẹ̀jáde, ti The First Church of Christ, Scientist, United States

O ṣeun fún àlàyé wọ̀nyí. Ète wa ní títọ́ka sí ọ̀rọ̀ dókítà oníṣègùn kan jẹ́ láti tẹnu mọ́ òkodoro òtítọ́ náà pé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa máa ń gba ìtọ́jú ìṣègùn. Nígbà tí a bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ àwọn ẹlòmíràn láti gbà gbọ́ bí wọ́n ṣe fẹ́, Jesu Kristi sọ ní tòótọ́ pé, “awọn ẹni tí ó ní ìlera kò nílò oníṣègùn, ṣugbọn awọn tí ń ṣòjòjò nílò rẹ̀.” (Matteu 9:12) Nígbà tí Paulu sì ń jíròrò ‘ọ̀ràn àìsàn Timoteu tí ó ṣe lemọ́lemọ́,’ òun kò dámọ̀ràn ìwòsàn tẹ̀mí, ṣùgbọ́n, ó dábàá ìtọ́jú ìṣègùn tí ó wọ́pọ̀. (1 Timoteu 5:23) Nípa báyìí, ojú ìwòye Bibeli nípa ìtọ́jú ìṣègùn ta kora pẹ̀lú ẹ̀kọ́ ìsìn Christian Science.—ED.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́