Ìwà Àìlèkóra-Ẹni-níjàánu—Ó Ha Ń ṣàkóso Ìgbésí Ayé Rẹ Bí?
Keitha sọ pé: “Mo máa ń jí ní agogo mẹ́fà òwúrọ̀ lójoojúmọ́. Mo yí agogo ahangan-anran mi kí ó lè máa han gan-anran ní agogo mẹ́fà. Mo mọ̀ pé mo ti yí i síbẹ̀. N kò yí i padà kúrò níbẹ̀ rí. Síbẹ̀, mo ṣáà máa ń yẹ̀ ẹ́ wò ṣáá ni. Lálaalẹ́ ni mo máa ń wò ó, ó kéré tán, ní ìgbà márùn-ún, kí n tóó lọ sùn. Mo sì máa ń rí i dájú pé gbogbo àwọn ìkànnì sítóòfù ni mò ń yí pa. Mo lè rí i pé wọ́n ti kú, àmọ́ mo máa ń padà lọ láti lọ tún un wò ní ìgbà kan, ìgbà méjì, ìgbà mẹ́ta—kí ń ṣáà kàn lè rí i dájú. Lẹ́yìn náà ni n óò yẹ ìlẹ̀kùn fìríìjì wò, n óò tún un yẹ̀ wò léraléra, láti rí i dájú pé ó tì. Lẹ́yìn náà ni n óò wò ó bóyá ìlẹ̀kùn aláwọ̀n tì, àti bóyá àwọn ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà ilé méjèèjì tì . . .”
ÀÌSÀN àìlèkóra-ẹni-níjàánu tí kò ṣeé ṣàkóso (OCD), tí a túmọ̀ sí ipò kan tí ń múni ṣàárẹ̀, tí àwọn ìrònú (ìrònú àròkúdórógbó) àti ìṣe (ìṣe àṣekúdórógbó) tí kò ṣeé ṣàkóso máa ń jẹ́ àmì rẹ̀, ń yọ Keithb lẹ́nu. Ẹnì kan tí ó bá ní OCD máa ń nímọ̀lára pé àwọn ìrònú àròkúdórógbó àti iṣe àṣekúdórógbó yìí jẹ́ ohun tí ń wá fúnra wọn pátápátá. Ńṣe ni ó dà bíi pé wọ́n já wọlé tí wọ́n sì já àkóso gbà.
Gbogbo ènìyàn ló máa ń ní àwọn èrò àti ìfẹ́ ọkàn tí a kò fẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀kan. Ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ tí OCD ni, ìwọ̀nyí máa ń di èyí tí ó ṣe lemọ́lemọ́ àti léraléra débi tí wọ́n fi máa ń dabarú ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó wà déédéé, tí wọ́n sì máa ń fa ìsoríkọ́ jíjinlẹ̀, tí ó lè yọrí sí ìdààmú ọkàn nígbà míràn. Ẹnì kan tí ó ní in sọ pé: “Ìjàkadì tí ń lọ léraléra nínú ọpọlọ mi lọ́hùn-ún sún mi láti gbìdánwò iṣekúpara-ẹni.” Gbé díẹ̀ lára àwọn àmì àrùn rírúni lójú yìí wò.
Kí Ojú Ó Rí I Kò Sọ Pé Kí Wọ́n Gbà Á Gbọ́
Nígbà tí Bruce bá ń wa ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ gba orí gegele kan, ẹ̀rù tí ń múni ṣòjòjò kan máa ń bò ó mọ́lẹ̀ ṣíbá. Ó máa ń bi ara rẹ̀ pé, ‘Àbí mo ti gun orí ẹnì kan tí ń fẹsẹ̀ rìn kọjá ni?’ Ìmọ̀lára náà máa ń lágbára sí i débi tí yóò tilẹ̀ fi di pé yóò padà síbi tí ó ti “dáràn” náà tí yóò sì lọ yẹ̀ ẹ́ wò—kì í ṣe lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, àmọ́ léraléra! Gẹ́gẹ́ bí a ṣe lè retí, Bruce kì í rí ẹni tí ń fẹsẹ̀ rìn kankan tí ó fara pa. Síbẹ̀, kì í dá a lójú! Nítorí bẹ́ẹ̀, nígbà tí ó darí délé, yóò tẹ́tí sí ìròyìn lórí tẹlifíṣọ̀n bóyá ó lè gbọ́ nípa jàm̀bà ẹnì kan tí wọ́n gbá, tí ọlọ́kọ̀ náà sì sá lọ. Yóò tilẹ̀ ké sí àwọn ọlọ́pàá láti “jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.”
Bíi Bruce, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ní OCD ni iyè méjì ń dà láàmú: ‘Àbí mo ti pa ẹnì kan lára ni? Ǹjẹ́ mo pa sítóòfù nígbà tí mo kúrò nílé? Ǹjẹ́ mo ti ìlẹ̀kùn?’ Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn lè ní irú èrò yìí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ ẹni tí ó bá ní OCD yóò máa tún un yẹ̀wò léraléra, síbẹ̀, kò ní tẹ́ ẹ lọ́rùn. Dókítà Judith Rapoport kọ̀wé pé: “Ó dà bí ẹni pé àwọn olùgbàtọ́jú mi tí ó ṣáà máa ń yẹ nǹkan wò ṣáá ń sọ pé, ‘láti inú àwọn agbára ìmọǹkan ni rírí nǹkan dájú ti ń wá.’ Nítorí ìdí èyí, wọ́n máa ń yí ọwọ́ ìlẹ̀kùn léraléra; wọn yóò máa tanná, wọn yóò máa pa á léraléra. Àwọn ìṣe wọ̀nyí máa ń mú ìsọfúnni wá lójú ẹsẹ̀, síbẹ̀ kì í wọnú orí wọn.”
Ohun Tí Ó Mọ́ Kò Mọ́ Tó
Ìrònú àròkúdórógbó dídi ẹni tí kòkòrò àrùn ràn ti bo Charles, ọmọ ọdún 14 mọ́lẹ̀. Ó di dandan pé kí ìyá rẹ̀ nu gbogbo ohun tí ó lè fọwọ́ kàn pẹ̀lú oògùn apakòkòrò àrùn. Síwájú sí i, Charles ń bẹ̀rù pé àwọn àlejò yóò kó èèràn wọlé láti ìta.
Fran máa ń bẹ̀rù tí ó bá ń fọ aṣọ rẹ̀. Ó sọ pé: “Bí aṣọ bá kan ara ẹ̀rọ ìfọṣọ nígbà tí mo bá ń kó wọn kúrò nínú rẹ̀, mo ní láti tún wọn fọ lẹ́ẹ̀kan sí i.”
Bíi Charles àti Fran, ọ̀pọ̀ àwọn tí ó ní OCD ni wọ́n máa ń ní ìrònú àròkúdórógbó tí ó dá lórí kòkòrò àrùn àti èèràn. Èyí lè fa kí wọ́n máa wẹ̀ láwẹ̀tunwẹ̀ tàbí kí wọ́n máa fọwọ́ láfọ̀tunfọ̀, nígbà míràn, débi tí ara wọn yóò fi máa lé ròrò—síbẹ̀, aláìsàn náà kì yóò gbà pé ara òún mọ́.
Èrò Ọkàn Ń Dá Wọ́n Lóró
Àwọn èrò aláìfọ̀wọ̀hàn nípa Ọlọrun, tí ń wá fúnra wọn, ń da Elaine láàmú. Ó sọ pé: “Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ àwọn nǹkan tí n kò tilẹ̀ lè pète rẹ̀ láé, tí n óò sì gbàdúrà kí n kú dípò tí n óò fi pète rẹ̀.” Síbẹ̀, àwọn èrò náà ń wá. “Nígbà míràn, ó máa ń rẹ̀ mí taratara ní alẹ́ nígbà tí mo bá ti fi gbogbo ọjọ́ bá àwọn èrò yìí jìjàkadì.”
Ìmọ̀lára ẹ̀bi tí Steven ń ní nítorí àwọn àṣìṣe rẹ̀ sún un jẹ́ “ẹ̀jẹ́” fún Ọlọrun. Ó sọ pé: “Ìfẹ́ láti ṣe èyí máa ń bà mi nínú jẹ́, nítorí pé ó dà bíi pé ó ń wá lòdì sí ìfẹ́ ọkàn mi. Lẹ́yìn náà, ẹ̀rí ọkàn mi máa ń gún mi ní kẹ́ṣẹ́ láti ṣe ohun tí mo jẹ́jẹ̀ẹ́. Nítorí èyí, ó di ọ̀ràn-anyàn fún mi láti ba ohun kan tí mo fẹ́ràn gidigidi jẹ́ nígbà kan.”
Elaine àti Steven ní ìrònú àròkúdórógbó tí ó jẹ́ pé lọ́kàn wọn nìkan ló máa ń wà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ènìyàn kò lè tètè kíyè sí àmì àrùn wọn, àwọn tí wọ́n ní èrò àròkúdórógbó wà nínú àhámọ́ ìmọ̀lára ẹ̀bi àti ìbẹ̀rù.
Díẹ̀ ni ìwọ̀nyí jẹ́ lára ọ̀pọ̀ àmì àrùn OCD.c Kí ní ń fa àrùn yìí? Báwo ni a ṣe lè pẹ̀rọ̀ sí i díẹ̀?
Ṣíṣàkóso Ohun Tí Kò Ṣeé Ṣàkóso
Dókítà kan sọ pé “àìlọgeerege ìṣiṣẹ́ ọpọlọ” nínú èyí ti ìsọfúnni iṣan ara kì í ti í wọlé, tí “ètò náà yóò sì máa ká lọ ká bọ̀” ní ń fa ìwà OCD. Kí ló ń fa àyílọyíbọ̀ yìí? Kò sí ẹni tó dá lójú. Ó dà bí ẹni pé ó ní í ṣe pẹ̀lú èròjà serotonin tí ń gbé ìsọfunni káàkiri nínú ọpọlọ, ṣùgbọ́n àwọn kan sọ pé o ní í ṣe pẹ̀lú àwọn apá míràn nínú ọpọlọ pẹ̀lú. Àwọn kan sọ pé àwọn ìrírí tí ènìyàn ní ní ìgbà kékeré lè ru OCD sókè nínú ènìyàn, àti bóyá pẹ̀lú àṣà tí ènìyàn jogún bá.
Bí ó ti wù kí ó ri, ohun yòówù kí ó jẹ́ okùnfà rẹ̀, òtítọ́ kan ṣe kedere pé: Kìkì sísọ fún àwọn tí ó ní OCD láti má ṣe fọ nǹkan mọ́ tàbí kí wọ́n má ṣe yẹ nǹkan wò mọ́ lè má ṣe nǹkan kan. Ohun tí ń ṣe wọ́n ju agbára wọn lọ.
Egbòogi tí ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́. Ọ̀nà míràn ni láti ṣi ẹni náà payá sí ipo tí ó máa ń bẹ̀rù, kí ènìyàn sì má jẹ́ kí ó ṣe bí ó ti máa ń ṣe. Fún àpẹẹrẹ, a lè sọ pé kí ẹnì kan tí ó ti di àṣà rẹ̀ láti máa fọ nǹkan mú ohun tí ó dọ̀tí lọ́wọ́, kí á sì máà jẹ́ kí ó fọ̀ ọ́. Ó dájú pé irú ìwòsàn bẹ́ẹ̀ kò ní wo ẹni náà sàn ní ọ̀sán kan, òru kan. Ṣùgbọ́n tí a bá tẹpẹlẹ mọ́ ọn, àwọn kan gbà pé ó lè pèsè ìtura.
Àwọn ògbógi tún ti wádìí pé àfàìmọ̀ kí OCD má ti jẹ jáde láti inú ìrírí ìgbà ọmọdé, ó kéré tán nínú ọ̀ràn àwọn kan. Wọ́n ti ṣàkíyèsí pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tí a lò nílòkulò máa ń nímọ̀lára àìníláárí tàbí ti ẹni tí ó dọ̀tí, tí ó di ara wọn nígbà tí wọ́n bá dàgbà, irú àwọn ọmọ báwọ̀nyí sì ti tipa bẹ́ẹ̀ mú àṣà fífọ nǹkan láfọ̀kúdórógbó dàgbà.
Ìtura Kúrò Lọ́wọ́ Ìrònú Àròkúdórógbó àti Ìṣe Àṣekúdórógbó
Bí o bá ní OCD, má ṣe nímọ̀lára pé o yàtọ̀ tàbí pé bóyá orí rẹ ń yí. Ọ̀mọ̀wé Lee Baer kọ̀wé pé: “Yàtọ̀ sí ẹ̀rù tí ó máa ń bà wọ́n, orí àwọn ènìyàn tí wọ́n ní OCD ṣì pé pérépéré pẹ̀lú àwọn apá ìgbésí ayé wọn mìíràn.” O lè rí ìrànlọ́wọ́! Rántí pé àìpé ló fa OCD. Kì í ṣe àmì àìlera ti ìwà híhù tàbí ti ìkùnà tẹ̀mí! Bẹ́ẹ̀ ni kò sì túmọ̀ sí àìní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọrun. “Oluwa ni aláàánú àti olóore, ó lọ́ra àtibínú, ó sì pọ̀ ní àánú. Nítorí tí ó mọ ẹ̀dá wa; ó rántí pé erùpẹ̀ ni wa.”—Orin Dafidi 103:8, 14.
Àmọ́ bí àwọn ìrònú àròkúdórógbó bá dà bí èyí tí kò fi ọ̀wọ̀ hàn tàbí tí ó jẹ́ ẹlẹ́gbin ńkọ́? Tí ènìyàn bá ní OCD, àwọn èrò tí kò tọ̀nà yóò máa tapo sí ìmọ̀lára ẹ̀bi, ìmọ̀lára ẹ̀bi sì tilẹ̀ lè wá máa tapo sí èrò tí kò tọ̀nà sí i. Elaine sọ pé: “Ó máa ń jẹ́ kí ará kan mí. Ó máa ń jẹ́ kí ara mi gbẹ̀kan—tí n óò sì máa ronú nígbà gbogbo pé Jehofa lè máa bínú sí mi.” Àwọn kan tilẹ̀ lè rò pé èrò àwọn tó ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì!
Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣe kedere pé ọ̀rọ̀ tí Jesu sọ nípa ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì, ẹ̀ṣẹ̀ lòdì sí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun, kò tọ́ka sí àwọn ìrònú aláìmọ̀ọ́mọ̀, àròkúdórógbó. (Matteu 12:31, 32) Jesu dojú ọ̀rọ̀ rẹ̀ kọ àwọn Farisí. Ó mọ̀ pé wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ń ṣe gbogbo àtakò tí wọn ń ṣe ni. Àwọn ìṣe àmọ̀ọ́mọ̀ṣe wọn wá láti inú ọkàn tí ìkórìíra kún.
Ní tòótọ́, àníyàn tí ènìyàn ń ṣe nípa pé bóyá ènìyàn ti ṣẹ Ọlọrun lè jẹ́ ẹ̀rí pé ènìyàn kò tí ì dá ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì. (Isaiah 66:2) Síwájú sí i, ó ń tuni lọ́kàn láti mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá lóye àrùn yìí. Òun jẹ́ aláàánú, ó sì “múra àtidárí jì.” (Orin Dafidi 86:5; 2 Peteru 3:9) Àní nígbà tí ọkàn àwa fúnra wa bá ń dá wa lẹ́bi pàápàá, “Ọlọrun tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ ó sì mọ ohun gbogbo.” (1 Johannu 3:20) Ó mọ bí àrùn tí ènìyàn kò lè ṣàkóso pátápátá ṣe lè fa ìrònú àti ìfẹ́ ọkàn tó. Tí ẹni tí OCD ń ṣe bá mọ èyí, ó lè tipa bẹ́ẹ̀ yẹra fún bíba ara rẹ̀ nínú jẹ́ pẹ̀lú ìmọ̀lára ẹ̀bi tí kò nídìí.
Ẹ wo bí a ti lè kún fún ọpẹ́ tó pé Jehofa ṣèlérí ayé tuntun kan nínú èyí tí ìtura yóò wà kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ìnira ti ara, ti ọpọlọ, àti ti ìmọ̀lára! (Ìṣípayá 21:1-4) Kí ó tó di àkókò náà, àwọn tí ó di dandan fún kí wọ́n fara da àrùn yìí lè gbé ìgbésẹ̀ tí ó níláárí láti mú kí ìrora wọ́n dín kù.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí.
b Jí! kò dábàá irú ìtọ́jú ìwòsàn pàtó kankan. Ó yẹ kí àwọn Kristian tí wọ́n bá ní àìsàn yìí ṣọ́ra, kí ó máà baà jẹ́ pé ìwòsàn tí wọ́n yàn yóò ta ko àwọn ìlànà Bibeli.
c Àwọn àmì díẹ̀ míràn ni kíka nǹkan tàbí kíkó nǹkan jọ tàbí ríronú àròkúdórógbó nípa mímú kí nǹkan wà lọ́gbọọgba.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]
Láti Pèsè Ìtìlẹ́yìn
GẸ́GẸ́ bi ọ̀rẹ́ tàbí mẹ́ḿbà ìdílé, o lè ṣe púpọ̀ láti ti ẹnì kan tí ń bá àrùn àìsàn àìníjàánu tí kò ṣeé ṣàkóso (OCD) wọ̀yá ìjà lẹ́yìn.
• Lákọ̀ọ́kọ́, yẹ ìṣarasíhùwà ìwọ fúnra rẹ wò. Bí o bá gbà gbọ́ pé aláìsàn náà kò lera, pé ó ya ọ̀lẹ, tàbí pé ó lágídí, ó dájú pé yóò rí èyí nínú ìṣarasíhùwà rẹ, a kò sì ní sún un láti ṣàtúnṣe.
• Bá aláìsàn náà sọ̀rọ̀. Mọ ohun tí ó ń bá wọ̀yá ìjà. Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ tí aláìsàn náà yóò gbé síhà ṣíṣàkóso àmì àrùn OCD ni níní alábàárò kan tí kì í fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, tí ó sì jẹ́ olóòótọ́.—Owe 17:17.
• Má ṣe máa fi wé ẹlòmíràn. Àrùn OCD máa ń mú àwọn ìfẹ́ ọkàn tí ó lágbára jáde, tí kò jọ irú èyí tí àwọn tí kò ní in máa ń ní. Nítorí náà, kì í gbéṣẹ́ láti máa sọ bí o ṣe kojú àwọn ìfẹ́ ọkàn tìrẹ.—Fi we Owe 18:13.
• Ran aláìsàn náà lọ́wọ́ láti gbé àwọn góńgó kalẹ̀, kí o sì lé wọn bá. Yan àmì àrùn kan, kí ó sì lapa ọ̀wọ́ àwọn góńgó kan láti kápá rẹ̀. Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú góńgó tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣòroó lé bá. Fún àpẹẹrẹ, góńgó kan lè jẹ́ pé kí ó má wẹ̀ ju ìwọ̀n àkókò pàtó kan lọ.
• Gbóríyìn fún un fún ìlọsíwájú tí ó ní. Oríyìn máa ń fún ìwà tí ó dára lókun. Gbogbo ìgbésẹ̀ ìtẹ̀síwájú—bí ì báà ti wù kí ó kéré tó—ṣe pàtàkì.—Owe 12:25.
Gbígbé pẹ̀lú aláìsàn OCD lè jẹ́ ohun tí ń tán ìmọ̀lára àwọn mẹ́ḿbà ìdílé lókun. Nítorí náà, àwọn ọ̀rẹ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí ó lóye, tí ó sì ń tini lẹ́yìn ní gbogbo ọ̀nà tí ó gbéṣẹ́, tí wọ́n bá lè ṣe é.—Owe 18:24b.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Yíyẹ nǹkan wò láyẹ̀wòkúdórógbó àti fífọ nǹkan láfọ̀kúdórógbó —méjì nínú àwọn àmì àrùn OCD