“Ká Ní Mo Lè Yí Ìgbà Padà Ni”
WỌ́N ní kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ kan ní California, U.S.A., kọ àròkọ lórí àkọlé tí ó wà lókè yìí. Eric, ọmọkùnrin ọlọ́dún 11 tí ó wá láti ìdílé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn aláṣekágbá tí ó kópa nínú ìdíje náà. Ó kọ àròkọ tí a gbé ka orí Bibeli, tí ó tẹ̀ lé e yìí.
“Ogun Àgbáyé Kejì jẹ́ ogun gbẹ̀mígbẹ̀mí. Ọ̀pọ̀ àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ ni ó kú. Ṣùgbọ́n ká ní mo lè yí ìgbà tí mo yàn padà ni, ogun náà ì bá tí ṣẹlẹ̀, tí a kò sì ní kọ nípa rẹ̀ sínú àwọn ìwé ọ̀rọ̀ ìtàn. Ronú nípa ikú tí a ṣe pa John F. Kennedy. Ọkùnrin yìí kú ikú ẹ̀sín, ṣùgbọ́n ká ní mo lè yí ìgbà tí mo yàn padà ni, èyí pẹ̀lú ì bá tí sí nínú àwọn ìwé ìtàn rárá. Martin Luther King, Jr., kú ní 1968, nítorí pé ó ń gbìyànjú láti yí ìrònú aráyé padà, ṣùgbọ́n ìgbà tí mo yàn ì bá ti yí àkókò yìí pẹ̀lú padà. Ká ní mo lè yí ìgbà yìí padà ni, ayé ì bá yàtọ̀, gbogbo ohun tí a ń rí ì bá yí padà, ohun gbogbo tí a sì mọ̀, títí kan ipò nǹkan àti àwọn ènìyàn, ì bá yàtọ̀. Ìgbà tí èyí ṣẹlẹ̀ gan-an, ipa ọ̀nà ọ̀rọ̀ ìtàn yí padà, ó sì sọ ayé di bí a ṣe mọ̀ ọ́n lónìí—gbẹ̀mígbẹ̀mí, oníwà ipá, oníwà ìbàjẹ́, àti aburú.
“Ó dára, ìwọ́ lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ṣe àrùn ni ìgbà yìí ni? Ṣé ìṣàkóso kan ni ìgbà yìí ni? Tàbí ṣe ogun ni ìgbà yìí ni?’ Bi ara rẹ léèrè pé, ‘Bí ó bá jẹ́ àrùn ni, báwo ni ó ṣe lè dènà kí ìṣe àwọn ọmọ ènìyàn máà jẹ́ búburú?’ Ìwọ́ lè sọ pé, ‘Kò lè jẹ́ bẹ́ẹ̀.’ Lẹ́yìn náà, o lè wá ronú pé, ‘Ó ní láti jẹ́ ìṣàkóso kan tí yóò yanjú gbogbo ìṣòro wa ni.’ Ṣùgbọ́n ènìyàn ní ń darí ìṣàkóso kan, gbogbo ènìyàn ló sì jẹ́ aláìpé, tí wọ́n sì ń kú. Nítorí náà, àwọn iṣẹ́ rere wọn kò ha ní kú pẹ̀lú wọn bí? Lẹ́yìn náà, o lè wá sọ pé, “Ó ní láti jẹ́ ogun kan tí ó dà bí Ogun Àgbáyé Kejì ni.’ Rárá! Kò lè jẹ́ ìyẹn nítorí pé ìhà kan ni ó máa ń borí nínú ogun, pẹ̀lú ìyẹn, ìhà kejì yóò pàdánù. Kò sí èyíkéyìí lára àwọn ohun tí a mẹ́nu kàn yìí tí yóò mú ikú, ìwà ipá, ìwà ìbàjẹ́, àti ìwà búburú kúrò. O lè máa ṣe kàyéfì nípa ohun tí ìgbà tí mo fẹ́ láti yí padà yìí jẹ́.
“Ẹ̀ṣẹ̀. Ikú. Ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ni àwọn ohun tí n óò yí padà. Ṣùgbọ́n lọ́nà wo? Ó ti pẹ́ tí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ti wà lórí wa. Ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú jẹ́ apá kan ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́. Nígbà náà, báwo ni o ṣe lè yí ohun tí ó ti wà lórí wa padà? Ìwọ yóò ní láti dá a dúró ní ìgbà tí ó bẹ̀rẹ̀. Ìṣọ̀tẹ̀ Adamu àti Efa sí ìṣàkóso Ọlọrun ni ó mú kí àwọn nǹkan máa rí bí ó ti rí lónìí. Àwọn tí ọ̀ràn kàn yàn láti máa ṣe nǹkan bí wọ́n ṣe fẹ́, a sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú wá.
“Nítorí náà, ìgbà náà gan-an tí a óò ní láti yí padà ni ìgbà tí Satani Eṣu pa irọ́ àkọ́kọ́ mọ́ ìṣàkóso pípé yẹn. Irọ́ yìí ni ó mú kí gbogbo wa máa jìyà ohun tí àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Adamu àti Efa, ṣe. Wọ́n ṣẹ̀ sí Aṣáájú ìṣàkóso tòótọ́ kan ṣoṣo náà, Ọlọrun.”
Ní Saturday, August 12, 1995, Eric ka àròkọ rẹ̀ ní ọjọ́ àpéjọ àkànṣe ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Norco, California. Inú àwùjọ náà dùn láti gbọ́ nípa bí èwe kan ṣe lo àǹfààní kan ní ilé ẹ̀kọ́ láti ṣe ìjẹ́rìí amúnironújinlẹ̀ kan nípa okùnfà ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn. Ẹ wo bí yóò ti pabambarì tó nígbà tí Jehofa Ọlọrun bá pa “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ naa” run, tí yóò sì mú gbogbo ìjìyà tí ń wá láti ọwọ́ Eṣu kúrò!—Ìṣípayá 12:9; 21:3, 4; Genesisi 3:1-6.