Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
PMS Ó yẹ kí ń fi ìmọrírì àtọkànwá mi hàn fún yín fún títẹ̀ tí ẹ tẹ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ nipa “Àkópọ̀ Àmì-Àrùn Ìṣáájú Rírí Nǹkan Oṣù—Ìtàn Àròsọ Ni Tàbí Òtítọ́?” (August 8, 1995) Mo ti gbàdúrà fún irú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí n kò ti lóye ìdí rẹ̀ tí mo fi máa ń ní ìmọ̀lára tí ń dà mí láàmú bẹ́ẹ̀ lóṣooṣù. Nígbà tí mo ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, ara tù mí; mo ti wá mọ̀ nísinsìnyí pé ìṣòro mi kì í ṣe nítorí àìlera tẹ̀mí.
Y. E., Jàmáíkà
Mo ti ń ní PMS fún ìgbà pípẹ́ gan-an, àmọ́ mo máa ń gbé e kúrò lọ́kàn nígbà gbogbo gẹ́gẹ́ bí ohun kan tí mo ní láti kojú. Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí ràn mí lọ́wọ́ láti wá mọ̀ pé PMS jẹ́ ìṣòro gidi kan, èyí tí ó yẹ ní ohun tí àá jíròrò.
Y. M., England
Fún nǹkan bí ọdún 12, PMS mi ti fa ìdààmú púpọ̀ fún ọmọ mi àti ọkọ mi. Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí ṣàlàyé àwọn àmì àrùn náà yékéyéké! Ohun tí ó tilẹ̀ mú mi láyọ̀ ni ìhùwà padà ọkọ mi tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, tí ó tí máa ń bẹnu àtẹ́ lu Jí! lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, ó sì sọ pé, ‘Inú mi dùn pé ọwọ́ wa tẹ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí.’
K. O., Japan
Panṣágà Ẹ ṣeun púpọ̀ fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Ojú-Ìwòye Bibeli: Panṣágà—Ṣé Kí N Dáríjì Í Tàbí Kí N Máṣe Dáríjì Í?” (August 8, 1995) Lẹ́yìn tí ọkọ mi ti fìyà jẹ mi fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, mo jáwèé fún un lọ́nà tí ó bá ìlànà Ìwé Mímọ́ mu. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn kan jẹ́ kí ó máa ṣe mi bíi pé mo jẹ̀bi fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀, mo sì ní láti bá ìmọ̀lára yìí jà fún ọ̀pọ̀ ọdún. Mo tilẹ̀ ronú pé Jehofa ti kọ̀ mí sílẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí sọ nípa ọ̀pọ̀ lára àwọn ìmọ̀lára mi, ó sì ti fún mi ní ìṣírí lọ́pọ̀lọpọ̀.
A. K., Czech Republic
Agọ̀ Áfíríkà Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yín, “Ohun Tí Agọ̀ náà Túmọ̀ Sí” (August 8, 1995), ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ gan-an ni. Ẹ sọ níbẹ̀ pé àwọn Kristian tòótọ́ kò ní ní irú agọ̀ bẹ́ẹ̀ nílé. Ṣùgbọ́n, àwọn agọ̀ tí wọ́n ń ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀ṣọ́ tàbí tí wọn kò tí ì lò fún ète ti ìsìn rí ńkọ́?
J. A., United States
Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wa ní pàtó dá lórí àwọn agọ̀ tí a ṣe fún ète ti ìsìn èké. A gbà pé “ìyàtọ̀ ńlá kan wà láàárín àwọn agọ̀ tí a ń lò nínú ìjọsìn àti àwọn àpẹẹrẹ àwòrán tí a gbẹ́ fún àwọn ilé-iṣẹ́ tí ń bójútó ìrìn-àjò afẹ́.” Ní àwọn ilẹ̀ apá Ìwọ̀ Oòrùn ayé, irú àwọn agọ̀ tí à ń ṣe láti tà bẹ́ẹ̀ kò ní ohunkóhun í ṣe pẹ̀lú ìsìn rárá, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ní gbogbogbòò lè wò wọ́n gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọnà. Kristian kọ̀ọ̀kan nígbà náà ni yóò ṣe ìpinnu ti ara rẹ̀, yálà òun yóò fi irú agọ̀ bẹ́ẹ̀ ṣe ilé òun lọ́ṣọ̀ọ́, tí yóò sí fi ipa tí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè ní lórí ẹ̀rí ọkàn àwọn mìíràn sọ́kàn. (1 Korinti 10:29)—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.
Ẹranko Rhinoceros Mo fẹ́ láti fi ìmọrírì mi hàn, kí n sì kan sáárá sí yín fún lílè sọ ìsọfúnni tí kò já mọ́ nǹkan kan di ohun tí ó gbádùn mọ́ni—àní fún ẹnì kan bíi tèmi tí kì í kàwé fún ìgbádùn. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ka “Ẹranko Tí Ó Ni Àwọn Ìwo Tí Ó Níyelórí Wọ̀nyẹn” (August 8, 1995), tán ni. Lọ́pọ̀ ìgbà, mo máa ń bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ báwọ̀nyí nítorí pé ó di dandan fún mi láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni. Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ẹnu máa ń yà mi nípa bí wọ́n ti gbádùn mọ́ mi láti kà tó lọ́pọ̀ ìgbà!
J. M., United States
Ìtàn Celeste Jones Ó ti pé ọdún 17 tí mo ti ń ka àwọn ìwé ìròyìn yín. Lẹ́yìn tí mo ka ìrírí Celeste Jones nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Bí Mo Ṣe Jàǹfààní Láti Inú Àbójútó Ọlọrun” (June 22, 1995), ó di dandan pé kí n kọ̀wé, kí ń sì fi ìmọrírì mi hàn.
M. M., Colombia
Celeste Jones kú ní October 27, 1995. Ṣaájú kí ó tó kú, ó gba ọ̀pọ̀ lẹ́tà láti ọ̀dọ̀ àwọn òǹkàwé káàkiri àgbáyé, tí wọ́n ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún sísọ ìrírí ara rẹ̀.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.