Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Wíwo Ayé Ìwé ìròyìn yín túbọ̀ ń runi lọ́kàn sókè sí i. Wọ́n ń jíròrò onírúurú kókó ẹ̀kọ́—àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́, eré ìdárayá, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. “Wíwo Ayé” ń runi lọ́kàn sókè gan-an. Mo lérò pé bí a bá gbé àwọn ìròyìn orí tẹlifíṣọ̀n karí apá fífani mọ́ra yìí, yóò túbọ̀ máa runi lọ́kàn sókè sí i.
R. S., Itali
Mo mọrírì àwọn kókó tí ẹ máa ń kọ sínú “Wíwo Ayé” gan-an. Ọ̀kan tí ó nítumọ̀ sí mi dájúdájú wà nínú ìtẹ̀jáde April 22, 1995. Àkòrí rẹ̀ ni “Kí Ní Ń Sọ Àwọn Olùkọ́ Di Gbajúmọ̀?” Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà sọ pé, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kì í fi bẹ́ẹ̀ yan olùkọ́ tí ń fúnni ní iṣẹ́ àmúrelé tí kò tó nǹkan láàyò, ṣùgbọ́n wọ́n fẹ́ràn àwọn olùkọ́ tí wọ́n jẹ́ onínúure, alánìíyàn, tí wọn kì í sì í ṣojúsàájú. Bí ó ti rí gan-an nìyẹn! Mo ti ní ìrírí púpọ̀ pẹ̀lú àwọn olùkọ́ tí ń ṣojúsàájú fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n gbajúmọ̀ kí àwọn pẹ̀lú lè gbajúmọ̀. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, irú àwọn olùkọ́ bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ gbajúmọ̀ mọ́. Ẹ ṣeun lẹ́ẹ̀kan sí i fún ìsọfúnni ṣíṣeyebíye yìí.
L. K., United States
Àwọn Ìsọtẹ́lẹ̀ Èké Ẹ ṣeun fún àwọn ọ̀wọ́ náà “Ìsọtẹ́lẹ̀ Èké Tàbí Àsọtẹ́lẹ̀ Tòótọ́—Báwo Ni O Ṣe Lè Mọ Ìyàtọ̀?” (June 22, 1995) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli fún ọdún 42, mo sì ti gbìyànjú láti lóye àwọn ìsọfúnni nípa àmì àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, mo lè sọ pé àlàyé kedere tí ẹ ṣe nípa gbogbo ìwé mímọ́ lórí kókó ẹ̀kọ́ yìí ràn mí lọ́wọ́ ní ti gidi. Ẹ mú kí kókó ẹ̀kọ́ yìí túbọ̀ rọrùn láti rántí. Àgbàyanu oúnjẹ tẹ̀mí ni!
M. B., United States
Jíjalè Mo jẹ́ ọmọ ọdún 13, ìṣòro tí mo máa ń ní tẹ́lẹ̀ rí sì ni olè jíjà. Mo máa ń jí owó, tàbí kí n lọ sí ilé ìtajà láti jí ṣingọ́ọ̀mù. Mo fẹ́ láti jáwọ́, ṣùgbọ́n kò sí ohun tí ó ràn mí lọ́wọ́ àyàfi ìgbà tí mo gba Jí! ti June 22, 1995, tí mo sì ṣí i síbi ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . “Ti Àìjalè Ti Jẹ́?” Ó mú mi lọ́kàn gidigidi. Ó ràn mí lọ́wọ́ láti gbàdúrà sí Jehofa, kí n sì mọ̀ pé òun yóò dárí jì mí lọ́nà gbígbòòrò. Mo fẹ́ láti wà nínú Ìjọba Ọlọrun, mo sì mọ̀ pé àwọn ènìyàn tí wọ́n bá ń jalè kò ní sí níbẹ̀. Ẹ ṣeun fún títẹ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí jáde.
J. A., Kánádà
Mo jẹ́ ọmọ ọdún 23, mo sì wà ní ìtìmọ́lé nítorí jíjalè. Ó bẹ̀rẹ̀ nítorí ìkìmọ́lẹ̀ ojúgbà. Wọ́n fẹ́ kí n ṣe wàyó fún ẹnì kan, láti ibẹ̀ sì ni ọ̀rọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í burú sí i. Òtítọ́ gidi ni ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà. Mo kàn nírètí pé kí àwọn ọ̀dọ́ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn náà kí ó tó pẹ́ jù ni. Lọ́nà yẹn, wọ́n lè yẹra fún bíbá ara wọn níbi tí mo wà—ọgbà ẹ̀wọ̀n.
M. S., United States
Ìtàn Ìgbésí Ayé Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ parí kíka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Bí Mo Ṣe Jàǹfààní Láti Inú Àbójútó Ọlọrun.” (June 22, 1995), ni. Kíkà nípa bí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé Celeste Jones ṣe hùwà burúkú sí i—tí ó sì di ìgbàgbọ́ rẹ̀ mú, tí ó sì forí tì í síbẹ̀—mú kí n ṣèlérí pé, n óò gbìyànjú gidigidi láti má ṣe ṣàròyé nípa àwọn ìṣòro ìlera mi mọ́ rárá.
J. P., United States
Èmi gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ya abirùn tó Celeste Jones, mo ní ìmọ̀ ráńpẹ́ nípa ìgboyà tí ó gbà á láti di ìdúróṣinṣin mú. Ọpẹ́ pàtàkì fún gbogbo àwọn tí wọ́n ti ṣèrànwọ́ fún Celeste lábẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì ti pèsè àbójútó tí ó pọn dandan fún un nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀.
W. R., Kánádà
Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà mú mi lọ́kàn. Ó fún ìgbàgbọ́ mi lókun, ó sì ràn mí lọ́wọ́ láti mọ̀ pé ọ̀nà gbígbéṣẹ́ jù lọ láti ran àwọn aládùúgbò wa lọ́wọ́ ni láti wàásù fún wọn lọ́nàkọnà tí ó bá ti ṣeé ṣe.
P. H. P., Nigeria
Ìrírí Celeste nípa lórí ìmọ̀lára mi gan-an, ó sì fún mi níṣìírí. Mo ti ń darúgbó, mo sì ń nírìírí gbogbo ìsánra àti ìrora tí ń bá ọjọ́ ogbó rìn, ṣùgbọ́n ìrírí rẹ̀ ń fún mi ní okùn púpọ̀ sí i láti máa fara dà á.
M. R., Jàmáíkà