Òmìnira Ọ̀rọ̀ Sísọ Nínú Ilé—Ipò Tí Yóò Dá Wàhálà Sílẹ̀ Ni Bí?
NÍGBÀ tí ẹnì kan bá kébòòsí “Iná!” tí kò sí nínú gbọ̀ngàn ìwòran kan tí èrò kún fọ́fọ́, tí a sì tẹ àwọn kan pa níbi tí wọ́n ti ń gbékú tà láti sá là, kò ha yẹ kí ẹni tí ó pariwo náà gbé ẹrù ẹ̀bi nítorí àwọn tí wọ́n kú àti àwọn tí wọ́n fara pa? Nígbà tí ẹnì kan bá sọ pé, “N kò fara mọ́ ohun tí o sọ, àmọ́ n óò gbèjà ẹ̀tọ́ rẹ láti sọ ọ́,” ìyẹn ha fún ọ ní agbára kíkún, òmìnira tí kò láàlà, láti sọ ohunkóhun tí ó bá wù ọ́ ní gbangba, láìka ìyọrísí rẹ̀ sí bí? Àwọn kan wà tí wọ́n ronú bẹ́ẹ̀.
Fún àpẹẹrẹ, ní ilẹ̀ Faransé, nígbà tí àwọn akọrin ọlọ́rọ̀ wótòwótò jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún pípa àwọn ọlọ́pàá, tí àwọn kan tí wọ́n gbọ́ orin náà sì pa àwọn ọlọ́pàá, ó ha yẹ kí a di ẹrù ẹ̀bi náà karí àwọn akọrin ọlọ́rọ̀ wótòwótò náà fún ríru àwọn ènìyàn sí ìwà ipá bí? Tàbí ó ha yẹ kí a dáàbò bò wọ́n lábẹ́ àbádòfin ẹ̀tọ́ bí? Nígbà tí àwọn agbóhùnsáfẹ́fẹ́ lórí rédíò àti tẹlifíṣọ̀n àti àwọn ìsokọ́ra kọ̀m̀pútà bá mú kí àwọn ìran oníwà ipá àti arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àwọn ọmọdé, tí àwọn díẹ̀ lára wọ́n fi àwọn ìran wọ̀nyí dánra wò pẹ̀lú ìyọrísí pípa àwọn àti àwọn ẹlòmíràn lára, ó ha yẹ kí àwọn tí wọ́n gbé irú ohun bẹ́ẹ̀ sáyé ru ẹrù ẹ̀bi náà bí?
Ìwé ìròyin U.S.News & World Report sọ pé, ìwádìí kan láti ọwọ́ Ẹgbẹ́ Afìṣemọ̀rònú Òun Ìhùwà ti America “ṣírò pé ọmọ kan, tí ń wo tẹlifíṣọ̀n fún wákàtí 27 lọ́sẹ̀, yóò wo 8,000 ọ̀ràn ìpànìyàn àti 100,000 ọ̀ràn ìwà ipá láti ọmọ ọdún 3 sí 12.” Àwọn òbí ha lè fọwọ́ rọ́ èyí sẹ́yìn lọ́nà ẹ̀tọ́ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó ní ipa ṣákálá lórí àwọn ọmọ wọn bí? Tàbí ó ha lè kan “ewu tí ó fara hàn gbangba tí ń ṣẹlẹ̀ ní lọ́wọ́lọ́wọ́” bí? Ìhín ha ni a gbọ́dọ̀ pààlà sí ni tàbí kí a fòpin sí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ?
Ìwádìí kan tí àwọn afìṣemọ̀rònú-ẹ̀dá ní yunifásítì ṣe fi hàn pé nígbà tí a ń fi àwọn àwòrán ẹ̀fẹ̀ “àwọn àgbà akọni abìjà” hàn déédéé fún àwùjọ àwọn ọmọ ọlọ́dún mẹ́rin kan, tí a sì ń fi “àwòrán ẹ̀dá píparọ́rọ́” hàn fún àwùjọ mìíràn, ó túbọ̀ ṣeé ṣe kí àwọn tí wọ́n wo ìjàkadì àwọn akọni máa gbá nǹkan, kí wọ́n sì ju nǹkan lẹ́yìnwá ìgbà náà. Bẹ́ẹ̀ sì ni ipa tí ìwà ipá orí tẹlifíṣọ̀n ní kì í pa rẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá kúrò ní ọmọdé. Lẹ́yìn ṣíṣàkíyèsí 650 ọmọdé láti 1960 sí 1995, ní gbígbé àṣa wíwo tẹlifíṣọ̀n àti ìwà wọn yẹ̀ wò, ìwádìí mìíràn ní yunifásítì rí i pé, àwọn tí wọ́n ń wo eré tẹlifíṣọ̀n tí ó níwà ipá jù lọ nígbà ọmọdé dàgbà di oníjàgídíjàgan, títí kan lílo alábàágbéyàwó nílòkulò àti mímutí yó wakọ̀.
Bí àwọn ọmọdé kan kò bá tilẹ̀ ní gba ipa tí tẹlifíṣọ̀n àti sinimá ní lórí wọn, àwọn kan yóò gbà á. Ní 1995, Children Now, ẹgbẹ́ aṣètìlẹ́yìn kan ní California, ṣèwádìí lórí àwọn 750 ọmọdé, tí ọjọ́ orí wọn wà láti ọdún 10 sí 16. Ìwádìí náà fi hàn pé, mẹ́fà nínú mẹ́wàá sọ pé ìbálòpọ̀ orí tẹlifíṣọ̀n ń nípa lórí àwọn ọmọdé láti ní ìbálòpọ̀ nígbà tí ọjọ́ orí wọ́n ṣì kéré jù.
Àwọn kan lè jiyàn pé àwọn ọmọdé kò lè fojú bí nǹkan ti rí gan-an wo ìwà ipá orí tẹlifíṣọ̀n àti sinimá àti pé gbogbo àwọn sinimá ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ kò ní ipa lórí wọn. Ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Britain kan sọ pé: “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, èé ṣe tí àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ kan ní agbedeméjì ìwọ̀ oòrùn America ṣe ní láti wí fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọdé pé kò sí Àwọn Èwe Ìjàpá Ninja Ayírapadà nínú àwọn kòtò ọ̀gbàrá tí ó wà ládùúgbò. Àwọn ọmọdé kan tí wọ́n jẹ́ olólùfẹ́ Ìjàpá ti ń rá kòrò lọ sínú kòtò náà láti wò wọ́n, ìdí nìyẹn.”
Lónìí, àríyànjiyàn gbígbóná kan ń dìde lórí ohun tí àwọn kan kà sí ìyàtọ̀ kedere láàárín òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ àti ìwà ipá tí ọ̀rọ̀ lórí ìgbógunti ìṣẹ́yún ní àwọn ibi púpọ̀ ní United States fà. Àwọn olùgbógunti ìṣẹ́yún ṣàròyé ní gbangba pé apànìyàn ni àwọn dókítà àti àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìtọ́jú aláìsàn tí ń ṣẹ́yún fúnni, kò sì tọ́ fún àwọn fúnra wọn láti wà láàyè. Àwọn díẹ̀ tí wọ́n jẹ́ onítara nínú wọ́n béèrè pé kí a pa àwọn dókítà wọ̀nyí àti àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. Wọ́n yan àwọn amí láti mú nọ́ḿbà ọkọ̀ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, wọ́n sì fún wọn ní orúkọ òun àdírẹ́sì wọn. Ní àbáyọrí rẹ̀, wọ́n da ọta bo àwọn dókítà àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìtọ́jú aláìsàn, wọ́n sì pa wọ́n.
Ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìfètòsọ́mọbíbí ti America ké jáde pé: “Ọ̀ràn òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ kọ́ lèyí. Ohun kan náà ni èyí já sí pẹ̀lú kíkébòòsí ‘Iná!’ nínú gbọ̀ngàn ìwòran kan tí èrò kún fọ́fọ́. A ní ipò ọ̀ràn tí ó jọ gbọ̀ngàn ìwòran kan tí èrò kún fọ́fọ́; sáà wo ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìpànìyàn tí ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn ilé ìtọ́jú aláìsàn ní àwọn ọdún díẹ̀ tó kọjá.” Àwọn tí wọ́n ń ṣalágbàwí ìwà ipá yìí jiyàn pé àwọ́n wulẹ̀ ń lo ẹ̀tọ́ àwọn tí a fún àwọn lábẹ́ Àtúnṣe Àkọ́kọ́ ti America ni—òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ. Bí ó sì ṣe ń bá a lọ nìyẹn. A óò máa bá jíja ìjàkadì lórí ẹ̀tọ́ yìí lọ ní àwọn ibi ìjíròrò ìta gbangba, àwọn ilé ẹjọ́ yóò sì ní láti yanjú ọ̀ràn náà, ó bani nínú jẹ́ pé kì í ṣe sí ìtẹ́lọ́rùn gbogbogbòò.
Ohun Tí Àwọn Òbí Lè Ṣe
Ó yẹ kí ilé jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ọmọ, kì í ṣe ibi tí wọ́n ti lè tètè di ẹran ìjẹ fún àwọn tí yóò kó wọn nífà, tí wọn óò sì ṣe wọ́n níṣekúṣe, tàbí ibi tí a ti lè yí àwọn ànímọ́ títòrò mìnì padà sí ṣíṣàfihàn ipò oníwà ipá léraléra. Ọ̀jọ̀gbọ́n ní yunifásítì kan ní United States sọ nígbà tí ó ń bá àwọn òbí sọ̀rọ̀ pé: “Ẹ lè nímọ̀lára ìdánilójú pé ọmọ yín kì yóò di oníwà ipá láé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń wo ìwà ipá lórí tẹlifíṣọ̀n lójú méjèèjì. Àmọ́ ẹ kò lè ní ìdánilójú pé ọmọ ẹlòmíràn, tí ń wo tẹlifíṣọ̀n lọ́nà kan náà, kò ní pa ọmọ yín tàbí kí ó ṣá a lọ́gbẹ́.” Ó wá rọni pé: “Ó yẹ kí pípààlà sí bí a ṣe ṣí àwọn ọmọdé payá sí ìwà ipá orí tẹlifíṣọ̀n di apá kan ìlapa ètò ìlera aráàlú, bí àwọn àga ààbò, akoto ìgunkẹ̀kẹ́, abẹ́rẹ́ àjẹsára àti oúnjẹ dáradára.”
Bí o kò bá ní fàyè gba àjèjì kan láti wọ ilé rẹ, kí ó máa bú èébú, kí ó sì máa sọ̀rọ̀ àlùfààṣá nípa ìbálòpọ̀ àti ìwà ipá sí ọmọ rẹ, nígbà náà má ṣe fàyè gba rédíò àti tẹlifíṣọ̀n láti jẹ́ àjèjì yẹn. Mọ ìgbà tí ó yẹ kí ó pa á tàbí yí i kúrò ní ìkànnì tí ó wà. Mọ ohun tí ọmọ rẹ ń wò, lórí tẹlifíṣọ̀n àti lórí kọ̀m̀pútà, àní níbi ìkọ̀kọ̀ inú iyàrá rẹ̀ pàápàá. Bí ó bá mọ kọ̀m̀pútà í lò, tí ó sì lè lo ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ̀, ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti mọ ohun tí ó ń gbà sọ́kàn lálaalẹ́. Bí o kò bá fọwọ́ sí ohun tí ọmọ rẹ ń wò, wulẹ̀ sọ pé bẹ́ẹ̀ kọ́, kí o sì ṣàlàyé ìdí rẹ̀. Bí o kò bá gbà á láyè, kò níí kú.
Ní paríparí rẹ̀, kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti fi àwọn ìwà-bí-Ọlọ́run kọ́ra, kì í sì í ṣe ìwà ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú yìí—pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àti ìṣe àlùfààṣá àti oníwà ipá rẹ̀. (Òwe 22:6; Éfésù 6:4) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwa Kristẹni ní àwọn àmọ̀ràn tí ó bọ́ sásìkò, tí ó yẹ kí gbogbo wa mú lò nínú ìgbésí ayé wa. “Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tàbí ìwà ìwọra láàárín yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́; bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà tí ń tini lójú tàbí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn akóninírìíra, àwọn ohun tí kò yẹ, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀ ìdúpẹ́.”—Éfésù 5:3, 4.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan lórí tẹlifíṣọ̀n lè ṣamọ̀nà sí ìwà ọ̀daràn àti ìwà pálapàla