Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Pílánẹ́ẹ̀tì Tí À Ń Wu Léwu Mo ń kọ̀wé nípa ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ “Pílánẹ́ẹ̀tì Wa Tí À Ń Wu Léwu—A Ha Lè Gbà Á Là Bí?” (January 8, 1996) Ó dára kí ènìyàn lè ka nǹkan tí ń fúnni níṣìírí. Ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ kẹta nínú ọ̀wọ́ náà fún wa ní ìrètí Párádísè, níbi tí a kì yóò ti ní láti máa dààmú nípa ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká wọn àti àwọn ihò nínú ìpele ozone mọ́! Mo ń retí láti wà láàyè nínú Párádísè yẹn pẹ̀lú ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́ mi.
A. C., United States
A gbádùn àpótí tí ó kún fún ìsọfúnni tí ó wà ní ojú ìwé 8 àti 9, tí ó sọ nípa irú àwọn ìṣòro bíi pípa igbó run, àìtó omi, àti irú ọ̀wọ́ tí à ń wu léwu. Àwọn ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ náà mú wa lóye ipò líle koko tí pílánẹ́ẹ̀tì wa bá ara rẹ̀ báyìí. A nímọ̀lára ààbò, ní mímọ̀ pé ojútùú kan ṣoṣo sí ìṣòro líle koko yìí wà lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá wa.
O. P. àti F. J. O., Sípéènì
Àlàyé Jessica Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ parí kíka “Àlàyé Jessica” nínú ìtẹ̀jáde January 8, 1996, ni. Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ìṣírí fún mi tó! Nígbà tí mo bá rí èwe aláápọn tí ń fi tayọ̀tayọ̀ àti pẹ̀lú ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́ sin Jèhófà, ó ń mú mi láyọ̀. Ìtàn Jessica rán mi létí pé ó yẹ kí á lo gbogbo àǹfààní tí a bá ní láti jẹ́rìí.
A. H., United States
Rí Ète Nínú Ìgbésí Ayé Ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ “Mo Ń Ráre Kiri, àmọ́ Mo Rí Ète Kan Nínú Ìgbésí Ayé” (January 8, 1996) wọ̀ mí lọ́kàn gan-an ni. Bí mo ṣe ń kà á, ńṣe ló dà bíi pé ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ náà ń sọ nípa mi. Èmi pẹ̀lú ti ń ráre kiri pẹ̀lú ojú ìwòye dídágùdẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la rí. Ṣùgbọ́n a ké sí mi sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nísinsìnyí, mo ń nípìn-ín tayọ̀tayọ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún, ní ríran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti rí ìrètí àgbàyanu tí Jèhófà ti fi hàn mí.
C. R., United States
Ìṣètọ́jú Àìlèbímọ Kókó ìròyìn “Ìrètí Titun fún Àwọn Tọkọtaya Aláìlèbímọ Kẹ̀?” lábẹ́ “Wíwo Ayé” gba àfiyèsí mi. (September 22, 1995) Mo fi han onímọ̀ nípa ohun alààyè kan, ó sì sọ pé òun kò gbọ́ nípa ìlànà náà rí, nínú èyí tí a ti ń lo abẹ́rẹ́ tí a fi ìgò tí ó mọ́ gan-an ṣe láti fi àtọ̀ ọkùnrin kan sórí ẹyin kan “nínú obìnrin.”
E. K., Germany
A gbé kókó ìròyin wa karí ìròyìn kan tí ilé iṣẹ́ ìròyin France-Presse ti ilẹ Faransé tí ó jíròrò lórí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí oníṣègùn Anders Nyboe Andersen tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Denmark ṣe. Ó dunni pé a kò ròyìn àwọn ọ̀ràn kan bí ó ti tọ́. Dókítà Andersen sọ fún “Jí!” pé lílo abẹ́rẹ́ tí a fi ìgò tí ó mọ́ gan-an ṣe láti fi àtọ̀ kan sórí ẹyin kan ni a ń ṣe ní gbangba, ìyẹn ni, lẹ́yìn òde ara obìnrin náà. A wá ń fi ẹyin tí ó gbàlejò náà sínú obìnrin náà. Ìròyin wá ṣe rẹ́gí pé a lè lo “àtọ̀ ọkọ rẹ̀, dípò ti olùfitọrẹ tí a kò mọ̀—tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú àwọn ìbéèrè tí ń ru ìmọ̀lára sókè ní ti ìsìn àti ìwàrere kúrò.” Bí ọ̀ràn náà sì ti rí bẹ́ẹ̀, tọkọtaya Kristẹni kan yóò ní láti ṣe ìpinnu ara ẹni nípa ìlànà yìí. (Wo “Ile-Iṣọ Naa,” December 1, 1981, ojú ìwé 31.)—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.
Aṣetinú Ẹni Ọ̀rẹ́ Mo ń kọ̀wé nípa ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe Bí Ọ̀rẹ́ Kan Bá Wọ Gàù?” (January 22, 1996) A yọ ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ jù lọ lẹ́gbẹ́ lọ́dún kan sẹ́yìn. Ó dà mí lọ́kàn rú. Mo nímọ̀lára pé n kò ràn án lọ́wọ́ dójú ìwọ̀n, n kò lo àkókò pẹ̀lú rẹ̀ tó, n kò sì já mọ́ ọ̀rẹ́ rere fún un. Nígbà tí mo kà á pé kì í ṣe ẹ̀bi mi pé ó kúrò nínú òtítọ́, ńṣe ni ó dà bíi pé a sọ ẹrù wíwúwo kan kalẹ̀ kúrò ní èjìká mi!
L. T., United States
Nínú ọ̀ràn tèmi, ẹni náà tí ó sún mọ́ mi, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí í “tẹ̀ lé àṣà ìgbésí ayé tí kò tọ̀nà” kì í wulẹ̀ í ṣe ọ̀rẹ́ mi lásán, bí kò ṣe ìyá mi tí kò ṣeé pààrọ̀ tí ó sì jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, mo mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tọ àwọn alàgbà ìjọ lọ, wọ́n sì yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Mo dá ara mi lẹ́bi fún sísọ fún àwọn alàgbà. Nísinsìnyí, mo fẹ́ẹ́ jìjàdù láti borí ìmọ̀lára ẹ̀bi òdì tí mo ní, nípa lílo àwọn ìdámọ̀ràn inú ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ náà.
I. Y., Japan