Fọ́tò—Bí O Ṣe Lè Yà Á Dáradára
Àwọn ohun díẹ̀ ni a máa ń ṣìkẹ́ ju fọ́tò àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn mẹ́ḿbà ìdílé ọ̀wọ́n. Ó ṣe tán, ìjójúlówó fọ́tò sàn ju kìkì fọ́tò yíyà lásán kan lọ; ó jẹ́ àwòrán tí a pète láti fiyè sí àkópọ̀ ànímọ́ ẹ̀dá ẹnì kan!
Ìṣòro ibẹ̀ ni pé ó jọ pé àwọn fọ́tò tí àwọn amọsẹ́dunjú yà máa ń wọ́nwó—tí àwa kan kò lè yàdí rẹ̀. Tí ìwọ fúnra rẹ bá sì gbìyànjú yíya fọ́tò, ìwọ yóò rí i pé ó ju gbígbé kámẹ́rà sójú, kí o sì yà á lọ. Èyí jẹ́ nítorí pé bí fọ́tò bá dára, kì í ṣe ẹni tí a yà ní fọ́tò nìkan ló jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n ìmọ́lẹ̀, ìrísí ọwọ́ ẹ̀yìn, àyíká, bí ó ṣe dúró, bí ojú rẹ̀ ṣe rí, àti àwọ̀.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, bí o bá ní kámẹ́rà, tí o sì fẹ́ láti kọ́ àwọn ìlànà díẹ̀ tí ó ṣe kókó, o lè ya àwọn fọ́tò tí ó bójú mu. Báwo? Láti dáhùn, a óò béèrè àwọn ìbéèrè kan lọ́wọ́ amọṣẹ́dunjú ayafọ́tò kan tí ó ti ń ṣiṣẹ́ náà fún ohun tí ó lé ní ọdún mẹ́wàá.
• Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ọ̀nà wo ló dára jù lọ láti mú kí ẹnì kan rẹ́rìn-ín músẹ́ níwájú kámẹ́rà? Rí i dájú pé ẹni tí o fẹ́ yà wà ní ipò àtiyafọ́tò! Fún àpẹẹrẹ, jẹ́ kí a sọ pé o fẹ́ láti ya ọmọdébìnrin kan ní fọ́tò. Bí ó bá rẹ̀ ẹ́ tàbí tí ebi ń pa á, yóò ṣòro láti ya fọ́tò náà yọrí. Yàtọ̀ sí ìyẹn, àárẹ̀ yóò mú àìfararọ wà nínú ìrísí ojú àti ẹyinjú rẹ̀, tí yóò ba àwòrán náà jẹ́. Nítorí náà, fún un níṣìírí láti rẹjú díẹ̀, kí ó sì jẹ ìpápánu níwọ̀nba, kí ẹ tóó bẹ̀rẹ̀ fọ́tò yíyà náà.
Ó tún máa ń ṣèrànwọ́ láti sọ̀rọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ẹni náà. Yára mọ́ ọn, kí o sì ṣọ̀yàyà. Mú un sinmẹ̀dọ̀ nípa jíjíròrò, ṣùgbọ́n má ṣe gbìyànjú láti jẹ́ kí ó rẹ́rìn-ín àrínjù. Èyí máa ń jẹ́ kí ojú fún pọ̀, ó sì máa ń jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ rọ́ wá sójú. Gbìyànjú yíya oríṣiríṣi ìrísí ojú. Bí o bá ṣe ya fọ́tò pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni àǹfààní yíya ìrísí tí ó fi ẹnì kan hàn lọ́nà dídára jù lọ yóò ṣe pọ̀ tó.
• Ìwọṣọ àti ìmúra ńkọ́? Nínú fọ́tò ẹgbẹ́, ìṣètò àwọ̀ bíbára mu máa ń fani lọ́kàn mọ́ra. Fún àpẹẹrẹ, bí o bá fẹ́ ya ìdílé kan ní fọ́tò, dámọ̀ràn pé kí wọ́n wọ àwọn aṣọ tí àwọ̀ wọ́n lè lọ pọ̀. Tàbí bóyá kí o jẹ́ kí gbogbo wọ́n wọ aṣọ tí ó ní àwọn àwọ̀ kan náà. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, rántí, pé àwọn tí wọ́n sanra máa ń dára gan-an nínú àwọn aṣọ aláwọ̀ ṣíṣú àti pé àwọn ènìyàn tí wọ́n pẹ́lẹ́ńgẹ́ máa ń dára gan-an nínú àwọn aṣọ aláwọ̀ títàn.
O tún gbọ́dọ̀ fiyè sí kúlẹ̀kúlẹ̀: Ǹjẹ́ aṣọ náà dúró ṣánṣán, tí kò sì rún jù bí? Ǹjẹ́ táì ọrùn rẹ̀ dúró ṣánṣán bí? Ǹjẹ́ irun rẹ̀ wà létòlétò bí? Ojú rẹ lè ṣàìrí àwọn irun tí ó já, ṣùgbọ́n kámẹ́rà yóò rí wọn! Bí ẹni tí o fẹ́ yà ní fọ́tò bá jẹ́ obìnrin, ṣe ó lo àwọn ohun ìṣojúlọ́ṣọ̀ọ́ dáradára?
• Àwọn tí wọ́n lo dígí ojú ńkọ́? Nítorí ìkọmànà, èyí lè jẹ́ ìṣòro kan. Lákọ̀ọ́kọ́, gbé kámẹ́rà rẹ sójú láti wò ó bí àwọn ìkọmànà èyíkéyìí tí a kò fẹ́ bá wà. Bí ó bá wà, jẹ́ kí ẹni tí o fẹ́ yà náà máa gbé orí díẹ̀díẹ̀ títí ìkọmànà náà yóò fi kúrò láàárín ojú rẹ̀ tàbí kí o máà rí i mọ́ rárá. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, jíjẹ́ kí ẹni tí o fẹ́ yà náà gbé irùngbọ̀n wálẹ̀ yóò ṣèrànwọ́—ṣùgbọ́n ṣọ́ra kí irùgbọ̀n rẹ̀ má baà gbé àwòrán oníṣẹ̀ẹ́po méjì jáde!
• Ohun tí ó wà lọ́wọ́ ẹ̀yìn ha ṣe nǹkan kan bí? Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n! Ọwọ́ ẹ̀yìn tí ó kún rẹpẹtẹ fún àwọn wáyà iná, ọ̀nà, tàbí ohun ìrìnnà yóò wulẹ̀ ba fọ́tò rẹ jẹ́ ni. Nítorí náà, wá ọwọ́ ẹ̀yìn kan tí ó lè mú kí ẹni tí o fẹ́ yà sunwọ̀n sí i tàbí kí ó fani mọ́ra, irú bí igi kan, igbó òdòdó, ògiri onípákó, tàbí ẹ̀gbẹ́ ògbólógbòó abà kan.
• Bí ó bá jẹ́ nínú iyàrá ni o ti fẹ́ ya fọ́tò náà ńkọ́? O lè gbìyànjú àtijẹ́ kí ẹni tí o fẹ́ yà náà jókòó sórí àga tàbí ìjókòó gbọọrọ onítìmùtìmù níwájú ògiri aláwọ̀ títàn tàbí níbi igi òdòdó kan tí ó wà nínú iyàrá. Ní pàtàkì, ó máa ń ru ọkàn ìfẹ́ sókè láti ya ẹnì kan tí ń ṣiṣẹ́ tàbí tí ń kópa nínú ohun àfipawọ́ tàbí ìgbòkègbodò kan, nídìí tábìlì iṣẹ́, àpótí, tàbí àwọn ohun ìránṣọ lọ́wọ́ ẹ̀yìn.
• Bí o kò bá rí ọwọ́ ẹ̀yìn tí ó fani mọ́ra ńkọ́? Gbìyànjú láti má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ ẹ̀yìn náà hàn kedere. Èyí máa ń ṣiṣẹ́ dáradára nínú àwọn fọ́tò tí a yà ní gbangba níbi tí o ti lè fi ẹni tí o fẹ́ yà sí ibi tí ó jìnnà sí ọwọ́ ẹ̀yìn. O lè ṣe èyí nípa yíyí adíwọ̀n àlàfo awò, tàbí ìdíwọ̀n àlàfo awò náà. Bí adíwọ̀n àlàfo awò bá wà ní nọ́ḿbà tí ó ga, irú bí f5.6, yóò jẹ́ kí ẹni tí o fẹ́ yà hàn kedere, ṣùgbọ́n yóò jẹ́ kí ọwọ́ ẹ̀yìn rí ràkọ̀ràkọ̀.—Wo fọ́tò 1.
• Ìsọfúnni èyíkéyìí ha wà nípa ìṣètògbékalẹ̀ bí? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó ń ṣèrànwọ́ láti gbé kámẹ́rà rẹ sórí ohun ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta kan; lẹ́yìn náà, o lè pọkàn pọ̀ sórí ìṣètògbékalẹ̀. Ní gbogbogbòò, àwọn fọ́tò sábà máa ń jẹ́ yálà èyí tí a kó tán, ìdajì ara (láti ìbàdí sókè), tàbí ojú lásán (orí àti èjìká tàbí orí nìkan). (Wo fọ́tò 2.) Kámẹ́rà tí awò rẹ̀ wà láàárín 105 sí 150 mìlímítà yóò dára fún yíya fọ́tò. Bí o kò bá lè yí awò ojú kámẹ́rà rẹ tàbí tí o kò lè pààrọ̀ rẹ̀, gbìyànjú láti sún mọ́ ẹni tí o fẹ́ yà dáradára tàbí kí o sún sẹ́yìn dáradára títí tí o fi máa rí àwòrán tí o fẹ́. Bákan náà, ó bọ́gbọ́n mu gan-an nígbà tí a bá ń ya fọ́tò láti fi àyè díẹ̀ sílẹ̀ lókè orí, lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì, àti nísàlẹ̀ ẹsẹ̀. Lọ́nà yìí, o kò ní gé orí, ẹsẹ̀, tàbí ara dànù bí a bá fọ fọ́tò náà tóbi. Wò ó, bí o bá ṣe fọ fọ́tò náà tóbi tó ni àwòrán náà lè máa rá tó, èyí sinmi lé bí fọ́tọ̀ náà bá ṣe tóbi tó.
Ìtọ́sọ́nà kan tí ó wúlò ni a ń pè ní ìlànà ẹlẹ́ẹ́ta. Èyí ní nínú jíjẹ́ kí ojú tàbí ẹyinjú ẹni tí o fẹ́ yà wà ní ìwọ̀n ìlàta àyè tí ó wà láti òkè, ìsàlẹ̀, tàbí ẹ̀gbẹ́ àwòrán náà. (Wo fọ́tò 3.) Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó máa ń dára láti jẹ́ kí ojú wà ní àárín fọ́tò náà.
• Mímú kí ẹni tí o fẹ́ yà náà dúró dáradára ńkọ́? Jẹ́ kí ẹni tí o fẹ́ yà kọjú sí kámẹ́rà ní ipò tí ó fara rọ, yálà ní ìjókòó, ìdúró, tàbí ní fífara ti nǹkan, ṣùgbọ́n kí ó tẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ díẹ̀. Bí ó bá jọ pé ojú rẹ̀ ṣe roboto jù, jẹ́ kí ẹni tí o fẹ́ yà náà yí orí tàbí ara rẹ̀ díẹ̀ kí ó baà lè jẹ́ pé kìkì ìlàjì ojú rẹ̀ ni a óò tanná sí. Apá ibi tí ó wà nínú òjìji ni ó yẹ kí ó sún mọ́ kámẹ́rà jù lọ. Èyí yóò jẹ́ kí ojú rẹ̀ túbọ̀ kéré. Ní ọwọ́ kejì, bí o bá fẹ́ kí gbogbo ojú rẹ̀ yọ, jẹ́ kí ẹni náà máa yí orí tàbí ara rẹ̀ títí iná yóò fi tàn sí gbogbo ojú rẹ̀.
Fún àwọn ọwọ́ rẹ̀ ní àfiyèsí pàtàkì. Ó yẹ kí wọ́n dà bí èyí tí ó fara rọ, kí wọ́n sì wà ní ipò àdánidá, irú bíi rírọra fi í lé irùngbọ̀n tàbí ẹ̀bátí. Bí ẹni náà bá wà ní ìdúró, yẹra fún àṣìṣe wíwọ́pọ̀ gan-an ti gbígbé apá sẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹ̀lú ọwọ́ tí ó wulẹ̀ dà sílẹ̀ ní tààràtà. Ó sàn láti jẹ́ kí àwọn ọwọ́ rẹ̀ di nǹkan mú tàbí kí wọ́n wà ní ipò àdánidá.
• Ìsọfúnni kankan ha wà nípa yíya tọkọtaya bí? Gbìyànjú jíjẹ́ kí wọ́n tẹ orí sọ́dọ̀ ara wọn díẹ̀. Ó sábà máa ń dára jù lọ láti má ṣe jẹ́ kí àwọn méjèèjì tẹ́ bẹẹrẹ. O lè gbìyànjú láti tò wọ́n kí ojú ẹnì kan wà ní déédéé imú ẹnì kejì.—Wo fọ́tò 4.
• Jẹ́ kí a sọ̀rọ̀ nípa ìmọ́lẹ̀. Ìgbà wo ni ó dára jù lọ lójú ọjọ́ láti ya fọ́tò ní gbangba? Lẹ́yìn ọjọ́kanrí. Ọwọ́ afẹ́fẹ́ sábà máa ń rọ̀, àwọ̀ ìmọ́lẹ̀ sì túbọ̀ máa ń tú yáyá. Gbìyànjú láti jẹ́ kí ọ̀rẹ́ rẹ wà ní ipò tí ìmọ́lẹ̀ oòrùn yóò fi tàn sí apá kan ojú rẹ̀, pẹ̀lú kìkì igun ìmọ́lẹ̀ tí ó hàn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ojú rẹ̀ nínú òjìji. Èyí kò ní jẹ́ kí ẹni náà fún ojú pọ̀. Bí o bá fẹ́ ya fọ́tò ẹ̀gbẹ́ orí, gbé kámẹ́rà rẹ sí apá ibi tí òjìji wà lójú rẹ̀. Bákan náà, rí i dájú pé o bo awò kámẹ́rà rẹ nítorí oòrùn.
• Bí ìmọ́lẹ̀ náà bá lágbára jù ńkọ́? Gbìyànjú láti jẹ́ kí ọ̀rẹ́ rẹ kẹ̀yìn sí oòrùn.
• Ṣé ìyẹn kò ní í jẹ́ kí òjìji wà lójú rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, ṣùgbọ́n o lè lo iná abùyẹ̀rì rẹ láti mú òjìji náà kúrò. Àwọn kámẹ́rà kan máa ń ṣe èyí fúnra wọn. Ojútùú mìíràn ni láti jẹ́ kí ọ̀rẹ́ kan ṣe ìrànlọ́wọ́. Ó lè gbé ohun agbémọ̀ọ́lẹ̀padà kan tàbí pépà funfun kan tí ó gbòòrò dání, kí ó sì mú kí ìmọ́lẹ̀ àyíká díẹ̀ tàn padà sójú ẹni tí o fẹ́ yà.
• Ìmọ́lẹ̀ inú iyàrá ńkọ́? O lè lo ìmọ́lẹ̀ àdánidá nípa jíjẹ́ kí ẹni tí o fẹ́ yà jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ fèrèsé. O lè lo aṣọ ìkélé kan tí ń fòdì kejì hàn láti jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ tàn yíká. Bí ó bá pọn dandan, o lè lo ẹnì kan tí ń gbé iná abùyẹ̀rì tàbí pépà tí ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ tàn padà láti mú kí àwọn apá ibi tí ó ṣú jù lójú rẹ̀ mọ́lẹ̀.—Wo fọ́tò 5.
• Bí ìmọ́lẹ̀ tí ó wà kò bá tó ńkọ́? Nínú irú ipò bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò ní láti lo iná abùyẹ̀rì rẹ. Gbìyànjú láti jẹ́ kí ẹni tí o fẹ́ yà wà ní ibi ti ẹ̀gbẹ́ ògiri rẹ̀ funfun. Tẹ iná abùyẹ̀rì rẹ kí ìmọ́lẹ̀ lè tàn yẹ̀rì padà láti ara ẹ̀gbẹ́ ògiri. Pẹ̀lú bí ìmọ́lẹ̀ náà ṣe ń bọ̀ láti ìhà ẹ̀gbẹ́, ìwọ yóò túbọ̀ lè ṣàkóso bí ìmọ́lẹ̀ ṣe tàn sójú rẹ̀ tó.
A gbà pé yóò gba ọ̀pọ̀ ìgbìyànjú wò láti rí àbájáde dídára. Ṣùgbọ́n àwọn ìlànà ìpìlẹ̀ ṣíṣe kókó nípa fọ́tò yíyà rọrùn. Pẹ̀lú ètò àfẹ̀sọ̀ṣe àti ìfiyèsí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀, pẹ̀lú kámẹ́rà àwọn ọ̀gbẹ̀rì pàápàá, o lè gbé fọ́tò dáradára kan kalẹ̀—èyí tí ìwọ àti àwọn olólùfẹ́ rẹ yóò ṣìkẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún tí ń bọ̀!