MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Fi Fóònù Tàbí Kámẹ́rà Wàásù
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Ìtẹ̀síwájú túbọ̀ ń bá ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ, ìwà ipá sì ń pọ̀ sí i. Èyí ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa lo fóònù tàbí kámẹ́rà lẹ́nu ọ̀nà wọn fún ààbò. Ó lè má rọrùn fún wa láti wàásù látorí irú àwọn kámẹ́rà yìí torí a ò rí ẹni náà. Àmọ́, àwọn àbá tó wà nísàlẹ̀ yìí á jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ tá a bá fẹ́ wàásù nírú ọ̀nà yìí.
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
Gbà pé ó ṣeé ṣe. Ọ̀pọ̀ ló máa ń fẹ́ bá wa sọ̀rọ̀ látorí fóònù tàbí kámẹ́rà
Àwọn kámẹ́rà kan wà tó máa ń ká ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyìíká, torí náà ó ṣeé ṣe kí onílé ti máa wò yín lẹ́nu ọ̀nà tàbí kó máa gbọ́ ohun tẹ́ ẹ̀ ń sọ
Tí onílé bá dá a yín lóhùn, bá a sọ̀rọ̀ lórí fóònù tàbí kámẹ́rà bíi pé ò ń rí i lójúkojú. Máa rẹ́rìn-ín músẹ́, kó o sì máa fara ṣàpèjúwe tó o bá ń sọ̀rọ̀. Sọ ohun tó o ti múra sílẹ̀ tẹ́ni náà bá jáde sí ẹ. Tí kámẹ́rà bá wà níbẹ̀, má ṣe sún mọ́ ọn jù tó o bá ń sọ̀rọ̀. Má ṣe sọ ohunkóhun tí onílé ò bá dá yín lóhùn
Lẹ́yìn tó o bá ti sọ̀rọ̀ tán, má gbàgbé pé onílé ṣì lè máa rí ẹ, kó sì máa gbọ́ ohun tó ò ń sọ