MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Máa Hùwà Tó Bójú Mu Lóde Ẹ̀rí
Àwa Kristẹni dà bí “ìran àpéwò ní gbọ̀ngàn ìwòran fún ayé.” (1Kọ 4:9) Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé àwọn kan máa ń yọjú wò wá láti ojú wíńdò wọn tàbí kí wọ́n máa kẹ́tí lẹ́yìn ilẹ̀kùn. Kámẹ́rà àti makirofóònù tiẹ̀ lè wà láwọn ilé kan, èyí tí wọ́n lè máa fi wò wá, tí wọ́n lè máa fi gbọ́ ohun tí à ń sọ, tí wọ́n sì lè fi gba ohùn àti àwòrán wa sílẹ̀. Díẹ̀ rèé lára àwọn ọ̀nà tá a lè máa gbà hùwà ọmọlúwàbí nígbà tá a bá lọ wàásù fún àwọn èèyàn.—2Kọ 6:3.
ÌWÀ RẸ (Flp 1:27):
Má ṣe yọjú wo inú ilé àwọn èèyàn, èyí á fi hàn pé o bọ̀wọ̀ fún wọn. Má ṣe máa jẹun, má ṣe mu nǹkan, má sì ṣe lo fóònù nígbà tó o bá ń kan ilẹ̀kùn wọn
Ọ̀RỌ̀ RẸ (Ef 4:29):
Tó o bá wà lẹ́nu ilẹ̀kùn àwọn èèyàn, má ṣe sọ ohunkóhun tó o mọ̀ pé ó lè bí àwọn ará ilé náà nínú. Àwọn akéde kan kì í tiẹ̀ fẹ́ láti tàkúrọ̀sọ rárá nígbà tí wọ́n bá wà lẹ́nu ọ̀nà àwọn èèyàn, kí wọ́n bàa lè pọkàn pọ̀ sórí ohun tí wọ́n fẹ́ sọ