Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Fi Fóònù Wàásù
Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì: Torí pé ọ̀nà míì ló jẹ́ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè gba ìmọ̀ pípéye sínú, èyí tó lè mú kí wọ́n rí ìgbàlà. (2 Pét. 3:9) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwàásù ilé-dé-ilé ni ọ̀nà pàtàkì tá à ń gbà kéde Ìjọba Ọlọ́run, tọkàntọkàn la fi máa ń lo àwọn ọ̀nà míì láti wàásù fáwọn tí kì í fi bẹ́ẹ̀ gbélé.—Mát. 24:14; Lúùkù 10:1-7; Ìṣí. 14:6.
Gbìyànjú Èyí Lóṣù Yìí:
Nígbà ìjọsìn ìdílé yín, ẹ ṣe ìdánrawò bí ẹ ṣe lè lo ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ẹnu ọ̀nà láti fi bá onílé sọ̀rọ̀. Kí ẹni tó máa ṣe bí onílé àti ẹni tó fẹ́ wàásù wà níbi tó jìnnà síra wọn.