Wíwo Ayé
Ìwé Mímọ́ Wà ní Èdè 2,123
Ìwé agbéròyìnjáde Wetterauer Zeitung ròyìn pé, Hannah Kickel-Andrae, akọ̀wé ìròyìn fún Ẹgbẹ́ Bíbélì ti Ilẹ̀ Germany, kéde láìpẹ́ yìí pé Ìwé Mímọ́ wà ní èdè tí ó lé ní 2,100. A fojú díwọ̀n pé aráyé ń sọ nǹkan bí 6,000 èdè ati èdè àdúgbò. Ìyẹn túmọ̀ sí pé, ó kéré tán, àwọn apá kan nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà ní èdè tí ó lé ní ìlàta gbogbo èdè tí a ń sọ. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Bibelreport ti sọ, a ti ṣe odindi Bíbélì jáde ní èdè 349. Ní àfikún sí i, “Májẹ̀mú Tuntun” wà ní èdè 841, àwọn apá mìíràn nínú Bíbélì sì wà ní èdè 933 fún àròpọ̀ 2,123 èdè. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwùjọ àwọn olùtúmọ̀ nílò nǹkan bí ọdún mẹ́rin láti túmọ̀ “Májẹ̀mú Tuntun” àti nǹkan bí ọdún mẹ́jọ fún “Májẹ̀mú Láéláé.” Iṣẹ́ ń lọ lọ́wọ́ lórí 600 ìdáwọ́lé iṣẹ́ ìtúmọ̀ míràn.
Ẹja Àbùùbùtán Tí Ó Ní Èròjà Onímájèlé
Ìwé agbéròyìnjáde International Herald Tribune sọ pé ẹja àbùùbùtán sperm kan, tí a rí òkú rẹ̀ ní àwọn ọ̀nà ọkọ̀ òkun tí a ń lò gan-an ní ìsọdá sáàárín òkun etíkun ìhà àríwá Denmark, ní ọ̀pọ̀ “èròjà mẹ́kúrì àti cadmium débi pé a ní láti bo ìfun rẹ̀ mọ́lẹ̀ ní agbègbè àkànṣe kan tí ó wà fún dída ìdọ̀tí olóró sí.” A kò tí ì mọ orísun àwọn mẹ́táàlì onímájèlé wọ̀nyí. Nígbà tí ìwé ìròyìn Time ń jíròrò lórí ìṣẹ̀lẹ̀ kan náà, ó fi kún un pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan rí èyí gẹ́gẹ́ bí àmì ṣíṣe kedere pé a ti sọ àwọn òkun di eléèérí, àwọn onímọ̀ nípa ẹranko tọ́ka sí àwọn okùnfà àdánidá. Onímọ̀ nípa ẹja àbùùbùtán náà, Carl Kinze, láti Ibi Àkójọ Ìṣẹ̀m̀báyé Àwọn Ẹranko ní Copenhagen, sọ pé octopus, ti díẹ̀ lára wọ́n ní ìwọ̀n gíga cadmium àdámọ́ni nínú ni lájorí ohun tí àwọn ẹja àbùùbùtán sperm máa ń jẹ́.
Owó Gọbọi Tí Tẹ́tẹ́ Títa Ń Náni
Ní ìpínlẹ̀ New South Wales ní Australia, ìwádìí kan tí ìjọba ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀ gbé àwọn ìṣirò amúnitakìjí díẹ̀ jáde nípa àwọn ipa tí tẹ́tẹ́ títa ń ní. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Sunday Telegraph ṣe sọ, ó tó ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí a fi ṣèwádìí tí wọ́n sọ pé àwọ́n ń ta tẹ́tẹ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Dájúdájú, ó lé ní 2 lára àwọn 10 tí wọ́n jẹ́wọ́ pé àwọ́n ń ná iye tí ó ju 100 dọ́là lọ lọ́sẹ̀ lórí àṣà náà. “Àwọn àpọ́n ọkùnrin tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí lílo ẹ̀rọ tẹ́tẹ́ tàbí kíkọ́ iyàn lórí àwọn eléré ìdárayá” ni ọ̀wọ́ àwọn tí ó ṣeé ṣe jù lọ kí wọ́n ní ìṣòro tẹ́tẹ́ títa. Ọ̀wọ́ àwọn mìíràn tí wọ́n wà nínú ewu jù ní nínú, “àwọn ẹni tí ń gba owó tí ó kéré sí 20,000 dọ́là lọ́dún, àti àwọn tí wọ́n ti fẹ̀yìn tì tàbí àwọn tí wọn kò ríṣẹ́ ṣe.” Síwájú sí i, ìwádìí náà fi hàn pé “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 15 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ìdílé ní NSW [New South Wales] tí tẹ́tẹ́ títa ré kọjá ààlà ti fà ìṣòro fún.” Ní àfikún, a fojú díwọ̀n pé “àwọn tí tẹ́tẹ́ títa ti di bárakú fún ń jẹ́ kí NSW pàdánù 50 mílíọ̀nù dọ́là lọ́dún lórí iye ìwọ̀n ìmújáde, ìwọkogbèsè àti ìkọ̀sílẹ̀.”
Àwọn Ẹni Àìsúnmọ́ Nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì Kẹ̀?
Ní Íńdíà, ni àwọn ọ̀rúndún tó ti kọjá, ọ̀pọ̀ lára àwọn tí a bí sínú ẹgbẹ́ àjẹbí tí a ń pè ní àwọn ẹni àìsúnmọ́ ti ń di ẹni àyílọ́kànpadà sí ìsìn Kátólíìkì pẹ̀lú ìrètí bíbọ́ lọ́wọ́ ètò ìgbékalẹ̀ ẹgbẹ́ àjẹbí Hindú. Ìwé agbéròyìnjáde Paris náà, Le Monde, sọ pé: “Ṣùgbọ́n ìyẹn kò túmọ̀ sí pé wọ́n lè bọ́ kúrò nínú ẹgbẹ́ àjẹbí onípò rírẹlẹ̀ wọn.” Àwọn Kátólíìkì ará Íńdíà, tí wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ àjẹbí onípò gíga, ṣì ń bá àwọn Kátólíìkì ẹgbẹ́ àjẹbí onípò rírẹlẹ̀ lò bí àwọn ẹni àìsúnmọ́. Ìwé agbéròyìnjáde Le Monde sọ pé: “Ní àbáyọrí rẹ̀, nígbà tí àwọn Kátólíìkì ẹgbẹ́ àjẹbí onípò rírẹlẹ̀ àti àwọn ti onípò gíga bá lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì láti lọ gbàdúrà, wọ́n máa ń jókòó sí ìpín àyè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.”
Àwọn Awúrúju Oyè Ẹ̀kọ́
Ní United States, àwọn orúkọ oyè náà “onímọ̀ nípa oúnjẹ aṣaralóore,” “oníṣègùn,” àti “onímọ̀ nípa èròjà oúnjẹ pípé” ni àwọn olùṣògo ara ẹni, tí kò tóótun sábà máa ń lò. Gẹ́gẹ́ bí lẹ́tà ìròyìn náà, Tufts University Diet & Nutrition Letter, ṣe sọ, ní ìpínlẹ̀ púpọ̀, “ẹnikẹ́ni, láìka ti ìmọ̀ ìwé rẹ̀ sí, lè sọ pé òún jẹ́ onímọ̀ nípa oúnjẹ aṣaralóore láìbẹ̀rù ohun tí òfin sọ.” Láìpẹ́ yìí, àwọn olùṣèwádìí yẹ àwọn atọ́nà tẹlifóònù wò ní àwọn ìpínlẹ̀ 32, wọ́n sì ṣàwárí pé “kò tó ìdajì àwọn tí a pè ní amọṣẹ́dunjú tí a kọ sábẹ́ àwọn àkọlé náà ‘àwọn onímọ̀ nípa oúnjẹ aṣaralóore’ àti ‘àwọn oníṣègùn’ tó jẹ́ orísun ìsọfúnni gbígbámúṣé nípa oúnjẹ aṣaralóore, tí a gbé karí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, tí ó ṣeé fọkàn tẹ̀.” Ní àwọn ojú ewé aláwọ̀ ìyeyè (ibi tí a to nọ́ḿbà tẹlifóònù àwọn oníṣòwò sí), nǹkan bí ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn onímọ̀ nípa oúnjẹ aṣaralóore tí a tò pé wọ́n ní oyè “Ph.D.” ni a rí i pé awúrúju oyè ẹ̀kọ́ ni wọ́n ní lọ́wọ́ tàbí pé wọ́n ní ìsọfúnni oníjìbìtì.
Agbára Ọmọdé
Ìwé ìròyìn Veja sọ pé: “Àwọn ọmọdé ní Brazil ti di aláṣẹ nínú ilé, wọ́n ń ní ipa lórí àwọn ìpinnu àwọn òbí wọn, wọ́n sì ń ná iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 50 bílíọ̀nù dọ́là (U.S.) lọ́dún. Àwọn ọmọdé ń dá yan ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹlifíṣọ̀n tí wọ́n fẹ́ nítorí pé àwọn ohun mìíràn ń gba àkókò àwọn àgbàlagbà. Wọ́n máa ń lọ sí ibi ìpàgọ́ àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ láìsí àbójútó bàbá tàbí ìyá wọn. . . . A ń fi wọ́n sílẹ̀ ní àwọn ibi àríyá, wọ́n sì ń sùn ní ilé àwọn ọ̀rẹ́ wọn.” Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn òbí “fẹ́ àwọn ọmọ tí wọn kò gbára lé ẹlòmíràn, tí wọ́n sì lómìnira, kódà bí wọn kò bá gbọ́ràn tó àwọn ọmọ ti àwọn ìran àtijọ́.” Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí amọṣẹ́dunjú nípa ìlera ọpọlọ, Alberto Pereira Lima Filho, ṣe sọ, “nípa pípa ipa wọn gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni tì, [àwọn òbí] kò lè pèsè ààlà ṣíṣe kedere fún àwọn ọmọ wọn.” Kò ní yani lẹ́nu pé ìwádìí kan fi hàn pé “ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọmọdé náà fẹ́ràn àwọn agbábọ́ọ̀lù ju àwọn òbí wọn lọ.”
Ìjọba Fọwọ́ sí Ìsìn Voodoo
Ìwé agbéròyìnjáde The Guardian ti Nàìjíríà sọ pé orílẹ̀-èdè Benin ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà ti fún “ìsìn voodoo” ní “ìkàsí tí a fàṣẹ tì lẹ́yìn.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde náà ṣe sọ, ó jẹ́ “ìgbà àkọ́kọ́ tí ìjọba èyíkéyìí” yóò fún “ìsìn ìbílẹ̀ Áfíríkà” kan ní ìkàsí tí a faṣẹ tì lẹ́yìn. Irú ìkàsí bẹ́ẹ̀ túmọ̀ sí pé àwọn onísìn voodoo ní ẹ̀tọ́ òfin láti kọ́ àwọn tẹ́ḿpìlì tí wọ́n ti lè máa ṣe àwọn ìrúbọ fún jíjọ́sìn àwọn ẹ̀mí àìrí àti títù wọ́n lójú. A fojú díwọ̀n pé ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ènìyàn Benin ní ń ṣe ìsìn voodoo.
Ìmúkúrò Ohun Ìjà Ogun Lọ́nà Nínáni Lówó Gọbọi
Gẹ́gẹ́ bí àwọn olùṣèwádìí ará Germany ti sọ, “láàárín 1985 sí 1994, ìnáwó lórí ohun ìjà ogun ti fi nǹkan bí ìpín 30 nínú ọgọ́rùn-ún wálẹ̀ jákèjádò ayé, sí 800 bílíọ̀nù dọ́là U.S. ‘péré.’” Ibùdó Ìṣèyípadà Àgbáyé ní Bonn (BICC) tẹ kókó ọ̀rọ̀ wọ̀nyí jáde nínú ìwé ọdọọdún wọn àkọ́kọ́, tí ó ní àkọlé náà, Conversion Survey 1996. Lára àwọn orílẹ̀-èdè 151, àwọn 82 dín iye tí wọ́n ń ná lórí ohun ìjà ogun kù, nígbà tí àwọn 60 fi kún un. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn ilẹ̀ Germany náà, Focus, ṣe sọ, “ìrètí fún ‘èrè àlàáfíà,’ ìyẹn ni pé, ìtúnpín àràádọ́ta ọ̀kẹ́ dọ́là fún ìdàgbàsókè àrànṣe àti àwọn ìṣètò ìfẹ́dàáfẹ́re, ni a kò tí ì mú ṣẹ títí di báyìí.” Àwọn ògbógi BICC sọ pé: “Dídín àwọn ohun èèlò ogun jíjà kù ti ṣokùnfà ìnáwó tí ó fagi lé owó tí a kó ná sórí ẹ̀ka ohun ìjà ogun.”
Àwọn Aṣọ Ìfọ̀wo Lè Kó Àìsàn Bá Ọ
Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti rí àwọn bakitéríà panipani púpọ̀ gan-an nínú àwọn asọ ìfọ̀wo tí a ti lò àti àwọn kànrìnkàn ilé ìdáná. Gẹ́gẹ́ bí lẹ́tà ìròyìn náà, UC Berkeley Wellness Letter, ti sọ, ìwádìí àìpẹ́ kan fi hàn pé lára 500 aṣọ àti kànrìnkàn tútù tí a yẹ̀ wò, “ìdá méjì nínú mẹ́ta ni ó ní bakitéríà tí ó lè kó àìsàn bá àwọn ènìyàn.” Nǹkan bí ìlàrin “ní bakitéríà salmonella tàbí staphylococcus, àwọn lájorí okùnfà àrùn tí oúnjẹ ń fà” ní United States. Àwọn ògbógi dámọ̀ràn pé kí a máa pààrọ̀ àwọn kànrìnkàn déédéé àti pé kí a máa fọ àwọn aṣọ ìfọ̀wo déédéé. Lẹ́tà ìròyìn Wellness Letter sọ pè: “O lè kó aṣọ ìfọ̀wo àti kànrìnkàn pọ̀ síbi ìfọ̀wo pẹ̀lú àwọn àwo dídọ̀tí, tàbí sínú ẹ̀rọ ìfọǹkan.” Lẹ́yìn tí wọ́n bá ní ìfarakanra pẹ̀lú ẹran tútù, a lè fi pépà ìnuwọ́ nu orí ibi tí a lò dípò lílo àwọn aṣọ tàbí kànrìnkàn tí a ṣì máa lò.
Iṣẹ́ Abẹ Ọkàn Àyà Ní Lílo Fídíò
Ìwé agbéròyìnjáde Le Monde ti Paris sọ pé, ilé ìwòsàn kan ní Paris gba ipò jíjẹ́ àkọ́kọ́ tí ó ṣe iṣẹ́ abẹ ọkàn àyà fún obìnrin ẹni 30 ọdún kan ní lílo fídíò. Ní ti ìlànà wíwọ́pọ̀, iṣẹ́ abẹ ọkàn àyà ń béèrè fún líla egungun àyà tó bíi 20 sẹ̀ǹtímítà nítòsí ikùn. Bí ó ti wù kí ó rí, ìlànà yìí wulẹ̀ béèrè fún gígé e wọnú fún sẹ̀ǹtímítà mẹ́rin péré, nígbà tí ihò kékeré mìíràn yóò fún kámẹ́rà onífọ́nrán ìmọ́lẹ̀ láyè láti ṣamọ̀nà oníṣẹ́ abẹ náà. Lọ́nà yìí, ìpàdánù ẹ̀jẹ̀, ìsoríkọ́ lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ, àti ewu àkóràn dín kù lọ́nà gíga. Agbàtọ́jú náà lè fi ilé ìwòsàn sílẹ̀ ní ọjọ́ 12 péré lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ náà. Lọ́dọọdún, nǹkan bíi mílíọ̀nù kan ènìyàn ní a ń ṣe iṣẹ́ abẹ ọkàn àyà fún ní ti ìlànà wíwọ́pọ̀ jákèjádò ayé.
Àjàkálẹ̀ Ikọ́ Ẹ̀gbẹ
Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London sọ pé: “Ìlàta iye àwọn olùgbé ayé ni àrùn TB [ikọ́ ẹ̀gbẹ] ń bá jà,” a sì retí pé kí àrùn náà ṣekú pa 30 mílíọ̀nù ènìyàn ní ẹ̀wádún yìí. Ètò Àjọ Ìlera Àgbáyé tẹnu mọ́ ọn pé àjàkálẹ̀ àrùn tuntun náà, gẹ́gẹ́ bí ó ti pè é, yóò tún ràn kálẹ̀, yóò sì ṣèparun púpọ̀ ju àrùn AIDS lọ, ó sì ṣeé ṣe kí ó kọ lu 300 mílíọ̀nù ènìyàn ní ọdún mẹ́wàá sí i. Òtítọ́ náà pé àwọn bakitéríà máa ń wà nínú afẹ́fẹ́ túmọ̀ sí pé ikọ́ ẹ̀gbẹ tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ èyí tí ń ranni gan-an. Ikọ́ ẹ̀gbẹ ti di àrànkálẹ̀ ná ní àwọn apá ibì kan ní Rọ́ṣíà. Ibùdó ìpèsè ìrànwọ́ ìṣègùn kan ní Britain ròyìn pé àwọn oríṣiríṣi bakitéríà tí kò gbóògùn ti yọjú nítorí pé ọ̀pọ̀ àwọn alárùn ikọ́ ẹ̀gbẹ kò lo oògùn agbógunti kòkòrò àrùn tí ó yẹ kí wọ́n lò fún oṣù mẹ́fà tán. Ní àbáyọrí rẹ̀, àwọn bakitéríà ń gbógun ti oògùn, wọ́n sì ń là á já.