Kíkàn sí Ilẹ̀ Ọba ẹ̀mí
ILÉELẸ̀ kan tí ó fani mọ́ra, tí wọ́n kùn ní ọ̀dà funfun àti aláwọ̀ ewé wà láàárín ìlú kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Ní iyàrá ìgbàlejò rẹ̀, àwọn akọ̀wé méjì ń tẹ̀wé lórí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé. Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn rọ̀gbọ̀kú sórí àwọn àga, wọ́n ń jókòó de babaláwo tí ń woṣẹ́.
Babaláwo náà fúnra rẹ̀ jókòó nídìí tábìlì kan, nínú ọ́fíìsì tí ó dojú kọ ìyẹn, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀rọ ìṣàdàkọ ìsọfúnni kan. Ó sanra, ewú ti ń yọ lórí rẹ̀, ó wọ ẹ̀wù funfun gígùn—olówó ńlá, tí wọ́n kó iṣẹ́ sí. Ó wí pé: “Woṣẹ́woṣẹ́ ni bàbá mi. Wọ́n bí mi sínú iṣẹ́ náà ni. Inú rẹ̀ ni mo dàgbà sí. Nígbà tí mo fi pé ọmọ ọdún márùn-ún, bí bàbá mi bá ń lọ woṣẹ́, mo máa ń bá a lọ. Mo máa ń wo bí ó ṣe ń ṣe é, mo sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ títí tí ó fi mọ́ mi lára.”
Babaláwo náà nawọ́ sí ọpọ́n ńlá kan tí ó to ìlànà iṣẹ́ wíwò tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ti ń lò láti ìrandíran sí. Ó dá lé dída èkùrọ́ 16, ó jẹ́ ìlànà kan tí ó ti tàn kálẹ̀ jákèjádò Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà àti ilẹ̀ òkèèrè. Ó sọ pé: “Àwọn ènìyàn máa ń bá onírúurú ìṣòro wá sọ́dọ̀ mi. Ìṣòro obìnrin, àìlèbímọ, àìríṣẹ́ṣe, àrùn ọpọlọ, ìlera, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó sinmi lórí èsì iṣẹ́ tí a bá wò, a máa ń bẹ yálà àwọn baba ńlá tàbí àwọn ẹ̀dá ọ̀run [àwọn irúnmọlẹ̀]. Ohun yòó wù kí ó jẹ́, a gbọ́dọ̀ rú àwọn ẹbọ kan.”
Ìsìn ìbílẹ̀, títí kan iṣẹ́ wíwò, fìdí múlẹ̀ gan-an ní agbègbè náà, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù náà fìdí múlẹ̀ níbẹ̀. Nítòsí ọ́fíìsì babaláwo náà, a rí àwọn ilé tí wọ́n kùn ní ọ̀dà funfun, tí wọ́n ní àwọn àkọlé wọ̀nyí níwájú wọn: Ṣọ́ọ̀ṣì Ọba Sólómónì Kejì, Kérúbù àti Séráfù, Ìjọ Mímọ́ Ti Kristi Láti Ọ̀run Wá, Ṣọ́ọ̀ṣì Christ Apostolic, Ṣọ́ọ̀ṣì Christ Trumpeters. Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì wọ̀nyí ń jùmọ̀ wà pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìsìn ìbílẹ̀, wọ́n sì máa ń tẹ́wọ́ gba àwọn àṣà ìsìn ìbílẹ̀ nígbà míràn. Babaláwo náà sọ pé: “Mo ń bá bíṣọ́ọ̀bù sọ̀rọ̀ láìpẹ́ yìí. Ó wá síhìn-ín. Lẹ́yìn tí a ti jíròrò àwọn ohun kan fún nǹkan bí 30 ìṣẹ́jú, ó sọ pé òún fẹ́ kí a ṣètò irú ìfikùnlukùn kan, tí àwọn Kristẹni àti àwọn onísìn ìbílẹ̀ yóò fi lè jókòó pọ̀ láti ṣàjọpín àwọn ojú ìwòye, kí wọn sì mú èdèkòyédè kúrò.”
Àwọn Ọ̀nà Tí Ó Lọ sí Ilẹ̀ Ọba Ẹ̀mí
Irú àwọn èdèkòyédè bẹ́ẹ̀ sábà máa ń jẹ́ nípa mímọ irú àwọn tí ń gbé ilẹ̀ ọba ẹ̀mí. Jákèjádò Áfíríkà ní gúúsù Sàhárà, èrò ìgbàgbọ́ tí ó tàn kálẹ̀ ti wà pé àwọn àwùjọ ẹ̀dá méjì ní ń gbé ilẹ̀ ọba ẹ̀mí. Àwùjọ èkínní jẹ́ àwọn irúnmọlẹ̀, tàbí àwọn ọlọ́run, tí wọn kò tí ì jẹ́ ènìyàn rí. Àwùjọ èkejì jẹ́ àwọn baba ńlá, tàbí ẹ̀mí àwọn òkú, tí iṣẹ́ wọ́n jẹ́ láti rí i dájú pé àwọn ìdílé wọn ń wà láàyè nìṣó, kí wọ́n sì láàsìkí láyé. Àwọn ènìyàn gbà gbọ́ pé àwọn irúnmọlẹ̀ àti àwọn baba ńlá ní agbára yálà láti ṣèrànwọ́ tàbí láti pa àwọn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ ayé lára. Lójú ìwòye èyí, wọ́n gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún àwọn méjèèjì lọ́nà bíbẹ́tọ̀ọ́mu.
A ń rí àwọn èrò ìgbàgbọ́ tí ó jọ èyí ní apá ibi púpọ̀ láyé. Àwọn ènìyàn níbi gbogbo ń lo oríṣiríṣi ọ̀nà láti bá àwọn ẹ̀mí alágbára tí ó ju ti àdánidá sọ̀rọ̀, ní wíwá ìmọ̀ nípa ọjọ́ iwájú àti ìrànlọ́wọ́ òun ìtọ́sọ́nà nípa gbogbo ìṣòro ìgbésí ayé ojoojúmọ́. Ó ha ṣeé ṣe ní ti gidi láti rí ìrànlọ́wọ́ láti ilẹ̀ ọba ẹ̀mí bí? Jésù Kristi, tí ó ti gbé ibẹ̀ rí, fi hàn pé ó ṣeé ṣe. Ó wí pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a óò sì fi í fún yín; ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ óò sì rí; ẹ máa bá a nìṣó ní kíkànkùn, a óò sì ṣí i fún yín.” (Mátíù 7:7) Ṣùgbọ́n láti rí ìrànlọ́wọ́ yẹn gbà, a gbọ́dọ̀ béèrè lọ́wọ́ ẹni tí ó yẹ, kí a wá a ní ọ̀nà tí ó yẹ, kí a sì kan ilẹ̀kùn tí ó yẹ. Bí a bá kan ilẹ̀kùn tí kò yẹ, ó lè jẹ́ ẹni tí yóò ṣe wá ní jàm̀bá, tí kò níí ṣe wá ní ire, ni yóò ṣí i fún wa.
Nígbà náà, ó ṣe pàtàkì láti mọ àwọn tí ń gbé ilẹ̀ ọba ẹ̀mí àti àwọn tí kì í gbé ibẹ̀. A tún ní láti mọ ìyàtọ̀ láàárín àwọn tí yóò ràn wá lọ́wọ́ àti àwọn tí yóò pa wá lára. Níkẹyìn, a ní láti mọ ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe láti rí ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n wà ní ipò láti fi fúnni. Àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e yóò gbé ọ̀ràn yìí yẹ̀ wo.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Fọ́tò ojú ìwé 3 àti 4: The Star, Johannesburg, S.A.