Olóyè kan Ṣàyẹ̀wò Ọjọ́-Ọ̀la Rẹ̀
OLÓYÈ náà ní Ìwọ̀-Oòrùn Africa jẹ́ olórí tí a fẹ́ràn gan-an tí a sì fún ní ọ̀wọ̀ tí ó jinlẹ̀ ní àdúgbò rẹ̀. Nígbà ọjọ́-ìbí ọdún kejìdínláàdọ́rín-in rẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, àwọn ẹbí, àti àwọn afẹ́nifẹ́re mìíràn kórajọpọ̀ láti bá a yọ̀. Nínú àsọyé kan, olóyè náà yan ẹsin-ọ̀rọ̀ kan tí kò wọ́pọ̀ ní irú àṣeyẹ-àkànṣe bẹ́ẹ̀. Ó sọ̀rọ̀ nípa èrò rẹ̀ nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú.
Ó sọ pé lẹ́yìn ayé yìí “ayé titun kan wà níbi tí kò ti sí ẹ̀tàn, ìlara àti ìwọra.” Ó ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ayé kan tí “a bo àwọn ohun ìjìnlẹ̀ mọ́lẹ̀ sí,” èyí tí kìkì àwọn olódodo ń gbé, tí wọn yóò ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọrun.
Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ láàárín àwọn ènìyàn jákèjádò Africa. Ní ìbámu pẹ̀lú ìsìn àbáláyé Africa, ikú kì í ṣe òpin ìwàláàyè ṣùgbọ́n ó wulẹ̀ jẹ́ ìyípòpadà, kíkọjá lọ sí ìwàláàyè ní ilẹ̀-ọba ẹ̀mí. Nígbà ikú ẹni kan ni a máa ń sọ pé ó rékọjá lọ láti ayé tí a lè fojúrí sí èyí tí a kò lè fojúrí. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí, ẹni náà lẹ́yìn náá ti wọ pápá àkóso tí àwọn babańlá rẹ̀ ń gbé.
Ọ̀pọ̀ àwọn ará Ìwọ̀-Oòrùn Africa gbàgbọ́ pé àwọn babańlá, tàbí ẹ̀mí àwọn babańlá, ń mójútó ire-aásìkí àwọn ìdílé wọn lórí ilẹ̀-ayé. Ìwé náà West African Traditional Religion sọ pé: “Kò sí ìyàtọ̀ tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ nípa ipa ìdarí láàárín àwọn mẹ́ḿbà àwùjọ tí ó ṣì wà lórí ilẹ̀-ayé, àti ti àwọn wọnnì tí ó wà ní ayé tọ̀hún. Nígbà tí wọ́n wà níhìn-ín lórí ilẹ̀-ayé, [àwọn babańlá] jẹ́ alábòójútó ìdílé wọn. Nísinsìnyí tí a kò rí wọn mọ́, wọ́n ṣì jẹ́ alábòójútó nínú ayé àwọn ẹ̀mí. Wọn kò jáwọ́ nínú níní ọkàn-ìfẹ́ sí ire gbogbogbòò ti àwọn ìdílé wọn.”
Nítorí náà, àgbàlagbà olóyè tí a mẹ́nukàn lẹ́ẹ̀kan nírètí àti darapọ̀ mọ́ àwọn babańlá rẹ̀ kí ó sì ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú wọn nínú ilẹ̀-ọba ẹ̀mí. Ó sọ pé: “Mo ní ìdánilójú tí ó lágbára nínú ìwàláàyè lẹ́yìn ikú àti ṣíṣeéṣe náà pé n óò máa báa lọ láti ṣiṣẹ́sìn—àní pàápàá lẹ́yìn ikú.”
Bí ó ti wù kí ó rí, nítorí ohun tí olóyè náà sọ tẹ̀lé e, ìwé ìròyìn Sunday Times dábàá pé ó “dàbí pé kò ní ìdánilójú pátápátá” nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú. Ó sọ fún àwọn èrò tí ó pésẹ̀ pé òun ti gbọ́ nípa ìwé kan tí ó sọ̀rọ̀ nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú. Olóyè náà ti ń wá ìwé náà fún ọdún márùn-ún. Ó háragàgà láti kà á débi pé ó ṣetán láti san iye tí ó tó $1,500 (U.S.) fún ẹnikẹ́ni tí ó bá lè mú ẹ̀dà kan wá fún un.
Olóyè náà ìbá ti yọ ara rẹ̀ nínú ìjàngbọ̀n nípa wíwádìí láti inú ìwé kan tí kò ṣòro láti rí. Ó jẹ́ ìwé kan tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó tí a kò ṣe láti ọwọ́ ènìyàn ṣùgbọ́n láti ọwọ́ Ẹlẹ́dàá gbogbo ènìyàn. (1 Tessalonika 2:13) Ìwé náà ni Bibeli. Kí ni ohun tí ó sọ nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú?