ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 11/15 ojú ìwé 3-4
  • Àwọn Òkú Ha Lè Rí Wa Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Òkú Ha Lè Rí Wa Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ibo Làwọn Baba Ńlá Wa Wà?
    Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
  • Níbo Ni Àwọn Òkú Wà?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ó Ha Yẹ Kí O Bẹ̀rù Òkú Bí?
    Jí!—1996
  • Olóyè kan Ṣàyẹ̀wò Ọjọ́-Ọ̀la Rẹ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 11/15 ojú ìwé 3-4

Àwọn Òkú Ha Lè Rí Wa Bí?

OBÌNRIN kan pa ọkọ rẹ̀. Ní ọdún méje lẹ́yìn náà àlá kan tí ó gbàgbọ́ pé ó jẹ́ àmì ìbínú ọkọ rẹ̀ tí ó ti kú bà á lẹ́rù. Láti tu “ẹ̀mí” rẹ̀ lójú, ó rán ọmọbìnrin rẹ̀ láti da ọtí ìrúbọ sórí sàréè rẹ̀.

Ọmọbìnrin náà kò mọ bí òun yóò ṣe bá ẹ̀mí bàbá òun sọ̀rọ̀, níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ọwọ́ ìyá òun tí ó pa á ni ẹbọ náà ti wá. Àbúrò rẹ̀ ọkùnrin ń wò ó láti ibi tí ó lúgọsí. Ó jáde wá, òun pẹ̀lú arábìnrin rẹ̀ sì gbàdúrà sí bàbá wọn pé kí ó ràn àwọn lọ́wọ́ láti gbẹ̀san ikú rẹ̀.

Ìran yìí wá láti inú ìwé The Libation Bearers, eré Griki kan tí a kọ ní èyí tí ó ju 2,400 ọdún sẹ́yìn. Ní àwọn apá ibìkan ní ayé, ní pàtàkì ní Africa, wọ́n ń ṣe irú àwọn ìrúbọ etí ibojì bẹ́ẹ̀ lónìí olónìí pàápàá.

Fún àpẹẹrẹ, gbé ìrírí Ibe yẹ̀wò, ẹni tí ń gbé ní Nigeria. Lẹ́yìn tí ikú pa ọmọ mẹ́ta mọ́ ọn lọ́wọ́, ó tọ babaláwo lọ, ẹni tí ó sọ fún Ibe pé ikú náà kò dédé ṣẹlẹ̀​—⁠bàbá Ibe tí ó ti kú ni ó ń bínú nítorí pé kò tíì ṣe òkú rẹ̀ lọ́nà tí ó yẹ.

Ní títẹ̀lé ìmọ̀ràn babaláwo náà, Ibe fi ewúrẹ́ rúbọ ó sì da ọtí líle àti ọtí wáìnì ìrúbọ sórí sàréè bàbá rẹ̀. Ó képe ẹ̀mí bàbá rẹ̀, ní bíbẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì, ní mímú ìfẹ́ rẹ̀ dá a lójú, àti bíbéèrè fún ìbùkún.

Ibe kò ṣiyèméjì pé bàbá òun lè rí òun kí ó sì gbọ́ ohun tí òun ń sọ. Òun kò gbàgbọ́ pé bàbá òun jẹ́ aláìlẹ́mìí ṣùgbọ́n pé nígbà tí ó kú ó “rékọjá” láti ayé tí a lè fojúrí sí ayé tí a kò lè fojúrí. Ibe gbàgbọ́ pé bàbá òun ti kọjá láti ayé àwọn ẹlẹ́ran-ara àti ẹ̀jẹ̀ sí ayé àwọn ẹ̀dá-ẹ̀mí, pápá-àkóso àwọn babańlá.

Bí Ibe ṣe ronú nìyí: ‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Bàbá kò sí láyé yìí mọ́, ó ṣì ń rántí mi ó sì lọ́kàn-ìfẹ́ nínú ire mi. Níwọ̀n bí òun sì ti di ẹ̀mí tí ó ní àlékún agbára nísinsìnyí, ó wà ní ipò tí ó sàn jù lọ́pọ̀lọpọ̀ láti ràn mí lọ́wọ́ ju ìgbà tí ó jẹ́ ènìyàn lórí ilẹ̀-ayé. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó lè bá Ọlọrun sọ̀rọ̀ ní tààràtà nítorí mi, níwọ̀n bí Ọlọrun pẹ̀lú ti jẹ́ ẹ̀mí. Bàbá lè máa bínú sí mi ní lọ́wọ́lọ́wọ́, ṣùgbọ́n bí mo bá fi ọ̀wọ̀ tí ó tọ́ hàn sí i, òun yóò dáríjì mí yóò sì súre fún mi.’

Ní Africa ìgbàgbọ́ náà pé àwọn òkú ń rí àwọn ènìyàn lórí ilẹ̀-ayé tí wọ́n sì ń lo agbára ìdarí lórí ìgbésí-ayé wọn wọ́pọ̀ láàárín àwọn ẹlẹ́sìn àbáláyé. Ó hàn gbangba láàárín àwọn Kristian aláfẹnujẹ́ pẹ̀lú. Fún àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí a bá gbé obìnrin kan nìyàwó ní ṣọ́ọ̀ṣì, kìí ṣe ohun tí ó ṣàjèjì pé kí ó lọ sí ilé àwọn òbí rẹ̀ láti lọ gba ìre lọ́nà ti ìṣẹ̀dálẹ̀. Níbẹ̀ ni a ti ń gbàdúrà sí àwọn babańlá, tí a sì ń ta ọtí ìrúbọ sílẹ̀ fún wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbàgbọ́ pé ìkùnà láti ṣe èyí ń mú ìjábá wá sórí ìgbéyàwó náà.

Wọ́n ronú pé àwọn babańlá náà, tàbí ẹ̀mí àwọn babańlá, ń rí i dájú pé àwọn ìdílé wọn lórí ilẹ̀-ayé ń báa lọ láti máa wàláàyè kí wọ́n sì máa láásìkí. Gẹ́gẹ́ bí ojú-ìwòye yìí ti sọ, wọ́n jẹ́ olùrànlọ́wọ́ lílágbára, tí ó lè mú ìkórè rere wá, mú ire-aásìkí sunwọ̀n síi, kí wọ́n sì dáàbòbò wọ́n kúrò lọ́wọ́ ewu. Wọ́n ń ṣìpẹ̀ nítorí ènìyàn. Ṣùgbọ́n, bí a kò bá kà wọ́n sí tàbí tí a bá ṣẹ̀ wọ́n, wọn yóò mú ìjábá​—⁠àìsàn, òṣì, àní ikú pàápàá wá. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, nípasẹ̀ ìrúbọ àti ètùtù, àwọn ènìyàn ń làkàkà láti di ipò-ìbátan dídára mú pẹ̀lú àwọn òkú.

Ìwọ ha gbàgbọ́ pé àwọn òkú ń sa ipa aláápọn nínú ìgbésí-ayé àwọn alààyè bí? Ìwọ ha ti fìgbà kan dúró lẹ́bàá sàréè olólùfẹ́ kan tí o sì rí i pé o bẹ̀rẹ̀ síí jẹnu wúyẹ́wúyẹ́, bóyá ní ìrètí pé ó lè gbọ́ ohun tí o ń sọ? Tóò, yálà àwọn òkú ń rí wa tàbí bẹ́ẹ̀kọ́ sinmi lórí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nígbà ikú. Ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò ohun tí Bibeli sọ nípa kókó-ọ̀rọ̀ pàtàkì yìí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́