ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 1/8 ojú ìwé 21
  • Ìràwọ̀ Onírù Fọ́ Yángá!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìràwọ̀ Onírù Fọ́ Yángá!
  • Jí!—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé Fẹ́ Parẹ́ Ni?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìjábá Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé Yóò Ha Pa Ayé Wa Run Bí?
    Jí!—1998
  • Àwọn Oníṣẹ́ Mẹ́fà Láti Gbalasa Òfuurufú
    Jí!—1996
Jí!—1997
g97 1/8 ojú ìwé 21

Ìràwọ̀ Onírù Fọ́ Yángá!

FÚN ọ̀sẹ̀ kan ní July 1994, bí nǹkan bí 20 àfọ́kù ìràwọ̀ onírù Shoemaker-Levy 9 ṣe forí sọ pílánẹ́ẹ̀tì Júpítà gba àfiyèsí àwọn tí ń wòran ìràwọ̀ yí ká ayé. Àwọn tí ń wòran ìràwọ̀ onírù wá rìrì, nítorí pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáá já sí “ìran àpéwò títayọ lọ́lá jù lọ ti ọ̀rúndún yìí,” gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà kan ṣe pè é. Kí ló mú kí ìṣẹ̀lẹ̀ yí kọjá ohun tí a fojú sọ́nà fún gan-an?

Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn àfọ́kù ìràwọ̀ onírù náà, tí ń yára sáré ní ìwọ̀n 200,000 kìlómítà láàárín wákàtí kan, fọ́n ká gan-an lọ́nà tí ó fi jẹ́ pé àsọtẹ́lẹ̀ tí ó légbá kan jù lọ nìkan ni ó tọ́ka sí i. Wíwọ̀ tí wọ́n wọ àyíká Júpítà fa ìbùyẹ̀rì tí ó wà fún kìkì ìṣẹ́jú àáyá díẹ̀. Lẹ́yìn náà, àwọn gáàsì gbígbóná janjan tú jáde sínú afẹ́fẹ́ àyíká náà, tí ó sì fa àwọn ìṣùpọ̀ oníná kíkàmàmà, tí àwọn ìfọ́yángá títóbi jù lọ wọn ní ìwọ̀n ìgbóná tí ó ju ti oòrùn lọ fún ìwọ̀n àkókò díẹ̀! Láàárín ìṣẹ́jú 10 sí 20 tí ó tẹ̀ lé e, ìrútúú eléèéfín gígùn gbọọrọ kan ga sókè tó 3,200 kìlómítà.

Síwájú sí i, ohun tí a kọ́kọ́ rò pé ó jẹ́ ipò ìríran tí kò dára tó wáá di èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pípé tán. Nítorí pé ipa tí ó ní náà wà ní apá tí ó ṣókùnkùn lára Júpítà, ó túbọ̀ rọrùn láti rí àwọn ìbùyẹ̀rì mímọ́lẹ̀ àti ìrútúú eléèéfín gígùn gbọọrọ náà. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, a lè rí orí àwọn ìrútúú eléèéfín gígùn gbọọrọ náà tí ó ga ju àgbègbè Júpítà lọ, yíyí tí Júpítà ń yí sì mú kí ó yí ipa ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti kàn án sí ibi tí a ti lè rí i dáradára láti orí ilẹ̀ ayé láàárín ìṣẹ́jú mẹ́wàá lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ìṣẹ́jú mẹ́wàá mìíràn mú kí ipa ibi tí ó ti kàn án náà yí sí ìmọ́lẹ̀ oòrùn. Nígbà yẹn, àwọn ìrútúú eléèéfín gígùn gbọọrọ náà ti tú ká, àwọn àmì títóbi tí ó dá dúdú lára pílánẹ́ẹ̀tì náà, ti rọ́pò wọn. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà kò sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn àmì wọ̀nyí—tí èyí tí ó tóbi jù lọ lára wọn jẹ́ ìlọ́po méjì bí ayé ṣe tóbi tó—síbẹ̀, wọ́n wáá di àmì ìdámọ̀ ṣíṣe kedere jù lọ tí a lè rí.

Ìhùmọ̀ agbéniresánmà Galileo pèsè àǹfààní rírí àwọn ipa náà ní tààrà. Nínú òpó ilẹ̀ ayé, Awò Awọ̀nàjíjìn Gbalasa Òfuurufú ti Hubble wo ipa náà ní ìwọ̀n gígùn ìgbì ìmọ́lẹ̀ tí ó ṣeé rí àti ti ìmọ́lẹ̀ jíjìnnà tí kò ṣeé rí. Àwọn ibi ìdúrówosánmà míràn díwọ̀n bí ìfọ́yángá ìràwọ̀ onírù náà ṣe lágbára tó ní onírúurú ìwọ̀n gígùn ìgbì tí a yàn ní pàtó láti fúnni ní ìsọfúnni tí ó níye lórí. Ní Ìhà Gúúsù Ilẹ̀ Ayé, oòrùn kò yọ, ó sì mú kí ó ṣeé ṣe láti wo gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ náà jálẹ̀jálẹ̀ láti inú awò awọ̀nàjíjìn South Pole Infrared Explorer.

Àwọn olùkíyèsí òfuurufú ti rí ohun adánilárayá ṣíṣọ̀wọ́n kan tí wọn kò retí. Nígbà wo ni ìran àpéwò ìràwọ̀ onírù tí ó kàn yóò tún ṣẹlẹ̀? Ó ṣeé ṣe kí ìràwọ̀ onírù Hale-Bopp, tí a ti lè fojúyòójú rí, jẹ́ ìràwọ̀ onírù mímọ́lẹ̀ jù lọ tí a rí ní ọ̀rúndún yìí. Yóò kọjá ní ìwọ̀n tí ó jìn tó mílíọ̀nù 198 kìlómítà sí pílánẹ́ẹ̀tì wa. Àwọn olùwo ìràwọ̀ onírù ní Àríwá Ìlàjì ayé yóò fẹ́ láti wo Hale-Bopp ní oṣù April 1997. Gbogbo èyí ń rán wa létí pé a ń gbé nínú àgbáálá ayé gbígbéṣẹ́, tí ń yí pa dà, tí Jèhófà, “Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá,” ṣẹ̀dá.—Jákọ́bù 1:17; Orin Dáfídì 115:16.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Àwọn àmì tí ó dá dúdú sàmì sí ibi tí àwọn àfọ́kù ìràwọ̀ onírù ti forí sọ Júpítà

[Credit Line]

Hubble Space Telescope Comet Team and NASA

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́