ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 2/22 ojú ìwé 31
  • Dáàbò Bo Agbára Ìgbọ́ròó Rẹ!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Dáàbò Bo Agbára Ìgbọ́ròó Rẹ!
  • Jí!—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ariwo—Ohun Tí O Lè Ṣe Nípa Rẹ̀
    Jí!—1997
  • Agbára Ìgbọ́ròó Rẹ—Ẹ̀bùn Tí Ó Yẹ Kí O Ṣìkẹ́
    Jí!—1997
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1999
  • Wíwo Ayé
    Jí!—2005
Jí!—1997
g97 2/22 ojú ìwé 31

Dáàbò Bo Agbára Ìgbọ́ròó Rẹ!

ÌWÁDÌÍ kan tí a ṣe láìpẹ́ yìí láàárín àwọn 400 èwe ní ilẹ̀ Faransé fi hàn pé ẹnì 1 nínú ẹni 5 wọn ti pàdánù agbára ìgbọ́ròó rẹ̀. Irú ìwádìí kan náà ní ẹ̀wádún kan ṣáájú fi hàn pé kìkì ẹnì 1 nínú ẹni 10 àwọn ọ̀dọ́ ni ó ní irú ìpàdánù bẹ́ẹ̀. Nítorí ìlọsókè nínú bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe ń pàdánù agbára ìgbọ́ròó wọn, lọ́dún tó kọjá, Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilẹ̀ Faransé ṣòfin láti fi òòté lé ìwọ̀n ìró ẹ̀rọ amìjìnjìn ara ẹni sí 100 decibel.

Ọ̀pọ̀ ẹ̀bi ìpàdánù agbára ìgbọ́ròó náà ni a gbé karí ìwọ̀n ìró tí ń jáde wá láti inú gbohùngbohùn àtẹ̀bọtí tí a ń lò pẹ̀lú àwọn ẹ̀rọ amìjìnjìn ti ara ẹni. Oníṣẹ́ abẹ etí, Jean-Pierre Cave, sọ pé àwọn ìró tí ó bá kọjá 100 decibel lè yọrí sí ìpalára wíwà títí lẹ́yìn wákàtí mélòó kan. Irú ìpalára bẹ́ẹ̀ yóò ṣẹlẹ̀ láàárín ìṣẹ́jú mélòó kan péré bí ìró náà bá kọjá 115 decibel. Ilé iṣẹ́ FNAC, olókìkí aláràtúntà ohun abánáṣiṣẹ́ ní ilẹ̀ Faransé, sọ pé ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn ẹ̀rọ amìjìnjìn ara ẹni ti òun ń pèsè ìró tí ó kọjá 100 decibel. Àwọn ẹ̀rọ amìjìnjìn ara ẹni kan lè pèsè 126 decibel, tí ó lágbára tó 100 decibel ní ìlọ́po 400!

Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ilẹ̀ Faransé náà, Christian Meyer-Bisch, ògbógi nípa ìgbọ́ròó, ṣe wí, ó ṣeé ṣe kí ijó rọ́ọ̀kì máa ṣèpalára fún àwọn ọ̀dọ́ púpọ̀ sí i ju bí àwọn ẹ̀rọ amìjìnjìn ara ẹní ṣe ń ṣe lọ. Ní gidi, àwọn tí ń lọ síbi ijó rọ́ọ̀kì déédéé ń pàdánù agbára ìgbọ́ròó lọ́nà kíkàmàmà bí a bá fi wọ́n wé àwọn abarapá ọmọ ọdún 18. Abájọ tí ọmọ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilẹ̀ Faransé náà, Jean-François Mattei, fi kìlọ̀ pé: “Ìran àwọn adití ni a ń mú jáde.”

Nítorí náà, láti dáàbò bo agbára ìgbọ́ròó rẹ, ṣọ́ra fún ariwo yẹn!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́