Georgia—Ogún Àtayébáyé Kan Tí A Pa Mọ́
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RỌ̀YÌN JÍ!
BÁWO ni yóò ṣe wù ọ́ tó láti gbé ní orílẹ̀-èdè kan tó ní àwọn àfonífojì ẹlẹ́tùlójú láàárín àwọn òkè tí òjò dídì bò, tí ó ga tó 4,600 mítà, níbi tí àwọn ènìyàn kan ti ń dàgbà tó 100 ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ? Ní ti àwọn olùgbé Georgia, èyí kì í ṣe àwòrán àfinúyà kan lásán. Ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní gidi ni.
Georgia wà ní ààlà ilẹ̀ àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ láàárín ilẹ̀ Yúróòpù àti Éṣíà. Látijọ́, Georgia jẹ́ ibi ìran pàtàkì kan ní Ọ̀nà Òwú, ọ̀nà kan náà tí Marco Polo gbà lọ sí China. Georgia jàǹfààní lára ìsopọ̀ yí láàárín ìhà Ìlà Oòrùn àti ìhà Ìwọ̀ Oòrùn, ní ti owó àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn akóguntini pẹ̀lú kà á sí àǹfààní níníyelórí láti gba ọ̀nà yí. Gẹ́gẹ́ bí ìfojúdíwọ̀n kan, wọ́n ti pa Tbilisi, olú ìlú Georgia, run ní ìgbà 29! Lónìí, Tbilisi jẹ́ ìlú ńlá ọlọ́pọ̀ èrò, tó ní ọ̀nà abẹ́lẹ̀ kan àti àwọn ilé ìgbàlódé tó wà láàárín àwọn ilé àmúpìtàn ọlọ́jọ́pípẹ́.
Nǹkan bí ìpín 87 nínú ọgọ́rùn-ún lára ojú ilẹ̀ Georgia ló jẹ́ olókè. Bẹ̀rẹ̀ láti ẹkùn ilẹ̀ olókè oníyìnyín tí kò ní olùgbé náà la àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ já ni 25,000 odò wà, tí púpọ̀ lára wọn ní àwọn ẹja omi tútù nínú. Ó lé ní ìdá mẹ́ta ojú ilẹ̀ orílẹ̀-èdè náà tí ó jẹ́ igbó tàbí tí ìgbẹ́ bò. Àwọn àsokọ́ra òkè ńlá Caucasus níhà àríwá ààlà ilẹ̀ Georgia ní ń dáàbò bo orílẹ̀-èdè náà lọ́wọ́ ojú ọjọ́ tútù nini tí ń wá láti ìhà àríwá. Ipò yí ń mú kí afẹ́fẹ́ ọlọ́rinrin tí ń wá láti Òkun Dúdú máa mú ìhà ìwọ̀ oòrùn Georgia móoru—ìdí kan tí Georgia fi jẹ́ ibi àyànláàyò kan fún àwọn tí ń lọ lo ìsinmi. Ipò ojú ọjọ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì náà tún ti dá kún ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà ọlọ́jọ́lórí tí a ń gbà ṣe ọtí wáìnì. Ní gidi, Georgia ń mú onírúurú èso àjàrà àti wáìnì tó lé ní 500 jáde!
Bí ó ti wù kí ó rí, búrùjí kíkọyọyọ jù lọ tí Georgia ní ni àwọn ènìyàn tó wà níbẹ̀. A mọ̀ wọ́n látayébáyé nítorí ìwà akin wọn, làákàyè wọn, àti ìwà ọ̀làwọ́ tí wọ́n ní sí àlejò, pa pọ̀ pẹ̀lú ànímọ́ ìpanilẹ́rìn-ín àti ìfẹ́ wọn fún ìwàláàyè. Àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn kún fún orin àti ijó, wọ́n sì sábà máa ń kọ àwọn orin ìbílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá jókòó lẹ́yìn oúnjẹ nínú àwọn ilé ní Georgia.
Georgia tún ní ìtàn ọlọ́jọ́pípẹ́ ní ti ìwé kíkọ, láti ọ̀rúndún karùn-ún wá. Èdè Georgian jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èdè tí a kọ́kọ́ túmọ̀ Bíbélì sí nípìlẹ̀, ní lílo àwọn ábídí àrà ọ̀tọ̀ tó sì rẹwà tó wà nínú èdè Georgian. Gbogbo àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọ̀nyí ló ń fa ìsopọ̀ òde òní mọ́ ìgbà àtijọ́ ilẹ̀ Georgia—ogún àtayébáyé kan tí a pa mọ́ ní orílẹ̀-èdè òde òní kan.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]
Pat O’Hara/Corbis
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
1. Bíbélì èdè Georgian
2. Àwọn olùgbé kan ń dàgbà tó 100 ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ!
3. Òpópónà kan tí èrò ti ń wọ́ lọ wọ́ bọ̀ ní Tbilisi
[Credit Line]
Dean Conger/Corbis