Nǹkan Ìyanu Méjì Ṣẹlẹ̀ Ní Àpéjọ Àgbègbè Kan Nílẹ̀ Georgia
ÀPÉJỌ mánigbàgbé kan wáyé lórílẹ̀-èdè Georgia lọ́dún 2006, nǹkan ìyanu méjì sì ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Ọjọ́ mẹ́ta gbáko làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ṣe Àpéjọ Àgbègbè wọn tí àkòrí rẹ̀ ń jẹ́ “Ìdáǹdè Kù sí Dẹ̀dẹ̀!” Ìlú mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n sì ti ṣe àpéjọ ọ̀hún lórílẹ̀-èdè Georgia. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ keje, wọ́n sì parí rẹ̀ ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù July ọdún 2006. Ó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún [17,000] èèyàn tó gbádùn ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní àpéjọ náà.
Lóṣù January ọdún 2006, wọ́n ṣe akitiyan láti wá ibi tó dára tó lè gba ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn níbi tí wọ́n ti fẹ́ ṣe àpéjọ náà nílùú Tbilisi tó jẹ́ olú ìlú Georgia. Láti ibẹ̀ ni àwọn tó wà nílùú márùn-ún yòókù yóò ti máa gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà nípasẹ̀ ẹ̀rọ tẹlifóònù.
Òmìnira láti ṣe ẹ̀sìn tó bá wuni ti ń wà díẹ̀díẹ̀ lórílẹ̀-èdè Georgia láti àwọn ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn. Láìka àtakò tó ti wà káàkiri tẹ́lẹ̀ sí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá ìmúrasílẹ̀ náà lọ, ọkàn wọ́n sì balẹ̀ pé wọ́n á rí ibi tí wọ́n ti máa ṣe àpéjọ àgbègbè yìí nílùú Tbilisi. Àwọn èèyàn ilẹ̀ Georgia jẹ́ ọlọ́yàyà, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ àlejò gan-an. Àmọ́ ẹ̀tanú nípa ìsìn ti wà lọ́kàn àwọn kan nínú àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè náà. Báwo ni wọ́n ṣe máa pa ẹ̀tanú yìí tì kí wọ́n sì gba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyè láti háyà ibi tí wọ́n fẹ́ lò náà?
Àwọn arákùnrin tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Àpéjọ Àgbègbè náà lọ wo oríṣiríṣi pápá ìṣiré àtàwọn gbọ̀ngàn eré ìdárayá tó tóbi. Àwọn ọ̀gá tó ń bójú tó àwọn pápá ìṣiré náà ṣèlérí pé àwọ́n á fi àwọn ibi ìṣiré náà háyà fún wọn, àmọ́ táwọn ará bá ti wá béèrè ọjọ́ tí wọ́n fẹ́ káwọn wá lò ó, wọ́n á láwọn ò gbà mọ́. Nítorí náà, ó ya àwọn ìgbìmọ̀ náà lẹ́nu nígbà táwọn alábòójútó Gbọ̀ngàn Ìkọrin Tbilisi gbà pé àwọn á fi gbọ̀ngàn àwọn háyà fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Gbọ̀ngàn ìkọrin náà wà láàárín ìlú níbi tí wọ́n ti máa ń ṣe ọ̀pọ̀ lára àwọn ayẹyẹ tó ṣe pàtàkì jù lọ.
Inú ìgbìmọ̀ náà dùn pé àwọ́n tí rí ohun táwọn ń wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ fún àpéjọ tó máa wáyé ní Tbilisi, àtàwọn yòókù tó máa wáyé láwọn ìlú kéékèèké àtàwọn ìlú ńlá káàkiri orílẹ̀-èdè náà, ìyẹn láwọn ibi márùn-ún yìí: Tsnori, Kutaisi, Zugdidi, Kaspi àti Gori. Wọ́n ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ láti fi ẹ̀rọ tẹlifóònù so àwọn ibi tí àpéjọ àgbègbè yìí ti máa wáyé káàkiri orílẹ̀-èdè náà pọ̀ káwọn èèyàn lè máa gbọ́ ọ̀rọ̀ àpéjọ yìí lẹ́ẹ̀kan náà. Ohun gbogbo ti wà ní sẹpẹ́ fún àpéjọ àgbègbè náà. Láìrò tẹ́lẹ̀, nígbà tó ku ọ̀sẹ̀ kan péré kí àpéjọ àgbègbè náà bẹ̀rẹ̀ ni àwọn alábòójútó Gbọ̀ngàn Ìkọrin Tbilisi sọ pé àwọn ò fi gbọ̀ngàn náà háyà mọ́. Wọn ò sì ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi sọ bẹ́ẹ̀.
Nǹkan Ìyanu Àkọ́kọ́
Kí làwọn ìgbìmọ̀ náà máa ṣe lákòókò tí nǹkan ti bọ́ sórí yìí? Kìkì ohun tí wọ́n lè ṣe kò ju kí wọ́n lọ lo ibì kan táwọn àgbẹ̀ fi ń dáko nílùú Marneuli tó wà ní ogójì kìlómítà sí Tbilisi. Ọ̀pọ̀ àpéjọ ni wọn ti ṣe níbẹ̀ lórí ilẹ̀ ìdílé kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ilẹ̀ náà ti fìgbà kan rí jẹ́ ọgbà ńlá tí wọ́n máa ń gbin nǹkan sí. Àmọ́ láti ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, ibẹ̀ nìkan ni ibi táwọn ìjọ tó wà ní Tbilisi ti máa ń ṣe àpéjọ àgbègbè wọn. Bẹ́ẹ̀, ìlú Marneuli yìí kan náà làwọn èèyànkéèyàn ti gbéjà ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n sì hùwà ìkà sí wọn nígbà kan rí.
Ọ̀kan lára àwọn ìwà ìkà tá à ń wí yìí wáyé ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù September ọdún 2000. Àwọn ọlọ́pàá láti ìlú Marneuli gbé àwọn nǹkan dábùú ojú ọ̀nà láti dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dúró kí wọ́n má bàa dé ibi àpéjọ wọn. Ẹ̀yìn ìyẹn làwọn bọ́ọ̀sì kan kó àwọn adàlúrú dé. Ẹni tó ṣáájú wọn ni Vasili Mkalavishvili, ìyẹn àlùfáà kan tí wọ́n ti yọ nípò ní Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì. Wọ́n dá àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àtàwọn bọ́ọ̀sì tó ń lọ sí àpéjọ àgbègbè tí wọ́n ń ṣe ní Marneuli dúró, wọ́n wọ́ àwọn kan jáde kúrò nínú ọkọ̀, wọ́n sì nà wọ́n nínàkunà, wọ́n tún kó ohun ìní àwọn kan lọ, títí kan Bíbélì àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Àwọn èèyànkéèyàn tí wọ́n tó nǹkan bí ọgọ́ta tún ya bo ibi àpéjọ àgbègbè náà ní Marneuli. Wọ́n ṣe nǹkan bí ogójì Ẹlẹ́rìí Jèhófà léṣe. Wọ́n fọ̀bẹ gún arákùnrin kan láyà. Àwọn kan lára àwọn èèyànkéèyàn náà gbé ìbọn sókè, wọ́n sì ń fìbínú yìn ín sójú òfuurufú. Ọ̀kan lára wọn na ìbọn sí obìnrin tó ni ilẹ̀ ibi tí wọ́n ti ń ṣe àpéjọ náà, ó sì béèrè owó àtàwọn ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀. Àwọn èèyànkéèyàn náà tú gbogbo ilé rẹ̀, tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ ibi àpéjọ náà, wọ́n sì kó gbogbo ohun iyebíye tó ní lọ. Lẹ́yìn tí wọ́n ti fọ́ gbogbo wíńdò ilé náà, wọ́n sun gbogbo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ìjókòó táwọn ará ti ṣe fún àpéjọ náà. Ìwọ̀n ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọn sun náà wúwo tó àpò sìmẹ́ǹtì márùndínlọ́gọ́rin [75]. Kàkà káwọn ọlọ́pàá paná ìwà ipá náà, ńṣe làwọn ọlọ́pàá tó wà níbẹ̀ lọ́wọ́ sí ìkà tí wọ́n ń ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà.a
Ohun méjì ló dojú kọ Ìgbìmọ̀ Àpéjọ Àgbègbè náà. Ó ṣeé ṣe káwọn kan wá gbéjà kò wọ́n, wọ́n sì tún ní láti bójú tó bí àyè tó ń gba ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ [2,500] èèyàn ṣe máa wá gba ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] èèyàn. Báwo ni wọ́n ṣe máa yanjú ìṣòro náà láàárín àkókò kúkúrú yìí? Bí iṣẹ́ ìyanu ló rí nígbà táwọn tó ni ilẹ̀ méjì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi àpéjọ náà wá bá àwọn ìgbìmọ̀ àpéjọ náà pé àwọ́n á fi ilẹ̀ oko àwọn háyà fún wọn.
Ṣíṣe àtúnṣe àwọn ilẹ̀ náà kí wọ́n lè dibi tó máa ṣeé lò fún àpéjọ àgbègbè kì í ṣe iṣẹ́ kékeré o. Ojú ọjọ́ kò jẹ́ kí nǹkan rọrùn rárá, odindi ọ̀sẹ̀ kan tó ṣáájú àpéjọ náà lòjò fi ń rọ̀. Ànàmọ́ ni wọ́n gbìn sórí ilẹ̀ méjèèjì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tí wọ́n ti máa ṣe àpéjọ náà, wọ́n sì ní láti kórè àwọn ànàmọ́ náà. Ohun tó kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ ni pé inú òjò tó ń rọ̀ lọ́wọ́ làwọn tó yọ̀ǹda ara wọn náà ti ń hú àwọn ànàmọ́ náà jáde. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbé ohun tí wọ́n fi ṣe ọ̀gbà yí ilẹ̀ náà ká kúrò, wọ́n sì ta ìbòrí síbẹ̀ kí oòrùn àti òjò má bàa pa àwọn èèyàn. Wọ́n nílò àwọn ìjókòó onígi púpọ̀ sí i, wọ́n sì tún gbé àwọn ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ púpọ̀ sí i síbi àpéjọ náà. Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ náà ń ṣiṣẹ́ tọ̀sán tòru, kódà àwọn kan lára wọn kì í sùn mọ́jú, bí wọ́n ti ń lagi, ni wọ́n ń kan ìṣó mọ́gi, tí wọ́n sì ń ṣe orísíríṣi iṣẹ́ téèyàn máa ń figi ṣe.
Gbogbo èèyàn ló ń béèrè pé, “Bí òjò bá ń rọ̀ nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ bá ń lọ lọ́wọ́ ńkọ́? Ṣé àwọn tó wà ní àpéjọ náà kò ní rì sínú ẹrẹ̀?” Wọ́n lọ wá pòròpórò ọkà, wọ́n sì dà á sí ilẹ̀ ẹrọ̀fọ̀ náà. Nígbà tó yá, oòrùn yọ! Gbogbo ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àpéjọ náà ni oòrùn fi ràn tí ilẹ̀ sì gbẹ́ fúrúfúrú.
Nígbà táwọn tó wá ṣe àpéjọ náà dé, àyíká ẹlẹ́wà ni wọ́n bá níbẹ̀. Ìrísí àyíká náà tòrò bíi ti ìgbèríko, ńṣe ló jọ bí ayé tuntun ṣe máa rí. Ara tu àwọn tó wá ní àpéjọ náà lórí ìjókòó wọn, kódà àwọn igi ọ̀pọ̀tọ́ àtàwọn igi mìíràn tún wà láyìíká wọn. Oko àgbàdo àti tòmátì sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Àwọn igi àjàrà ló ṣe ẹ̀yìn pèpéle ìsọ̀rọ̀ náà lọ́ṣọ̀ọ́. Bí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ti ń lọ́ lọ́wọ́ làwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ń gbọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan báwọn àkùkọ adìyẹ ti ń kọ àti báwọn abo adìyẹ ṣe ń dún bí wọ́n ti ń kó ẹyin wọn jọ. Àwọn ariwo mìíràn tún wà láyìíká àmọ́ ńṣe ni wọ́n dà bí orin tó rọra ń dún lábẹ́lẹ̀. Kàkà kí nǹkan wọ̀nyí dí wọn lọ́wọ́, wọn ò tiẹ̀ fiyè sí i, ńṣe ni wọ́n tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ sáwọn ọ̀rọ̀ tó dáa gan-an tá a gbé karí Bíbélì yìí. Síbẹ̀, àwọn ohun mánigbàgbé mìíràn tún wáyé ní àpéjọ àgbègbè náà.
Nǹkan Ìyanu Kejì
Ní ìparí àpéjọ àárọ̀ ọjọ́ Friday, ó ya àwọn tó ń ṣe àpéjọ náà lẹ́nu gan-an nígbà tí arákùnrin Geoffrey Jackson, tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kéde pé á mú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Georgian.b Omijé ayọ̀ lé sójú ọ̀pọ̀ àwọn ará, nítorí pé ohun ìyanu ló jẹ́. Ìdílé kan sọ̀rọ̀ tìdùnnú-tìdùnnú, wọ́n ní: “A ò ní yéé dúpẹ́ nítorí ohun ìyanu tó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà yìí. Ẹ wo iṣẹ́ bàǹtàbanta tí wọ́n ṣe láàárín àkókò kúkúrú!”
Arábìnrin kan láti ìlú Tsalendjikha tó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà látorí tẹlifóònù sọ pé: “Mi ò lè sọ bí ayọ̀ mi ti pọ̀ tó nígbà tí mo gba Bíbélì náà. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún àpéjọ ọlọ́jọ́ mẹ́ta tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí. Àpéjọ mánigbàgbé ni lóòótọ́.” Ìdílé kan ní ìjọ tó wà ní ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Georgia, tó wà ní ààlà Òkun Dúdú sọ pé: “Láti ìgbà yìí wá, Bíbélì kan ṣoṣo la ní nínú ìdílé wa, àmọ́ nísinsìnyí, àwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ni ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Ní báyìí, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”
Síbẹ̀ náà, àwọn nǹkan kan wà tí kò lọ geere bí kò tilẹ̀ hán sáwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n tẹ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí wọ́n sì kó o wá sí orílẹ̀-èdè Georgia kí àpéjọ àgbègbè náà tó bẹ̀rẹ̀, àwọn aláṣẹ Ibodè kọ̀ jálẹ̀ pé àwọn ò ní jẹ́ kí wọ́n kó Bíbélì náà wọlé. Àwọn arákùnrin náà ké gbàjarè lọ sọ́dọ̀ Ilé Iṣẹ́ Agbọ̀ràndùn. Agbọ̀ràndùn náà ṣèrànwọ́, ó sì mú káwọn aláṣẹ Ibodè jẹ́ kí wọ́n kó Bíbélì náà wọlé, bí àpéjọ àgbègbè náà ṣe fẹ́ bẹ̀rẹ̀ gẹ́ẹ́ ni Bíbélì náà dé. Ó tiẹ̀ tún rán igbákejì rẹ lọ sí àpéjọ ti ìlú Marneuli láti gba àwọn ẹ̀dà Bíbélì tuntun náà wá fún ilé iṣẹ́ wọn.
Àwọn Ará Georgia Máa Ń Fọ̀yàyà Kíni
Ìdí mìíràn tún wà tí àpéjọ àgbègbè tí wọ́n ṣe nílùú Marneuli fi jẹ́ àpéjọ àrà ọ̀tọ̀ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Georgia. Ìdí náà ni pé ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà lára àwọn tó sọ̀rọ̀ níbẹ̀. Inú gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ dùn gan-an débi pé wọ́n fẹ́ fọ̀yàyà kí arákùnrin náà lọ́nà táwọn ará ibẹ̀ gbà ń kí àlejò. Arákùnrin Jackson ní láti dúró láti máa kí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin fún wákàtí mélòó kan, ìyẹn ṣáájú kí àpéjọ tó bẹ̀rẹ̀, nígbà àpéjọ àti lẹ́yìn tí àpéjọ parí, síbẹ̀ inú rẹ̀ dún láti kí wọn.
Nígbà yẹn lọ́hùn-un lọ́dún 1903 tí àpéjọ àgbègbè kan fẹ́ parí ní Atlanta, ní ìpínlẹ̀ Georgia lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, arákùnrin kan sọ pé: “Bí wọ́n bá tiẹ̀ fún mi ní ẹgbẹ̀rún [1000] dọ́là pé kí n fi rọ́pò gbogbo ohun rere tí mo ti rí gbà ní àpéjọ àgbègbè yìí, mi ò ní gbà á bó tilẹ̀ jẹ́ pé tálákà ni mi.” Ọgọ́rùn-ún ọdún tí kọjá lẹ́yìn ìyẹn, síbẹ̀, èrò kan náà yẹn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ṣe àwọn àpéjọ àgbègbè mánigbàgbé lórílẹ̀-èdè Georgia nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 2006 ní.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá ń fẹ́ mọ̀ sí i nípa inúnibíni tí wọ́n ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Georgia, wo ìwé ìròyìn Jí! ti January 22, 2002, ojú ìwé 18 sí 24 (Lédè Gẹ̀ẹ́sì).
b Wọ́n tẹ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun jáde lédè Georgian lọ́dún 2004.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]
“Ẹni Tí Ó Kéré” Ti Di Púpọ̀
Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Aísáyà 60:22, tó sọ pé: “Ẹni tí ó kéré yóò di ẹgbẹ̀rún, ẹni kékeré yóò sì di alágbára ńlá orílẹ̀-èdè. Èmi tìkára mi, Jèhófà, yóò mú un yára kánkán ní àkókò rẹ̀” ti nímùúṣẹ lórílẹ̀-èdè Georgia. Láàárín ogún ọdún péré, iye àwọn tó ń kéde Ìjọba Ọlọ́run lórílẹ̀-èdè Georgia ti pọ̀ gan-an, látorí ohun tó dín lọ́gọ́rùn-ún sí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún [16,000]. Àwọn òjíṣẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọ̀nyí sì ń fi tọkàntara kọ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ [8,000] èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, tó fi hàn pé àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run yóò túbọ̀ pọ̀ sí i lórílẹ̀-èdè Georgia.
[Àwòrán/Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 16]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ILẸ̀ RỌ́ṢÍÀ
GEORGIA
⇨ Zugdidi
⇨ Kutaisi
Marneuli ⇨ Gori
⇨ Kaspi
⇨ Tsnori
TBILISI
TURKEY
ARMENIA
AZERBAIJAN
[Credit Line]
Globe: Based on NASA/Visible Earth imagery
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ère kan ní Tbilisi
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Orí ẹ̀rọ tẹlifóònù làwọn tó wà níbi márùn-ún yòókù nílẹ̀ Georgia ti ń tẹ́tí sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ tí wọ́n ṣe nílùú Marneuli
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ó ya gbogbo àwọn tó wá sí àpéjọ àgbègbè náà lẹ́nu gan-an nígbà tí Bíbélì “Ìtumọ̀ Ayé Tuntun” jáde lédè Georgian, inú wọn sì dùn jọjọ