JỌ́JÍÀ
Ọkọ Mi Ò Ṣíwọ́ Kíka Bíbélì!
Marina Kopaliani
WỌ́N BÍ I NÍ 1957
Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1990
ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Marina àti Badri ọkọ rẹ̀ di akéde onítara bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọmọkùnrin méjì ni wọ́n ń tọ́ lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, Badri di ọ̀kan nínú Ìgbìmọ̀ Orílẹ̀-èdè, ó sì jẹ́ olóòótọ́ títí ó fi kú lọ́dún 2010.
LỌ́DÚN 1989, èmi àti ọkọ mi bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé lọ́dọ̀ aládùúgbò wa kan. Arákùnrin Givi Barnadze ló ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ òun fúnra rẹ̀ ò ní Bíbélì, torí kò rọrùn láti rí Bíbélì ní Jọ́jíà lákòókò yẹn.
Ohun tá a gbọ́ múnú wa dùn, a sì pinnu láti ni Bíbélì. Nígbà tí ọkọ mi rí ọmọ ìyá rẹ̀ ọkùnrin, ó sọ fún un pé òun ń wá Bíbélì. Ó yà á lẹ́nu nígbà tí ọmọ ìyá ẹ̀ yìí sọ fún un pé òun ṣẹ̀ṣẹ̀ ra Bíbélì kan lédè Jọ́jíà ni àti pé á wu òun láti fi ṣe ẹ̀bùn fún un.
Nígbà tí Badri délé, ó jókòó sídìí tábìlì, ó sì ń ka Bíbélì náà títí ilẹ̀ fi ṣú. Nígbà tó jí láàárọ̀ ọjọ́ kejì, ṣe ló tún gbé e tó ń kà á. Tí mo fi dé láti ibi iṣẹ́, ìdí tábìlì ni mo bá a tó ń ka Bíbélì. Kò ṣíwọ́ nídìí ẹ̀! Mo wá ní kó gbàyè ọjọ́ díẹ̀ níbi iṣẹ́ kó lè kà á parí. Kò pẹ́ tó fi ka gbogbo Bíbélì látòkè délẹ̀.
Nígbà tí Arákùnrin Barnadze wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìwé Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, inú wa ń dùn pé a ní Bíbélì tiwa. Rẹ́gí ló ṣe torí a ò ní ìwé Òtítọ́ tiwa, ẹni tó ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ náà ò sì ní Bíbélì! Nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà ni èmi àti Badri ṣèrìbọmi.